ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/1 ojú ìwé 8-13
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Ní Ìlòdìsí Àwọn Ọlọrun Èké

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Ní Ìlòdìsí Àwọn Ọlọrun Èké
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Abrahamu Jẹ́rìí sí Òtítọ́
  • Orílẹ̀-Èdè Àwọn Ẹlẹ́rìí
  • Dídán Àwọn Ọlọrun Wò
  • “Ẹ̀yin Ni Ẹlẹ́rìí Mi”!
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
  • Àwọn Kristian Ẹlẹ́rìí Fún Ipò Ọba-aláṣẹ Àtọ̀runwá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ọlọ́run Tòótọ́ Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìdáǹdè
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
  • “Ẹ̀yin Ni Ẹlẹ́rìí Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/1 ojú ìwé 8-13

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ní Ìlòdìsí Àwọn Ọlọrun Èké

“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ni Oluwa wí, àti ìránṣẹ́ mi ti mo ti yàn.”—ISAIAH 43:10.

1. Ta ni Ọlọrun tòótọ́ náà, ní àwọn ọ̀nà wo ni ó sì fi ga nípò ju ògìdìgbó ọlọrun tí a ń sìn lónìí?

TA NI Ọlọrun tòótọ́ náà? Lónìí, ìbéèrè tí ó ṣe pàtàkì jù lọ yìí dojú kọ gbogbo aráyé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn ń jọ́sìn ògìdìgbó ọlọrun, Ọ̀kan ṣoṣo ni ó lè fún wa ní ìyè kí ó sì fún wa ní ọjọ́-ọ̀la aláyọ̀. Ọ̀kan ṣoṣo ni a lè sọ nípa rẹ̀ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni awa ní ìwàláàyè tí a sì ń rìn tí a sì wà.” (Ìṣe 17:28) Ní tòótọ́, Ọlọrun kan ṣoṣo ni ó ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ ẹni-àájọ́sìn. Gẹ́gẹ́ bí ègbè orin ti òkè ọ̀run nínú ìwé Ìṣípayá ti sọ pé: “Jehofa, àní Ọlọrun wa, iwọ ni ó yẹ lati gba ògo ati ọlá ati agbára, nitori pé iwọ ni ó dá ohun gbogbo, ati nitori ìfẹ́-inú rẹ ni wọ́n ṣe wà tí a sì dá wọn.”—Ìṣípayá 4:11.

2, 3. (a) Báwo ni Satani ṣe fi irọ́ pe ẹ̀tọ́ Jehofa gẹ́gẹ́ bí ẹni-àájọ́sìn níjà? (b) Kí ni ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ Efa fùn Efa àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀ fún Satani?

2 Nínú ọgbà Edeni, Satani fi irọ́ pe ẹ̀tọ́ Jehofa láti jẹ ẹni-àájọ́sìn níjà. Ní lílo ejò kan, ó sọ fún Efa pé bí ó bá ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Jehofa tí ó sì jẹ láti inú igi tí Jehofa ti kà léèwọ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò dàbí Ọlọrun. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: “Ọlọrun mọ̀ pé, ni ọjọ́ tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, nígbà náà ni ojú yín yóò là, ẹ̀yin óò sì dàbí Ọlọrun, ẹ óò sì mọ rere àti búburú.” (Genesisi 3:5) Efa gba ejò náà gbọ́ ó sì jẹ èso tí a kà léèwọ̀ náà.

3 Àmọ́ ṣáá o, irọ́ ni Satani pa. (Johannu 8:44) Ọ̀nà kan ṣoṣo tí Efa gbà “dàbí Ọlọrun” nígbà tí ó dẹ́sẹ̀ ni pé ó sọ ọ́ di ẹru iṣẹ́ tìrẹ fúnra rẹ̀ láti pinnu ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ohun kan tí ó yẹ kí ó fi sílẹ̀ fún Jehofa. Láìsì ka irọ Satani sí, ó kú ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Nítorí náà, Satani nìkan ní olùjàǹfààní ní ti gidi nínú ẹ̀ṣẹ̀ Efa. Ní tòótọ́, góńgó tí Satani kò mẹ́nu kàn nínú yíyí Efa lérò padà láti dẹ́ṣẹ̀ ni kí òun fúnra rẹ̀ di ọlọrun. Nígbà tí Efa dẹ́ṣẹ̀, ó di ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ tí ó di ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kò pẹ́ kò jìnnà Adamu sì dara pọ̀ mọ́ ọn. Kì í ṣe pé a bí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ wọn “nínú ẹ̀ṣẹ̀” nìkan ní, ṣùgbọ́n wọ́n tún ṣubú sábẹ́ agbára ìdarí Satani, àti láìpẹ́, gbogbo ayé tí a sọ di àjèjì sí Ọlọrun tòótọ́ wá sí ojútáyé.—Genesisi 6:5; Orin Dafidi 51:5.

