ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/15 ojú ìwé 30
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
  • Jèhófà Gbé Orúkọ Rẹ̀ Lékè
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/15 ojú ìwé 30

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ní Filippi 2:9, Paulu sọ nípa Jesu pé: “Ọlọrun . . . gbé e sí ipò gíga . . . ó sì fi inúrere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.” Kí ni orúkọ tuntun yìí? Bí Jesu bá sì rẹlẹ̀ sí Jehofa, báwo ni orúkọ Jesu ṣe lékè gbogbo orúkọ mìíràn?

Filippi 2:8, 9 kà pé: “Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó [Jesu] rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró. Fún ìdí yii gan-an pẹlu ni Ọlọrun fi gbé e sí ipò gíga tí ó sì fi inúrere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.”

Àyọkà yìí kò túmọ̀ sí pé, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Jehofa nìkan ni ó ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn pátápátá, Jesu gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹnì kan náà pẹ̀lú Jehofa. Bí àyíká ọ̀rọ̀ Filippi orí 2 ti fi hàn, Jesu gba orúkọ rẹ̀ tí a gbé ga, lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀. Ṣáájú ìgbà náà, kò tí ì ní in. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, Jehofa ti fìgbà gbogbo jẹ́ ẹni gíga lọ́lá jù lọ, ipò rẹ̀ kò sì tí ì yí padà. Òkodoro òtítọ́ náà pé, Jesu gba orúkọ kan tí ó ga lọ́lá ju orúkọ tí ó ní ṣáájú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé jẹ́rìí pé kì í ṣe ẹni kan náà pẹ̀lú Jehofa. Nígbà tí Paulu wí pé a fún Jesu ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, ó ní in lọ́kàn pé, nísinsìnyí, Jesu ní orúkọ tí ó ga lọ́lá jú lọ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọrun.

Kí ni orúkọ Jesu tí ó ga lọ́lá? Isaiah 9:6 ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn. Nígbà tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Messia tí ń bọ̀ náà, Jesu, ẹsẹ náà sọ pé: “Ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀: a óò sì máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun Alágbára, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Níhìn-ín, “orúkọ” Jesu ní í ṣe pẹ̀lú ipò gíga rẹ̀ àti ọlá àṣẹ rẹ̀, tí ó jẹ́ bákan náà pẹ̀lú bí a ṣe lóye “orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn,” tí a mẹ́nu kàn ní Filippi 2:9 sí. A pàṣẹ fún gbogbo eékún láti tẹ̀ ba fún Jesu, ní mímọyì ọlá àṣẹ onípò gíga tí Jehofa ti fún un—ipò ọlá àṣẹ tí ó ga ju èyí tí a fún ẹ̀dá mìíràn lọ. Ọ̀rọ̀ náà “mìíràn” nínú ìtumọ̀ yìí kò sí nínú ìpìlẹ̀ ẹsẹ ìwé Griki ní tààràtà, ṣùgbọ́n, òye ẹsẹ náà ni a fi túmọ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀. “Orúkọ” Jesu kò lékè orúkọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n ó lékè orúkọ gbogbo ẹ̀dá mìíràn.

Ẹ wo bí a ti kún fún ayọ̀ tó láti dara pọ̀ mọ́ àwọn áńgẹ́lì àti ẹ̀dá ènìyàn ní títẹ eékún ba, ní mímọyì orúkọ Jesu! A ń ṣe èyí nípa fífi ara wa sábẹ́ Jesu nínú ipò alágbára, tí a sì gbé ga, tí Jehofa fún un—“fún ògo Ọlọrun Baba.”—Filippi 2:11; Matteu 28:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́