ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/15 ojú ìwé 26-30
  • William Tyndale Ọkùnrin Aríranjìnnà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • William Tyndale Ọkùnrin Aríranjìnnà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbésẹ̀ Ìgbàgbọ́
  • Fífàáké Kọ́rí—Èé Ṣe?
  • Ó Di Europe, Àwọn Ìṣòro Tuntun Jẹ Yọ
  • Àṣeyọrí—Láìka Àtakò Sí
  • Lílọ sí Antwerp, Dídà Á, àti Ikú Rẹ̀
  • Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ibi Ìsádi Fún Títẹ Bíbélì
    Jí!—2002
  • Wọ́n Mọyì Bíbélì—Díẹ̀ Nínú Ìtàn William Tyndale
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Wọ́n Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/15 ojú ìwé 26-30

William Tyndale Ọkùnrin Aríranjìnnà

A bí William Tyndale ní England, “ní ààlà Wales,” ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ní Gloucestershire, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ọ̀gangan ibẹ̀ àti ọjọ́ náà gan-an. Ní October 1994, England ṣàjọyọ̀ àjọ̀dún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ọjọ́ ìbí ọkùnrin náà tí “ó pèsè Bibeli lédè Gẹ̀ẹ́sì fún wa.” Nítorí iṣẹ́ yìí ni a ṣe pa Tyndale. Èé ṣe?

WILLIAM TYNDALE ta yọ nínú ẹ̀kọ́ Griki àti Latin. Ní July 1515, nígbà tí kò tí ì ju ẹni ọdún 21 lọ, ó gba oyè ìjìnlẹ̀ kejì ní Oxford University. Nígbà tí yóò fi di 1521, a ti fi í joyè àlùfáà Roman Katoliki. Nígbà yẹn, ìsìn Katoliki fa ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ní Germany nítorí ìgbòkègbodò Martin Luther. Ṣùgbọ́n England ṣì jẹ́ orílẹ̀-èdè Katoliki títí tí Ọba Henry Kẹjọ fi gé okùn àjọṣe tí ń bẹ láàárín òun àti Romu ní 1534.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì wọ́ pọ̀ nígbà ayé Tyndale, Latin ni a fi ń kọ́ni ní gbogbo ẹ̀kọ́. Òun tún ni èdè ṣọ́ọ̀ṣì àti Bibeli. Ní 1546, Ìgbìmọ̀ Trent tẹnu mọ́ ọn pé, ìtumọ̀ Latin Vulgate ti Jerome, ti ọ̀rúndún karùn-ún, nìkan ṣoṣo ni a óò máa lò. Ṣùgbọ́n, kìkì àwọn ọ̀mọ̀wé nìkan ni ó lè kà á. Èé ṣe tí a fi ní láti fi ẹ̀tọ́ níní Bibeli ní èdè Gẹ̀ẹ́sì àti kíkà á du àwọn ará England? Kókó àríyànjiyàn Tyndale ni pé: “Bí Jerom[e] bá lè túmọ̀ bibeli sí èdè ìbílẹ̀ rẹ̀: èé ṣe tí àwa pẹ̀lú kò fi lè ṣe bẹ́ẹ̀?”

Ìgbésẹ̀ Ìgbàgbọ́

Lẹ́yìn àkókò tí ó lò ní Oxford, bóyá tí ó sì fi kẹ́kọ̀ọ́ sí i ní Cambridge, Tyndale kọ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin John Walsh fún ọdún méjì ní Gloucestershire. Ní àkókò yìí ó mú ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ dàgbà láti túmọ̀ Bibeli sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, kò sì sí iyèméjì pé ó ní àǹfààní láti mú òye iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìtumọ̀ dàgbà sí i pẹ̀lú ìrànwọ́ Bibeli tuntun tí Erasmus ṣe, tí ó ní Griki àti Latin ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Ní 1523, Tyndale fi ìdílé Walsh sílẹ̀, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí London. Ète rẹ̀ ni láti gba ìyọ̀ǹda fún ìtúmọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Cuthbert Tunstall, bíṣọ́ọ̀bù London.