4. (a) Ta ni ọlọrun ayé yìí? (b) Kí ni àìní kánjúkánjú wà fún?

4 A pa ayé yẹn run nígbà Ìkún-Omi. (2 Peteru 3:6) Lẹ́yìn Ìkùn-Omi náà ayé kejì tí ó di àjèjì sí Jehofa rúyọ, ó sì wà síbẹ̀síbẹ̀. Bibeli sọ nípa rẹ̀ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” (1 Johannu 5:19) Nípa gbígbé ìgbésẹ̀ lòdì sí ẹ̀mí Jehofa àti àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì nínú òfin rẹ̀, ayé yìí ń mu góńgó Satani ṣẹ. Òun ni ọlọrun rẹ̀. (2 Korinti 4:4) Síbẹ̀, ọlọrun aláìlágbára ni òun jẹ́ ní ti gidi. Kò lè mú kí àwọn ènìyàn láyọ̀ tàbí kí ó fún wọn ní ìwàláàyè; Jehofa nìkan ni ó lè ṣe ìyẹn. Nítorí náà, àwọn ènìyàn tí ń fẹ́ ìgbésí-ayé tí ó nítumọ̀ àti ayé tí ó dara jù gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ pé Jehofa ni Ọlọrun tòótọ́, lẹ́yìn náà kí wọ́n sì kọ́ láti ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. (Orin Dafidi 37:18, 27, 28; Oniwasu 12:13) Nípa báyìí àìní kánjúkánjú kan ń bẹ fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ láti jẹ́rìí, tàbí láti pòkìkí òtítọ́, nípa Jehofa.

5. “Àwọsánmà awọn ẹlẹ́rìí” wo ni Paulu mẹ́nu kàn? Dárúkọ àwọn ènìyàn kan tí òun ṣàkọsílẹ̀ orúkọ wọn.

5 Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, irú àwọn olùṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ ti fara hàn lórí ilẹ̀ ayé. Aposteli Paulu, nínú Heberu orí 11, tò wọ́n gẹ̀ẹ̀rẹ̀gẹ̀, ó sì pè wọ́n ní “àwọsánmà awọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.” (Heberu 12:1) Ọmọkùnrin kejì tí Adamu àti Efa bí, Abeli, ni àkọ́kọ́ lórí àkọsílẹ̀ Paulu. A tún mẹ́nu kàn Enoku àti Noa láti àkókò tí ó ṣáájú Ìkún-Omi. (Heberu 11:4, 5, 7) Ayọríọlá ni Abrahamu, babańlá ìran àwọn Júù. Abrahamu, ẹni tí a pè ní “ọ̀rẹ́ Jehofa,” di babańlá Jesu, “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ati olóòótọ́.”—Jakọbu 2:23; Ìṣípayá 3:14.

Abrahamu Jẹ́rìí sí Òtítọ́

6, 7. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ìgbésí-ayé Abrahamu àti ìgbésẹ̀ rẹ̀ fi jẹ́ ẹ̀rí pé Jehofa ni Ọlọrun tòótọ́?

