Ṣọ́ra Fún Jíjẹ́ Olódodo Lójú Ara Ẹni!
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìíní, àwọn Farisi gbádùn orúkọ rere ti jíjẹ́ olódodo olùjọ́sìn Ọlọrun. Wọ́n jẹ́ aláápọn, akẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, wọ́n sì máa ń gbàdúrà léraléra. Àwọn kan kà wọ́n sí oníwà pẹ̀lẹ́ àti afòyebánilò. Josephus òpìtàn Júù kọ̀wé pé: “Àwọn Farisi ní ìfẹ́ni sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, wọ́n sì ń mú ipò ìbátan tí a so pọ̀ ṣọ̀kan dàgbà pẹ̀lú àpapọ̀ àwùjọ.” Abájọ nígbà náà, tí ó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn ni ẹni tí a bọ̀wọ̀ fún jú lọ, tí a sì kà sí gidigidi láwùjọ àwọn Júù nígbà náà lọ́hùn-ún!
Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí ọ̀rọ̀ náà “bíi Farisi” àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fara pẹ́ ẹ buni kù, ó ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú onífọkànsìn àgàbàgebè, jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni, èrò ìwà-tèmi-lọ̀gá, onífọkànsìn àṣerégèé, àti aláàrékérekè. Èé ṣe tí àwọn Farisi fi pàdánù orúkọ rere wọn?
Ó jẹ́ nítorí pé, láìdà bí ọ̀pọ̀ àwọn Júù, ìrísí òde àwọn Farisi kò tan Jesu Kristi jẹ. Ó fi wọ́n wé “awọn sàréè tí a kùnlẹ́fun, tí wọ́n farahàn lóde bí ẹlẹ́wà nítòótọ́ ṣugbọn ní inú wọ́n kún fún egungun òkú ènìyàn ati gbogbo onírúurú ohun àìmọ́.”—Matteu 23:27.
Lóòótọ́, wọ́n ń gbàdúrà gígùn nígbà tí wọ́n bá ń dúró ní àwọn ibi gbàgede, ṣùgbọ́n èyí wulẹ̀ jẹ́ kí àwọn mìíràn baà lè rí wọn, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti wí. Arúmọjẹ lásán ni ìjọsìn wọn jẹ́. Wọ́n kúndùn àwọn ibi yíyọrí ọlá ní ibi oúnjẹ alẹ́ àti àwọn ìjókòó iwájú nínú sínágọ́gù. Bí ó tilẹ̀ di dandan fún gbogbo àwọn Júù láti so ìṣẹ́tí mọ́ ẹ̀wù wọn, àwọn Farisi gbìyànjú láti mú orí àwọn ènìyàn wú nípa síso àwọn ìṣẹ́tí gígùn gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ mọ́ ẹ̀wù wọn. Wọ́n ń fi àwọn akóló ìkówèémímọ́sí wọn, tí wọ́n ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí oògùn àsomọ́ra yangàn. (Matteu 6:5; 23:5-8) Àgàbàgebè wọn, ìwọra wọn, àti ìgbéraga wọn kó ìtìjú bá wọn nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Jesu kéde bí Ọlọrun ṣe kọ àwọn Farisi sílẹ̀ pé: “Ẹ̀yin alágàbàgebè, Isaiah sọtẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nipa yín, nígbà tí ó wí pé, ‘Awọn ènìyàn yii ń fi ètè wọn bọlá fún mi, síbẹ̀ ọkàn-àyà wọ́n jìnnà réré sí mi. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nitori pé wọ́n ń fi awọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.’” (Matteu 15:7-9) Ní ti gidi, ìwà òdodo wọn jẹ́ jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni. Lọ́nà bíbọ́gbọ́n mu, Jesu kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà awọn Farisi.” (Luku 12:1) Lónìí, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ “ṣọ́ra” fún jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni tàbí kí a dènà, dídi alágàbàgebè onísìn.
Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀sán kan òru kan ni ẹnì kan ń di olódodo lójú ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìtẹ̀sí yìí ń yọ́ wọlé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́. Kódà láìmọ̀, ẹnì kan lè ní àwọn ànímọ́ tí a kò fẹ́, ti àwọn Farisi.
Ìṣarasíhùwà Èmi-Lọ̀gá
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ tí a gbọ́dọ̀ “ṣọ́ra” fún? Ìwé gbédègbéyọ̀ náà Encyclopædia of Religion and Ethics ṣàlàyé pé, àwọn tí wọ́n jẹ́ olódodo lójú ara wọn sábà máa ń “sọ̀rọ̀, wọn a sì dúró, wọ́n a sì máa wò bí ẹni pé wọn kò tí ì hùwà àìtọ́ kankan rí.” Àwọn tí wọ́n jẹ́ olódodo lójú ara wọn tún máa ń fọ́nnu, wọ́n sì máa ń gbé ara wọn ga, èyí tí ó jẹ́ olórí ìṣòro àwọn Farisi.
