“Ìfẹ́ Kì Í Kùnà Láé”
GẸ́GẸ́ BÍ SAMUEL D. LADEṢUYI ṢE SỌ Ọ́
Ẹnu yà mí nígbà tí mo bojú wẹ̀yìn padà sí àwọn ọdún tí ó ti kọjá tí mo sì rí gbogbo ohun tí a ti ṣàṣeparí rẹ̀. Jehofa ti ń ṣe àwọn ohun ìyanu jákèjádò ilẹ̀ ayé. Ní Ileṣa, Nigeria, àwa díẹ̀ tí a bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní 1931 ti di ìjọ 36. Nǹkan bí 4,000 tí ń kéde ní Nigeria nígbà tí àkọ́kọ́ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde láti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead dé ní 1947 ti pọ̀ tó iye tí ó lé ní 180,000. Ní àwọn ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀, a kò retí, bẹ́ẹ̀ ni a kò lálàá ìgbòòrò tí yóò wáyé. Ẹ wo bí mo ti kún fún ọpẹ́ tó pé mo ti kópa nínú iṣẹ́ àgbàyanu yìí! Ẹ jẹ́ kí n sọ fún un yín nípa rẹ̀.
BÀBÁ mi ń ṣòwò ìbọn àti ẹ̀tù láti ìlú dé ilú; kì í sábàá gbélé. Ó ní ìyàwó méje tí mo mọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ní ń bá a gbé. Bàbá mi ṣú ìyá mi lópó láti ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti kú. Ìyá mi di ìyàwó rẹ̀ kejì, mo sì ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀.
Ní ọjọ́ kan Bàbá darí wálé láti ibi tí ó ti lọ bẹ ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ wò, ẹni tí ń gbé ní abúlé kan nítòsí. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó gbọ́ pé ọbàkan mi ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Ọbàkan mi jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, ọjọ́ orí kan náà bíi tèmi. Nítorí náà Bàbá pinnu pé èmi náà gbọ́dọ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Ó fún mi ní náín—tọ́rọ́ fún ìwé àti sísì fún síléètì. Ìyẹn jẹ́ ní 1924.
A Dá Àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Sílẹ̀
Láti ìgbà kékeré mi ni mo ti ní ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Mo gbádùn àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní ilé ẹ̀kọ́, àwọn olùkọ́ mi ní ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ Ìsinmi sì máa ń gbóríyìn fún mi nígbà gbogbo. Nítorí náà ní 1930, mo lo àǹfààní náà láti lọ sí ibi àsọyé tí Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan tí ń ṣèbẹ̀wò sọ, ọkàn lára àwọn tí ó kọ́kọ́ wàásù ní Ileṣa. Lẹ́yìn àsọyé náà, ó fi ẹ̀dà ìwé náà Duru Ọlọrun sílẹ̀ fún mi.
Mo ti máa ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ Ìsinmi déédéé. Nísinsìnyí mo bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìwé Duru Ọlọrun dáni lọ mo sì ń lò ó láti já àwọn ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n ń kọni níbẹ̀ nírọ́. Àríyànjiyàn bẹ́ sílẹ̀, léraléra ni àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì sì kìlọ̀ fún mi lòdì sí títẹ̀lé ‘ẹ̀kọ́ tuntun’ yìí.
Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, bí mo ti ń dọ́gbẹ̀ẹ́rẹ́ lọ ní òpópónà, mo rí àwọn àwùjọ ènìyàn kan tí ń tẹ́tí sílẹ̀ sí ọkùnrin kan tí ń sọ àsọyé fún wọn. Alásọyé náà ni J. I. Owenpa, Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan. William R. Brown (tí a sábà máa ń pè ní Bible Brown), ẹni tí ń bójú tó ìṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà láti Eko, ni ó rán an wá.a Mo gbọ́ pé a ti dá àwùjọ akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kékeré kan sílẹ̀ ní Ileṣa láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Duru Ọlọrun, nítorí náà mo dara pọ̀ mọ́ wọn.
