Ẹ̀yin Òbí Àti Ẹ̀yin Ọmọ: Ẹ Fi Ọlọrun Sí Ipò Kìíní!
“Bẹ̀rù Ọlọrun kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́.”—ONIWASU 12:13.
1. Ìbẹ̀rù wo ni àwọn òbí àti ọmọ ní láti mú dàgbà, kí sì ni yóò mú wá fún wọn?
ÀSỌTẸ́LẸ̀ kan nípa Jesu Kristi sọ pé, “ìgbádùn yóò sì wà fún un nínú bíbẹ̀rù Jehofa.” (Isaiah 11:3, NW) Ìbẹ̀rù rẹ̀ ní pàtàkì jẹ́ ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọrun, ìbẹ̀rù láti ṣe ohun tí kò wu Ọlọrun nítorí tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àwọn òbí àti àwọn ọmọ ní láti mú irú ìbẹ̀rù Ọlọrun bẹ́ẹ̀ dàgbà bí Kristi ti ṣe, èyí tí yóò fún wọn ní ìgbádùn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún Jesu. Wọ́n ní láti fi Ọlọrun sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn nípa ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Bibeli kan ti sọ, “èyí ni àìgbọdọ̀máṣe fún gbogbo ènìyàn.”—Oniwasu 12:13.
2. Èwo ni àṣẹ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Òfin, ta ni a sì fi fún ní pàtàkì?
2 Èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Òfin, pé, a ní láti ‘fi gbogbo àyà wa, àti gbogbo ọkàn wa, àti gbogbo agbára wa fẹ́ OLUWA,’ ni a fún àwọn òbí ní pàtàkì. A fi èyí hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Òfin náà síwájú sí i pé: “Kí ìwọ kí ó sì máa fi [àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa nínífẹ̀ẹ́ Jehofa] kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ í sọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà, àti nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ bá dìde.” (Deuteronomi 6:4-7; Marku 12:28-30) Nípa báyìí, a pàṣẹ fún àwọn òbí láti fi Ọlọrun sí ipò kìíní nípa nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀ fúnra wọn àti nípa kíkọ́ àwọn ọmọ wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
Ẹrù Iṣẹ́ Kristian
3. Báwo ni Jesu ṣe fi ìjẹ́pàtàkì fífún àwọn ọmọ ní àfiyèsí hàn?
3 Jesu ṣàṣefihàn ìjẹ́pàtàkì fífún àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá ní àfiyèsí. Ní àkókò kan bí ó ti ń sún mọ́ òpin iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jesu lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó hàn gbangba pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbàgbọ́ pé ọwọ́ Jesu dí púpọ̀ ju kí a tún dà á láàmú lọ, wọ́n gbìyànjú láti dá àwọn ènìyàn náà lẹ́kun. Ṣùgbọ́n Jesu bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí kíkankíkan pé: “Ẹ jẹ́ kí awọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe gbìyànjú lati dá wọn lẹ́kun.” Jesu tilẹ̀ “gbé awọn ọmọ naa sí apá rẹ̀,” tí ó sì tipa báyìí fi ìjẹ́pàtàkì fífún àwọn ògowẹẹrẹ ní àfiyèsí hàn ní ọ̀nà tí ó wọni lọ́kàn.—Luku 18:15-17; Marku 10:13-16.
4. Àwọn wo ni a fún ní àṣẹ náà láti “sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn,” kí sì ni èyí yóò béèrè pé kí wọ́n ṣe?
4 Jesu tún mú un ṣe kedere pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní ẹrù iṣẹ́ láti kọ́ àwọn mìíràn yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tiwọn. Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde rẹ̀, Jesu “farahàn fún èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta awọn ará lẹ́ẹ̀kan”—títí kan àwọn òbí kan. (1 Korinti 15:6) Ó ṣe kedere pé èyí ṣẹlẹ̀ ní òkè ńlá kan ní Galili, níbi tí àwọn aposteli rẹ̀ 11 ti pé jọ pẹ̀lú. Níbẹ̀ ni Jesu ti rọ gbogbo wọn pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.” (Matteu 28:16-20) Kò sí Kristian kankan tí ó lè fi ẹ̀tọ́ pa àṣẹ yìí tì! Kí àwọn bàbá àti ìyá baà lè ṣe é, ó ń béèrè pé kí wọ́n bójú tó àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì nípìn-ín nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni ní gbangba bákan náà.
