ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/1 ojú ìwé 5-7
  • Ojú Ọ̀nà Tóóró Sí Òmìnira

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ojú Ọ̀nà Tóóró Sí Òmìnira
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ọ̀nà Tóóró náà Ṣe Ń Túni Sílẹ̀
  • A Mú Ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun Dá Wa Lójú
  • Wọn Ṣíwọ́ Rírìn Ní Ojú Ọ̀nà Fífẹ̀ Náà
  • Ojú Ọ̀nà Gbayawu Tí Ó Ní Òmìnira Kékeré
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ṣé Gbogbo Ìsìn ni Ìsìn Tòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ẹ Máa ‘Fetí sí Jésù’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Jẹ́ Kí Jèhófà Ṣamọ̀nà Rẹ Síbi Tí Ojúlówó Òmìnira Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/1 ojú ìwé 5-7

Ojú Ọ̀nà Tóóró Sí Òmìnira

ÀWỌN olóye ènìyàn díẹ̀ kò gbà pé àgbáyé ni àwọn òfin àdánidá ń ṣàkóso. Àwọn òfin wọ̀nyí ń darí ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn átọ́ọ̀mù bín-ín-tín dé orí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ńláńlá tí ó ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ni, kì bá tí sí ìṣètò kankan kì bá sì tí sí òye; ìgbésí ayé fúnra rẹ̀ kì bá tí wà. Nípa lílóye àwọn òfin àdánidá àti ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn, ó ti ṣeé ṣe fún ènìyàn láti ṣe ohun yíyanilẹ́nu, irú bí rírìn lórí òṣùpá àti fífi àwọn àwòrán aláwọ̀ mèremère ránṣẹ́ láti ibikíbi lórí ilẹ̀ ayé tàbí láti ibi tí ó ré kọjá àyíká ilẹ̀ ayé pàápàá sí orí awò tẹlifíṣọ̀n ní àwọn ilé wa.

Ṣùgbọ́n kí ni nípa àwọn òfin ìwà híhù? Fífara mọ́ wọn ha ń ṣàǹfààní bákan náà tí ó sì ń mú èso wá bí? Ó dàbí ẹni pé ọ̀pọ̀ ń ronú pé kò sí àwọn òfin ìwà híhù rárá tí wọ́n sì yan ọgbọ́n èrò-orí tí ó gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí ìsìn tí ó bá ìfẹ́-ọkàn wọn mu.

Bí ó ti wu kí ó rí, àwọn kan wà tí wọ́n yan ọ̀nà mìíràn, ‘ọ̀nà tóóró tí ó lọ sí ìyè’ gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án nínú Bibeli. Kò níláti yà wá lẹ́nu pé kìkì àwọn kéréje ni ó yan èyí, nítorí Jesu sọ nípa ọ̀nà tóóró náà pé: “Ìwọ̀nba díẹ̀ sì ni awọn ẹni tí ń rí i.” (Matteu 7:14) Èé ṣe tí ó fi jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀?

Nítorí ọ̀nà tóóró náà ni àwọn òfin àti àwọn ìlànà Ọlọrun pààlà sí. Kìkì ẹnì kan tí ó bá fi tọkàntọkàn ní ìfẹ́-ọkàn láti mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun mu ni yóò fà mọ́ra. Ní ìyàtọ̀ gédégbé sí ojú ọ̀nà fífẹ̀ náà, èyí tí ń fúnni ní òmìnira tí ń ṣini lọ́nà ṣùgbọ́n ní ti gidi tí ń fini sínú oko-ẹrú, ojú ọ̀nà tóóró náà, tí ó dàbí èyí tí ń káni lọ́wọ́ kò, ń tú ènìyàn sílẹ̀ lómìnira ní gbogbo ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì. Àwọn ààlà rẹ̀ ni a gbé kalẹ̀ nípa “òfin pípé naa tí í ṣe ti òmìnira.”—Jakọbu 1:25.