Jesu ṣàpèjúwe ìṣarasíhùwà ti àwọn Farisi yìí pẹ̀lú àkàwé kan pé: “Awọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sínú tẹmpili lati gbàdúrà, ọ̀kan Farisi ati èkejì agbowó-orí. Farisi naa dúró ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà awọn nǹkan wọnyi sí ara rẹ̀, ‘Óò Ọlọrun, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé emi kò rí gẹ́gẹ́ bí awọn ènìyàn yòókù, awọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòdodo, panṣágà, tabi gẹ́gẹ́ bí agbowó-orí yii pàápàá. Mo ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì lọ́sẹ̀, mo ń fúnni ní ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí mo ní.’” Ní ìyàtọ̀ gédégbé agbowó orí náà fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba àwọn àṣìṣe rẹ̀, ó sì fi hàn pé òun jẹ́ olódodo ju Farisi afọ́nnu náà lọ. Jesu sọ àkàwé yìí fún àwọn tí wọ́n “gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn pé awọn jẹ́ olódodo tí wọ́n sì ka awọn yòókù sí aláìjámọ́ nǹkankan.”—Luku 18:9-14.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè máa nímọ̀lára pé a sàn ju àwọn mìíràn lọ nítorí àwọn ipá àdánidá àti àǹfààní tí a ní. Ṣùgbọ́n àwọn Kristian ní láti gbé irú èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn ní kíá mọ́sá. O lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìrírí ìgbésí ayé Kristian. O lè jẹ́ ọ̀jáfáfá olùkọ́ni ní Bibeli. Tàbí bóyá o ti sọ pé a ti fi àmì òróró yàn ọ́ láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní òkè ọ̀run. Àwọn kan nínú ìjọ ń gbádùn àwọn àǹfààní àkànṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, alàgbà, tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bí ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ni yóò jẹ́ èrò Jehofa bí mo bá lo ohun tí ó fún mi gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ láti rò pé mo ga lọ́lá ju àwọn yòókù lọ?’ Dájúdájú, èyí kì yóò dùn mọ́ ọn nínú.—Filippi 2:3, 4.
Nígbà tí Kristian kan bá fi ẹ̀mí ìgalọ́lá jù lọ hàn nítorí àwọn ipá, àǹfààní, tàbí ọlá àṣẹ tí Ọlọrun fún un, ní tòótọ́ ó ń ja Ọlọrun lólè ògo àti ìyìn tí ó yẹ fún Òun nìkan. Bibeli gba àwọn Kristian níyànjú lọ́nà tí ó ṣe kedere pé, ‘kí wọ́n máṣe ro ara wọn ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.’ Ó rọ̀ wá pé: “Ẹ máa ní èrò-inú sí awọn ẹlòmíràn ní ọ̀nà kan naa bí ẹ ti ní sí ara yín; ẹ máṣe máa gbé èrò-inú yín ka awọn ohun gíga fíofío, ṣugbọn kí a máa ṣamọ̀nà yín lọ pẹlu awọn ohun rírẹlẹ̀. Ẹ máṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n-inú ní ojú ara yín.”—Romu 12:3, 16.
“Ẹ Dẹ́kun Dídánilẹ́jọ́”
Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Bibeli kan ṣe sọ, olódodo lójú ara rẹ̀ “máa ń ka ara rẹ̀ sí adúróṣánṣán, yálà ní ti ọ̀nà ìwà híhù tàbí pé òun ní ìdúró tí ó tọ́ pẹ̀lú Ọlọrun, nítorí pé ó ń rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú òfin, láìbìkítà fún ohun tí wọ́n túmọ̀ sí.” Ìwé mìíràn ṣàpèjúwe olódodo lójú ara ẹni gẹ́gẹ́ bí “àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ aláṣerégèé ní ti ìsìn, tí wọ́n ń lo gbogbo àkókò wọn láti wá ìwà búburú àwọn ẹlòmíràn.”
Àwọn Farisi jẹ̀bi èyí. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn òfin àtọwọ́dá wọn dà bí ohun tí ó wá ṣe pàtàkì ju àwọn òfin àti ìlànà Ọlọrun lọ. (Matteu 23:23; Luku 11:41-44) Wọ́n yan ara wọn sípò gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́, wọ́n sì ní ìtẹ̀sí láti dá ẹnikẹ́ni tí kò bá bá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni tí wọ́n gbé kalẹ̀ mu lẹ́bi. Ìṣarasíhùwà èmi-lọ̀gá tí wọ́n ní àti iyì ara ẹni aláṣerégèé ṣokùnfà àìní náà láti máa darí àwọn ẹlòmíràn. Àìṣeé ṣe fún wọn láti darí Jesu bí wọn nínú, nítorí náà wọ́n gbìmọ̀ láti pa á.—Johannu 11:47-53.