5. (a) Kí ni ó fi hàn pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn aposteli ni ó gbéyàwó, tí ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n bímọ? (b) Ìmọ̀ràn wo ni ó yẹ kí àwọn olórí ìdílé mú ní ọ̀kúnkúndùn?
5 Ní ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì, àwọn aposteli pàápàá ní láti mú ẹrù iṣẹ́ ìdílé wọn wà déédéé pẹ̀lú àìgbọdọ̀máṣe náà láti wàásù àti láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọrun. (Johannu 21:1-3, 15-17; Ìṣe 1:8) Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni ó ti gbéyàwó. Nítorí náà, aposteli Paulu ṣàlàyé pé: “Awa ní ọlá-àṣẹ lati máa mú arábìnrin kan káàkiri gẹ́gẹ́ bí aya, àní gẹ́gẹ́ bí awọn aposteli yòókù ati awọn arákùnrin Oluwa ati Kefa, àbí a kò ní?” (1 Korinti 9:5; Matteu 8:14) Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn aposteli ní ọmọ. Àwọn òpìtàn ní àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, irú bí Eusebius, sọ pé Peteru ní. Gbogbo àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní láti fetí sílẹ̀ sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ pé: “Dájúdájú bí ẹni kan kò bá pèsè fún awọn wọnnì tí [wọ́n] jẹ́ tirẹ̀, ati ní pàtàkì fún awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, oun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.”—1 Timoteu 5:8.
Ẹrù Iṣẹ́ Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ
6. (a) Ìpèníjà wo ni àwọn Kristian alàgbà tí wọ́n ní ìdílé ní? (b) Kí ni ẹrù iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ fún alàgbà?
6 Àwọn Kristian alàgbà, tí wọ́n ní ìdílé lónìí, wà ní ipò tí ó fara jọ ti àwọn aposteli. Wọ́n ní láti mú ẹrù iṣẹ́ wọn ti bíbójú tó àìní àwọn ìdílé wọn nípa tẹ̀mí àti nípa ti ara, wà déédéé pẹ̀lú àìgbọdọ̀máṣe wọn láti wàásù ní gbangba àti láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọrun. Ìgbòkègbodò wo ni ó ní láti gba ipò iwájú? Ilé-Ìṣọ́nà ti March 15, 1964 (Gẹ̀ẹ́sì), ṣàkíyèsí pé: “Àìgbọdọ̀máṣe [tí bàbá ní] lákọ̀ọ́kọ́ jẹ́ fún ìdílé rẹ̀, ní tòótọ́, òun kò lè ṣiṣẹ́ sìn bí ó ti yẹ, bí kò bá bójú tó àìgbọdọ̀máṣe yìí.”
7. Báwo ni àwọn bàbá tí wọ́n jẹ́ Kristian ṣe ń fi Ọlọrun sí ipò kìíní?
7 Nítorí náà, àwọn bàbá ní láti fi Ọlọrun sí ipò kìíní nípa ìkọbiara sí àṣẹ náà ‘láti máa bá a lọ ní títọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà nínú ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.’ (Efesu 6:4) Ẹrù iṣẹ́ náà ni a kò lè fà lé ẹlòmíràn lọ́wọ́, àní bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá lè ní iṣẹ́ àyànfúnni láti bójú tó àwọn ìgbòkègbodò nínú ìjọ Kristian. Báwo ni irú àwọn bàbá báyìí ṣe lè bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ wọn—pípèsè nípa ti ara, tẹ̀mí, àti ti èrò ìmọ̀lára fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé—kí wọ́n máa darí, kí wọ́n sì máa pèsè àbójútó nínú ìjọ ní àsìkò kan náà?