Ọlá àṣẹ Tunstall pọn dandan nítorí pé, àfilélẹ̀ tí ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn ní Oxford ṣe ní 1408, tí a mọ̀ sí Òfin Oxford, ní ìfòfinde ìtumọ̀ tàbí kíka Bibeli ní èdè ìbílẹ̀ nínú, àyàfi bí bíṣọ́ọ̀bù bá fọwọ́ sí i. Nítorí gbígbójúgbóyà láti rú òfin yìí, a dáná sun ọ̀pọ̀ oníwàásù arìnrìn àjò tí a mọ̀ sí Lollard, gẹ́gẹ́ bí aládàámọ̀. Àwọn Lollard wọ̀nyí ka Bibeli John Wycliffe, ìtumọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì kan láti ìtumọ̀ Vulgate, wọ́n sì pín in kiri. Tyndale rò pé, àkókò náà ti dé, láti túmọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ Kristian láti Griki sí ẹ̀dà tuntun tí ó ṣeé gbàgbọ́, fún ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, àti àwọn ará England.

Ọ̀mọ̀wé tó pójú owó ni Bísọ́ọ̀bù Tunstall, ẹni tí ó ti ṣe gudugudu méje láti fún Erasmus níṣìírí. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí òye iṣẹ́ rẹ̀ fúnra rẹ̀, Tyndale ti túmọ̀ ọ̀kan lára àwọn afọ̀ amẹ̀sọ Isocrates, ìwé Griki kan tí ó le, kí Tunstall lè fọwọ́ sí i. Ó dá Tyndale lójú hán-ún hán-ún pé, Tunstall yóò bá òun dọ́rẹ̀ẹ́, yóò ti òun lẹ́yìn, yóò sì tẹ́wọ́ gba èrò òun láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́. Kí ni bíṣọ́ọ̀bù náà yóò ṣe?

Fífàáké Kọ́rí—Èé Ṣe?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Tyndale ní lẹ́tà tí ń sọ ohun tí ó bá wá, Tunstall kò gbà kí ó wọlé. Nítorí náà, Tyndale ní láti kọ̀wé béèrè fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. A kò mọ̀ bóyá Tunstall gbà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti pàdé Tyndale, ṣùgbọ́n èsì rẹ̀ ni pé, ‘Ilé mi kún.’ Èé ṣe tí Tunstall fi mọ̀ọ́nmọ̀ fojú pa Tyndale rẹ́ bẹ́ẹ̀?

Iṣẹ́ alátùn-únṣe tí Luther ń ṣe ní àgbáálá ilẹ̀ Europe ń kó àníyàn ńláǹlà bá Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki, pẹ̀lú àwọn ìyọrísí ní England. Ní 1521, Ọba Henry Kẹjọ tẹ àkọsílẹ̀ lílágbára jáde tí ń gbèjà póòpù lòdì sí Luther. Láti lè fi ìmoore hàn, póòpù fi òye “Agbèjà Ìgbàgbọ́” dá Henry lọ́lá.a Kádínà Wolsey, ti Henry, pẹ̀lú jẹ́ ògbóṣáṣá, ní dídáná sun àwọn ìwé, tí Luther kó wọlé láìbófin mu láti ilẹ̀ òkèèrè. Gẹ́gẹ́ bíi bíṣọ́ọ̀bù Katoliki tí ó dúró ṣinṣin ti póòpù, ọba, àti kádínà rẹ̀, ojúṣe Tunstall ni láti tẹ èrò èyíkéyìí tí ó bá lè bá Luther ọlọ̀tẹ̀ kẹ́dùn rì. Tyndale ni olórí ẹni tí a fura sí. Èé ṣe?

