ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 2/1 ojú ìwé 21-26
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jehofa àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jehofa àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yẹra fún Gbígbẹ́kẹ̀ lé Ọgbọ́n Ayé
  • Gbéjà Ko Ìtẹ̀sí Láti Ṣiyè Méjì
  • Títẹ̀ lé Ìtọ́sọ́nà Jehofa Nínú Ìgbéyàwó
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Tẹ́tí Sílẹ̀ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
  • Ẹyin Èwe—Ki Ni Ẹyin Ń Lépa?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ǹjẹ́ o Ti Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Iyèméjì Ba Ìgbàgbọ́ Rẹ Jẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ohun Táá Jẹ́ Kí Tọkọtaya Bára Wọn Kalẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 2/1 ojú ìwé 21-26

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jehofa àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀

“Àwọn tí ó . . . mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀ lé ọ.”—ORIN DAFIDI 9:10.

1. Èé ṣe tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé nínú Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀ lóde òní?

NÍNÚ ayé òde oní, ìkésíni náà láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọrun àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, lè dà bí èyí tí kò gbéṣẹ́, tí kò sì ṣeé ṣe. Síbẹ̀, jálẹ̀ àkókò gígùn, ọgbọ́n Ọlọrun ti fi ẹ̀rí jíjẹ́ òtítọ́ hàn. Ẹlẹ́dàá ọkùnrin àti obìnrin ni Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbéyàwó àti ìdílé, ó sì mọ àìní wa ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun kò-ṣeé-mánìí fún ẹ̀dá ènìyàn kò ti yí padà, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọ̀nà pàtàkì láti kúnjú àwọn àìní wọ̀nyẹn kò tí ì yí padà. Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Bibeli fúnni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ṣì pèsè ìtọ́sọ́nà dídára jú lọ fún àṣeyọrí nínú gbígbé ìgbésí ayé àti yíyanjú àwọn ìṣòro. Kíkọbi ara sí i, ń yọrí sí ayọ̀ púpọ̀—àní nínú ayé ọ̀làjú, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí a ń gbé yìí pàápàá!

2. (a) Èso rere wo ni ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọrun ti mú jáde nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn Jehofa? (b) Ohun mìíràn wo ni Jehofa ṣèlérí fún àwọn tí ń ṣègbọràn sí i àti sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀?

2 Gbígbẹ́kẹ̀ lé Jehofa àti fífi àwọn ìlànà Bibeli sílò ń mú àǹfààní tí ó gbéṣẹ́ wá lójoojúmọ́. Ẹ̀rí èyí hàn nínú ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa káàkiri ayé, àwọn tí wọ́n ti ní ìdálójú ìgbàgbọ́ àti ìgboyà láti fi ìmọ̀ràn Bibeli sílò. Ní ti wọn, ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ẹlẹ́dàá àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti fi ẹ̀rí wíwà ní ipò rere hàn. (Orin Dafidi 9:9, 10) Ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọrun tí mú kí wọ́n túbọ̀ jẹ́ ẹni rere nígbà tí ọ̀ràn bá di ti wíwà ní mímọ́ tónítóní, jíjẹ́ aláìlábòsí, aláápọn, níní ọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè àti ohun ìní àwọn ẹlòmíràn, àti jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú oúnjẹ àti ohun mímu. Ó ti yọrí sí ìfẹ́ tòótọ́ àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ láàárín agbo ìdílé—jíjẹ́ aláájò àlejò, onísùúrù, aláàánú àti adáríjini—àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn nǹkan mìíràn. Dé ìwọ̀n àyè gbígbòòrò, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti yẹra fún àwọn èso búburú ti ìbínú, ìkórìíra, ìpànìyàn, ìlara, ìbẹ̀rù, ọ̀lẹ, ìgbéraga, irọ́, ìbanijẹ́, ìṣekúṣe àti ìwà pálapàla. (Orin Dafidi 32:10) Ṣùgbọ́n, Ọlọrun ń ṣe ju ṣíṣe ìlérí àbájáde rere fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ lọ. Jesu wí pé, àwọn tí ń tẹ̀ lé ọ̀nà Kristian yóò gba “ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yii, . . . awọn ìyá ati awọn ọmọ ati awọn pápá, pẹlu awọn inúnibíni, ati ninu ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”—Marku 10:29, 30.