Pípèsè Ìtìlẹ́yìn Tí Ó Yẹ
8. Báwo ni ìyàwó alàgbà kan ṣe lè tì í lẹ́yìn?
8 Ó dájú pé, àwọn alàgbà tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ ìdílé lè jàǹfààní láti inú ìtìlẹ́yìn. Ilé-Ìṣọ́nà tí a fàyọ lókè yìí ṣàkíyèsí pé Kristian aya kan lè ṣètìlẹyìn fún ọkọ rẹ̀. Ó sọ pé: “Ó lè mú kí ó rọrùn fún un bí ó bá ti ṣeé ṣe tó láti múra onírúurú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ sílẹ̀, kí ó sì ṣèrànwọ́ láti má ṣe fi àwọn àkókò tí ó ṣeyebíye fún un àti fún ara rẹ̀ ṣòfò nípa níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó dára nínú ilé, kí ó se oúnjẹ ní àkókò, kí ó ṣe tán láti lọ sí ìpàdé ní gbọ̀ngàn ìjọba ní àkókò. . . . Lábẹ́ ìdarísọ́nà ọkọ rẹ̀, Kristian aya kan lè ṣe púpọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ dàgbà ní ọ̀nà tí wọn yóò tọ̀ láti wu Jehofa.” (Owe 22:6) Bẹ́ẹ̀ ni, a dá ìyàwó láti jẹ́ “olùrànlọ́wọ́,” ọkọ rẹ̀ yóò sì tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n. (Genesisi 2:18) Ìtìlẹ́yìn rẹ̀ lè mú kí ó ṣeé ṣe fún un láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìdílé àti nínú ìjọ ní ọ̀nà tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́.
9. Nínú ìjọ Tessalonika, àwọn wo ni a fún ní ìṣírí láti ran àwọn mẹ́ḿbà yòókù nínú ìjọ lọ́wọ́?
9 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn aya àwọn Kristian alàgbà nìkan kọ́ ni wọ́n lè nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò tí ń ṣètìlẹyìn fún alábòójútó tí ó gbọ́dọ̀ “ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo Ọlọrun,” kí ó sì bójú tó agboolé tirẹ̀. (1 Peteru 5:2) Àwọn wo ni wọ́n tún lè ṣe bẹ́ẹ̀? Aposteli Paulu rọ àwọn arákùnrin ní Tessalonika láti ní ọ̀wọ̀ fún àwọn tí wọ́n “ń ṣe àbójútó lórí” wọn. Síbẹ̀, nígbà tí ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn arákùnrin kan náà wọ̀nyí lọ—ní pàtó àwọn wọnnì tí wọ́n kì í ṣe àbójútó—Paulu kọ̀wé pé: “A ń gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, kí ẹ máa fún awọn tí ń ṣe ségesège ní ìṣílétí, ẹ máa sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún awọn ọkàn tí ó sorí kọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún awọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tessalonika 5:12-14.
10. Àbájáde àtàtà wo ni ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn arákùnrin lè ní lórí ìjọ?
10 Ẹ wo bí ó ti dára tó nígbà tí àwọn arákùnrin nínú ìjọ bá ní ìfẹ́ tí ń sún wọn láti tu àwọn tí wọ́n sorí kọ́ nínú, láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn aláìlera, láti sọ̀rọ̀ ìṣítí fún àwọn tí ń ṣe ségesège, àti láti ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn! Àwọn ará ní Tessalonika, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bibeli láìka jíjìyà ìpọ́njú ńlá sí, fi ìmọ̀ràn Paulu láti ṣe èyí sílò. (Ìṣe 17:1-9; 1 Tessalonika 1:6; 2:14; 5:11) Ronú nípa àbájáde rere tí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ onífẹ̀ẹ́ wọn ní nípa fífún ìjọ lápapọ̀ lókun àti mímú un ṣọ̀kan! Bákan náà, nígbà tí àwọn arákùnrin lónìí bá tuni nínú, tí wọ́n ṣètìlẹ́yìn, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ ìṣítí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, ó túbọ̀ máa ń mú ẹrù iṣẹ́ ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn ti àwọn alàgbà tí wọ́n sábà máa ń ní àwọn ìdílé láti bójú tó, rọrùn láti kápá.
11. (a) Èé ṣe tí ó fi bọ́gbọ́n mu láti dé orí èrò náà pé àwọn obìnrin wà lára ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀yin ará”? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo ni Kristian obìnrin tí ó dàgbà dénú, lè ṣe fún àwọn obìnrin, tí ọjọ́ orí wọ́n kéré lónìí?