Nígbà tí ó ń gbé pẹ̀lú ìdílé Walsh, Tyndale ti fi tìgboyàtìgboyà sọ̀rọ̀ lòdì sí àìmọ̀kan àti orí kunkun àwùjọ àlùfáà àdúgbò. Lára wọn ní John Stokesley, tí ó ti mọ Tyndale ní Oxford. Ó rọ́pò Cuthbert Tunstall gẹ́gẹ́ bíi bíṣọ́ọ̀bù London lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Àtakò sí Tyndale hàn gbangba nígbà tí ó ko àlùfáà onípò gíga kan lójú, ẹni tí ó wí pé: “Ì bá dára kí a wà láìsí òfin Ọlorun, ju kí a wà láìsí òfin póòpù.” Nínú àwọn ọ̀rọ̀ mánigbàgbé rẹ̀, èsì Tyndale ni pé: ‘Mo pe Póòpù àti gbogbo òfin rẹ̀ níjà. Bí Ọlọrun bá dá ẹ̀míì mi sí, kí ọ̀pọ̀ ọdún tó kọjá, èmi yóò jẹ́ kí ọ̀dọ́mọkùnrin tí ń wa ohun èlò ìtúlẹ̀ mọ apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ ju bí o ti mọ̀ ọ́n lọ.’

Tyndale ní láti fara hàn níwájú alákòóso ẹkùn bíṣọ́ọ̀bù ti Worcester lórí ẹ̀sùn èké ti àdámọ̀. Lẹ́yìn náà, Tyndale rántí pé: “Ó fìyà jẹ mí gidigidi, ó sì kẹ́gàn mi,” ó fi kún un pé, a hùwà sí òun bí “ajá.” Ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí kankan láti dá Tyndale lẹ́bi lórí ẹ̀sùn àdámọ̀. Àwọn òpìtàn gbàgbọ́ pé, a fi gbogbo ọ̀ràn yìí tó Tunstall létí ní bòókẹ́lẹ́ láti lè nípa ìdarí lórí ìpinnu rẹ̀.

Lẹ́yìn tí ó ti lo ọdún kan ní London, Tyndale parí èrò sí pé: “Kò sí àyè ní ààfin kábíyèsí ní London láti túmọ̀ Májẹ̀mú tuntun, ṣùgbọ́n kò sì sí . . . àyè láti ṣe é ní England.” Kò purọ́. Nínú àyíká ipò ìkìmọ́lẹ̀ tí iṣẹ́ Luther fà, òǹtẹ̀wé wo ní England ni yóò lórí láyà láti tẹ Bibeli jáde lédèe Gẹ̀ẹ́sì? Nítorí náà, ní 1524, Tyndale ré Ààlà Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọjá, kò sì padà wá mọ́.

Ó Di Europe, Àwọn Ìṣòro Tuntun Jẹ Yọ

Pẹ̀lú àwọn ìwé ṣíṣeyebíye rẹ̀, William Tyndale rí ibi ìsádi ní Germany. Ó mú pọ́nùn mẹ́wàá tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Humphrey Monmouth, oníṣòwò pàtàkì kan ní London, fi inú rere fún un dání. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ẹ̀bùn yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó fún Tyndale láti tẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Griki tí ó pinnu láti túmọ̀. Lẹ́yìn èyí, a fàṣẹ ọba mú Monmouth fún gbígbárùkù ti Tyndale, àti fún bíbá Luther kẹ́dùn. A fọ̀rọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, a sì jù ú sí ẹ̀wọ̀n Ilé Gogoro ti London, a dá Monmouth sílẹ̀ kìkì lẹ́yìn tí ó kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí Kádínà Wolsey fún ìdáríjì.

A kò mọ ibi pàtó tí Tyndale lọ ní Germany. Àwọn ẹ̀rí kan tọ́ka sí Hamburg, níbi tí ó ti lè lo ọdún kan. Ó ha bá Luther pàdé bí? Èyí kò dájú, àní bí ẹ̀sùn tí a fi kan Monmouth tilẹ̀ sọ pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun kan tí ó dájú ni pé: Ọwọ́ Tyndale dí fún títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Griki. Níbo ni yóò ti rẹ́ni bá a tẹ ìwé rẹ̀? Ó fa iṣẹ́ náà lé Peter Quentell lọ́wọ́ ní Cologne.