Ẹ wo bí ó ti ń nini lára tó láti wà ní sàkání ẹnì kan tí ó gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́, tí ó máa ń wá àṣìṣe nígbà gbogbo, tí ó ń yẹ ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń bẹ láyìíká rẹ̀ wò, tí ó sì ń ṣọ́ wọ́n lọ́wọ́lẹ́sẹ̀. Ní ti gidi, kò sí ẹnì kankan nínú ìjọ tí ó ní ọlá àṣẹ láti gbé èro tirẹ̀ tàbí àwọn òfin àtọwọ́dá ti ara ẹni karí àwọn ẹlòmíràn. (Romu 14:10-13) Àwọn Kristian tí wọ́n wà déédéé mọ̀ pé, ọ̀pọ̀ apá ẹ̀ka ìgbésí ayé ojoojúmọ́ jẹ ìpinnu ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ní pàtàkì, àwọn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí láti jẹ́ olójú ìwòye ọ̀pá ìdiwọ̀n tèmi ò gbọdọ̀ yingin àti amúnilápàpàǹdodo gbọ́dọ̀ yẹra fún dídá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́.
Lóòótọ́, a fún ìjọ Kristian ní ọlá àṣẹ láti ní àwọn ìlànà tí yóò mú kí ètò àjọ Jehofa lórí ilẹ̀ ayé máa lọ ní mẹ̀lomẹ̀lọ. (Heberu 13:17) Ṣùgbọ́n àwọn kan ti yí àwọn ìlànà wọ̀nyí po tàbí ti fi àwọn òfin tiwọn kún un. Ní agbègbè kan, gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun ní láti wọ tòkètilẹ̀, kí wọ́n sì de bọ́tìnnì jákẹ́ẹ̀tì wọn nígbà tí wọ́n bá ń sọ àwíyé. Akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó bá sì kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀, ni a kì yóò jẹ́ kí ó sọ àwíyé ní ọjọ́ mìíràn. Kàkà tí a óò fi gbé irú àwọn òfin líle koko bẹ́ẹ̀ kalẹ̀, kì yóò ha túbọ̀ lọ́gbọ́n nínú, tí yóò sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun láti fúnni ní ìtọ́sọ́nà ara ẹni tí a nílò lọ́nà tí ó fi inúrere hàn bí?—Jakọbu 3:17.
Jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni tún lè gbé ojú ìwòye náà lárugẹ pé, bí Kristian kan bá ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro ara ẹni, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ pé ó kù díẹ̀ káàtó fún un ni, nípa tẹ̀mí. Ohun tí Elifasi, Bildadi, àti Sofari, tí wọ́n jẹ́ olódodo lójú ara wọn rò gan-an nípa Jobu olùṣòtítọ́ nìyẹn. Wọn kò mọ bí ipò náà ti rí gan-an, nítorí náà ó jẹ́ ìwà ìkùgbùù fún wọn láti fi ẹ̀sùn ìwà àìtọ́ kan Jobu. Jehofa bá wọn wí fún àyẹ̀wò tí a gbé gbòdì tí wọ́n ṣe nípa àdánwò Jobu.—Wo Jobu, orí 4, 5, 8, 11, 18, 20.
Ìtara Òdì
Jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni àti ìtara sábà máa ń ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Aposteli Paulu sọ nípa àwọn Júù tí wọn lẹ́mìí ìsìn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n ní “ìtara fún Ọlọrun; ṣugbọn kì í ṣe ní ìbámu pẹlu ìmọ̀ pípéye; nitori, fún ìdí naa pé wọn kò mọ òdodo Ọlọrun ṣugbọn tí wọ́n ń wá ọ̀nà lati gbé tiwọn kalẹ̀, wọn kò fi ara wọn sábẹ́ òdodo Ọlọrun.” (Romu 10:2, 3) Gẹ́gẹ́ bíi Farisi, Paulu fúnra rẹ̀ ti jẹ́ onítara àṣelékè, bí ó tilẹ̀ gbé ìtara rẹ̀ gbòdì, kò gbé e karí òdodo Jehofa.—Galatia 1:13, 14; Filippi 3:6.
Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, Bibeli gbani níyànjú pé: “Má ṣe òdodo àṣelékè; bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó má ṣe fi ara rẹ ṣe ọlọ́gbọ́n àṣelékè: nítorí kí ni ìwọ óò ṣe run ara rẹ?” (Oniwasu 7:16) Nínú ìjọ, Kristian kan lè fi tọkàntọkàn bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tí ń fi tọkàntọkàn àti ìtara ṣe lè yọrí sí jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni. Nígbà tí ọgbọ́n ẹ̀dá ènìyàn bá ń darí ẹní dípò òdodo Jehofa, ìtara ìsìn lè pa àwọn ẹlòmíràn lára. Báwo?
Fún àpẹẹrẹ, ọwọ́ àwọn òbí lè dí gan-an ní bíbójú tó àìní àwọn ẹlòmíràn nípa tẹ̀mí, ní ṣíṣe èyí, wọ́n lè pa àwọn àìní ìdílé tiwọn fúnra wọn tì. Tàbí kí àwọn òbí jẹ́ onítara aláṣerégèé, tí wọ́n ń fi dandan gbọ̀n béèrè nǹkan lọ́wọ́ àwọn ọmọ ju bí agbára wọn bá ṣe mọ lọ. (Efesu 6:4; Kolosse 3:21) Àwọn ọmọ kan, nígbà tí wọn kò bà lè kájú àwọn ohun tí a fi dandan gbọ̀n béèrè fún láìfòyebánilò bẹ́ẹ̀, ń hùwà padà nípa gbígbé ìgbésí ayé méjì. Òbí kan tí ń fòye báni lò yóò gba ohun tí agbára ìdílé rẹ̀ ká yẹ̀ wò, yóò sì ṣe àwọn àtúnṣe tí ó yẹ.—Fi wé Genesisi 33:12-14.
Ìtara àníjù tún lè fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ìfọ̀rànrora-ẹni-wò, àti jẹ̀lẹ́ńkẹ́ dù wá, àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ẹnì kan lè máa ṣiṣẹ́ kára láti mú kí àwọn ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú. Bí ó ti wù kí ó rí, ìtara àṣelékè rẹ̀ lè pa àwọn ènìyàn lára níbi tí ó ti ń fi hàn. Paulu wí pé: “Bí mo bá sì ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ tí mo sì di ojúlùmọ̀ gbogbo àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ ati gbogbo ìmọ̀, bí mo bá sì ní gbogbo ìgbàgbọ́ lati ṣí awọn òkè-ńlá nípò padà, ṣugbọn tí emi kò ní ìfẹ́, emi kò jámọ́ nǹkankan. Bí mo bá sì yọ̀ǹda gbogbo nǹkan ìní mi lati fi bọ́ awọn ẹlòmíràn, tí mo sì fi ara mi lénilọ́wọ́, kí emi baà lè ṣògo, ṣugbọn tí emi kò ní ìfẹ́, emi kò ní èrè rárá.”—1 Korinti 13:2, 3.
Ọlọrun Ń Fi Ojú Rere Hàn sí Àwọn Onírẹ̀lẹ̀
Gẹ́gẹ́ bíi Kristian, a ní láti lè dá ìwuléwu jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni mọ̀ ṣáájú kí ó tó bẹ̀rẹ̀. A gbọ́dọ̀ yẹra fún ìṣarasíhùwà èmi-lọ̀gá, ìwà dídá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́, àti ìtara tí a kò ronú lé lórí, tí a gbé karí ọgbọ́n ènìyàn.
Bí a ti ń “ṣọ́ra” fún ìṣarasíhùwà bíi ti àwọn Farisi, dípò tí a óò fi dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́ pé wọ́n jẹ́ olódodo lójú ara wọn, yóò jẹ́ ohun tí ó sàn jù láti pa àfiyèsí wa pọ̀ sórí àwọn ìtẹ̀sí àti ìsúnniṣe tiwa fúnra wa. Lóòótọ́, Jesu ṣèdájọ́ àwọn Farisi, ó sì dá wọn lẹ́bi pé wọ́n jẹ́ “àmújáde-ọmọ paramọ́lẹ̀,” tí wọ́n yẹ fún ìparun ayérayé. Ṣùgbọ́n Jesu lè mọ èrò ọkàn àwọn ènìyàn. Àwa kò lè ṣe bẹ́ẹ̀.—Matteu 23:33.
Ẹ jẹ́ kí a máa wá òdodo Ọlọrun, kì í ṣe tiwa fúnra wa. (Matteu 6:33) Nígbà náà nìkan ni a lè ní ojú rere Jehofa, nítorí Bibeli gba gbogbo wa níyànjú pé: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nìkínní kejì, nitori Ọlọrun kọ ojú ìjà sí awọn onírera, ṣugbọn ó ń fi inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún awọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 Peteru 5:5.