6 Báwo ni Abrahamu ṣe ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí? Nípa ìgbàgbọ́ lílágbára rẹ̀ nínú Jehofa àti ìgbọràn adúróṣinṣin rẹ̀ sí i. Nígbà tí a pàṣẹ fún un láti fi ìlú ńlá Uri sílẹ̀ kí ó sì lọ gbé ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ ni ilẹ̀ tí ó jìnnà réré, Abrahamu ṣègbọràn. (Genesisi 15:7; Ìṣe 7:2-4) Àwọn ẹ̀yà-ìran alárìnkiri yóò pa ìgbésí ayé alárìnkiri wọn tì lọ́pọ̀ ìgbà, tí wọn yóò sì fìdí kalẹ̀ fún ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ láàbò ní ìlú-ńlá. Nítorí náà, nígbà tí Abrahamu fi ìlú-ńlá náà sílẹ̀ láti lọ máa gbé nínú àgọ́, ó fi ẹ̀rí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ lílágbára nínú Jehofa Ọlọrun hàn. Ìgbọràn rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí fún àwọn tí ń kíyè sí i. Jehofa bùkún Abrahamu jìngbìnnì nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àgọ́ ni ó ń gbé, Abrahamu láásìkí nípa ti ara. Nígbà tí a kó Loti àti ìdílé rẹ̀ ni ìgbèkùn, Jehofa fún Abrahamu ní àṣeyọrí nínú ìlépa rẹ̀, débi pé ó ṣeé ṣe fún un láti dá wọn nídè. Aya Abrahamu bí ọmọkùnrin kan ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀, a mú ìlérí Jehofa pé Abrahamu yóò di bàbá fún irú-ọmọ kan dáni lójú. Nípasẹ̀ Abrahamu, àwọn ènìyàn rí i pé Jehofa jẹ́ Ọlọrun alààyè tí ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.—Genesisi 12:1-3; 14:14-16; 21:1-7.

7 Nígbà tí ó ń padà bọ̀ láti ibi tí ó ti lọ dá Loti nídè, Melkisedeki, ọba Salemu (tí a wá ń pè ní Jerusalemu lẹ́yìn náà) kí Abrahamu káàbọ̀, ní sísọ pé: “Ìbùkún ni fún Abramu, ti Ọlọrun ọ̀gá-ògo.” Ọba Sodomu pẹ̀lú pàdé rẹ̀ ó sì fẹ́ fún un ní ẹ̀bùn. Abrahamu kọ̀. Èé ṣe? Kò fẹ́ kí iyèméjì kankan wà nípa Orísun ìbùkún rẹ̀. Ó wí pé: “Mo ti gbé ọwọ́ mi sókè sí OLUWA, Ọlọrun ọ̀gá-ògo, tí ó ni ọ̀run àti ayé, pé, èmi kì yóò mú láti fínrín òwú títí dé okùn bàtà, àti pé, èmi kì yóò mú ohun kan tí í ṣe tìrẹ, kí ìwọ ó má baà wí pé, Mo sọ Abramu di ọlọ́rọ̀.” (Genesisi 14:17-24) Ẹ wo irú ẹlẹ́rìí àtàtà tí Abrahamu jẹ́!

Orílẹ̀-Èdè Àwọn Ẹlẹ́rìí

8. Báwo ni Mose ṣe fi ìgbàgbọ́ ńláǹlà hàn nínú Jehofa?

8 Mose, àtọmọdọ́mọ Abrahamu, pẹ̀lú fara hàn lórí àkọsílẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí tí Paulu kọ. Mose kọ ẹ̀yìn sí ọrọ̀ Egipti lẹ́yìn náà ni ó sì dojú kọ olùṣàkóso agbára ayé ńláǹlà yẹn tìgboyàtìgboyà láti baà lè ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Israeli sí òmìnira. Ibo ni ó ti rí ìgboyà náà? Láti inú ìgbàgbọ́ rẹ̀. Paulu sọ pé: “[Mose] ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni naa tí a kò lè rí.” (Heberu 11:27) Àwọn ọlọrun Egipti ṣeé rí, wọ́n ṣeé fọwọ́ kàn. Lónìí pàápàá, àwọn ère wọn ń mú orí àwọn ènìyàn wú. Ṣùgbọ́n Jehofa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè rí i, túbọ̀ jẹ́ ẹni gidi sí Mose ju gbogbo àwọn ọlọrun èké wọ̀nyẹn lọ. Mose kò ṣe iyèméjì pé Jehofa ń bẹ àti pé yóò san èrè fún àwọn olùjọsìn Rẹ̀. (Heberu 11:6) Mose di ẹlẹ́rìí tí ó tayọ lọ́lá.

