Òpin Pátápátá Sí Ìwà Ipá—Báwo?
LÁTI dín ìwà ipá kù, ọ̀pọ̀ ìlú ńlá ní United States dán èrò tuntun kan wò—fífún àwọn tí ó bá dá ìbọn wọn padà ní owó tàbí ẹrù, láìbéèrè ìbéèrè kankan. Kí ni ó yọrí sí? Fún àpẹẹrẹ, ó ná ìlú ńlá St. Louis ní 341,000 dọ́là, láti lè rí 8,500 ìbọn gbà. Ètò tí ó fara jọ ọ́ ní New York City rí ohun tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún ohun ìjà gbà.
Ipa wo ni gbogbo èyí ní lórí ìwà ọ̀daràn? Lọ́nà tí ó múni kábàámọ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ ni. Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, ìpànìyàn tí ó jẹ mọ́ lílo ìbọ́n dé góńgó tí ó ju tí ìgbàkígbà rí lọ ní St. Louis. Ní New York City, a fojú díwọ̀n pé ìbọn tí ó tó mílíọ̀nù méjì ṣì wà lọ́wọ́ àwọn mẹ̀kúnnù. Ní United States, nǹkan bí 200 mílíọ̀nù ìbọn wà lọ́wọ́ àwọn aládàáni, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹyọ kan fún ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé kọ̀ọ̀kan. Ní àwọn ilẹ̀ míràn, ìwà ipá tí ó jẹ mọ́ ìbọn ń peléke sí i lọ́nà tí ń bani lẹ́rù. Ní Britain, ìwé ìròyìn The Economist sọ pé: “Ní 1983 sí 1993, iye àwọn ẹ̀sùn tí àwọn ọlọ́pàá kọ sílẹ̀, nínú èyí tí a ti lo ìbọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì, sí 14,000.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìwọ̀n ìpànìyàn kéré ní ìfiwéra, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan ohun ìjà tí kò bófin mu wà ní orílẹ̀-èdè náà.
Dájúdájú, ìlọsílẹ̀ èyíkéyìí nínú iye bíbani lẹ́rù wọ̀nyẹn jẹ́ ìgbésẹ̀ ìtẹ̀síwájú. Ṣùgbọ́n, ekukáká ní irú àwọn ìgbésẹ̀ tí a ṣàpèjúwe lókè yìí fi ń dé orísun okùnfà ìwà ipá. Kí ni àwọn okùnfà wọ̀nyẹn? A ti mẹ́nu kan àwọn kókó abájọ púpọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ lára wọ́n ṣe pàtàkì. Ìdílé tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ àti àìsí ìtọ́ni lórí ọ̀nà ìwà híhù ti sún ọ̀pọ̀ èwe láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ jàǹdùkú láti lè ní ìmọ̀lára wíwà pa pọ̀ tímọ́tímọ́. Òòfà èrè ńlá ń sún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti yíjú sí ìwà ipá. Àìsí ìdájọ́ òdodo ń ti àwọn ẹlòmíràn láti fi ìwà ipá yanjú ọ̀ràn. Fífi orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà ìran, tàbí ipò nínú ìgbésí ayé yangàn ń mú kí àwọn ènìyàn ṣá ìjìyà àwọn ẹlòmíràn tì. Àwọn wọ̀nyí ni kókó abájọ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí kò ní ojútùú rírọrùn.
Kí Ni A Lè Ṣe?
Níní ọlọ́pàá púpọ̀ sí i, sáà ìfisẹ́wọ̀n tí ó le koko sí i, ṣíṣàkóso ìbọn, dídájọ́ ikú fúnni—gbogbo èyí ní a ti dábàá, tí a sì ti lò wò gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti dáwọ́ ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá dúró. Wọ́n ti mú ìwọ̀n àṣeyọrí tí ó yàtọ̀ wá, ṣùgbọ́n, òkodoro òtítọ́ tí ó bani nínú jẹ́ ni pé, ìwà ipá ṣì wà láàárín wa síbẹ̀. Èé ṣe? Ìdí ni pé, àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí wulẹ̀ bójú tó àwọn àmì ìṣòro náà ni.
Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi rò pé, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ni kọ́kọ́rọ́ sí mímú òpin dé bá ìwà ipá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò yìí dára, a gbọ́dọ̀ ṣàkíyèsí pé, ìwà ipá kò mọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí àǹfààní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ kò ti tó nǹkan. Ní ti gidi, ó dà bíi pé, àwọn kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwà ipá pọ̀ sí jù lọ tún jẹ́ àwọn tí wọ́n ní ìlànà gíga jù lọ ní ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Kò ṣòro láti rí i pé, ohun tí a nílò kì í ṣe ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ṣákálá, bí kò ṣe irú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó yẹ. Irú èwo ni ìyẹn yóò jẹ́? Ẹnì kan ha wà tí ó lè kọ́ àwọn ènìyàn láti jẹ́ ẹni àlàáfíà, àti adúróṣinṣin bí?
