Ẹni Ọgọ́rùn-ún Ọdún Tí Ń ta Kébékébé
GẸ́GẸ́ BÍ RALPH MITCHELL ṢE SỌ Ọ́
Bàbá mi, ọkùnrin kan tí ó ga mọ níwọ̀n, jẹ́ oníwàásù Mẹ́tọ́díìsì. A ń gbé e láti ṣọ́ọ̀ṣì kan sí òmíràn lọ́dún méjìméjì tàbí mẹ́tamẹ́ta, àti láti ìlú kékeré kan sí òmíràn, títí dé Asheville, North Carolina, U.S.A., níbi tí a bí mi sí ní February 1895. Nítorí náà, mo gbọ́njú mọ Kirisẹ́ńdọ̀mù dáradára.
MO RÁNTÍ pé a darí mi gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin kan lọ sórí “àga aṣọ̀fọ̀” ní àwọn ìpàdé ìsọjí láti lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà—láti “gba ìsìn,” gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń pè é. A ní kí n jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, kí n pa Òfin Mẹ́wàá mọ́, kí n sì jẹ́ ẹni rere. Nípa báyìí, èmi yóò lè lọ sọ́run tí mo bá kú. Mo sọ fún ara mi pé, ‘Ó dára, mo tànmọ́ ọ̀n pé, n óò lọ sí ọ̀run àpáàdì nítorí pé n kò lè dára tó ẹni tí yóò lọ sọ́run.’ Mo ronú pé àwọn àgbà nìkan—ní pàtàkì àwọn oníwàásù—ní ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli.
Ṣùgbọ́n, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí àgàbàgebè nínú ìsìn àní, ṣáájú kí n tó di ọ̀dọ́langba. Fún àpẹẹrẹ, bàbá mi yóò pa àìní nípa ti ara ti ìdílé rẹ̀ tì, kìkì láti lè gbé owó ńlá kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí owó bíṣọ́ọ̀bù ní ìpàdé àpérò gbogbogbòò. Ó rò pé èyí yóò mú kí a yan òun sí ṣọ́ọ̀ṣì tí ó tóbi sí i. Mo rántí oníwàásù kan tí ó tún jẹ́ àgbẹ̀ olówùú. Ó hára gàgà láti rí ipò yíyọrí ọlá, nítorí náà, ó ta ọgọ́rùn-ún ìdì òwú, ó sì gbé owó tabua lọ sí ìpàdé àpérò gbogbogbòò. Lẹ́yìn tí ó dà bíi pé wọ́n ti gba gbogbo owó tí wọ́n lè rí gbà tán lọ́wọ́ àwùjọ—tí púpọ̀ nínú wọn jẹ́ oníwàásù—oníwàásù tí ó jẹ́ àgbẹ̀ olówùú yìí fò dìde, ó sì kígbe pé: “Ṣé gbogbo ohun tí ẹ óò fún bíṣọ́ọ̀bù yín nìyí? Èmi yóò gbé dọ́là mẹ́wàá kalẹ̀ dípò dọ́là márùn-ún tí oníwàásù kọ̀ọ̀kan bá san!” Ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan dọ́là tí wọ́n rí gbà, bíṣọ́ọ̀bù sì yan ọkùnrin yìí láti jẹ́ alàgbà alábòójútó lórí bàbá mi. Èmi kò lè gbà gbọ́ pé irú ìyànsípò bẹ́ẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Láti ìgbà náà lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa ohunkóhun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn.
A fi tìpátìkúùkù sọ mí di ológun nígbà tí United States kó wọnú Ogun Àgbáyé Kìíní. Mo rántí dáradára bí àlùfáà ológun náà ti ń wàásù fún àwa sójà pé kí a fi ìṣòtítọ́ jà fún orílẹ̀-èdè wa, èyí sì wulẹ̀ mú kí ìkórìíra mi fún ìsìn túbọ̀ ga sí i. Góńgó mi ni kí n yè bọ́, kí n parí ẹ̀kọ́ mi, lẹ́yìn náà kí n gbéyàwó. N kò ronú nípa ìsìn rárá.
