ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/15 ojú ìwé 30
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fiyè Sí Ẹ̀kọ́ Rẹ Nígbà Gbogbo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àbúrò Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • A Ti Mú Wa Gbára Dì Fún Iṣẹ́ Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/15 ojú ìwé 30

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni ohun tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jakọbu ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé: “Kì í ṣe púpọ̀ ninu yín ni ó níláti di olùkọ́, ẹ̀yin arákùnrin mi, ní mímọ̀ pé awa yoo gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù”?—Jakọbu 3:1.

Dájúdájú kì í ṣe pé Jakọbu ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn Kristian láti má ṣe kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́. Ní Matteu 28:19, 20, Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ‘sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, kí wọ́n máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí ó ti pa láṣẹ fún wọn mọ́.’ Nítorí náà, gbogbo Kristian ní láti jẹ́ olùkọ́. Aposteli Paulu gba àwọn Kristian Heberu nímọ̀ràn nítorí pé wọn kò tí ì di olùkọ́. Ó kọ̀wé pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ ní ojú-ìwòye ibi tí àkókò dé yii, ẹ̀yin tún nílò ẹni kan lati máa kọ́ yín lati ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ awọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ninu awọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́-ọlọ́wọ̀ ti Ọlọrun.”—Heberu 5:12.

Nígbà náà, kí ni ohun tí Jakọbu ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Ó ń tọ́ka sí àwọn tí wọ́n ní àkànṣe àǹfààní ìkọ́ni nínú ìjọ. Ní Efesu 4:11, a kà pé: “Ó [Jesu Kristi, Orí ìjọ] . . . fúnni ní awọn kan gẹ́gẹ́ bí aposteli, awọn kan gẹ́gẹ́ bí wòlíì, awọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, awọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn ati olùkọ́.” Àwọn àkànṣe ipò ìkọ́ni wà láàárín ìjọ Kristian ọ̀rúndún kìíní gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà lónìí. Fún àpẹẹrẹ, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń ṣojú fún “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” ó sì ní àkànṣe ẹrù iṣẹ́ láti ṣàbójútó kíkọ́ ìjọ tí ó wà káàkiri ayé. (Matteu 24:45) Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti alàgbà ìjọ pẹ̀lú ní àkànṣe ẹrù iṣẹ́ kíkọ́ni.

Jakọbu ha ń sọ fún àwọn Kristian ọkùnrin tí ó tóótun pé wọn kò gbọdọ̀ tẹ́wọ́ gba ipa iṣẹ́ olùkọ́ nítorí ìbẹ̀rù ìdájọ́ Ọlọrun tí ó wúwo jù bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ipò iṣẹ́ alàgbà jẹ́ àǹfààní ńláǹlà kan, gẹ́gẹ́ bí 1 Timoteu 3:1 ṣe tọ́ka sí i, èyí tí ó sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ àtàtà ni ó ní ìfẹ́-ọkàn sí.” Ọ̀kan lára àwọn ohun àbéèrèfún fún yíyàn sípò gẹ́gẹ́ bí alàgbà ìjọ ni pé, ọkùnrin kan ní láti “tóótun lati kọ́ni.” (1 Timoteu 3:2) Jakọbu kò tako àwọn ọ̀rọ̀ Paulu tí a mí sí.

Bí ó ti wù kí ó rí, ó dà bíi pé ní ọ̀rúndún kìíní C.E., àwọn kan ń yan ara wọn bí olùkọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò tóótun tí a kò sì yàn wọ́n sípò. Bóyá, wọ́n lérò pé àwọn ìyọrí ọlá kan wà nínú ipa iṣẹ́ náà, wọ́n sì lọ́kàn ìfẹ́ sí ògo ara ẹni. (Fi wé Marku 12:38-40; 1 Timoteu 5:17.) Aposteli Johannu mẹ́nu kan Diotrefe, ẹni tí ó ‘fẹ́ lati gba ipò àkọ́kọ́ láàárín wọn, ṣùgbọ́n tí kò fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gba ohunkóhun lati ọ̀dọ̀ Johannu.’ (3 Johannu 9) Timoteu kìíní 1:7 sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tí wọ́n ‘fẹ́ lati jẹ́ olùkọ́ òfin, ṣugbọn tí wọn kò róye yálà awọn ohun tí wọn ń sọ tabi awọn ohun nipa èyí tí wọn ń ṣe ìkéde-àtẹnumọ́ líle.’ Àwọn ọ̀rọ̀ Jakọbu 3:1 bá àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ mu ní pàtàkì, àwọn ẹni tí ń lọ́kàn ìfẹ́ láti jẹ́ olùkọ́ ṣùgbọ́n, tí wọ́n ní ète ìsúnniṣe tí ó lòdì. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè ṣe ìpalára gidigidi fún agbo, wọn yóò sì gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.—Romu 2:17-21; 14:12.

Jakọbu 3:1 tún jẹ́ ìránnilétí tí ó dára fún àwọn wọnnì tí wọ́n tóótun tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́. Níwọ̀n bí a ti fi púpọ̀ sí ìkáwọ́ wọn, púpọ̀ ni a óò béèrè lọ́wọ́ wọn. (Luku 12:48) Jesu wí pé: “Gbogbo àsọjáde aláìlérè tí awọn ènìyàn ń sọ, ni wọn yoo jíhìn nipa rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́.” (Matteu 12:36) Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì nípa àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn tẹ̀wọ̀n lọ́nà gíga lọ́lá, àwọn alàgbà tí a yàn sípò.

Àwọn alàgbà yóò jíhìn fún ọ̀nà tí wọ́n bá gbà bá àwọn àgùntàn Jehofa lò. (Heberu 13:17) Ohun tí wọ́n ń sọ ń nípa lórí ìgbésí ayé. Nítorí náà, alàgbà kan ní láti ṣọ́ra kí ó má ṣe gbé èrò tirẹ̀ lárugẹ, tàbí hùwà ìkà sí àwọn àgùntàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn Farisi ti ṣe. Ó gbọ́dọ̀ làkàkà láti ṣàfihàn irú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ kan náà tí Jesu fi hàn. Nínú gbogbo ipò kíkọ́ni, àti ní pàtàkì nígbà tí ó bá kópa nínú ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́, alàgbà kan ní láti wọn àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wò, kí ó má ṣe máa lo àwọn gbólóhùn tí a kò ronú lé lórí dáradára, tàbí sọ àwọn èrò tí ó jẹ́ ti ara ẹni gbáà. Nípa gbígbáralé Jehofa, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ìdarísọ́nà rẹ̀ nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ pátápátá, olùṣọ́ àgùtàn náà yóò gba ìbùkún jìngbìnnì ti Ọlọrun, kì í ṣe “ìdájọ́ tí ó wúwo jù.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́