9. Báwo ni orílẹ̀-èdè Israeli ṣe níláti ṣiṣẹ́ sin Jehofa?

9 Lẹ́yìn ṣíṣamọ̀nà àwọn ọmọ Israeli sí òmìnira, Mose di alárinà màjẹ̀mú kan láàárín Jehofa àti àwọn àtọmọdọ́mọ Abrahamu nípasẹ̀ Jekọbu. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, orílẹ̀-èdè Israeli wá sí ojútáyé gẹ́gẹ́ bí àkànṣe ohun-ìní Jehofa. (Eksodu 19:5, 6) Fún ìgbà àkọ́kọ́, ẹ̀rí ti orílẹ̀-èdè ni a níláti pèsè. Àwọn ọ̀rọ̀ Jehofa nípasẹ̀ Isaiah, ní nǹkan bí 800 ọdún lẹ́yìn náà, ṣeé fi sílò ní ti ìlànà láti ìgbà tí orílẹ̀-èdè náà ti wà pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ni Oluwa wí, àti ìránṣẹ́ mi ti mo ti yàn: kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ kí ó sì yé yin pé, Èmi ni.” (Isaiah 43:10) Báwo ni orílẹ̀-èdè tuntun yìí yóò ṣe ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́rìí Jehofa? Nípa ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn wọn àti nípa ìgbésẹ̀ Jehofa nítorí wọn.

10. Ní ọ̀nà wo ni àwọn iṣẹ́ alágbára ti Jehofa nítorí Israeli gbà pèsè ẹ̀rí kan, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?

10 Nǹkan bí 40 ọdún lẹ́yìn tí ó bẹ̀rẹ̀, Israeli ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gba Ilẹ̀ Ìlérí náà. Àwọn amí jáde lọ láti lọ ṣalamí ìlú-ńlá Jeriko, Rahabu, olùgbé Jeriko sì dáàbò bò wọ́n. Èé ṣe? Ó wí pé: “Àwa ti gbọ́ bí OLUWA ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú yín, nígbà tí ẹ̀yin jáde ní Egipti; àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí àwọn ọba méjì ti àwọn Amori, tí ń bẹ ní ìhà kejì Jordani, Sihoni àti Ogu, tí ẹ̀yin parun túútúú. Lọ́gán bí àwa ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí àyà wa já, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí agbára kan nínú ọkùnrin kan mọ́ nítorí yín; nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín, òun ni Ọlọrun lókè ọ̀run, àti nísàlẹ̀ ayé.” (Joṣua 2:10, 11) Ìròyìn àwọn iṣẹ́ agbára tí Jehofa ṣe sún Rahabu àti ìdílé rẹ̀ láti fi Jeriko àti àwọn ọlọrun èké rẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n sì jọ́sìn Jehofa pẹ̀lú àwọn ọmọ Israeli. Ó hàn kedere pé, Jehofa ti pèsè ẹ̀rí tí ó lágbára nípasẹ̀ Israeli.—Joṣua 6:25.

11. Ẹrù-iṣẹ́ wo ni gbogbo àwọn òbí tí ó jẹ́ ọmọ Israeli ní ní ti jíjẹ́rìí?

11 Nígbà tí àwọn ọmọ Israeli ṣì wà ní Egipti, Jehofa rán Mose sí Farao, ó sì wí pé: “Wọlé tọ Farao lọ: nítorí tí mo mú àyà rẹ le, àti àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kí èmi kí ó lè fi iṣẹ́-àmì mi wọ̀nyí hàn níwájú rẹ: àti kí ìwọ kí ó lè wí ní etí ọmọ rẹ, àti ti ọmọ ọmọ rẹ, ohun tí mo ṣe ní Egipti, àti iṣẹ́-àmì mi tí mo ṣe nínú wọn; kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” (Eksodu 10:1, 2) Àwọn ọmọ Israeli onígbọràn yóò ròyìn àwọn ìṣe alágbára-ńlá ti Jehofa fún àwọn ọmọ wọn. Àwọn ọmọ wọn náà pẹ̀lú, yóò ròyìn fún àwọn ọmọ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì máa ṣe é láti ìran dé ìran. Nípa báyìí, a óò máa rántí àwọn iṣẹ́-àrà tí ó lágbára ti Jehofa. Bákan náà lónìí, àwọn òbí ní ẹru iṣẹ́ jíjẹ́rìí fún àwọn ọmọ wọn.—Deuteronomi 6:4-7; Owe 22:6.