Ìṣarasíhùwà Yí Padà
Ní 1922, ìfẹ́ omidan kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Louise, kó sí mi lórí. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, òún jẹ́ Kátólíìkì olùfọkànsìn, nígbà tí a sì pinnu láti ṣègbéyàwó, òún ń fẹ́ ìgbéyàwó Kátólíìkì. Ó dára, èmi kò fẹ́ ayẹyẹ ìsìn irú èyíkéyìí, nítorí náà, ó gbà pé, a óò gbéyàwó nínú ilé ìlú ńlá ní New York City.
Lákọ̀ọ́kọ́, a kò ní èdèkòyedè nítorí ìsìn. Mo wulẹ̀ fi yé e kedere pé, n kò ní ìgbọ́kànlé kankan nínú ìsìn, àti pé a óò máa gbádùn ara wa lọ, níwọ̀n bí a kò bá ti mẹ́nu kàn án. Lẹ́yìn náà, láàárín ọdún 1924 sí 1937, àwọn ọmọ bẹ̀rẹ̀ sí í dé—lọ́kọ̀ọ̀kan, títí tí a fi ní ọmọkùnrin márùn-ún àti ọmọbìnrin márùn-ún! Louise fẹ́ kí àwọn ọmọ wa lọ sí ilé ìwé Kátólíìkì. N kò fẹ́ kí wọ́n ní irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ ìsìn èyíkéyìí, nítorí náà, a jiyàn nípa ìyẹn.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ 1939, ohun kan ṣẹlẹ̀ tí yóò yí ojú ìwòye mi nípa ìsìn padà pátápátá. Méjì nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, Henry Webber àti Harry Piatt wá sí ilé mi ni Roselle, New Jersey. Ó hàn gbangba lójú ẹsẹ̀ pé, wọ́n fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa kókó ẹ̀kọ́ náà tí n kò nífẹ̀ẹ́ láti jíròrò—ìsìn. A ti ba ìgbàgbọ́ mi jẹ́ nípa òkodoro òtítọ́ náà pé àlùfáà ológun náà sọ pé, ‘Ẹ jà fún orílẹ̀-èdè yín,’ nígbà tí àwọn onísìn nílé lọ́hùn-ún sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.’ Ẹ wo irú àgàbàgebè tí èyí jẹ́! Mo rò pé, n óò lè tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí méjì wọ̀nyí sọ́nà. Mo sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí n sọ ohun kan fún-un yín. Bí ìsìn yín bá jẹ́ òtítọ́, nígbà náà, èké ni gbogbo àwọn yòókù. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ọ̀kan ṣoṣo péré nínú àwọn yòókù bá jẹ́ òtítọ́, nígbà náà, èké ni gbogbo àwọn ìsìn yòókù títí kan tiyín. Ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ni ó lè wà.” Ó yà mí lẹ́nu gidigidi pé wọ́n gbà pẹ̀lú mi!
Lẹ́yìn náà, wọ́n ní kí n gbé Bibeli mi, kí n sì ṣí i sí 1 Korinti 1:10. Níbẹ̀ mo kà pé: “Mo sì bẹ̀ yín, ará, ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi, kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ohun kan náà, àti kì ìyapa kí ó má ṣe sí nínú yín; ṣùgbọ́n kí a lè ṣe yín pé ní inú kan náà, àti ní ìmọ̀ kan náà.” (King James Version) Ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí fà mí lọ́kàn mọ́ra. Bákan náà, mo ń bẹ̀rù pé, àwọn ọkùnrin méjì yìí ń gbìyànjú láti mú mi wọnú ẹgbẹ́ awo kan. Síbẹ̀ mo ti kọ́ ohun kan—pé, kò yẹ kí ìyapa wà láàárín àwọn Kristian. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè míràn ń bẹ lọ́kàn mi. Fún àpẹẹrẹ, Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn nígbà ikú? Ẹ wo bí n óò ti nífẹ̀ẹ́ láti jíròrò ìbéèrè yẹn pẹ̀lú wọn tó! Ṣùgbọ́n, mo rò pé ìyẹn yóò dá ọ̀pọ̀ awuyewuye ìsìn sílẹ̀ nílé.
Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin méjì náà sọ pé: “A óò fẹ́ láti padà wá ní ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀ láti tún bá ọ sọ̀rọ̀.” Mo fẹ́ fi ọgbọ́n yẹ̀ wọ́n sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìyàwó mi fọhùn. Ó wí pé: “Ralph, wọ́n fẹ́ mọ ìgbà tí wọ́n lè padà wá.” Èyí yà mí lẹ́nu, níwọ̀n bí òun ti jẹ́ Kátólíìkì onítara! Síbẹ̀, mo ronú pé, ‘Bóyá ní àbárèbábọ̀, a lè fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn kókó kan lórí ọ̀ràn ìsìn.’ Nítorí náà, mo gbà pé, kí Henry Webber àti Harry Piatt padà wá ní Friday tí ó tẹ̀ lé e.
Báyìí ni mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn èyí, a ké sí mi láti pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ kan ni Gbàgede Ọgbà Madison ní New York City. Mo rántí ní kedere, àwíyé Joseph F. Rutherford náà, “Ìjọba àti Àlááfíà,” tí ó sọ ní June 25, 1939. Mo wà lára àwọn 18,000 ènìyàn tí ó pésẹ̀. Ní ti gidi, 75,000 ni ó gbọ́ àwíyé náà, bí o bá ka àwọn tí a fi ètò àsopọ̀ onítẹlifóònù àti rédíò yíká ayé so pọ̀ mọ́ ọn.
Ṣùgbọ́n, àwọn nǹkan kò fara rọ. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn àlùfáà Kátólíìkì, Charles Coughlin, ti halẹ̀ láti da àpéjọ náà rú, bí ó sì ti rí gan-an, nígbà tí àwíyé Arákùnrin Rutherford dé ìdajì, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn onírunú ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, wọ́n sì ń kígbe àwọn ọ̀rọ̀ bíi, “Ti Hitler ni ìgbàlà!” àti “Kí Franco pẹ́!” Rúkèrúdò náà pọ̀ débi pé, a lè gbọ́ ariwo ìdàrúdàpọ̀ náà lórí tẹlifóònù! Ó gba àwọn adènà tó ìṣẹ́jú 15 láti kápá àwùjọ ènìyànkénìyàn náà. Ní gbogbo àsìkò yìí, Arákùnrin Rutherford ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ láìfòyà, bí àtẹ́wọ́ léraléra láti ọ̀dọ̀ àwùjọ ti ń fún un ní ìṣírí.
Nísinsìnyí, mo fẹ́ rí fìn-ín ìdí kókò. Èé ṣe tí àlùfáà Kátólíìkì kan yóò fi ru ìkórìíra tí ó tó bẹ́ẹ̀ sókè lòdì sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? Mo wòye pe, òtítọ́ ní láti wà nínú ohun tí Rutherford ń wàásù—ohun kan tí àwùjọ àlùfáà náà kò fẹ́ kí àwọn ènìyàn bíi tèmi gbọ́. Nítorí náà, mo ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ, mo sì ń tẹ̀ síwájú. Níkẹyìn ní October 1939, mo fi ìyàsímímọ́ mi fún Jehofa hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọ mi ṣe ìrìbọmi ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, Louise, aya mi, sì ṣe ìrìbọmi ní 1941.
Dídojú Kọ Àdánwò
Láìpẹ́ lẹ́yìn tí mo tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ìyá mi dolóògbé, mo sì ní láti padà sí North Carolina fún ìsìnkú rẹ̀. Mo ronú pé, n kò lè fi ẹ̀rí ọkàn rere pésẹ̀ sí ibi ìsìnkú náà tí a óò ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì. Nítorí náà, kí n tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò, mo tẹ bàbá mi láago, mo sì sọ fún un pé, kí ó fi pósí náà sílẹ̀ sí ilé ìsìnkú. Ó gbà, ṣùgbọ́n nígbà tí mo débẹ̀, wọ́n ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, níbi tí wọ́n rò pé, láìsí tàbí ṣùgbọ́n, n óò dara pọ̀ mọ́ wọn.