Yẹra fún Gbígbẹ́kẹ̀ lé Ọgbọ́n Ayé

3. Nínú bíbá a nìṣó láti máa fi ìgbẹ́kẹ̀lé sínú Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìṣòro wo ni àwọn Kristian ń dojú kọ nígbà míràn?

3 Ìṣòro kan tí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé ní ni pé, wọ́n ní ìtẹ̀sí láti fojú kéré ohun tí Ọlọrun ń béèrè tàbí kí wọ́n gbà gbé rẹ̀. Wọ́n tètè máa ń ronú pé àwọn gbọ́n jù lọ tàbí pé, ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ àwọn amòye ayé yìí ju ti Ọlọrun lọ, pé ó bá ìgbà mu jù ú lọ. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lè mú ìṣarasíhùwà yìí dàgbà pẹ̀lú, bí wọ́n ti ń gbé láàárín ayé yìí. Nípa báyìí, ní nínawọ́ ìkésíni onífẹ̀ẹ́ náà láti fetí sí ìmọ̀ràn rẹ̀, Bàbá wa ọ̀run tún fi ìkìlọ̀ yíyẹ wẹ́kú pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé òfin mi; sí jẹ́ kí àyà rẹ kí ó pa òfin mi mọ́. Nítorí ọjọ́ gígùn, àti ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà ni wọn óò fi kún un fún ọ. Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Oluwa; má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ. Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ: òun óò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ. Má ṣe ọlọgbọ́n lójú ara rẹ; bẹ̀rù Oluwa, kí o sì kúrò nínú ibi.”—Owe 3:1, 2, 5-7.

4. Báwo ni “ọgbọ́n ayé yii” ti ṣe gbilẹ̀ tó, èé sì ti ṣe tí ó fi jẹ́ “ìwà òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun”?

4 Ọgbọ́n ayé yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní yanturu, ó sì ń wá láti orísun púpọ̀. Ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ ń bẹ, ‘kò sì sí opin nínú kíkọ ìwé púpọ̀.’ (Oniwasu 12:12) Wàyí o, ohun tí a fẹnu lásán pè ní ọ̀nà márosẹ̀ ìfìsọfúnniránṣẹ́ nínú sànmánì ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà, ṣèlérí láti pèsè ìsọfúnni púpọ̀ rẹpẹtẹ lórí kókó ẹ̀kọ́ èyíkéyìí. Ṣùgbọ́n níní gbogbo ìmọ̀ yìí lárọ̀ọ́wọ́tó kò mú kí ayé túbọ̀ gbọ́n tàbí kí ó yanjú àwọn ìṣòro rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ipò ayé túbọ̀ ń burú sí i lójoojúmọ́. Lọ́nà tí ó yéni, Bibeli sọ fún wa pé, “ọgbọ́n ayé yii jẹ́ ìwà òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun.”—1 Korinti 3:19, 20.

5. Àwọn ìkìlọ̀ wo ni Bibeli fúnni ní ti “ọgbọ́n ayé yii”?

5 Nínú apá tí ó kẹ́yìn yìí nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó yẹ kí a máa retí pé, olórí ẹlẹ́tàn náà, Satani Èṣù, yóò gbé irọ́ rẹpẹtẹ kalẹ̀ nínú ìsapá láti ké ìgbọ́kànlé nínú ìjótìítọ́ Bibeli nígbèrí. Àwọn aṣelámèyítọ́ ìtàn àti ìtumọ̀ ìwé mímọ́ ti ṣe ọ̀pọ̀ ìwé ìméfò, tí ó pe ìjótìítọ́ gidi àti ìṣeégbáralé Bibeli níjà. Paulu kìlọ̀ fún Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Óò Timoteu, máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lori ohun tí a tòjọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ, yẹra fún awọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ ati fún awọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’ Nitori ní ṣíṣe àṣehàn irúfẹ́ ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ awọn kan ti yapa kúrò ninu ìgbàgbọ́.” (1 Timoteu 6:20, 21) Bibeli kìlọ̀ síwájú sí i pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹni kan lè wà tí yoo gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ọgbọ́n èrò-orí ati ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹlu òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹlu awọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé tí kò sì sí ní ìbámu pẹlu Kristi.”—Kolosse 2:8.