12. Báwo ni ìbùkún Jehofa lórí Solomoni àti Israeli ṣe jẹ́ ẹ̀rí kan?

12 Ìbùkún jìngbìnnì ti Jehofa tí ó wà lórí Israeli nígbà tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́, jẹ́ ẹ̀rí kan fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ lẹ́yìn tí ó ṣe àtúnsọ àwọn ìbùkún tí Jehofa ṣèlérí pé: “Gbogbo ènìyàn ayé yóò sì rí i pe orúkọ OLUWA ni a fi ń pè ọ́; wọn óò sì máa bẹ̀rù rẹ.” (Deuteronomi 28:10) A fún Solomoni ní ọgbọ́n àti ọrọ̀ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Orílẹ̀-èdè náà láásìkí ó sí gbádùn sáà gígùn alálàáfíà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. Nípa àkókò náà a kà pé: “Ẹni púpọ̀ sì wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni; àní láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọba ayé, tí ó gbúròó ọgbọ́n rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 4:25, 29, 30, 34) Ọkàn tí ó yọrí ọlá lára àwọn tí ó ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Solomoni ni ayaba Ṣeba. Lẹ́yìn fífi ojú ara rẹ̀ rí ìbùkún Jehofa lórí orílẹ̀-èdè náà àti ọba rẹ̀, ó wí pé: “Olùbùkún ni Oluwa Ọlọrun rẹ, tí ó fẹ́ràn rẹ láti gbé ọ ka orí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣe ọba fún Oluwa Ọlọrun rẹ: nítorí tí Ọlọrun rẹ fẹ́ràn Israeli.”—2 Kronika 9:8.

13. Kí ni ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹ̀rí gbígbéṣẹ́ jù lọ tí Israeli ní, báwo sì ni a ṣe ń jàǹfààní láti inú rẹ̀?

13 Aposteli Paulu mẹ́nu kan ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹ̀rí gbígbéṣẹ́ jù lọ ti Israeli. Nígbà tí ó ń jíròrò nípa Israeli ti ara pẹ̀lú ìjọ Kristian ní Romu, ó wí pé: “A fi awọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́-ọlọ́wọ̀ ti Ọlọrun sí ìkáwọ́ wọn.” (Romu 3:1, 2) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Mose, a mí sí àwọn ọmọ Israeli kan tí wọ́n jẹ̀ olùṣòtítọ́ láti ṣàkọsílẹ̀ ìbálò Jehofa pẹ̀lú àwọn ọmọ Israeli, papọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ràn rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Nípasẹ̀ àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí àwọn akọ̀wé ìgbàanì wọ̀nyí jẹ́rìí fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀—títí kan tiwa lónìí—pé Ọlọrun kan ṣoṣo ní ń bẹ, orúkọ rẹ̀ sì ni Jehofa.—Danieli 12:9; 1 Peteru 1:10-12.

14. Èé ṣe tí àwọn kan tí wọ́n jẹ́rìí fún Jehofa fi jìyà inúnibíni?

14 Ó bani nínú jẹ́ pé, léraléra ni Israeli kùnà láti lo ìgbàgbọ́, Jehofa sì níláti rán àwọn ẹlẹ́rìí sí orílẹ̀-èdè tirẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ni a ṣe inúnibíni sí. Paulu wí pé àwọn kan “rí àdánwò wọn gbà nipa ìfiṣẹlẹ́yà ati ìnàlọ́rẹ́, nítòótọ́, ju èyíinì lọ, nipa awọn ìdè ati ẹ̀wọ̀n.” (Heberu 11:36) Àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ ni wọ́n nítòótọ́! Ẹ wo bí ó ti bani nínú jẹ́ tó pé lọ́pọ̀ ìgbà ni inúnibíni wọn máa ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n jọ jẹ́ orílẹ̀-èdè tí Jehofa yàn! (Matteu 23:31, 37) Ní tòótọ́, ẹ̀ṣẹ̀ orílẹ̀-èdè náà kàmàmà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé ní 607 B.C.E., Jehofa mú àwọn ará Babiloni wá láti pa Jerusalemu pẹ̀lú tẹmpili rẹ̀ run kí wọ́n sì kó èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ Israeli tí ó là á já lọ sí ìgbèkùn. (Jeremiah 20:4; 21:10) Ìyẹn ha jẹ́ òpin ìjẹ́rìí ti orílẹ̀-èdè sí orúkọ Jehofa bí? Rárá o.