Tóò, n kò ṣe bẹ́ẹ̀, èyí sì dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ nínú ìdílé mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi àti Edna arábìnrin mi ti fìgbà gbogbo jẹ́ kòríkòsùn, ó bá mi yodì lẹ́yìn ìsìnkú Màmá. Mo kọ lẹ́tà púpọ̀, ṣùgbọ́n kò fèsì. Gbogbo ìgbà ẹ̀rùn tí Edna bá wá sí New York fún ẹ̀kọ́ àwọn olùkọ́ ní City College ni mo máa ń gbìyànjú láti rí i. Ṣùgbọ́n yóò kọ̀ láti yọjú sí mi, ní sísọ pé ọwọ́ òún dí. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó sú mi, níwọ̀n bí ó ti dà bíi pé mo wulẹ̀ ń yọ ọ́ lẹ́nu ni. Ọ̀pọ̀ ọdún kọjá kí n tún tó gbúròó rẹ̀.
Ní 1941, a lé mẹ́fà nínú àwọn ọmọ mi kúrò ní ilé ìwé, nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti kí àsíá, gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ ọmọ mìíràn ní United States àti Canada. Kí ó ba lè ṣeé ṣe láti dójú ìlà ohun tí òfin béèrè ní ti ìmọ̀ ẹ̀kọ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò àwọn ilé ìwé tiwọn fúnra wọn, tí a pè ní Kingdom Schools. Ilé ìtura kan tẹ́lẹ̀ rí ní Lakewood, New Jersey, ni ọ̀gangan ilé ìwé tí àwọn ọmọ mi ń lọ. Gbọ̀ngàn Ìjọba kan wà ní àjà kìíní pẹ̀lú yàrá ilé ìwé, ilé ìdáná àti ibi ìjẹun. Yàrá àwọn ọmọbìnrin wà ní àjà kejì, yàrá àwọn ọmọkùnrin sì wà ní àjà kẹta. Ilé ìwé náà dára. Òpin ọ̀sẹ̀ ni púpọ̀ àwọn ọmọ tí ń gbé ibẹ̀ máa ń lọ sílé. Àwọn tí ń gbé ibi tí ó túbọ̀ jìnnà máa ń lọ sílé ní ọ́sẹ̀ méjìméjì.
Láti ìgbà àwọn ọdún àkọ́kọ́ mi nínú òtítọ́, mo ní ìfẹ́ ọkàn mímúná láti di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ajíhìnrere alákòókò kíkún. Ní àpéjọpọ̀ 1941, ní St. Louis, Missouri, arákùnrin kan tí ó ní iṣẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sọ nípa bí òun ṣe lè ṣe aṣáájú ọ̀nà nígbà tí òun ń tọ́ ọmọ 12. Mo ronú pé, ‘Bí òun bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú ọmọ 12, mo lè ṣe aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú ọmọ 10.’ Bí ó ti wù kí ó rí, ipò mi kò gbà mí láyè láti bẹ̀rẹ̀ aṣáájú ọ̀nà títí di ọdún 19 lẹ́yìn náà. Níkẹyìn, ní October 1, 1960, ó ṣeé ṣe fún mi láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sin Jehofa gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé.
Ìbẹ̀wò Àgbàyanu Kan
Ní 1975, mo gba ìkésíni orí fóònù láti ọ̀dọ̀ arábìnrin mi Edna. Mo ti di ẹni 80 ọdún nísinsìnyí, n kò sì tíì rí i tàbí gbọ́ ohùn rẹ̀ fún nǹkan bí 20 ọdún. Ó ń ké sí mi láti ibùdókọ̀ òfuurufú, ó sọ pé kí n wá gbé òun àti ọkọ òun. Mo láyọ̀ láti tún rí Edna lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu tí ó pabambarì ṣì kù. Bí a ti ń lọ sílé, ọkọ rẹ̀ sọ pé, “O ní ẹnì kan tí ó ti yí padà.” N kò mọ ohun tí ó ní lọ́kàn. Nígbà tí a délé, ó tún sọ lẹ́ẹ̀kan sí i pé, “Ẹnì kan tí ó ti yí padà ń bẹ níhìn ín.” Ìyàwó mi lóye rẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Ní yíyíjú sí arábìnrin mi, ó béèrè pé, “Edna, Ẹlẹ́rìí ha ni ọ́ bí?” Edna dáhùn pé: “Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni.”