Èmi ni mo kéré jù nínú àwùjọ náà—ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lásán, tí ó jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún 16. Ó yẹ kí ojú máa tì mí, kí n tilẹ̀ máa bẹ̀rù, láti máa bá àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti tó 30 ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ kẹ́gbẹ́ pọ̀. Ṣùgbọ́n inú wọn dùn pé mo wà láàárín wọn, wọ́n sì fún mi ní ìṣírí. Wọ́n dàbí bàbá fún mi.
Àtakò Àwùjọ Àlùfáà
Láìpẹ́ a bẹ̀rẹ̀ sí dojú kọ àtakò tí ó gbóná janjan láti ọ̀dọ̀ àwùjọ àlùfáà. Àwọn Katoliki, Anglikan, àti àwọn mìíràn, tí wọ́n ti ń bá ara wọn jà tẹ́lẹ̀, pawọ́ pọ̀ wàyí lòdì sí wa. Wọ́n dìtẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olóyè àdúgbò láti gbé ìgbésẹ̀ láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Wọ́n rán àwọn ọlọ́pàá láti gba àwọn ìwé wa, ní sísọ pé wọ́n lè ṣèpalára fún àwọn ènìyàn. Bí ó ti wù kí ó rí, alábòójútó ẹkùn náà kìlọ̀ pé wọn kò ní ẹ̀tọ́ láti kó àwọn ìwé náà, wọ́n sì dá àwọn ìwé náà padà ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà.
Lẹ́yìn èyí a pè wá sí ìpàdé kan níbi tí a ti pàdé ọba, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí wọ́n yọrí-ọlá ní ìlú . A tó nǹkan bí 30 ní àkókò náà. Ète wọn ni láti dá wa dúró láti má ṣe ka àwọn ìwé “tí ó léwu” náà. Wọ́n béèrè bóyá àlejò ni wá, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wo ojú wa fínnífínní, wọ́n sọ pé, “Ọmọ wa ni àwọn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlejò díẹ̀ wà láàárín wọn.” Wọ́n sọ fún wa pé àwọn kò fẹ́ kí a máa báa lọ ní kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé ìsìn tí yóò pa wá lára.
A lọ sílé láìsọ ohunkóhun, nítorí pé a ti pinnu láti má ṣe dá àwọn ènìyàn tí ó yọrí-ọlá wọ̀nyẹn lóhùn. Ọ̀pọ̀ nínú wa ni inu wa ń dùn sí ohun tí a ti ń kọ́ a sì ti pinnu láti máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́. Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn díẹ̀ lára wa ni jìnnìjìnnì bò tí wọ́n sì fà sẹ́yìn kúrò lára àwùjọ wa, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tí a ń ṣe ní ìsọ̀ káfíntà kan. A kò ní olùdarí. A ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà a sì wulẹ̀ ń pín àwọn ìpínrọ̀ ìwé náà kà. Lẹ́yìn nǹkan bí i wákàtí kan, a óò tún gbàdúrà a óò sì lọ sí ilé. Ṣùgbọ́n a ń ṣamí wa, àwọn olóyè àti àwọn aṣáájú ìsìn sì ń bá a lọ láti máa pè wá lọ́sẹ̀ méjìméjì tí wọn sì ń kìlọ̀ fún wa lòdì sí kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
Láàárín àkókò náà, a ń gbìyànjú láti lo ìwọ̀nba ìmọ̀ díẹ̀ tí a ní láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ sì ń gbà pẹ̀lú wa. Lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn ènìyàn ń dara pọ̀ mọ́ wa. Inú wa dùn púpọ̀, ṣùgbọ́n síbẹ̀ a kò tí ì mọ púpọ̀ nípa ìsìn tí a ń dara pọ̀ mọ́.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ 1932 arákùnrin kan wá láti Eko láti ṣèrànlọ́wọ́ nínú ṣíṣètò wa, bákan náà ní April “Bible” Brown pẹ̀lú wá. Ní rírí i pé àwùjọ kan wà tí ó tó 30, Arákùnrin Brown wádìí nípa ìtẹ̀síwájú tí a ń ṣe nínú ìwé kíkà wa. A sọ gbogbo ohun tí a mọ̀ fún un. Ó sọ pé a ti ṣetán láti ṣe batisí.