Dídán Àwọn Ọlọrun Wò

15. Báwo ni a ṣe pèsè ẹ̀rí ní ìgbèkùn Babiloni pàápàá?

15 Àní ní ìgbèkùn Babiloni pàápàá, àwọn mẹ́ḿbà olùṣòtítọ́ ti orílẹ̀-èdè náà kò lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́rìí nípa jíjẹ́ tí Jehofa jẹ́ Ọlọrun àti nípa agbára rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Danieli fi tìgboyàtìgboyà túmọ̀ àwọn àlá Nebukadnessari, ó ṣàlàyé àkọlé ara ògiri fún Belṣassari, ó sì kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀ níwájú Dariusi nínú ọ̀ràn àdúrà. Àwọn Heberu mẹ́ta pẹ̀lú, nígbà tí wọ́n kọ̀ láti forí balẹ̀ fún ère, jẹ́rìí àgbàyanu fún Nebukadnessari.—Danieli 3:13-18; 5:13-29; 6:4-27.

16. Báwo ni Jehofa ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìpadàbọ̀ Israeli sí ilẹ̀ wọn, kí ni yóò sì jẹ́ ète ìpadàbọ̀ yìí?

16 Síbẹ̀, Jehofa pète pé ìjẹ́rìí ti orílẹ̀-èdè ni a óò pèsè lẹ́ẹ̀kan sí i ní orí ilẹ̀ Israeli. Esekieli, ẹni tí ó sọ tẹ́lẹ̀ láàárín àwọn Júù tí ó wà ní ìgbèkùn ní Babiloni, kọ̀wé nípa ìpinnu Jehofa ní ti ilẹ̀ tí ó dahoro náà pé: “Èmi óò sì mú ènìyàn bí sí i lórí yín, gbogbo ilé Israeli, àní gbogbo rẹ̀: àwọn ìlú yóò sì ní olùgbé, a óò sì kọ́ ibi tí ó di ahoro.” (Esekieli 36:10) Èé ṣe tí Jehofa fi níláti ṣe èyí? Lákọ̀ọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún orúkọ tirẹ̀. Nípasẹ̀ Esekieli ó wí pé: “Èmi kò ṣe èyí nítorí tiyín, ṣùgbọ́n fún orúkọ mímọ́ mi, tí ẹ̀yin ti bàjẹ́ láàárín àwọn kèfèrí, níbi tí ẹ̀yin lọ.”—Esekieli 36:22; Jeremiah 50:28.

17. Kí ni àyíká ọ̀rọ̀ Isaiah 43:10?

17 Ìgbà tí a ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìpadàbọ̀ Israeli láti ìgbèkùn Babiloni ni a mí sí wòlíì Isaiah láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah 43:10, ní sísọ pé Israeli jẹ́ ẹlẹ́rìí Jehofa, àti ìránṣẹ́ rẹ̀. Ní Isaiah 43 àti 44, Jehofa ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, Olùmọ, Ọlọrun, Ẹni Mímọ́, Olùgbàlà, Olùràpadà, Ọba, àti Olùṣẹ̀dá Israeli rẹ̀. (Isaiah 43:3, 14, 15; 44:2, NW) A yọ̀ǹda fún ìkónígbèkùn Israeli nítorí pé orílẹ̀-èdè náà kùnà léraléra láti yìn ín lógo gẹ́gẹ́ bí irú ẹní bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n ṣì jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Jehofa ti sọ fún wọn pé: “Má bẹ̀rù: nítorí mo ti rà ọ́ padà, mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, ti èmi ni ìwọ.” (Isaiah 43:1) Ìkónígbèkùn Israeli ní Babiloni yóò dópin.

18. Báwo ni ìdásílẹ̀ lómìnira Israeli kúrò ní Jerusalemu ṣe fi ẹ̀rí hàn pé Jehofa nìkanṣoṣo ni Ọlọrun òtítọ́?

18 Ní tòótọ́, Jehofa sọ dídá Israeli sílẹ̀ lómìnira kúrò ní Babiloni di dídán àwọn ọlọrun wò. Ó pe àwọn ọlọrun èké àwọn orílẹ̀-èdè níjà láti mú ẹlẹ́rìí wọn wá, ó sì pe Israeli ní ẹlẹ́rìí tirẹ̀. (Isaiah 43:9, 12) Nígbà tí ó já ìdè ìkónígbèkùn Israeli, ó fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ọlọrun Babiloni kì í ṣe ọlọrun rárá àti pé òun nìkan ṣoṣo ni Ọlọrun tòótọ́. (Isaiah 43:14, 15) Ní nǹkan bí 200 ọdún ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, nígbà tí ó pe Kirusi ará Persia ní ìránṣẹ́ rẹ̀ ní dídá àwọn Júù sílẹ̀, ó tún fi ẹ̀rí síwájú sí i nípa jíjẹ́ tí òun jẹ́ Ọlọrun hàn. (Isaiah 44:28) A óò dá Israeli sílẹ̀ lómìnira. Èé ṣe? Jehofa ṣàlàyé pé: “Wọn [Israeli] óò sì fi ìyìn mi hàn.” (Isaiah 43:21) Yóò tún pèsè àǹfààní síwájú sí i fún ìjẹ́rìí.