Báwo ni Edna ṣe tẹ́wọ́ gba òtítọ́? Ó dára, ní 1972, nínú ìsapá mi láti ṣe àtúnṣe ipò ìbátan wa tí kò dán mọ́rán, mo fi ẹ̀bùn àsansílẹ̀ owó Ilé-Ìṣọ́nà ránṣẹ́ sí i. Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, Edna ṣàìsàn, a sì gbé e lọ sí ilé rẹ̀. Àwọn ìwé ìròyìn náà ṣì wà nínú àpò ìwé wọn lórí àpótí ìwé rẹ̀. Láti rí fìn-ín ìdí kókò, Edna ṣí ọ̀kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Lẹ́yìn kíka ìwé ìròyìn náà tán, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Òtítọ́ náà rèé!’ Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò fi ṣèbẹ̀wò sílé rẹ̀, ó ti ka gbogbo ìdì ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà náà tán. Ó tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kò pẹ́ kò jìnnà, ó di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Kíkojú Àdánù
Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àrùn àtọ̀gbẹ kọlu Louise aya mi, ipò rẹ̀ sì túbọ̀ burú sí i títí di 1979, nígbà tí ó kú ní ẹni ọdún 82. Nígbà tí Louise kú, apá kan mi kú pẹ̀lú. Gbogbo ayé mi dúró gbagidi. N kò mọ ohun tí mo lè ṣe. N kò ní ìwéwèé kankan fún ọjọ́ ọ̀la, mo sì nílò ìṣírí gan-an. Richard Smith, alábòójútó arìnrìn àjò kan, fún mi níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi lọ. Mo rí i pé, ìtùnú gíga jù lọ tí mo ní wá láti inú títu àwọn mìíràn tí wọ́n ti pàdánù àwọn olólùfẹ́ wọn nínú ikú nínú.
Ní 1979, Watch Tower Society ń ṣètò ìrìn àjò sí Israeli, nítorí náà, mo forúkọ sílẹ̀. Ìrìn àjò yìí jẹ́ ìṣírí ńláǹlà fún mi, nígbà tí mo sì padà délé, mo padà lọ tààràtà láti ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Ní gbogbo ọdún kọ̀ọ̀kan láti ìgbà náà wa, mo ti sọ ọ́ di ẹrù iṣẹ́ mi láti ṣèrànwọ́ ní àgbègbè ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni tàbí tí a kì í ṣe déédéé ní apá ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè náà. Láìka pé mo ti darúgbó sí, mo ṣì lè mú ara mi wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àǹfààní yìí.
Mo díwọ̀n rẹ̀ pé láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, mo ti láyọ̀ láti ran àwọn 50 ènìyàn lọ́wọ́ sí ojú ọ̀nà ìyè. Púpọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọ mi wà nínú òtítọ́. Méjì lára àwọn ọmọbìnrin mi ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Louise Blanton tí í ṣe ọmọbìnrin mi mìíràn ń sìn pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, George, ní orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ní Brooklyn, New York, ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin mi sì ti ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Àmọ́, nítorí àìpé tí a jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, gbogbo wa lè ṣàìsàn a sì lè kú. (Romu 5:12) Ó dájú pé ìgbésí ayé mi kò tí ì bọ́ lọ́wọ́ ìwóra àti ìrora. Lọ́wọ́lọ́wọ́, àrùn làkúrègbé ń bá mi jà ní ẹsẹ̀ òsì mi. Nígbà míràn, ó máa ń ni mí lára gan-an, ṣùgbọ́n kò tí ì dá mi gúnlẹ̀. Mo sì gbàdúrà pé kí ó má ṣe bẹ́ẹ̀. Mo fẹ́ máa báṣẹ́ lọ. Ìfẹ́ ọkàn mi gíga jù lọ ni láti máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà títí dé òpin, ní ṣíṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti sọ orúkọ àti ète Jehofa di mímọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Pẹ̀lú Rita, ọmọbìnrin mi