O Ha Ní Ẹ̀mí Fífúnni Bí?
OHA ti ṣàkíyèsí pé, ẹ̀mí tí ń sún àwọn ènìyàn láti fúnni ju ẹyọ kan lọ bí? Ẹ̀bùn lè jẹ́ fífi ìfẹ́, ìwà ọ̀làwọ́, àti ìmọrírì hàn. Síbẹ̀, o kò ha ti ṣàkíyèsí pé, ẹ̀bùn tún lè wá láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan tí ó fẹ́ kí a fi ojú rere wo òun bí? Tàbí a tilẹ̀ lè fúnni kìkì nítorí a lérò pé ó jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe tàbí nítorí pé, ẹni tí ń fúnni náà ń fẹ́ ohun kan tí a óò fi san án padà.
Ẹ̀bùn náà lè wà nínú ẹrù tí a fi ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ mèremère dì. Ṣùgbọ́n, kì í ha í ṣe òtítọ́ pé, ẹ̀bùn dáradára kan tún lè jẹ́ ìdìpọ̀ òdòdó, oúnjẹ àrà ọ̀tọ̀ kan, tàbí ìṣe onínúure bí? Ní tòótọ́, ẹ̀bùn tí a sábà máa ń mọrírì lọ́nà jíjinlẹ̀ jù lọ, sábà máa ń ní í ṣe pẹ̀lú fífi ara ẹni fúnni.
O Ha Ń Wá Ojú Rere Ẹnì Kan Bí?
Kì í ṣe ohun tuntun kí a fún ẹnì kan tí a ń wá ojú rere rẹ̀ lẹ́bùn. Ní àwọn ilẹ̀ kan, ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń wọ́nà láti fa ọkàn ẹni tí ó ṣeé ṣe kí ó di ìyàwó rẹ̀ mọ́ra, lè mú òdòdó wá fún un. Ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n obìnrin náà lóye ré kọjá ẹ̀bùn náà. Ó ń ronú nípa bóyá ẹ̀mí tí ń bẹ lẹ́yìn ẹ̀bùn ọ̀dọ́kùnrin náà jẹ́ onífẹ̀ẹ́, tí yóò mú kí ó jẹ́ ọkọ rere pẹ̀lú. Irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀, bí ó bá fi ẹ̀mí oníwà-bí-Ọlọ́run hàn, lè yọrí sí ayọ̀ púpọ̀ fún ẹni tí ó fúnni àti ẹni tí a fún.
Bibeli sọ nípa àkókò kan, nígbà tí Abigaili, aya Nabali, yára pèsè ẹ̀bùn ọlọ́làwọ́ fún Dafidi, tí òún mọ̀ pé Ọlọrun ti yàn láti di ọba Israeli ní ọjọ́ iwájú. Òun pẹ̀lú wá ojú rere. Ọkọ rẹ̀ ti gan Dafidi, ó sì ti ṣépè fún àwọn ọkùnrin Dafidi. Gẹ́gẹ́ bí olórí ẹgbẹ́ nǹkan bí 400 ọmọ ogun, Dafidi ti múra láti lọ pa Nabali àti agbo ilé rẹ̀ run. Abigaili dá sí i, ó fi ẹ̀bùn ìpèsè oúnjẹ ọlọ́làwọ́ ṣọwọ́ sí Dafidi, fún àwọn ọkùnrin rẹ̀, ní kíá mọ́sá. Òun fúnra rẹ̀ dé tẹ̀ lé ẹ̀bùn rẹ̀, lẹ́yìn tí ó sì ti bẹ̀bẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ nítorí ohun tí ọkọ rẹ̀ ṣe, bí ó ṣe bá Dafidi jíròrò fi ẹ̀rí ìwòyemọ̀ ńláǹlà hàn.
Ète rẹ̀ gbámúṣe, àbájáde rẹ̀ sí dára. Dafidi tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn rẹ̀, ó sì wí fún un pé: “Gòkè lọ ní àlàáfíà sí ilé rẹ, wò ó, èmi ti gbọ́ ohùn rẹ, inú mi sì dùn sí ọ.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, lẹ́yìn tí Nabali kú, àní Dafidi tún ṣètò láti fẹ́ Abigaili, ó sì fi tayọ̀tayọ̀ gbà.—1 Samueli 25:13-42.
Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àwọn ọ̀ràn kan, ojú rere tí ẹnì kan ń wá lè ní ṣíṣe ojúsàájú nínú, àní yíyí ìdájọ́ òdodo po pàápàá. Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ẹ̀bùn náà jẹ́ àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Olùfúnni náà rò pé òun yóò jàǹfààní, ṣùgbọ́n ó fi ìbàlẹ̀ ọkàn du ara rẹ̀. Ewu pé àwọn mìíràn lè mọ̀ máa ń fìgbà gbogbo wà, pé a lè ní kí òún wá sọ tẹnu òun. Àní bí a bá ṣe ojú rere tí ó ń fẹ́ náà, ẹni náà tí ń wá a lè rí i nísinsìnyí pé, òún ti di ẹni tí a lè gbé ìbéèrè dìde sí ìsúnniṣe rẹ̀. Ní gbígbé ọgbọ́n Ọlọrun yọ, Bibeli kìlọ̀ lòdì sí irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀.—Deuteronomi 16:19; Oniwasu 7:7.
Ẹ̀bùn Náà Ha Tọkàn Wá Bí?
Kò sí iyè méjì nípa rẹ̀ pé—fífún ẹnì kan tí o nífẹ̀ẹ́ ní nǹkan nítorí pé o fẹ́ bẹ́ẹ̀, ń mú ayọ̀ púpọ̀ wá ju fífúnni nítorí pé àwọn mìíràn mú kí o rò pé o ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ.
Ní tí kíkó àwọn ìpèsè ìrànwọ́ jọ fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ aláìní nípa ti ara, aposteli Paulu fi àwọn ìlànà dídára lélẹ̀ ní ti fífúnni. Ó kọ̀wé pé: “Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹlu ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹlu ohun tí ènìyàn kò ní.” Ó fi kún un pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí oun ti gbèrò pinnu ninu ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìlọ́tìkọ̀ tabi lábẹ́ àfipáṣe, nitori Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Korinti 8:12; 9:7) Nípa báyìí, èyí tí ó pọ̀ jù kù sọ́wọ́ọ̀ rẹ. Dípò jíjẹ gbèsè lórí fífúnni lẹ́bùn yàà, o ha ń ṣe bí o ti mọ bí? Kàkà kí o ronú pé ó di dandan gbọ̀n láti fúnni, kìkì nítorí ìkìmọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tàbí ti ìṣòwò, o ha ń ṣe ohun tí o ti pinnu ní ọkàn rẹ bí? Ní ti àwọn Kristian ìjímìjí tí ó lo irú àwọn ìlànà Ọlọrun bẹ́ẹ̀, Paulu kọ̀wé pé: “Awọn lati inú ìdánúṣe awọn fúnra wọn ń bẹ̀ wá ṣáá pẹlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere ati fún ìpín ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ tí a ti yántẹ́lẹ̀ fún awọn ẹni mímọ́.”—2 Korinti 8:4.
Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ìyẹn, ìròyìn Royal Bank Letter ti November/December 1994 sọ nípa àwọn ọ̀sẹ̀ tí ó ṣáájú Kérésìmesì pé: “A lè rí àkókò náà gẹ́gẹ́ bí ipò arùmọ̀lárasókè àtọwọ́dá, tí ire ọrọ̀ ajé ru sókè láti lè rọ àwọn olùrajà láti ra àwọn nǹkan tí wọn kì bá tí rà.” Bí a bá rà á láwìn, ìtẹ́lọ́rùn èyíkéyìí tí a lè rí láti inú fífúnni ní ẹ̀bùn náà lè tètè pòórá, nígbà tí àkókò bá tó láti san gbèsè náà.
Kí Ní Jẹ Ọ́ Lógún—Ayẹyẹ Náà? Tàbí Fífi Ìfẹ́ Hàn?
O ha rí i pé o sábà máa ń fúnni lẹ́bùn nígbà àwọn ayẹyẹ tí ó dà bí ẹní béèrè fún un bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè máa pàdánù ayọ̀ púpọ̀ tí fífúnni láìrò tẹ́lẹ̀ lè mú wá.
