Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ọlọrun ha ṣojúsàájú ní yíyan àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní ipò àtilẹ̀wá kan náà níti ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè fún ẹgbẹ́ olùṣàkóso ìjímìjí—níwọ̀n bí gbogbo wọn ti jẹ́ Júù bí?
Bẹ́ẹ̀kọ́, dájúdájú òun kò ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn wọnnì tí Jesu kọ́kọ́ pè gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́ Júù. Lẹ́yìn náà, ní Pentekosti 33 C.E., àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù ni a kọ́kọ́ fi ẹ̀mí mímọ́ yàn tí wọ́n sì tipa báyìí tóótun láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. Kìkì lẹ́yìn náà ni a tó fi àwọn ará Samaria àti Kèfèrí aláìkọlà kún un. Nítorí náà, ó jẹ́ ohun tí a lè lóye pé ẹgbẹ́ olùṣàkóso náà ní àkókò yẹn jẹ́ kìkì àwọn Júù, “awọn aposteli ati awọn àgbààgbà” ní Jerusalemu, gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nubà á ní Ìṣe 15:2. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní ìmọ̀ tí ó jinlẹ̀ nípa Ìwé Mímọ́ àti ìrírí ọ̀pọ̀ ọdún nínú ìjọsìn tòótọ́, wọ́n sì ti ní àkókò púpọ̀ síi láti dàgbà di àwọn alàgbà Kristian tí ó dàgbàdénú.—Fiwé Romu 3:1, 2.
Nígbà tí yóò fi di ìgbà ìpàdé ẹgbẹ́ olùṣàkóso náà tí a kọ sílẹ̀ nínú Ìṣe orí 15, ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí ni ó ti di Kristian. Èyí ní nínú àwọn ará Africa, Europe, àti àwọn ènìyàn láti àwọn ẹkùn mìíràn. Síbẹ̀, kò sí àkọsílẹ̀ kankan pé, èyíkéyìí nínú irú àwọn Kèfèrí bẹ́ẹ̀ ni a fi kún ẹgbẹ́ olùṣàkóso náà láti mú kí ìsìn Kristian fa àwọn tí kì í ṣe Júù mọ́ra. Níwọ̀n bí àwọn Kèfèrí tí wọ́n jẹ́ Kristian tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn padà wọ̀nyí ti jẹ́ mẹ́ḿbá onípò kan náà nínú “Israeli Ọlọrun,” wọn yóò ti bọ̀wọ̀ fún ìdàgbàdénú àti ìrírí púpọ̀ síi tí àwọn Kristian tí wọ́n jẹ́ Júù, irú bí àwọn aposteli, tí wọ́n jẹ́ apákan ẹgbẹ́ olùṣàkóso nígbà náà lọ́hùn-ún ní jù wọ́n lọ. (Galatia 6:16) Ṣàkíyèsí nínú Ìṣe 1:21, 22 bí a ṣe mọyì irú ìrírí bẹ́ẹ̀ tó.—Heberu 2:3; 2 Peteru 1:18; 1 Johannu 1:1-3.
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, Ọlọrun ti bá orílẹ̀-èdè Israeli lò lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀, láti inú èyí tí Jesu ti yan àwọn aposteli rẹ̀. Kì í ṣe àṣìṣe tàbí àìṣèdájọ́ òdodo pé kò sí aposteli kankan tí ó wá láti ibi tí a mọ́ nìsinsìnyí sí South America tàbí Africa tàbí Far East. Bí ó bá ya àwọn ọkùnrin àti obìnrin láti àwọn ibi wọ̀nyẹn yóò ní àǹfààní láti jàǹfààní tí ó tóbi lọ́la ju ti jíjẹ́ aposteli lórí ilẹ̀-ayé, jíjẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ọ̀rúndún kìn-ínní, tàbí yíyàn wọ́n sípò èyíkéyìí láàárín àwọn ènìyàn Ọlọrun lónìí.—Galatia 3:27-29.
A sún aposteli kan láti sọ pé: “Ọlọrun kì í ṣe ojúsàájú, ṣugbọn ní gbogbo orílẹ̀-èdè ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Bẹ́ẹ̀ni, àǹfààní ìràpadà Kristi wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún gbogbo wa, láìsí ojúsàájú. Ẹnì kọ̀ọ̀kan láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè ni a óò sì fi kún Ìjọba ti ọ̀run àti ogunlọ́gọ̀ ńlá tí yóò wàláàyè títí láé lórí ilẹ̀-ayé.
Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀dá ènìyàn máa ń tètè fi ìmọ̀lára wọn hàn sí ipò àtilẹ̀wá ti ẹ̀yà-ìran, èdè, tàbí ti orílẹ̀-èdè. Èyí ni a ṣàpèjúwe pẹ̀lú ohun tí a kà ní Ìṣe 6:1 nípa àríyànjiyàn kan tí ó fa kíkùn láàárín àwọn Kristian tí ń sọ èdè Griki àti àwọn wọnnì tí ń sọ èdè Heberu. A lè ti tọ́ wa dàgbà tàbí kí a ti rì sínú títètè fi ìmọ̀lára wa hàn sí ipò àtilẹ̀wá ti èdè, ẹ̀yà-ìran, ẹ̀yà-èdè, tàbí ẹ̀yà akọ tàbí abo. Lójú ìwòye ṣíṣeéṣe náà níti tòótọ́ gan-an, yóò dára láti lo ìsapá àfìpinnuṣe láti gba ojú-ìwòye Ọlọrun láyè láti ní agbára ìdarí lórí ìmọ̀lára àti ìhùwàpadà wa, èyí tí ó jẹ́ pé lójú rẹ̀ bákan náà ni gbogbo ẹ̀dá ènìyàn rí, láìka bí ìrísí òde wa ṣe lè rí. Nígbà tí Ọlọrun ti mú kí a ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí a ń béèrè fún lọ́wọ́ àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́, kò mẹnu kan ipò àtilẹ̀wá ti ẹ̀yà-ìran àti ti orílẹ̀-èdè. Rárá, ó darí àfiyèsí sí ohun tẹ̀mí tí a béèrè fún lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n lè wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣiṣẹ́sìn. Ìyẹn jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn alàgbà àdúgbò, alábòójútó arìnrìn-àjò, àti àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹ̀ka lónìí, gẹ́gẹ́ bí o tí jẹ́ òtítọ́ nípa ti ẹgbẹ́ olùṣàkóso ní ọ̀rúndún kìn-ínní.