Bí Ọ̀nà Tóóró náà Ṣe Ń Túni Sílẹ̀

Lóòótọ́, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti dúró sí ojú ọ̀nà tóóró náà. Gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tí ó wà láàyè jẹ́ aláìpé wọ́n sì ní ìtẹ̀sí àjogúnbá sí ohun tí ó burú. Nítorí náà, ẹnì kan lè ní ìtẹ̀sí láti ṣako lọ díẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn àǹfààní fífara mọ́ ‘ojú ọ̀nà híhá’ yẹ fún ìbára-ẹni-wí tàbí àtúnṣe èyíkéyìí tí a nílò, nítorí Ọlọrun ‘ń kọ́ wa láti lè ṣe ara wa láǹfààní.’—Isaiah 48:17, NW; Romu 3:23.

Láti ṣàkàwé: Àwọn òbí ọlọgbọ́n ṣètò ‘ọ̀nà híhá’ ìdíwọ̀n oúnjẹ fún àwọn ọmọ wọn. Nígbà mìíràn èyí máa ń béèrè ṣíṣàìgba gbẹ̀rẹ́ nígbà oúnjẹ. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ náà bá dàgbà sí i, wọn yóò mọrírì ìbáwí onífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn. Gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà, wọn yóò ti mú ìgbádùn fún oúnjẹ afúnninílera dàgbà. Oríṣiríṣi oúnjẹ afáralókun tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó yóò sì fagi lé níní ìmọ̀lára ìkálọ́wọ́kò.

Ní ọ̀nà tẹ̀mí, Ọlọrun ń ṣe ohun kan náà fún àwọn tí wọ́n wà ní ojú ọ̀nà tóóró tí ó lọ sí ìyè. Ó ń mú ìfẹ́-ọkàn tí ó gbámúṣé tí ń yọrí sí ayọ̀ àti òmìnira tòótọ́ dàgbà nínú àwọn onínú tútù. Èyí ni ó ń ṣe nípa pípèsè Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Ní àfikún sí i, ó ké sí wa láti gbàdúrà fún ẹ̀mí rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́, ó sì pàṣẹ fún wa láti kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lè fún wa ní ìṣírí láti dúró sí ọ̀nà tóóró náà. (Heberu 10:24, 25) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́, ànímọ́ rẹ̀ tí ó ga jù lọ yìí jẹ́ ìpìlẹ̀ àwọn góńgó ìlépa rẹ̀ àti ọ̀nà ìgbàṣe rẹ̀.—1 Johannu 4:8.

Nígbà tí ìfẹ́, àlàáfíà, ìwàrere, ìkóra-ẹni-níjàánu, àti àwọn èso ẹ̀mí mìíràn ti Ọlọrun bá gbilẹ̀, ojú ọ̀nà tóóró náà kò dàbí ohun tí ó káni lọ́wọ́ kò. Gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti sọ, “kò sí òfin kankan lòdì sí irúfẹ́ awọn nǹkan báwọ̀nyí.” (Galatia 5:22‚ 23) “Níbi tí ẹ̀mí Jehofa bá . . . wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” (2 Korinti 3:17) Àní nísinsìnyí pàápàá, àwọn ojúlówó Kristian ń rí ìtọ́wò òmìnira yìí gbà. Wọ́n dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìbẹ̀rù tí ń jẹ àwọn ènìyàn níyà lónìí, irú bí ìbẹ̀rù ọjọ́ iwájú àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti ìbẹ̀rù ikú. Ẹ wo bí ó ti ru ìmọ̀lára sókè tó láti ronú nípa ọjọ́ iwájú nígbà tí “ayé yóò kún fún ìmọ̀ Oluwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo òkun”! (Isaiah 11:9) Nígbà náà, ìbẹ̀rù ìwà ọ̀daràn pàápàá kì yóò sí mọ́. Kọ́kọ́rọ́ àti àwọn irin ìdábùú kì yóò sí mọ́ títí láé. Gbogbo ènìyàn yóò nímọ̀lára òmìnira àti àìséwu—tọ̀sán-tòru, nílé àti lóde. Ìyẹn yóò jẹ́ òmìnira nítòótọ́!