Gbogbo nǹkan lọ déédéé títí tí John Dobneck alátakò, tí a tún mọ̀ sí Cochlaeus, fi mọ̀ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Lójú ẹsẹ̀ ní Cochlaeus fi àwárí rẹ̀ tó ọ̀rẹ́ kò rí kò sùn Henry Kẹjọ kan létí, ẹni tí ó gba àṣẹ ìgbẹ́sẹ̀lé náà ní kánmọ́, kí Quentell má ṣe tẹ ìtumọ̀ tí Tyndale ṣe.

Tyndale àti adelé rẹ̀, William Roye, sá àsálà fún ẹ̀mí wọn, wọ́n sì mú àwọn ojú ìwé Ìhìn Rere Matteu tí a ti tẹ̀ lọ́wọ́. Wọ́n tukọ̀ kọjá odò Rhine sí Worms, níbi tí wọ́n ti parí iṣẹ́ wọn. Nígbà tí ó ṣe, a mú 6,000 ẹ̀dá ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ti Májẹ̀mú Tuntun ti Tyndale jáde.b

Àṣeyọrí—Láìka Àtakò Sí

Ìṣòro kan ni títúmọ̀ àti títẹ̀wé. Òmíràn ni bí Bibeli náà yóò ṣe dé Britain. Àwọn aṣojú ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn aláṣẹ tí kì í ṣe ti ìsìn pinnu láti dènà kíkó o ré kọjá Ààlà Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ṣùgbọ́n àwọn oníṣòwò oníwà bí ọ̀rẹ́ ní ojútùú kan. Ní dídì í mọ́ ìgàn aṣọ àti àwọn ọjà mìíràn, a yọ́ kó àwọn ìdìpọ̀ náà wọ etíkun England títí fi dé Scotland. Ó fún Tyndale ní ìṣírí, ṣùgbọ́n ìjàkadì rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.

Ní February 11, 1526, Kádínà Wolsey, pẹ̀lú àwọn bíṣọ́ọ̀bù 36 àti àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn ní ṣọ́ọ̀ṣì, péjọ pọ̀ ní Kàtídírà Paulu Mímọ́ ní London “láti rí dídáná sun àwọn agbọ̀n tí ó kún fún ìwé.” Àwọn ẹ̀dà ìtumọ̀ ṣíṣeyebíye ti Tyndale kan wà nínú wọn. Nínú ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ yìí, ẹyọ méjì péré ni ó wà nísinsìnyí. Ọ̀kan ṣoṣo tí ó pé pérépéré (ojú ìwé orúkọ ìwé náà nìkan ni kò ní) wà ní Ilé Àkójọ Ìwé Britain. Ó yani lẹ́nu pé, èkejì, tí ojú ìwé 71 ti sọnù níbẹ̀, ni a rí ní Ilé Àkójọ Ìwé ti Kàtídírà Paulu Mímọ́. Bó ṣe débẹ̀, ẹnikẹ́ni kò lè sọ.

Láìfòyà, Tyndale ń bá mímú ìtẹ̀jáde tuntun ti ìtumọ̀ rẹ̀ jáde, tí àwùjọ àlùfáà ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń fọgbọ́n gbẹ́sẹ̀ lé, tí wọ́n sì ń dáná sun. Lẹ́yìn náà, Tunstall yíwọ́ rẹ̀ padà. Ó wọnú àdéhùn pẹ̀lú oníṣòwò kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Augustine Packington láti ra ìwé èyíkéyìí tí Tyndale bá kọ, títí kan Májẹ̀mú Tuntun, láti lè dáná sun wọ́n. A bá Tyndale ṣètò èyí, ẹni tí Packington ti bá ṣe àdéhùn. Ìwé Chronicle ti Halle sọ pé: “Bíṣọ́ọ̀bù ló gbàwé, Packington ló gbọpẹ́, Tyndale ló sì gbowó. Lẹ́yìn náà, nígbà tí a tẹ́ Májẹ̀mú Tuntun púpọ̀ sí i, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ dé sí England.”