19. Ẹ̀rí wo ni a pèsè nípasẹ̀ kíkésí tí Kirusi ké sí àwọn ọmọ Israeli láti padà lọ sí Jerusalemu àti nípasẹ̀ ìgbésẹ̀ àwọn Júù olùṣòtítọ́ lẹ́yìn pípadà wọn?

19 Nígbà tí àkókò náà tó, Kirusi ará Persia ṣẹ́gun Babiloni gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀. Kirusi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ kèfèrí, pòkìkí jíjẹ́ tí Jehofa jẹ́ Ọlọrun nígba tí ó kéde fún àwọn Júù tí ó wà ní Babiloni pé: “Ta ni nínú yín nínú gbogbo ènìyàn rẹ̀? kí Ọlọrun rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalemu, tí ó wà ní Juda, kí ó sì kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun Israeli, òun ni Ọlọrun, tí ó wà ní Jerusalemu.” (Esra 1:3) Ọ̀pọ̀ àwọn Júù dáhùn padà. Wọ́n fẹsẹ̀ rìn padà sí Ilẹ̀ Ìlérí náà wọ́n sì kọ́ pẹpẹ kan sórí ibi tí tẹmpili ìgbàanì wà. Láìka ìrẹ̀wẹ̀sì àti àtakò lílekoko sí, ó ṣeé ṣe fún wọn nígbẹ̀yìngbẹ́yín láti tún tẹmpili náà àti ìlú-ńlá Jerusalemu kọ́. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jehofa fúnra rẹ̀ ti wí pé, “kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa ẹ̀mí [rẹ̀].” (Sekariah 4:6) Àwọn àṣeparí wọ̀nyí pèsè ẹ̀rí síwájú sí i pé Jehofa ni Ọlọrun tòótọ́.

20. Láìka àwọn àìlera Israeli sí, kí ni a lè sọ nípa jíjẹ́rìí tí wọ́n jẹ́rìí sí orúkọ Jehofa ní ayé ìgbàanì?

20 Nípa báyìí, Jehofa ń bá a nìṣó láti lo Israeli, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè àwọn aláìpé tí wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ nígbà mìíràn. Ní ayé tí ó ṣáájú sànmánì àwọn Kristian, orílẹ̀-èdè náà, pẹ̀lú tẹmpili àti àlùfáà rẹ̀, dúró gẹ́gẹ́ bí ọ̀gangan ìdarí ìjọsìn tòótọ́ lágbàáyé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu nípa àwọn ìṣe Jehofa ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Israeli kò lè ṣiyè méjì lọ́nàkọnà pé Ọlọrun tòótọ́ kan ṣoṣo ní ń bẹ, Jehofa sì ni orúkọ rẹ̀. (Deuteronomi 6:4; Sekariah 14:9) Bí ó ti wù kí ó rí, ìjẹ́rìí tí ó kàmàmà sí i ni a níláti fún orúkọ Jehofa, a óò sì jíròrò èyí nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Báwo ni Abrahamu ṣe pèsè ẹ̀rí pé Jehofa ni Ọlọrun tòótọ́?

◻ Ànímọ́ títayọ lọ́lá wo tí Mose ní ni ó mú kí ó ṣeé ṣe fun un láti di ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́?

◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni Israeli gbà pèsè ẹ̀rí ti orílẹ̀-èdè nípa Jehofa?

◻ Báwo ni ìdásílẹ̀ Israeli lómìnira kúrò ní Babiloni ṣe fi hàn pé Jehofa ni Ọlọrun tòótọ́ kan ṣoṣo náà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nípa ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn rẹ̀, Abrahamu pèsè ẹ̀rí tí ó tayọ lọ́lá ní ti jíjẹ́ tí Jehofa jẹ́ Ọlọrun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́