11 Àwọn obìnrin ha wà lára “ẹ̀yin ará” tí aposteli Paulu ń bá sọ̀rọ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n wà, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ti di onígbàgbọ́. (Ìṣe 17:1‚ 4; 1 Peteru 2:17; 5:9) Irú ìrànlọ́wọ́ wo ni irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ lè pèsè? Tóò, àwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin, tí wọ́n ní ìṣòro ṣíṣàkóso “òòfà-ọkàn wọn fún ìbálòpọ̀ takọtabo” tàbí tí wọ́n ní “ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,” wà nínú ìjọ. (1 Timoteu 5:11-13) Àwọn obìnrin kan lónìí ní àwọn ìṣòro tí ó fara jọ èyí. Ó lè jẹ́ pé ohun tí wọ́n nílò jù lọ ni kìkì ẹni tí yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn tàbí ẹni tí yóò fi ìgbatẹnirò hàn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, Kristian obìnrin kan tí ó dàgbà dénú ni ẹni tí ó dára jù lọ láti pèsè irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó lè jíròrò àwọn ìṣòro ara ẹni pẹ̀lú obìnrin mìíràn tí Kristian ọkùnrin kan lóun nìkan kò lè yanjú dáradára. Nígbà tí ó ń tẹnu mọ́ ìníyelórí pípèsè irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, Paulu kọ̀wé pé: “Kí awọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí . . . jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere; kí wọ́n lè pe orí awọn ọ̀dọ́bìnrin wálé lati nífẹ̀ẹ́ awọn ọkọ wọn, lati nífẹ̀ẹ́ awọn ọmọ wọn, lati jẹ́ ẹni tí ó yèkooro ní èrò-inú, oníwàmímọ́, òṣìṣẹ́ ní ilé, ẹni rere, tí ń fi ara wọn sábẹ́ awọn ọkọ tiwọn, kí ọ̀rọ̀ Ọlọrun má baà di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.”—Titu 2:3-5.
12. Ìdarísọ́nà ta ni ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìjọ tẹ̀ lé?
12 Ẹ wo irú ìbùkún tí àwọn arábìnrin onírẹ̀lẹ̀ jẹ́ nínú ìjọ, nígbà tí wọ́n bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ṣètìlẹyìn fún àwọn ọkọ wọn àti àwọn alàgbà! (1 Timoteu 2:11, 12; Heberu 13:17) Àwọn alàgbà tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ ìdílé ní pàtàkì máa ń jàǹfààní nígbà tí gbogbogbòò bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ran ara wọn lọ́wọ́ lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú ẹmí ìfẹ́, àti nígbà tí gbogbo wọn bá juwọ́ sílẹ̀ fún ìdarísọ́nà àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí a yàn sípò.—1 Peteru 5:1, 2.
Ẹ̀yin Òbí, Kí Ni Ẹ Ń Fi Sí Ipò Kìíní?
13. Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn bàbá ṣe ń já àwọn ìdílé wọn kulẹ̀?
13 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, olùdánilárayá kan tí ó lókìkí ṣàkíyèsí pé: “Mo rí àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí tí wọ́n ń darí àwọn ilé iṣẹ́ tí ó ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ènìyàn nínú; wọ́n mọ bí a ti ń dojú kọ gbogbo ipò, bí a ti ń bá ni wí àti bí a tí ń san èrè fúnni nínú iṣẹ́ òwò. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ wọn tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí wọ́n ń darí ni ti ìdílé wọn, wọ́n sì ti kùnà.” Èé ṣe? Kì í ha ṣe nítorí pé wọ́n fi iṣẹ́ àti àwọn ohun agbanilọ́kàn mìíràn sí ipò kìíní, tí wọ́n sì pa ìmọ̀ràn Ọlọrun tì ni bí? Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo paláṣẹ . . . , kí ìwọ kí ó . . . máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ.” A sì ní láti máa ṣe é lójoojúmọ́. Àwọn òbí kò ní láti ṣahun àkókò wọn—àti ní pàtàkì ìfẹ́ àti àníyàn wọn tí ó jinlẹ̀.—Deuteronomi 6:6-9.