Èé ṣe tí àwùjọ àlùfáà fi ta ko ìtumọ̀ Tyndale lọ́nà rírorò bẹ́ẹ̀? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtumọ̀ Latin Vulgate dagọ̀ bo ọ̀rọ̀ ẹsẹ ìwé mímọ́, fún ìgbà àkọ́kọ́, ìtumọ̀ Tyndale láti inú Griki ìpilẹ̀ṣẹ̀ gbé ìhìn iṣẹ́ Bibeli jáde fún àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní èdè ṣiṣe kedere. Fún àpẹẹrẹ, Tyndale yàn láti túmọ̀ ọ̀rọ̀ Griki náà a·gaʹpe sí “ìfẹ́” dípò “inú rere” nínú 1 Korinti orí 13. Ó rinkinkin mọ́ “ìjọ” dípò “ṣọ́ọ̀ṣì” láti tẹnu mọ́ àwọn olùjọsìn, kì í ṣe àwọn ilé ṣọ́ọ̀ṣì. Ṣùgbọ́n, kókó abájọ tí àwùjọ àlùfáà kò lè fara dà mọ́ dé nígbà tí Tyndale fi “alàgbà” rọ́pò “àlùfáà,” tí ó sì lo “ronú pìwà dà” dípò “ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀,” tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gba agbára tí àwùjọ àlùfáà gbé wọ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà lọ́wọ́ wọn. David Daniell sọ nípa èyí pé: “Pọ́gátórì kò sí níbẹ̀; kò sí ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti iṣẹ́ ìrònúpìwàdà. Méjì lára igi lẹ́yìn ọgbà fún ọrọ̀ àti agbára Ṣọ́ọ̀ṣì wó.” (William Tyndale—A Biography) Ìpèníjà tí ìtumọ̀ Tyndale gbé kalẹ̀ nìyẹn, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ òde òní sì fọwọ́ sí ìpéye ìlò èdè rẹ̀.

Lílọ sí Antwerp, Dídà Á, àti Ikú Rẹ̀

Láàárín 1526 sí 1528, Tyndale ṣí lọ sí Antwerp, níbi tí ó ti lè gbé láìséwu láàárín àwọn oníṣòwò ọmọ ilẹ́ Gẹ̀ẹ́sì. Níbẹ̀ ni ó ti kọ ìwé The Parable of the Wicked Mammon, The Obedience of a Christian Man, àti The Practice of Prelates. Tyndale ń ba iṣẹ́ ìtumọ̀ rẹ̀ lọ, òun sì ni ó kọ́kọ́ lo orúkọ Ọlọrun, Jehofa, nínú ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Orúkọ náà fara hàn ju ìgbà 20 lọ.

Níwọ̀n ìgbà tí Tyndale ṣì ń bá ọ̀rẹ́ àti olóore rẹ̀ Thomas Poyntz gbé ní Antwerp, ó bọ́ lọ́wọ́ ìdìtẹ̀ Wolsey àti àwọn amí rẹ̀. A mọ̀ ọ́n bí ẹni mowó fún àbójútó rẹ̀ fún àwọn aláìsàn àti àwọn òtòṣì. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọmọ England náà, Henry Phillips, fi ọgbọ́n àrékérekè fa ojú Tyndale mọ́ra. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ní 1535, a da Tyndale, a sì mú un lọ sí Ilé Olódi Vilvorde, kìlómítà mẹ́wàá sí àríwá Brussels. A fi sí àhámọ́ níbẹ̀, fún oṣù 16.

A kò lè fi pẹ̀lú ìdánilójú sọ ẹni tí ó bẹ Phillips lọ́wẹ̀, ṣùgbọ́n a fura sí Bíṣọ́ọ̀bù Stokesley, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dí nígbà náà fún dídáná sun “àwọn aládàámọ̀” ní London. Nígbà tí ó wà ní bèbè ikú ní 1539, W. J. Heaton nínú ìwé náà, The Bible of the Reformation, sọ pé, Stokesley “dunnú pé òun ti dáná sun àádọ́ta àwọn aládàámọ̀ nígbà ayé òun.” William Tyndale wà lára àwọn aládàámọ̀ tí ó dáná sun náà, ẹni tí a yí lọ́rùn, kí a tó dáná sun ara rẹ̀ ní gbangba ní October 1536.