Gbéjà Ko Ìtẹ̀sí Láti Ṣiyè Méjì

6. Èé ṣe tí wíwà lójúfò fi ṣe pàtàkì láti dènà kí iyè méjì ta gbòǹgbò nínú ọkàn?

6 Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mìíràn tí Èṣù ń lò ni gbígbin iyè méjì síni lọ́kàn. Ó máa ń wà lójúfò nígbà gbogbo láti rí àwọn àìlera kan nínú ìgbàgbọ́, kí ó sì lò ó. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣiyè méjì yẹ kí ó rántí pé, ẹni náà tí ń bẹ lẹ́yìn irú iyè méjì bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó sọ fún Efa pé: “Òótọ́ ni Ọlọrun wí pè, Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ gbogbo èso igi ọgbà?” Gbàrà tí Adẹniwò náà ti gbin iyè méjì sínú ọkàn rẹ̀, ìgbésẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e ni láti parọ́ fún un, èyí tí obìnrin náà sì gbà gbọ́. (Genesisi 3:1, 4, 5) Láti yẹra fún jíjẹ́ kí iyè méjì pa ìgbàgbọ́ wa run bíi ti Efa, a ní láti wà lójúfò. Bí iyè méjì bínńtín nípa Jehofa, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tàbí ètò àjọ rẹ̀ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í wà nínú ọkàn rẹ, gbé ìgbésẹ̀ kíá mọ́sá láti mú un kúrò kí ó tóó gbilẹ̀ di ohun kan tí yóò ba ìgbàgbọ́ rẹ jẹ́.—Fi wé 1 Korinti 10:12.

7. Kí ni a lè ṣe láti mú iyè méjì kúrò?

7 Kí ni a lè ṣe? Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìdáhùn náà ni, kí a gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. “Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, nitori oun a máa fifún gbogbo ènìyàn pẹlu ìwà-ọ̀làwọ́ ati láìsí gíganni; a óò sì fi í fún un. Ṣugbọn kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè ninu ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá, nitori ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dàbí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì tí a sì ń fẹ́ káàkiri.” (Jakọbu 1:5, 6; 2 Peteru 3:17, 18) Nítorí náà, àdúrà onítara ọkàn sí Jehofa ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. (Orin Dafidi 62:8) Lẹ́yìn náà, má ṣe lọ́ra láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ. (Ìṣe 20:28; Jakọbu 5:14, 15; Juda 22) Wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wá orísun iyè méjì rẹ̀, èyí tí ó lè jẹ́ nítorí ìgbéraga tàbí àwọn èrò òdì kan.