14. (a) Báwo ni àwọn òbí ṣe ní láti bójú tó àwọn ọmọ wọn? (b) Kí ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó tọ́ fún àwọn ọmọ ní nínú?
14 Bibeli rán wa létí pé àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jehofa. (Orin Dafidi 127:3) O ha ń bójú tó àwọn ọmọ rẹ bí i dúkìá Ọlọrun, ẹ̀bùn kan tí ó fi sí ìkáwọ́ rẹ bí? Ó ṣeé ṣe kí ọmọ rẹ dáhùn padà bí o bá fọwọ́ gbá a mọ́ra, tí ó tipa báyìí fi àbójútó onífẹ̀ẹ́ àti àfiyèsí rẹ hàn. (Marku 10:16) Ṣùgbọ́n láti “tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀” béèrè fún ju kìkì gbígbá a mọ́ra àti fífi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ. Láti múra rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n láti yẹra fún ọ̀fìn ìgbésí ayé, ọmọ kan nílò ìbáwí onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú. Òbí kan ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn nípa ‘wíwá ọmọ rẹ̀ láti bá a wí.’—Owe 13:1, 24, NW; 22:6.
15. Kí ni ó fi hàn pé ìbáwí àwọn òbí pọndandan?
15 Bí ìbáwí òbí ti ṣe pàtàkì tó ni a lè rí nínú bí olùgbaninímọ̀ràn ní ilé ẹ̀kọ́ kan ṣe ṣàpèjúwe àwọn ọmọ tí ń wá sí ọ́fíìsì rẹ: “Àánú wọn yóò ṣe ọ, wọn ní ìdààmú ọkàn, wọn kò sì ní ìrètí. Wọ́n ń sunkún bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ti rí. Ọ̀pọ̀—iye tí ó pọ̀ ju bí ẹnì kan ti lè rò lọ—ti gbìyànjú láti para wọn, kì í ṣe nítorí pé inú wọn dùn ní àdùnjù; ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí pé inú wọn kò dùn, a kò bìkítà nípa wọn, wọ́n sì ní ìkìmọ́lẹ̀ nítorí pé bí ọjọ́ orí wọn ti kéré tó, ohun tí ó pọ̀ jù fún wọn láti bójú tó ‘wà ní ìkáwọ́ wọn.’” Ó fi kún un pé: “Ó jẹ́ ohun tí ó bani lẹ́rù fún ọmọdé kan láti máa nímọ̀lára pé àwọn nǹkan wà ní ìkáwọ́ òun.” Lóòótọ́, àwọn ọmọ lè kọ ìbáwí, ṣùgbọ́n ní ti gidi, wọ́n mọrírì ìtọ́sọ́nà àti ìkálọ́wọ́kò àwọn òbí. Wọ́n láyọ̀ pé àwọn òbí wọn bìkítà tó láti pa ààlà fún wọn. Ọ̀dọ́langba kan tí àwọn òbí rẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ sọ pé: “Ó ti jẹ́ ohun ìtura fún mi.”
16. (a) Kí ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ kan tí a tọ́ dàgbà nínú ilé Kristian? (b) Èé ṣe tí ipa ọ̀nà tí ọmọ kan tí ó yàyàkuyà ń tọ̀ kò fi dandan túmọ̀ sí pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn òbí rẹ̀ fún un kò dára?
16 Síbẹ̀, láìka níní àwọn òbí tí ó nífẹ̀ẹ́ wọn, tí ó sì ń pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtàtà fún wọn sí, àwọn ọ̀dọ́mọdé kan, bí ọmọ onínàákúnàá nínú àkàwé Jesu, ń kọ ìtọ́sọ́nà òbí, wọ́n sì ń ṣìnà. (Luku 15:11-16) Bí ó ti wù kí ó rí, ìyẹn fúnra rẹ̀, lè máà túmọ̀ sí pé àwọn òbí kò ṣe ojúṣe wọn láti kọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí ó tọ́, gẹ́gẹ́ bí Owe 22:6 ṣe tọ́ni sọ́nà. Ọ̀rọ̀ náà nípa ‘títọ́ ọmọ ní ọ̀nà tí yóò tọ́, nígbà tí ó sì dàgbà tán, òun kì yóò kúrò nínú rẹ̀’ ni a fúnni gẹ́gẹ́ bí ìlànà gbogbogbòò. Ó bani nínú jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí ọmọ onínàákúnàá, àwọn ọmọ kan yóò ‘gan àtigbọ́ ti òbí.’—Owe 30:17.
