O Ha Ti Rí Ìgbàlà Bí?
ỌMỌ ọdún mẹ́wàá ni Johnny nígbà tí ọkùnrin kan dá a dúró níbi ìpàtẹ ọjà kan, tí ó sì bi í pé: “Ọ̀dọ́mọkùnrin, o ha gbà Jesu Kristi bí Oluwa àti Olùgbàlà rẹ bí?” Ìyẹn dún bí ìbéèrè àjèjì létí Johnny, níwọ̀n bí òún ti fìgbà gbogbo nígbàgbọ́ nínú Jesu. Nítorí náà, ó dáhùn pé, “Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni.” Ọkùnrin náà lọgun fáyé gbọ́ pé: “Ẹ yin Oluwa lógo! A ti gba ọkàn míràn là fún Kristi!”
Ìgbàlà ha fi bẹ́ẹ̀ rọrùn bí? Johnny ha “ti rí ìgbàlà” ní gbàrà tí ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọnyẹn bí, láìka ohun tí yóò fi ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe sí? Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn olóòótọ́ ọkàn yóò dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú onísìn kan máa ń sọ pé, kí o kọ ọjọ́ tí “o rí ìgbàlà” sílẹ̀, kí o baà lè máa rántí rẹ̀.
Àlùfáà kan kọ̀wé pé, “gbàrà tí ẹnì kan tí fi ìgbàgbọ́ díẹ̀ hàn nínú Kristi . . . kádàrá ẹni náà ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ pátápátá.” Ó ní Bibeli sọ pé, ìgbàlà sinmi lórí “ìṣe ìgbàgbọ́” ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo, “kì í ṣe lórí bíbá ìgbàgbọ́ nìṣó.” Òǹkọ̀wé ìsìn míràn kọ̀wé pé: “Èyí jẹ́ iṣẹ́ tí ó ti parí. A ti bá ọ parí rẹ̀ . . . ‘Ogun’ rẹ ‘ti parí.’ ‘A ti mú ẹ̀ṣẹ̀’ rẹ ‘kúrò.’” Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí wọn gbà gbọ́ dájú hán-únhán-ún pé èyí jẹ́ òtítọ́ pàápàá lè rí ìṣòro kan níbẹ̀. Ó ṣe kedere pé, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí a ti sọ fún pé wọ́n “ti rí ìgbàlà” kì í gbé ní ọ̀nà tí Bibeli sọ pé, ó yẹ kí wọ́n máa gbé. Àlàyé tí ó wọ́pọ̀ ni pé, bóyá wọn kò tí ì “gba” Kristi ní ti gidi.
Nítorí náà, kí ni “gbígba” Jesu túmọ̀ sí ní ti gidi? Ó ha jẹ́ ìṣe ìgbàgbọ́ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo, tàbí ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tí ń bá a nìṣó bí? Ìgbàgbọ́ wa ha ní láti lágbára tó láti lè sún wa gbé ìgbésẹ̀ bí? A ha lè gba àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jesu láìsí ẹrù iṣẹ́ ti títẹ̀ lé e bí?
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fẹ́ ìbùkún, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ ẹrù iṣẹ́ ti títẹ̀ lé Jesu àti ṣìṣe ìgbọràn sí i. Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ náà, “ìgbọràn,” sábà máa ń dà wọ́n láàmú. Síbẹ̀, Jesu wí pé: “Wá di ọmọlẹ́yìn mi.” (Luku 18:18-23) Bibeli sì sọ pé: “Awọn wọnnì tí kò ṣègbọràn sí ìhìnrere nipa Jesu Oluwa wa . . . yoo faragba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.”—2 Tessalonika 1:8, 9; Matteu 10:38; 16:24.
Bibeli sọ ohun púpọ̀ tí ó gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì dìde nípa ohun tí a ti fi kọ́ni nípa ìgbàlà. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti rí àrídájú ohun tí Bibeli sọ ní ti gidi lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí, ìwọ yóò rí àwọn ojú ewé tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí pé wọ́n gbádùn mọ́ni gan-an. Ṣí Bibeli rẹ, kí o sì ka àwọn ẹsẹ tí a yàn, láti rí ohun tí Jesu àti àwọn aposteli rẹ̀ fi kọ́ni nípa ọ̀ràn pàtàkì yìí.