8. Báwo ni ìrònú apẹ̀yìndà ṣe sábà máa ń bẹ̀rẹ̀, kí sì ni ojútùú rẹ̀?

8 Kíkà tàbí títẹ́tí sí èrò àwọn apẹ̀yìndà tàbí ọgbọ́n èrò orí ayé ha ti mú iyè méjì onímájèlé wá bí? Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, Bibeli gbani nímọ̀ràn pé: “Sa gbogbo ipá rẹ lati fi ara rẹ hàn fún Ọlọrun ní ẹni tí a fi ojúrere tẹ́wọ́gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan lati tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́. Ṣugbọn máa yẹ awọn òfìfo ọ̀rọ̀ sílẹ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́; nitori tí wọn yoo tẹ̀síwájú sí àìṣèfẹ́ Ọlọrun síwájú ati síwájú, ọ̀rọ̀ wọn yoo sì tàn kálẹ̀ bí egbò kíkẹ̀.” (2 Timoteu 2:15-17) Yóò dára láti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti di ẹran ìjẹ fún ìpẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ ní ipa ọ̀nà òdì, nípa kíkọ́kọ́ ṣàròyé nípa bí wọ́n ṣe rò pé a ti bá wọn lò nínú ètò àjọ Jehofa. (Juda 16) Wíwá àríwísí sí èrò ìgbàgbọ́ wá lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Gan-an gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ abẹ kan ṣe tètè ń gbé ìgbésẹ̀ láti gé egbò kíkẹ̀ kúrò, tètè gbé ìgbésẹ̀ láti mú ìtẹ̀sí èyíkéyìí láti ṣàròyé kúrò lọ́kàn, láti di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀nà tí a gbà ń ṣe àwọn nǹkan nínú ìjọ Kristian. (Kolosse 3:13, 14) Gé ohunkóhun tí ó bá ń mú irú iyè méjì bẹ́ẹ̀ wá kúrò.—Marku 9:43.

9. Báwo ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò ti ìṣàkóso Ọlọrun tí ó gbámúṣe yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onílera nínú ìgbàgbọ́?

9 Dìrọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ Jehofa àti ètò àjọ rẹ̀. Fi ìdúróṣinṣin ṣàfarawé Peteru, ẹni tí ó fi tìpinnutìpinnu sọ pé: “Oluwa, ọ̀dọ̀ ta ni awa yoo lọ? Iwọ ni ó ní awọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Johannu 6:52, 60, 66-68) Ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbígbámúṣé tí ó jẹ́ ti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Jehofa, kí o baà lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́ alágbára, bí apata ńlá, tí ó lè “paná gbogbo awọn ohun-ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú naa.” (Efesu 6:16) Máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian, fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Lójoojúmọ́, ṣàṣàrò lọ́nà tí ó fi ìmọrírì hàn, nípa bí Jehofa ti ṣe bù kún ọ. Dúpẹ́ pé o ní ìmọ̀ òtítọ́. Ṣíṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ Kristian, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti láyọ̀, láti fara dà, àti láti bọ́ lọ́wọ́ iyè méjì.—Orin Dafidi 40:4; Filippi 3:15, 16; Heberu 6:10-12.

Títẹ̀ lé Ìtọ́sọ́nà Jehofa Nínú Ìgbéyàwó

10. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì ní ti gidi láti yíjú sí Jehofa fún ìtọ́sọ́nà nínú ìgbéyàwó Kristian?

10 Ní ṣíṣètò fún ọkùnrin àti obìnrin láti gbé pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya, Jehofa kò pète láti fi ènìyàn kún ilẹ̀ ayé lọ́nà tí ó tuni lára nìkan, ṣùgbọ́n láti fi kún ayọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n, ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti mú àwọn ìṣòro líle koko wá sínú ipò ìbátan ìgbéyàwó. Àwọn Kristian kò yọ nínú èyí, níwọ̀n bí àwọn pẹ̀lú ti jẹ́ aláìpé, tí wọ́n sì ń nírìírí àwọn pákáǹleke ìgbésí ayé òde òní. Síbẹ̀, títí dé ìwọ̀n àyè tí wọ́n bá fi gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn Kristian lè ṣe àṣeyọrí sí rere nínú ìgbéyàwó àti nínú títọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà. Kò sì àyè kankan fún àwọn àṣà àti ìṣe ayé nínú ìgbéyàwó Kristian. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà wá níyànjú pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nitori Ọlọrun yoo dá awọn àgbèrè ati awọn panṣágà lẹ́jọ́.”—Heberu 13:4.