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ìgbà ẹ̀rùn, a níláti rìnrìn-àjò lọ sí odò kan tí ó jẹ́ kìlómítà 14 sí Ileṣa, a sì batisí àwa bí 30. Láti ìgbà náà lọ a rí ara wa gẹ́gẹ́ bí oníwàásù Ìjọba náà a sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti ilé dé ilé. A kò ronú tẹ́lẹ̀ pé a óò ṣe èyí, ṣùgbọ́n a ti ń háragàgà nísinsìnyí láti ṣàjọpín ohun tí a mọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. A níláti múra sílẹ̀ dáradára kí a baà lè rí ìtìlẹyìn Bibeli láti já àwọn ìgbàgbọ́ èké tí a bá dojú kọ nírọ́. Nítorí náà ní àwọn ìpàdé wa, a máa ń jíròrò àwọn ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ náà, ní ríran ara wa lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí a mọ̀.
Ìgbòkègbodò Ìwàásù Wa
A kárí gbogbo ìlú náà pẹ̀lú ìwàásù wa. Àwọn ènìyàn fi wá ṣe ẹlẹ́yà wọ́n sì pariwo lé wa lórí, ṣùgbọ́n a kò dá wọn lóhùn. Ìdùnnú wa ga nítorí tí a ní òtítọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ṣì ní ohun púpọ̀ láti kọ́.
A ń lọ láti ilé dé ilé ní gbogbo ọjọ́ Sunday. Àwọn ènìyàn yóò béèrè ìbéèrè, a óò sì gbìyànjú láti dá wọn lóhùn. Ní àwọn ìrọ̀lẹ́ Sunday a óò sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. A kò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, nítorí náà a ń ṣe ìpàdé ní ìta gbangba. A óò kó àwọn ènìyàn jọ, a óò sọ àsọyé, a óò sì ké sí wọn láti béèrè àwọn ìbéèrè. Nígbà mìíràn a ń wàásù nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì.
A tún ń rìnrìn-àjò lọ sí àwọn àdúgbò tí àwọn ènìyàn kò tíì gbúròó àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rí. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a máa ń gun kẹ̀kẹ́ lọ, ṣùgbọ́n nígbà mìíràn a óò háyà bọ́ọ̀sì. Nígbà tí a bá dé abúlé kan, a óò fun ipè kíkankíkan. Gbogbo abúlé yóò gbọ́ wa! Àwọn ènìyàn yóò rọ́ gìrìrì wá láti mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Nígbà náà ni a óò jẹ́ ìhìn iṣẹ́ wa. Lẹ́yìn tí a bá ti ṣe tán, àwọn ènìyàn yóò máa dù láti gba ẹ̀dà ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. A fi iye tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ sóde.
A fi ìháragàgà retí dídé Ìjọba Ọlọrun. Mo rántí pé nígbà tí a gba ìwé Yearbook 1935, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rí ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìjíròrò ẹ̀kọ́ fún ọdún náà, ó béèrè pé: “Èyí ha túmọ̀ sí pé a óò parí odindi ọdún mìíràn ṣáájú kí Armageddoni tó dé bí?”
Ní ìdáhùnpadà olùdarí béèrè pé: “Arákùnrin, o ha rò pé bí Armageddoni bá tilẹ̀ dé lọ́la, a óò ṣíwọ́ kíka ìwé Yearbook bí?” Nígbà tí arákùnrin náà sọ pé rárá, olùdarí náà sọ pé: “Nígbà náà kí ló dé tí o fi ń dààmú?” A háragàgà, a ṣì tún ń háragàgà síbẹ̀ fún ọjọ́ Jehofa.
Àwọn Ọdún Ogun
Nígbà ogun àgbáyé kejì, a fòfin de kíkó àwọn ìwé wa wọlé. Arákùnrin kan ní Ileṣa ṣèèṣì fi ìwé náà Ọrọ lọ ọlọ́pàá kan. Ọlọ́pàá náà béèrè pé: “Ta ló ni ìwé yìí?” Arákùnrin náà sọ pé ti òun ni. Ọlọ́pàá náà sọ pé ìwé tí a ti fòfin dè ni, ó mú un lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, ó sì tì í mọ́lé.