17. Láti inú kí ni àwọn òbí àwọn ọmọ tí wọ́n ti yàyàkuyà ti lè rí ìtùnú?
17 Bàbá ọmọ kan tí ó ti yàyàkuyà kédàárò pé: “Mo ti gbìyànjú láti dé inú ọkàn rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. N kò mọ ohun tí mo lè ṣe mọ́, nítorí pé mo ti gbìyànjú ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan. Kò sí èyí tí ó ṣiṣẹ́.” Ìrètí wà pé, irú àwọn ọmọ tí wọ́n ti yàyàkuyà bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó bá yá, yóò rántí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n rí gbà, kí wọ́n sì padà gẹ́gẹ́ bí onínàákúnàá tí ṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, òtítọ́ náà ni pé àwọn ọmọ kan ń ṣọ̀tẹ̀, wọ́n sì ń hu ìwà pálapàla, èyí sì jẹ́ ìbànújẹ́ ńláǹlà fún àwọn òbí wọn. Àwọn òbí lè rí ìtùnú nínú mímọ̀ pé olùkọ́ títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tí ì gbé ayé rí pàápàá rí i tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́, Judasi Iskariotu, dà á. Ó sì dájú pé Jehofa fúnra rẹ̀ banú jẹ́ nígbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ rẹ̀ ẹ̀mí kọ ìmọ̀ràn rẹ̀, tí wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ láìjẹ́ pé Òun ni ó fà á.—Luku 22:47, 48; Ìṣípayá 12:9.
Ẹ̀yin Ọmọ—Ta ni Ẹ̀yin Yóò Wù?
18. Báwo ni àwọn ọmọ ṣe lè fi hàn pé àwọn ń fi Ọlọrun sí ipò kìíní?
18 Jehofa rọ ẹ̀yin ọmọdé pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí awọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Oluwa.” (Efesu 6:1) Àwọn ọmọdé ń fi Ọlọrun sí ipò kìíní nípa ṣíṣe èyí. Má ṣe ya aṣiwèrè! Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Aṣiwèrè gan ẹ̀kọ́ bàbá rẹ̀.” Má ṣe fi ìgbéraga rò pé o kò nílò ìbáwí. Òkodoro òtítọ́ náà ni pé, “ìran kan wà, tí ó mọ́ ní ojú ara rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò tí ì wẹ̀ ẹ́ nù kúrò nínú èérí rẹ̀.” (Owe 15:5; 30:12, American Standard Version) Nítorí náà tẹ́tí sí ìtọ́ni àtọ̀runwá—“gbọ́,” “gbà,” “má ṣe gbàgbé,” “fiyè sí,” ‘pa mọ́,’ “má sì ṣe kọ” àwọn àṣẹ àti ìbáwí àwọn òbí sílẹ̀.—Owe 1:8; 2:1; 3:1; 4:1; 6:20.
19. (a) Ìdí tí ó lágbára wo ni àwọn ọmọ ní láti ṣègbọràn sí Jehofa? (b) Báwo ni àwọn ọmọdé ṣe lè fi hàn pé àwọn ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun?