11. Nínú yíyanjú àwọn ìṣòro ìdílé, kí ni ó yẹ kí tọkọtaya mọ̀?

11 Ìgbéyàwó tí ó bá ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Bibeli ń ní àyíká onífẹ̀ẹ́, ẹlẹ́rù iṣẹ́ àti aláàbò. Ọkọ àti aya ń lóye ìlànà ipò orí, wọn sì ń bọ̀wọ̀ fún un. Nígbà tí ìṣòro bá dìde, wọ́n sábà máa ń jẹ́ nítorí àwọn àìbìkítà kan nínú fífi ìmọ̀ràn Bibeli sílò. Láti lè yanjú ìṣòro kan tí ń jẹ yọ, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn méjèèjì fi tòótọ́tòótọ́ pa àfiyèsí pọ̀ sórí ohun tí ìṣòro náà jẹ́ gan-an, kí wọ́n sì dojú kọ okùnfà rẹ̀ dípò àwọn àmì ìṣòro. Bí àwọn ìjíròrò lọ́ọ́lọ́ọ́ bá ti yọrí sí ìfohùnṣọ̀kan díẹ̀ tàbí àìsí ìfohùnṣọ̀kan rárá, tọkọtaya náà lè béèrè fún ìrànlọ́wọ́ aláìṣègbè láti ọ̀dọ̀ alábòójútó onífẹ̀ẹ́ kan.

12. (a) Àwọn ìṣòro wíwọ́pọ̀ wo nínú ìgbéyàwó ni Bibeli pèsè ìmọ̀ràn fún? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí tọkọtaya máa ṣe nǹkan ní ọ̀nà Jehofa?

12 Ìṣòro náà ha wé mọ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, ọ̀wọ̀ fún ìmọ̀lára ẹnì kíní kejì, ọ̀wọ̀ fún ipò orí, tàbí bí a ṣe ń ṣe ìpinnu bí? Ó ha ní í ṣe pẹ̀lú títọ́ àwọn ọmọ, tàbí wíwà déédéé ní ti ojúṣe ìbálòpọ̀ bí? Àbí ó ha jẹ́ ìṣúnná owó ti ìdílé, eré ìtura, ìbákẹ́gbẹ́pọ̀, bóyá aya yóò máa ṣiṣẹ́, tàbí ibi tí ẹ óò máa gbé? Èyí ó wù kí ìṣòro náà jẹ́, Bibeli fúnni ní ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́, yálà ní tààràtà nípasẹ̀ àwọn òfin tàbí láìṣe tààràtà, nípasẹ̀ àwọn ìlànà. (Matteu 19:4, 5, 9; 1 Korinti 7:1-40; Efesu 5:21-23, 28-33; 6:1-4; Kolosse 3:18-21; Titu 2:4, 5; 1 Peteru 3:1-7) Nígbà tí tọkọtaya náà bá yàgò fún fífi ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan béèrè fún nǹkan, tí wọ́n sì jẹ́ kí ìfẹ́ ṣiṣẹ́ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú ìgbéyàwó wọn, ó máa ń yọrí sí ayọ̀ ńláǹlà. Tọkọtaya náà ní láti ní ìfẹ́ ọkàn ńláǹlà láti ṣe ìyípadà tí ó bá yẹ, láti ṣe nǹkan ní ọ̀nà Jehofa. “Ẹni tí ó fi òye ṣe ọ̀ràn yóò rí ire; ẹni tí ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Oluwa, ìbùkún ni fún un.”—Owe 16:20.

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Tẹ́tí Sílẹ̀ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun

13. Èé ṣe tí kò fi rọrùn fún àwọn ọ̀dọ́ Kristian láti dàgbà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ lílágbára nínú Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀?