A Mú Ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun Dá Wa Lójú

Lóòótọ́, gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun gba ìsapá, síbẹ̀ “awọn àṣẹ rẹ̀ kì í . . . ṣe ẹrù-ìnira,” àní fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé pàápàá. (1 Johannu 5:3) Bí a ti ń mú ara wa bá ọ̀nà tóóró náà mu tí a sì ń nímọ̀lára àwọn àǹfààní ti rírìn nínú rẹ̀, a ń mú ìkórìíra dàgbà fún àwọn ọ̀nà àti ìrònú tí ó jẹ́ ànímọ́ àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà fífẹ̀. (Orin Dafidi 97:10) Ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọrun ń fa ẹ̀rí-ọkàn tí Ọlọrun fi fún gbogbo wa mọ́ra. Dípò “ìbànújẹ́ ọkàn” àti “ìròbìnújẹ́ ọkàn” tí ó jẹ́ ànímọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, Ọlọrun ṣèlérí pé: “Kíyè sí i, àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin fún inúdídùn.” Bẹ́ẹ̀ ni, ọkàn-àyà tí Jehofa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ onídùnnú àti olómìnira.—Isaiah 65:14.

Jesu kú kí òmìnira tòótọ́ baà lè ṣeé ṣe fún wa. Bibeli sọ pé: “Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀ má baà parun ṣugbọn kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Johannu 3:16) Nísinsìnyí, gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọrun ti ọ̀run, Jesu ń fúnni ní àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà náà. Láìpẹ́, lẹ́yìn “ìpọ́njú ńlá naa,” nígbà tí ojú ọ̀nà fífẹ̀ náà àti àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ yóò wá sí ìparun wọn, òun yóò bẹ̀rẹ̀ sí í fi sùúrù tọ́ àwọn aráyé onígbọràn sọ́nà gba ọ̀nà tóóró tí ó ṣẹ́kù títí dé òpin rẹ̀, ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn. (Ìṣípayá 7:14-17; Matteu 24:21, 29-31) Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín a óò ní ìrírí ìmúṣẹ àwọn ìlérí kíkọyọyọ náà pé: “A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹlu sílẹ̀ lómìnira kúrò ninu ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́ yoo sì ní òmìnira ológo ti awọn ọmọ Ọlọrun.” Ohunkóhun kò lè ta òmìnira yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun yọ. Ikú pàápàá kì yóò sí mọ́.—Romu 8:21; Ìṣípayá 21:3, 4.

Nípa rírí ibi tí ojú ọ̀nà tóóró náà ń lọ àti lílóye rẹ̀ kedere, yóò túbọ̀ ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti yan ọ̀nà yìí kí ó sì máa báa lọ ní rínrìn nínú rẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ ní pàtàkì ni a ràn lọ́wọ́ láti má ṣe ní ojú ìwòye tí ó kúrú àti láti má ṣe ní ìmọ̀lára ìkórìíra nípa ohun tí wọ́n kà sí ìkálọ́wọ́kò tí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun gbé kalẹ̀. Wọ́n kọ́ láti rí ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìfẹ́ Ọlọrun àti gẹ́gẹ́ bí odi lòdì sí àwọn ibi tí ó wà ní ojú ọ̀nà fífẹ̀ náà. (Heberu 12:5, 6) Àmọ́ ṣáá o, ẹnì kan níláti ní sùúrù, ní rírántí pé ó ń gba àkókò láti mú àwọn ànímọ́ àti ìfẹ́-ọkàn lọ́nà ti Ọlọrun dàgbà, gan-an bí ó ṣe ń gba àkókò fún igi eléso láti mú èso tí ó dára jáde. Ṣùgbọ́n igi náà yóò mú èso jáde bí a bá ro oko mọ́ ọn tí a sì bu omi rin-ín.