Mo lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, mo sì ṣe onídùúró fún arákùnrin náà, lẹ́yìn tí mo ti ṣe ìwádìí. Lẹ́yìn náà mo fóònù Arákùnrin Brown ní Eko láti sọ fún un nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Mo tún béèrè bí òfin kankan bá wà tí ó fòfin de ìpínkiri àwọn ìwé wa. Arákùnrin Brown sọ fún mi pé kìkì ìkówọlé àwọn ìwé wa ni a fòfin dè, kì í ṣe ìpínkiri rẹ̀. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, Arákùnrin Brown rán arákùnrin kan wá láti Eko láti wá wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Arákùnrin yìí pinnu pé gbogbo wa gbọ́dọ̀ lọ láti ṣiṣẹ́ ìwàásù ní ọjọ́ kejì pẹ̀lú àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé ńlá.
A forí lé ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lẹ́yìn nǹkan bí i wákàtí kan, ìròyìn kàn mí pé èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn arákùnrin wa ni a ti fàṣẹ ọba mú. Nítorí náà, èmi àti arákùnrin tí ó bẹ̀ wá wò lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Àwọn ọlọ́pàá kọ̀ láti fetí sílẹ̀ sí àlàyé wa pé àwọn ìwé náà ni a kò fòfin dè.
Àwọn arákùnrin 33 tí a ti fàṣẹ ọba mu ni a kó lọ sí Ilé-Ẹjọ́ Gíga ní Ifẹ, mo sì bá wọn lọ. Àwọn ará ilú tí wọ́n rí wa nígbà tí wọ́n ń mú wa lọ pariwo pé, “Ti àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti tán lónìí. Wọn kò ní padà wá síhìn-ín mọ́.”
A gbé ẹjọ́ náà síwájú adájọ́ àgbà kan, tí ó jẹ́ ọmọ Nigeria. A tẹ́ gbogbo àwọn ìwé ńlá àti àwọn ìwé ìròyìn náà sílẹ̀. Ó béèrè ẹni tí ó fún ọ̀gá ọlọ́pàá láṣẹ láti fàṣẹ ọba mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ọ̀gá ọlọ́pàá náà dáhùn pé òun ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ alábòójútó ẹkùn náà. Adájọ́ àgbà náà pe ọ̀gá ọlọ́pàá àti mẹ́rin lára àwọn aṣojú wa, àti èmi náà, lọ sí yàrá ilé-ẹjọ́ rẹ̀.
Ó béèrè ẹni tí Ọ̀gbẹ́ni Brown jẹ́. A sọ fún un pé òun ni aṣojú Watch Tower Society ní Eko. Lẹ́yìn náà ni ó sọ fún wa pé òun tí gba wáyà kan láti ọ̀dọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Brown nípa wa. Ó sún ẹjọ́ náà síwájú ní ọjọ́ náà ó sì gbà kí a ṣe onídùúró fún àwọn arákùnrin náà. Ní ọjọ́ kejì ó dá àwọn arákùnrin náà sílẹ̀, lómìnira, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti dá àwọn ìwé náà padà.
A padà lọ sí Ileṣa, torintorin. Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí wọ́n ń sọ pé, “Wọ́n tún ti padà dé o!”
A Mú Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Jehofa Nípa Ìgbéyàwó Ṣe Kedere
Ọdún 1947 ni àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde Gilead dé sí Nigeria. Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin yìí, Tony Attwood, ṣì wà níhìn-ín, tí ń ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹtẹli ti Nigeria. Láti ìgbà náà wá, a rí ìyípadà ńláǹlà nínú ètò-àjọ Jehofa ní Nigeria. Ọ̀kan lára àwọn ìyípadà ńláǹlà náà ni ojú ìwòye wa nípa àṣà ìkóbìnrinjọ.