13 Kò rọrùn fún àwọn ọ̀dọ́ Kristian láti dàgbà di alágbára nínú ìgbàgbọ́ nígbà tí ayé búburú bá ṣì wà yí wọn ká. Ìdí kan ni pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa,” Satani Èṣù. (1 Johannu 5:19) Àwọn ọ̀dọ́ wà lábẹ́ ìgbéjàkò láti ọ̀dọ̀ ọ̀tá rírorò yìí, tí ó lè mú kí ohun búburú dà bí ohun rere. Ẹ̀mí ìrònú tèmi làkọ́kọ́, ìlépa onímọ̀tara ẹni nìkan, ìyánhànhàn fún ohun tí ó jẹ́ ìwà pálapàla àti ìwà ìkà, àti ìlépa adùn lọ́nà tí kò tọ́—gbogbo èyí para pọ̀ jẹ́ ọ̀nà ìrònú wíwọ́pọ̀, tí ń lo agbára ìdarí, tí a ṣàpèjúwe nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí ninu awọn ọmọ àìgbọ́ràn.” (Efesu 2:1-3) Satani ti fi ọgbọ́n àrékérekè gbé “ẹ̀mí” yìí lárugẹ nínú àwọn ìwé ilé ẹ̀kọ́, nínú ọ̀pọ̀ àwọn orin tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, nínú eré ìdárayá, àti nínú irú àwọn eré ìnàjú mìíràn. Ó yẹ kí àwọn òbí wà lójúfò láti ṣẹ́gun irú ipa ìdarí bẹ́ẹ̀, nípa ríran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti dàgbà nínú gbígbẹ́kẹ̀ lé Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

14. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè “sá fún awọn ìfẹ́-ọkàn tí ó sábà máa ń bá ìgbà èwe rìn”?

14 Paulu fún ọ̀dọ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, Timoteu, ní ìmọ̀ràn bíi ti bàbá pé: “Sá fún awọn ìfẹ́-ọkàn tí ó sábà máa ń bá ìgbà èwe rìn, ṣugbọn máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, papọ̀ pẹlu awọn wọnnì tí ń ké pe Oluwa lati inú ọkàn-àyà tí ó mọ́.” (2 Timoteu 2:22) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo “ìfẹ́-ọkàn tí ó sábà máa ń bá ìgbà èwe rìn” ni ó burú fúnra rẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ ní láti “sá fún” wọn, ní ti pé wọn kì yóò jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí di ohun ìdíwọ́, ní fífi ìwọ̀nba àyè díẹ̀ sílẹ̀ fún ìlépa ìwà-bí-Ọlọ́run tàbí kí ó má tilẹ̀ sí àyè fún un rárá. Mímú ẹran ara dàgbà sí i, eré ìdárayá, orin, eré ìnàjú, ìgbòkègbodò àfipawọ́ àti ìrìn àjò, bí wọn kò tilẹ̀ burú ní ti gidi, lè jẹ́ ìdẹkùn bí wọ́n bá di ohun pàtàkì nínú ìgbésí ayé. Sá pátápátá fún ìjíròrò aláìléte, fífẹsẹ̀ palẹ̀ kiri, ọkàn ìfẹ́ tí kò tọ́ nínú ìbálòpọ̀, jíjókòó lásán, kí gbogbo nǹkan sì súni àti ṣíṣàròyé pé àwọn òbí rẹ kò lóye rẹ.

15. Kí ni àwọn nǹkan tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní kọ́lọ́fín inú ilé, tí ó lè pakún kí àwọn ọ̀dọ́ máa gbé ìgbésí ayé méjì?