Inú ọ̀pọ̀ ènìyàn kì í dùn sí àwọn ìyọrísí fífúnni lẹ́bùn ní àwọn ọjọ́ kan pàtó. Ìyá kan, tí ó tún jẹ́ òǹkọ̀wé, sọ pé ìwọra máa ń hàn lára àwọn ọmọ òun bí ọjọ́ náà tí wọ́n ń retí ẹ̀bùn ti ń sún mọ́lé. Ó gbà pé a ba ìgbádùn tí òun ì bá rí nínú ẹ̀bùn rèterète kan jẹ́, nítorí pé, ohun mìíràn ni òún ń retí. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìròyìn sọ pé, àwọn àkókò họlidé tí ó kún fún àríyá àti ṣíṣe pàṣípààrọ̀ ẹ̀bùn tún jẹ́ àkókò ìsoríkọ́ ti ìmí ẹ̀dùn púpọ̀ àti ìmukúmu.
Lẹ́yìn tí ó ṣàkíyèsí pé, gbígbé ìtẹnumọ́ karí fífúnni lẹ́bùn nígbà họlidé nígbà míràn máa ń nípa lórí àwọn ọmọdé lọ́nà tí kò dára, ọ̀jọ̀gbọ́n kan lórí ìfìṣemọ̀rònú ẹ̀dá, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ yọ nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times, dámọ̀ràn pé: “Ronú nípa fífúnni ní ẹ̀bùn díẹ̀ ní àwọn ọjọ́ mìíràn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti dín másùnmáwo kù.” O ha rò pé ìyẹn yóò ní ipa rere bí?
Tammy, ọmọ ọdún 12 nínú agbo ilé kan tí kì í ṣe Kérésìmesì àti ọjọ́ ìbí, kọ̀wé pé: “Ó ń dùn mọ́ni púpọ̀ jù láti rí ẹ̀bùn gbà nígbà tí o kò retí rẹ̀ rárá.” Ó wí pé, dípò fífúnni ní ẹ̀bùn lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, àwọn òbí òun ń fún òun àti arákùnrin òun ní ẹ̀bùn yípo ọdún. Ṣùgbọ́n ohun kan wà tí ó ṣe pàtàkì fún un ju àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyẹn lọ. Bí ó ṣe wí, “Mo ní ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀.”
Ìwé náà, Secrets of Strong Families, sọ ní ṣàkó pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ń lo àkókò àti owó ní ọ̀pọ̀ ìgbà lọ́dún ní yíyan ẹ̀bùn tí ó yẹ wẹ́kú fún ọjọ́ ìbí, àjọ̀dún tàbí họlidé fún àwọn ènìyàn tí a fẹ́ràn. Ẹ̀bùn tí ó dára jù lọ kì yóò náni ní kọ́bọ̀. O kò sì ní láti fi nǹkan wé e. Bí o bá gbà gbọ́, bí àwọn ènìyàn púpọ̀ jù lọ, pé ìwàláàyè rẹ ni ohun ìní ṣíṣeyebíye jù lọ tí o ní, nígbà náà, díẹ̀ lára àkókò rẹ ni ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye jù lọ tí o lè fúnni. A ń fúnni lẹ́bùn ṣíṣeyebíye náà nínú iye àkókò wa tí a ń fún àwọn tí a fẹ́ràn.”
O lè jẹ́ kí fífúnni náà lọ ré kọjá ìdílé tìrẹ fúnra rẹ. Fífúnni láìrò tẹ́lẹ̀ láti kúnjú àìní kan tí ó hàn gbangba tí àwọn ẹlòmíràn ní, lè mú ìtẹ́lọ́rùn àkànṣe wá. Jesu Kristi rọ̀ wá láti fi irú ìbìkítà onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn fún àwọn òtòṣì, àwọn amúkùn-ún, àwọn afọ́jú, ó sì fi kún un pé: “Iwọ yoo sì láyọ̀, nitori tí wọn kò ní nǹkankan lati fi san án padà fún ọ.”—Luku 14:12-14.
Ìwé agbéròyìnjáde Rockland Journal-News (U.S.A.) sọ àpẹẹrẹ irú fífúnni bẹ́ẹ̀ láìpẹ́ yìí. Nígbà tí ilé obìnrin àgbàlagbà afọ́jú kan wó, àwọn ọ̀rẹ́ kọ́ ilé tuntun fún un. Àwọn onírúurú ilé iṣẹ́ ṣètọrẹ, ilé iṣẹ́ aṣojú ìjọba ìbílẹ̀ sì gbé owó kalẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde náà wí pé: “Ṣùgbọ́n, èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, nǹkan bí 150 ènìyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí púpọ̀ jù lọ lára wọn ń lọ sí ìjọ Haverstraw ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, yọ̀ọ̀da àkókò wọn láti kọ́ ilé náà.”
Ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà ń bá a lọ pé: “Àwọn ìtòpelemọ ohun èlò tí ó fẹ̀gbẹ́ ti tábìlì tí oúnjẹ kún fọ́fọ́ wà lórí ilẹ̀ ilé náà. Ní ọjọ́ méjì, àwọn òṣìṣẹ́ náà kọ́ ilé alájà mẹ́ta tí ó gba ìdílé méjì. . . . A mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún agbára wọn láti yára kọ́lé. . . . Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ìyárakọ́lé bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ìwàpẹ́títí iṣẹ́ wọn: láti fi iṣẹ́ onífẹ̀ẹ́ pèsè ohun tí ó lè tọ́jọ́. Ìyá ààfin Blakely lè máà lè fojú rí ilé rẹ̀ tuntun, ṣùgbọ́n ó lè fi ọwọ́ rẹ̀ kàn án, ọkàn rẹ̀ sì mọ bí ìgbésẹ̀ aláìmọtara-ẹni-nìkan yìí ti sún un tó.”
Ẹ̀mí Ọ̀làwọ́ Jálẹ̀ Ọdún
Àwọn ẹlẹ́mìí ọ̀làwọ́ ní tòótọ́ kì í dúró de àwọn ọjọ́ àkànṣe. Wọn kò gbé ìgbésí ayé wọn karí ara ẹni. Nígbà tí wọ́n bá rí nǹkan rere gbà, wọ́n ń gbádùn ṣíṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Èyí kò túmọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ afidandangbọ̀n-fúnni-lẹ́bùn. Kò túmọ̀ sí pé wọ́n ń fúnni débi pé àwọn ìdílé wọn yóò jìyà rẹ̀. Kò túmọ̀ sí pé wọ́n ń fúnni láìronú nípa ipá tí yóò ní lórí ẹni tí wọ́n fún. Síbẹ̀, wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n “sọ fífúnni dàṣà,” bí Jesu ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.—Luku 6:38.
Wọ́n mọ ipò àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà, tí wọ́n ń ṣàìsàn, tàbí tí wọ́n nílò ìṣírí ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn. “Ẹ̀bùn” wọn lè jẹ́ lílọ bá wọn ra nǹkan tàbí ṣíṣèrànwọ́ láti ṣe iṣẹ́ ilé. Ó lè jẹ́ líla igi tàbí kíkó yìnyín kúrò. Ó lè jẹ́ oúnjẹ aládùn kan tí a sè tàbí àkókò wákàtí kan láti ṣèbẹ̀wò àti láti kàwé papọ̀. Ìgbésí ayé wọn lè kún fún iṣẹ́, ṣùgbọ́n ọwọ́ wọn lè máà dí jù láti ranni lọ́wọ́. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí pe ní tòótọ́, “ayọ̀ púpọ̀ wà ninu fífúnni ju èyí tí ó wà ninu rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Àmọ́ ṣáá o, Olùfúnni títóbi jù lọ ni Ẹlẹ́dàá wa, Jehofa Ọlọrun. Ó “fún gbogbo ènìyàn ní ìyè ati èémí ati ohun gbogbo.” (Ìṣe 17:25) Nínú Bibeli, ó tún pèsè òye inú fún wa nípa ète rẹ̀ láti fòpin sí ìwà ibi, àìsàn àti ikú, àti láti sọ ilẹ̀ ayé yìí di Paradise. (Orin Dafidi 37:10, 11; Ìṣípayá 21:4, 5) Nígbà tí wọ́n kọ́ nípa èyí, àwọn ẹlẹ́mìí ọ̀làwọ́ kò fi ìhìn rere náà mọ sọ́dọ̀ ara wọn. Ọ̀kan lára ohun tí ń dùn mọ́ wọn jù lọ ni láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ní tòótọ́, tiwọ́n jẹ́ ẹ̀mí fífúnni oníwà-bí-Ọlọ́run. Irú ẹ̀mí yẹn ni o ha ń mú dàgbà bí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye jù lọ kì í náni ní kọ́bọ̀