Mo gbé Ọlabisi Fashugba níyàwó ní February 1941 mo sì ní ìmọ̀ tí ó tó láti má ṣe ní ìyàwó kankan sí i. Ṣùgbọ́n títí di 1947 nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì dé, àṣà ìkóbìnrinjọ wọ́pọ̀ nínú ìjọ. Àwọn arákùnrin tí wọ́n ní ìyàwó púpọ̀ ni a sọ fún pé wọ́n ti fi àìmọ̀kan fẹ́ ju ìyàwó kan lọ. Nítorí náà bí wọ́n bá ní ìyàwó méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin tàbí márùn ún, wọ́n lè máa fẹ́ wọn lọ, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ òmíràn sí i. Ìlànà tí a gùn lé nìyẹn.
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ní ń dàníyàn láti dara pọ̀ mọ́ wa, ní pàtàkì àwọn Cherubim and Seraphim Society ní Ileṣa. Wọ́n sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nìkan ni àwọn ènìyàn tí ń fòtítọ́ kọ́ni. Wọ́n fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ wa wọ́n sì fẹ́ láti yí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọn padà di Gbọ̀ngàn Ìjọba. A ń ṣiṣẹ́ kára láti mú kí èyí ṣeé ṣe. A tilẹ̀ ní àwọn ibi ìpàdé láti kọ́ àwọn alàgbà wọn lẹ́kọ̀ọ́.
Nígbà náà ni ìdarísọ́nà tuntun dé nípa ìkóbìnrinjọ. Ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì náà sọ̀rọ̀ àsọyé kan ní àpéjọ àyíká kan ní 1947. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìwà rere àti àṣà. Lẹ́yìn náà ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú 1 Korinti 6:9, 10, tí ó sọ pé àwọn aláìṣòdodo kì yóò jogún Ìjọba Ọlọrun. Ó fi kún un nígbà náà pé: “Àti àwọn tí ń kóbìnrinjọ ni kì yóò jogún Ìjọba Ọlọrun!” Àwọn ènìyàn tí ó wà ní àwùjọ pariwo pé: “Hẹ̀ẹ̀hẹ́n, àwọn tí ń kóbìnrinjọ kì yóò jogún Ìjọba Ọlọrun kẹ̀!” Ìyapa bẹ̀rẹ̀. Ńṣe ni ó dàbí ogun. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ fà sẹ́yìn, ní sísọ pé: “Ọlọrun ṣeun, a kò tíì lọ jìnnà.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn arákùnrin wa bẹ̀rẹ̀ sí í tún ọ̀nà wọn ṣe nípa fifi àwọn ìyàwó wọn sílẹ̀. Wọ́n fún wọn lówó wọ́n sì sọ fún wọn pé, ‘Bí o bá ṣì kéré, lọ wá ọkọ mìíràn fẹ́. Àṣìṣe ni mo ṣe nípa fífẹ́ ọ. Nísinsìnyí mo níláti jẹ́ ọkọ aya kan.’
Láìpẹ́ ìṣòro mìíràn dìde. Àwọn kan, lẹ́yìn tí wọ́n ti pinnu láti mú ìyàwó kan kí wọ́n sì jọ̀wọ́ àwọn yòókù, wọ́n yí ìrònú wọn padà wọ́n sì pinnu pé àwọn fẹ́ láti mú ọ̀kan padà lára àwọn ìyàwó tí wọ́n ti fi sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ kí wọ́n sì fi èyí tí wọ́n mú tẹ́lẹ̀ sílẹ̀! Nítorí náà ìjàngbọ̀n bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
Ìdarísọ́nà síwájú sí i wá láti orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn, tí a gbé karí Malaki 2:14, tí ó tọ́ka sí “aya èwe rẹ.” Ìdarísọ́nà náà ni pé àwọn ọkọ gbọ́dọ̀ mú ìyàwó tí wọ́n kọ́kọ́ fẹ́. Báyìí ni wọ́n ṣe yanjú ìbéèrè náà.