19 O ní ìdí lílágbára láti ṣègbọràn sí Jehofa. Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì ti fúnni ní àwọn òfin rẹ̀, títí kan òfin tí ó wà fún àwọn ọmọdé láti ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn, láti dáàbò bò ọ́ àti láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀. (Isaiah 48:17) Ó tún ti fúnni ní Ọmọkùnrin rẹ̀ láti kú fún ọ, kí a ba lè gbà ọ́ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kí o sì gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. (Johannu 3:16) O ha ń dúpẹ́ bí? Ọlọrun ń wò ọ́ láti ọ̀run wá, ó ń ṣàyẹ̀wò ọkàn rẹ láti rí i bí o bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní tòótọ́, tí o sì mọrírì àwọn ìpèsè rẹ̀. (Orin Dafidi 14:2) Satani náà ń wò ọ́, ó sì ń gan Ọlọrun, ní sísọ pé o kò ní ṣègbọràn sí I. Nígbà tí o bá ṣàìgbọràn sí Ọlọrun, o ń mu inú Satani dùn, ó sì ń “ba” Jehofa “nínú jẹ́.” (Orin Dafidi 78:40‚ 41) Jehofa ń rọ̀ ọ́ pé: “Ọmọ mi, kí ìwọ kí ó gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn [nípa jíjẹ́ onígbọràn sí mi]; kí èmi kí ó lé dá ẹni tí ń gàn mí lóhùn.” (Owe 27:11) Bẹ́ẹ̀ ni, ìbéèrè náà ni pé, Ta ni ìwọ yóò wù, Satani tàbí Jehofa?
20. Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe di ìgboyà mú láti sin Jehofa àní pàápàá nígbà tí ẹ̀rù ń bà á?
20 Kò rọrùn láti ṣèfẹ́ Ọlọrun lójú ìkìmọ́lẹ̀ tí Satani àti ayé rẹ̀ ń gbé kà ọ́ lórí. Ó lè bani lẹ́rù. Ọ̀dọ́ kan ṣàkíyèsí pé: “Bíbẹ̀rù dà bíi kí otútù máa múni. O lè ṣe nǹkan nípa rẹ̀.” Ó ṣàlàyé pé: “Nígbà tí òtútù bá ń mú ọ, ìwọ yóò wọ ẹ̀wù òtútù. Bí òtútù bá ṣì ń mú ọ, ìwọ yóò wọ òmíràn. Ìwọ yóò sì máa bá a lọ láti máa wọ nǹkan títí òtútù náà yóò fi lọ, tí kò sì ní mú ọ mọ́. Nítorí náà, gbígbàdúrà sí Jehofa nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà ọ́ dà bí wíwọ ẹ̀wù òtútù nígbà tí òtútù bá ń mú ọ. Bí ẹ̀rù bá ṣì ń bà mí lẹ́yìn gbígbàdúrà lẹ́ẹ̀kan, n óò gbàdúrà léraléra títí tí ẹ̀rù kì yóò fi bà mí mọ́. Ó sì ń ṣiṣẹ́. Ó ti yọ mí kúrò nínú ewu!”
21. Báwo ni Jehofa yóò ṣe tì wá lẹ́yìn bí a bá fi í sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa?
21 Bí a bá gbìyànjú láti fi Ọlọrun sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa ní tòótọ́, Jehofa yóò tì wá lẹ́yìn. Òun yóò fún wa lókun, nípa pípèsè ìrànwọ́ áńgẹ́lì nígbà tí àìní bá wà fún un, àní pàápàá bí ó ti ṣe fún Ọmọkùnrin rẹ̀. (Matteu 18:10; Luku 22:43) Gbogbo ẹ̀yin òbí àti ọmọ, ẹ ní ìgboyà. Ẹ ní ìbẹ̀rù bí i ti Kristi, yóò sì mú ìgbádùn wá fún yín. (Isaiah 11:3) Bẹ́ẹ̀ ni, “bẹ̀rù Ọlọrun kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́: nítorí èyí ni fún gbogbo ènìyàn.”—Oniwasu 12:13.
O Ha Lè Dáhùn Bi?
◻ Àwọn ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu ní ìgbàanì ní láti mú wà déédéé?
◻ Ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn Kristian òbí ní láti mú ṣẹ?
◻ Ìrànwọ́ wo ni ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn Kristian alàgbà tí wọ́n ní ìdílé?
◻ Iṣẹ́ tí ó níye lórí wo ni àwọn arábìnrin lè gbé ṣe nínú ìjọ?
◻ Ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà tí ó ṣe pàtàkì wo ni àwọn ọmọ ní láti tẹ́tí sí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, Kristian obìnrin kan tí ó dàgbà dénú lè pèsè ìrànlọ́wọ́ tí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan nílò fún un
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìtùnú wo ni àwọn òbí àwọn ọmọ tí wọ́n ti yàyàkuyà lè rí gbà láti inú Ìwé Mímọ́?