Mẹ́ta lára àwọn ọ̀mọ̀wé nínú ẹ̀kọ́ ìsìn tí wọ́n yọrí ọlá, láti Louvain University ti àwọn Katoliki, níbi tí Phillips ti kàwé, wà lára ìgbìmọ̀ tí ó gbẹ́jọ́ Tyndale. Àlùfáà mẹ́ta láti Louvain àti bíṣọ́ọ̀bù mẹ́ta pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn mìíràn pésẹ̀ láti rí bí a ṣe dá Tyndale lẹ́bi fún àdámọ̀, tí a sì gba ipò àlùfáà rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ikú rẹ̀ ní ẹni ọdún 42 dùn mọ́ gbogbo wọn nínú.

Ní nǹkan tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, òǹkọ̀wé ìtàn ìgbésí ayé, Robert Demaus, wí pé: “Tyndale di gbajúmọ̀ nígbà gbogbo nítorí àìlábòsí aláìṣojo rẹ̀.” Tyndale kọ̀wé sí John Frith, alájọgbìmọ̀ rẹ̀ tí Stokesley dáná sun ní London, pé: “Èmi kò fìgbà kankan rí yí ègé ọ̀rọ̀ kan nínú ọ̀rọ̀ Ọlọrun padà láti hùwà lòdì sí ẹ̀rí ọkàn mi, n kò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí, àní bí a óò bá fún mi ní gbogbo ohun tí ń bẹ ní ayé, yálà adùn, ọlá, tàbí ọrọ̀.”

Bí William Tyndale ṣe fi ìgbésí ayé rẹ̀ lélẹ̀ fún àǹfààní fífún àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní Bibeli tí wọ́n lè tètè lóye nìyẹn. Ẹ wo irú ìrúbọ tí ó ṣe—àmọ́ ẹ wo irú ẹ̀bùn aláìṣeé díyelé tí ó jẹ́!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kò pẹ́ kò jìnnà, a ń tẹ Fidei Defensor sára owó ilẹ̀ àkóso náà, Henry sì ní kí a máa fi oyè yìí da àwọn àtẹ̀lé òun lọ́lá. Lónìí ó yí orí aláyélúwà tí ó wà lára owó ilẹ̀ Britain ká gẹ́gẹ́ bíi Fid. Def., tàbí ní ṣókí F.D. Ó dùn mọ́ni pé, a tẹ “Agbèjà Ìgbàgbọ́” lẹ́yìn náà sínú Bibeli King James Version ti 1611, ní yíyà á sí mímọ́ fún Ọba James.

b Iye yìí kò dáni lójú; àwọn aláṣẹ kan sọ pé 3,000 ni.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

ÌTUMỌ̀ ÌGBÀ ÌJÍMÌJÍ

ÌJÍRẸ̀Ẹ́BẸ̀ tí Tyndale ṣe fún títúmọ̀ Bibeli sí èdè tí àwọn mẹ̀kúnnù lóye, kì í ṣe èyí tí kò lọ́gbọ́n nínú tàbí tí a kò rí irú rẹ̀ rí. A ṣe ìtumọ̀ kan sí èdè Anglo-Saxon ní ọ̀rúndún kẹwàá. Àwọn Bibeli tí a tẹ̀ jáde, tí a sì túmọ̀ láti Latin ti wà káàkiri Europe láìsí ìdíwọ́ ní òpin ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún: èdè German (1466), èdè Italian (1471), èdè French (1474), èdè Czech (1475), èdè Dutch (1477), àti èdè Catalan (1478). Ní 1522, Martin Luther tẹ Májẹ̀mú Tuntun jáde ní èdè German. Kìkì ohun tí Tyndale béèrè ni pé, èé ṣe tí kò fí yẹ kí a gba England láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Bibeli ni ó wà lẹ́yìn rẹ̀: © The British Library Board; William Tyndale: Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da onínúure Principal, Fellows, and Scholars of Hertford College, Oxford

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́