Àǹfààní Iṣẹ́-Ìsìn
Ní 1947 Society bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ìjọ lókun wọ́n sì ń ṣètò wọn sí àwọn àyíká. Wọ́n fẹ́ láti yan àwọn arákùnrin tí wọ́n dàgbà dénú gẹ́gẹ́ bí ‘ìránṣẹ́ àwọn arákùnrin,’ tí a mọ̀ lónìí sí alábòójútó àyíká. Arákùnrin Brown béèrè lọ́wọ́ mi bí èmi yóò bá tẹ́wọ́ gba irú yíyàn bẹ́ẹ̀. Mo sọ pé ìdí tí mo fi ṣe batisí ni láti ṣe ìfẹ́-inú Jehofa, mo sì fi kún un pé: “Ìwọ ni o tilẹ̀ batisí mi. Nígbà tí àyè wà nísinsìnyí láti sin Jehofa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ sí i, o ha rò pé èmi yóò kọ̀ bí?”
Ní October ọdún yẹn, méje lára wa ni a pè lọ sí Eko tí a sì fún wa ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣáájú kí a tó rán wa lọ sí iṣẹ́ àyíká. Ní àwọn ìgbà yẹn àwọn àyíká tóbi gan-an. Odindi orílẹ̀-èdè ni a pín sí àyíká méje péré. Ìjọ kò tó nǹkan.
Iṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ fún àwọn arákùnrin le gan-an ni. A ń fẹsẹ̀ rin ọ̀pọ̀ ibùsọ̀ lójúmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà la igbó-ẹgàn ilẹ̀ olóoru kọjá. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ a níláti rìnrìn-àjò láti abúlé sí abúlé. Nígbà mìíràn mo máa ń nímọ̀lára bí pé ẹsẹ̀ mi yóò dá. Nígbà mìíràn mo máa ń nímọ̀lára pé mo ń kú lọ! Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìdùnnú wà pẹ̀lú, ní pàtàkì ní rírí iye àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ sí i tí ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Họ́wù, ní ọdún méje péré, iye àwọn akéde ní orílẹ̀-èdè ti lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́rin!
Mo nípìn-ín nínú iṣẹ́ àyíká títí di 1955 nígbà tí àìsàn sọ ọ́ di dandan fún mi láti padà wá sí Ileṣa, níbi tí a ti yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìlú-ńlá. Wíwà nílé mú kí ó ṣeé ṣe fún mi láti fi àkókò púpọ̀ sí i sílẹ̀ láti ran ìdílé mi lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Lónìí àwọn ọmọ mi mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sin Jehofa.
Ìfẹ́ Tòótọ́ Kì í Kùnà Láé
Nígbà tí mo bojú wẹ̀yìn padà sí àwọn ọdún tí ó ti kọjá, mo ní ohun púpọ̀ láti dúpẹ́ fún. Ìjánikulẹ̀, ìdààmú, àti àìsàn wà, ṣùgbọ́n ìdùnnú tí ó pọ̀ tún wà pẹ̀lú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ wa àti òye wa ti pọ̀ sí i bí ọdún ti ń gorí ọdún, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ ìtumọ̀ 1 Korinti 13:8, tí ó sọ pé: “Ìfẹ́ kì í kùnà láé” láti inú ìrírí. Bí o bá nífẹ̀ẹ́ Jehofa tí o sì dúró gbọn-ín-gbọ́n-in nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, òun yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ la àwọn ìṣòro rẹ kọjá yóò sì bùkún ọ jìngbìnnì.
Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i. Ní àwọn ọjọ́ tí a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, a lérò pé Armageddoni yóò dé kíákíá; ìdí nìyẹn tí a fi ń kánjú láti ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe. Ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ fún àǹfààní wa. Ìdí nìyẹn tí mo fi gba pẹ̀lú ọ̀rọ̀ onipsalmu náà pé: “Èmi yóò yin Jehofa nígbà tí mo wà láàyè. Èmi yóò kọrin adùnyùngbà sí Ọlọrun níwọ̀n ìgbà tí mo bá ṣì ń bẹ.”—Orin Dafidi 146:2, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Arákùnrin Brown ni a ń pè ní Bible Brown nítorí àṣà rẹ̀ ti títọ́ka sí Bibeli gẹ́gẹ́ bí ọlá-àṣẹ tí ó ga ju lọ.—Wo “Ìkórè ti Ajihinrere Tòótọ́ Kan” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti September 1, 1992, ojú-ìwé 32.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Samuel pẹ̀lú Milton Henschel ní 1955
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Samuel pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, Ọlabisi