Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Johannu Kìn-ínní 4:18 sọ fún wa pé: “Kò sí ìbẹ̀rù ninu ìfẹ́, ṣugbọn ìfẹ́ pípé a máa ju ìbẹ̀rù sóde.” Ṣùgbọ́n Peteru kọ̀wé pé: “Ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ awọn ará, ẹ máa bẹ̀rù Ọlọrun.” (1 Peteru 2:17) Báwo ni a ṣe lè mú àwọn ẹsẹ̀ méjèèjì wọ̀nyí báramu?
Peteru àti Johannu jẹ́ aposteli tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ ní tààràtà láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi fúnra rẹ̀. Nípa báyìí ọkàn wa lè balẹ̀ pé ohun tí wọ́n kọ báramu. Nípa àwọn ẹsẹ̀ tí a fàyọ lókè, kọ́kọ́rọ́ náà ni pé àwọn aposteli méjèèjì ń sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀rù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ gbé ìmọ̀ràn Peteru yẹ̀wò. Gẹ́gẹ́ bí àyíká ọ̀rọ̀ náà ti fi hàn, Peteru ń fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àmọ̀ràn tí a mí sí nípa ìṣarasíhùwà wọn sí àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ipò ọlá-àṣẹ. Ní èdè mìíràn, ó ń sọ̀rọ̀ àkíyèsí nípa ojú-ìwòye tí ó tọ́ nípa ìtẹríba ní àwọn ọ̀nà kan. Nípa báyìí, ó fún àwọn Kristian ní àmọ̀ràn láti tẹríba fún àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà ní ipò ọlá-àṣẹ nínú ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn, irú bí àwọn ọba tàbí gómìnà. (1 Peteru 2:13, 14) Ní bíbá a nìṣó, Peteru kọ̀wé pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ awọn ará, ẹ máa bẹ̀rù Ọlọrun, ẹ máa fi ọlá fún ọba.”—1 Peteru 2:17.
Ní ṣíṣàyẹ̀wò àyíká ọ̀rọ̀, ó hàn gbangba pé nígbà tí Peteru sọ pé àwọn Kristian níláti “máa bẹ̀rù Ọlọrun,” ohun tí ó ní lọ́kàn ni pé a níláti ní ọ̀wọ̀ ńlá, tí ó jinlẹ̀ fún Ọlọrun, ìbẹ̀rù láti máṣe mú aláṣẹ tí ó ga jùlọ bínú.—Fiwé Heberu 11:7.
Kí ni nípa ti ọ̀rọ̀ àkíyèsí ti aposteli Johannu? Ṣáájú nínú 1 Johannu orí 4, aposteli náà sọ̀rọ̀ nípa yíyẹ tí ó yẹ láti dán “àgbéjáde onímìísí” wò irú bí èyí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì èké. Dájúdájú àwọn àgbéjáde wọ̀nyẹn kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun; wọ́n wá tàbí wọ́n ṣàgbéyọ ayé búburú.
Ní òdìkejì, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró “pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.” (1 Johannu 4:1-6) Nítorí ìyẹn rí bẹ́ẹ̀, Johannu rọ̀ wá pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nìkínní kejì, nitori pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìfẹ́ ti wá.” Ọlọrun lo àtinúdá nínú lílo ìfẹ́—ó “rán Ọmọkùnrin rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Johannu 4:7-10) Báwo ni a ṣe níláti dáhùnpadà?
Ní kedere, a níláti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọrun wa onífẹ̀ẹ́. A kò níláti páyà rẹ̀ tàbí kí a máa gbọ̀n nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn títọ̀ ọ́ lọ nínú àdúrà. Ṣáájú Johannu gbaninímọ̀ràn pé: “Bí ọkàn-àyà wa kò bá dá wa lẹ́bi, awa ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ sọ́dọ̀ Ọlọrun; ohun yòówù tí a bá sì béèrè ni a ń rí gbà lati ọ̀dọ̀ rẹ̀, nitori a ń pa awọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Johannu 3:21, 22) Bẹ́ẹ̀ni, ẹ̀rí-ọkàn tí ó dára ń fún wa ní òmìnira láti tọ Ọlọrun lọ láìsí ìbẹ̀rù tí ń sọni di aláìlágbára tàbí tí ń múni sá fún un. Nítorí ìfẹ́, a kì í lọ́tìkọ̀ láti sọ̀rọ̀, tàbí tọ Jehofa lọ nínú àdúrà. Lọ́nà yìí, “kò sí ìbẹ̀rù ninu ìfẹ́.”
Nígbà náà ẹ jẹ́ kí a mú àwọn èrò méjèèjì papọ̀. Kristian kan gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Jehofa, tí ó wá láti inú ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ̀ fún ipò, agbára, àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀. Ṣùgbọ́n a tún nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí Bàbá wa a sì ń nímọ̀lára wíwà tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ àti òmìnira láti tọ̀ ọ́ lọ. Kàkà kí ìbẹ̀rù rẹ̀ mú wa sá fún un, a ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a lè tọ̀ ọ́ lọ, bí ọmọ kan ṣe lómìnira láti tọ àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ lọ.—Jakọbu 4:8.