Nítorí náà kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristian yòókù, kí o sì “gbàdúrà láìdábọ̀” fún ẹ̀mí mímọ́. (1 Tessalonika 5:17) Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọrun láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti “tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.” (Owe 3:5, 6) Ṣùgbọ́n gbogbo èyí ha ṣeé mú lò bí? Ó ha gbéṣẹ́ ní ti gidi bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó gbéṣẹ́ fún Tom gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún Mary, tí a mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú.

Wọn Ṣíwọ́ Rírìn Ní Ojú Ọ̀nà Fífẹ̀ Náà

Tom kọ̀wé pé: “Ní àárín àwọn ọdún 1970, a bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pàdé nígbà tí ọ̀kan lára wọn kàn sí ilé wa. Ìjíròrò náà yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í tún ìgbésí ayé mi ṣe. Mo ṣe batisí ní 1982 mo sì ń ṣiṣẹ́ sìn ní ijọ àdúgbò nísinsìnyí. Ọmọkùnrin wa pẹ̀lú tí ṣe batisí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó mi fún níní ìpamọ́ra ní gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí ṣáájú kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Kristi Jesu, fún gbogbo ohun tí wọ́n fún wa àti fún ìrètí tí a ní nísinsìnyí fún ọjọ́ iwájú.”

Kí sì ni nípa Mary? Tóò, ó lérò pé Ọlọrun kì yóò dáríji òun, ṣùgbọ́n ó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nítorí ti àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà tí ó gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń kọ́ aládùúgbò rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nínú Bibeli, òun pẹ̀lú béèrè fún ìrànlọ́wọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwà búburú rẹ̀ tí ó ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù mú kí ìtẹ̀síwájú ṣòro. Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ń lọ sókè sódò. Bí ó ti wù kí ó rí, ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ọlọ́dún méje, fún un ní ìṣírí. Yóò sọ pé: “Màmá, ẹ má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Ẹ lè ṣe é!” Nígbà náà ni Mary yóò túbọ̀ múra.

Nígbà tí ọkọ tí ó fẹ́ ẹ níṣu-lọ́kà, tí òun pẹ̀lú jẹ́ ajòògùnyó, darí dé ilé, òun náà dara pọ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ àwọn méjèèjì borí àwọn àṣàkaṣà wọn. Nígbà náà, lẹ́yìn tí wọ́n ti forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin tí wọ́n sì jọ̀wọ́ ara wọn fún ìbatisí, wọ́n ní ìrírí ayọ̀ ńláǹlà, wọn sì nímọ̀lára gẹ́gẹ́ bí ìdílé gidi kan fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó bani nínú jẹ́ pé àrùn AIDS gba ẹ̀mí Mary níkẹyìn, ṣùgbọ́n ó kú pẹ̀lú ọkàn-àyà rẹ̀ tí ó tẹjú mọ́ ìlérí Bibeli nípa àjíǹde àti ìyè nínú paradise orí ilẹ̀ ayé, tí a tí fọ̀ mọ́ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ojú ọ̀nà fífẹ̀ náà tí ó burú-bògìrì.

Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe láti kúrò ní ojú ọ̀nà fífẹ̀ tí ó sì láyè gbígbòòrò tí ń lọ sí ìparun. Kristi Jesu sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo naa sínú, ati ti ẹni naa tí iwọ rán jáde, Jesu Kristi.” (Johannu 17:3) Èé ṣe nígbà náà, tí o kò fi pọkàn pọ̀ láti fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tóóró náà tí ó lọ sí ìyè? Nípa fífi àwọn ohun tí ó kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ́kàn kí o si fi í sílò, ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lè ní ìrírí ìlérí Bibeli tí ń mọ́kànyọ̀ náà pé: “Ẹ óò sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yoo sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Johannu 8:32.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́