15 Àní ní ibi kọ́lọ́fín nínú ilé pàápàá, ewú lè lúgọ de àwọn ọ̀dọ̀. Bí wọ́n bá ń wo àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ oníwà pálapàla tàbí oníwà ipá lórí tẹlifíṣọ̀n àti fídíò, ó lè gbin ìfẹ́ ọkàn láti ṣe ohun búburú sí wọn lọ́kàn. (Jakọbu 1:14, 15) Bibeli gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ̀yin tí ó fẹ́ Oluwa, ẹ kórìíra ibi.” (Orin Dafidi 97:10; 115:11) Jehofa mọ bí ẹnì kan bá ń gbìdánwò láti gbé ìgbésí ayé méjì. (Owe 15:3) Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Kristian, ẹ wo yàrá yin yí ká. Ẹ ha lẹ àwòrán àwọn oníwà pálapàla olókìkí nínú eré ìdárayá tàbí orin ayé mọ́ ògiri bí, tàbí ẹ ha lẹ àwọn ohun tí ó gbámúṣe tí ó jẹ́ ìránnilétí rere bí? (Orin Dafidi 101:3) Níbi ìkáṣọsí yín, ẹ ha ní àwọn aṣọ oníwọ̀ntunwọ̀nsì, àbí àwọn kan nínú àwọn ẹ̀wù yín ń fi àṣà ìwọṣọ aláṣerégèé tí ó jẹ́ ti ayé hàn bí? Ní àwọn ọ̀nà àyínìke, Èṣù lè dẹkùn mú un yín bí ẹ bá gba ìdẹwò náà láyè, láti dán ohun búburú wò. Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, Bibeli gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ pa awọn agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyèsára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ.”—1 Peteru 5:8.

16. Báwo ni ìmọ̀ràn Bibeli ṣe lè ran ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ láti mú kí gbogbo ẹnì tí ó ṣe pàtàkì sí i, lè fi í yangàn?

16 Bibeli ní kí o kíyè sí ẹgbẹ́ tí ò ń kó. (1 Korinti 15:33) Àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ rẹ yẹ kí ó jẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù Jehofa. Má ṣe juwọ́ sílẹ̀ fún ìdarí ojúgbà rẹ lórí rẹ. (Orin Dafidi 56:11; Owe 29:25) Jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí rẹ̀ olùbẹ̀rù Ọlọrun. (Owe 6:20-22; Efesu 6:1-3) Yíjú sí àwọn alàgbà fún ìtọ́sọ́nà àti ìṣírí. (Isaiah 32:1, 2) Máa pa ọkàn àti ojú rẹ pọ̀ sórí àwọn ìlànà àti góńgó tẹ̀mí. Wá àǹfààní láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, kí o sì lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Kọ́ bí o ṣe lè fi ọwọ́ rẹ ṣe nǹkan. Dàgbà di alágbára àti onílera nínú ìgbàgbọ́, nígbà náà ni ìwọ yóò lè fi hàn pé ẹnì kan ni ọ́ ní tòótọ́—ẹnì kan tí ó yẹ fún ìwàláàyè nínú ayé tuntun ti Jehofa! Bàbá wa ọ̀run yóò lè fi ọ́ yangàn, inú àwọn òbí rẹ orí ilẹ̀ ayé yóò dùn sí ọ, ìwọ yóò jẹ́ ìṣírí fún àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin rẹ. Ìyẹn ni ó ṣe pàtàkì jù lọ!—Owe 4:1, 2, 7, 8.

17. Àwọn àǹfààní wo ni ó ń tọ àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá?

17 A mí sí onipsalmu náà láti kọ̀wé ní lílo àpólà ọ̀rọ̀ ewì pé: “Jehofa fúnra rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlẹ́bi. Jehofa àwọn ọmọ ogun, aláyọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ.” (Orin Dafidi 84:11, 12, NW) Àní, ayọ̀ àti àṣeyọrí ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, kì í ṣe ìjákulẹ̀ àti ìkùnà.—2 Timoteu 3:14, 16, 17.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Èé ṣe tí àwọn Kristian kò fi ní láti fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú “ọgbọ́n ayé yii”?

◻ Kí ni ó yẹ kí a ṣe bí a bá ń ṣiyè méjì?

◻ Báwo ni ṣíṣe àwọn nǹkan lọ́nà ti Jehofa ṣe ń mú àṣeyọrí àti ayọ̀ wá nínú ìgbéyàwó?

◻ Báwo ni Bibeli ṣe ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti “sá fún awọn ìfẹ́-ọkàn tí ó sábà máa ń bá ìgbà èwe rìn”?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn Kristian ń yíjú sí Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọ́n ń ṣá “ọgbọ́n ayé yii” tì gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwọn ìdílé tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń ṣàṣeyọrí sí rere, wọ́n sì ń láyọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́