“Èmi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, tí ó kọ́ ọ fún èrè, ẹni tí ó tọ́ ọ ní ọ̀nà tí ìwọ ì bá máa lọ. Ì bá ṣe pé ìwọ́ fetí sí òfin mi! nígbà náà ni àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì omi òkun.” (Isaiah 48:17, 18, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Báwo ni Jehofa Ọlọrun ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn láti jẹ́ ẹni àlàáfíà àti olódodo? Ní pàtàkì nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, ni.
Agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
Bibeli jìnnà fíìfíì sí àkójọ lásán ti àwọn àlọ́ àtijọ́ àti àwọn àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí kò bá ìgbà mu mọ́, tí kò sì bá ohun tí ń ṣẹlẹ̀ mu. Ó ní àwọn ìlànà àti èrò tí ó ti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá aráyé wá nínú, ẹni tí ó mọ bí ẹ̀dá ènìyàn ti rí ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, láti ojú ìwòye rẹ̀ tí ó ga lọ́lá jù lọ. Jehofa Ọlọrun wí pé: “Bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yin lọ, àti èrò mi ju èrò yin lọ.”—Isaiah 55:9.
Nítorí ìdí èyí, aposteli Paulu jẹ́rìí sí i pé, “ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè ó sì ń sa agbára ó sì mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn ati ẹ̀mí níyà, ati awọn oríkèé oun mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú ati awọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Heberu 4:12) Àní, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní agbára láti dé inú ọkàn-àyà ẹni, kí ó sì gbún un ní kẹ́ṣẹ́, kí ó sì yí ìrònú àti ìwà rẹ̀ padà. Kì í ha í ṣe èyí ni ohun tí a nílò láti yí àwọn ọ̀nà oníwà ipá àwọn ènìyàn padà lónìí bí?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí iye wọ́n jẹ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-ún nísinsìnyí ní àwọn ilẹ̀ tí ó lé ní 230, jẹ́ ẹ̀rí tí ó ṣeé fojú rí pé ní tòótọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní agbára láti yí ìgbésí ayé padà sí rere. Àwọn ènìyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè, èdè àti ẹ̀yà ìran wà lára wọn. Wọ́n sì wá láti gbogbo onírúurú ipò nínú ìgbésí ayé àti ipò àtilẹ̀wá ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Àwọn kan lára wọn ti gbé ìgbésí ayé oníwà ipá àti onídààmú tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n, dípò tí wọn ì bá fi yọ̀ọ̀da fún irú àwọn kókó abájọ bẹ́ẹ̀ láti ru kèéta, ìbáradíje, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìkórìíra sókè láàárín wọn, wọ́n ti kọ́ láti borí àwọn ìdènà wọ̀nyí, wọ́n sì ti di ènìyàn àlàáfíà, tí wọ́n sì wà níṣọ̀kan káàkiri àgbáyé. Kí ni ó ti mú kí èyí ṣeé ṣe?
Ìgbétásì Tí Ó Fòpin Sí Ìwà Ipá
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fi ara wọn fún ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa ète Ọlọrun bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, ti ṣí i payá. Ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, wọ́n ń ṣàwárí àwọn tí wọ́n fẹ́ láti kọ́ nípa àwọn ọ̀nà Jehofa, tí wọ́n sì fẹ́ kí ó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ìsapá wọn ń méso jáde. Ìyọrísí ìgbétáásì ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ni pé, àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu kan ti ń ní ìmúṣẹ.
Ní 2,700 ọdún sẹ́yìn, a mí sí wòlíì náà, Isaiah, láti kọ̀wé pé: “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ ìkẹyìn, . . . ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò sì lọ, wọn óò sì wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè Oluwa, sí ilé Ọlọrun Jakọbu; Òun óò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa óò sì máa rìn ní ipa rẹ̀.”—Isaiah 2:2, 3.
Dídi ẹni tí Jehofa kọ́, àti rírìn ní ipa rẹ̀, lè mú ìyípadà yíyani lẹ́nu wá nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn. A sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn ìyípadà náà nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan náà: “Wọn óò fi idà wọn rọ ọ̀bẹ píláù, wọn óò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.” (Isaiah 2:4) Àwọn ènìyàn púpọ̀ ti ka ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí. A tilẹ̀ gbẹ́ ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí sí ara ògiri Gbàgede Ilé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní New York City. Ó jẹ́ ìránnilétí ohun tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń fẹ́ láti ṣàṣeparí, ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti ṣe. Ọwọ́ ètò àjọ òṣèlú èyíkéyìí tí ènìyàn gbé kalẹ̀ kò lè tẹ mímú ogun àti ìwà ipá kúrò. Jehofa Ọlọrun nìkan ṣoṣo ni ó ní agbára láti ṣe é. Báwo ni yóò ṣe ṣàṣeparí èyí?
Ó dájú pé, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni yóò dáhùn padà sí ìkésíni náà láti “lọ sí òkè Oluwa” kí ‘a sì kọ́ wọn ní ọ̀nà rẹ̀’ kí wọ́n sì “rìn ní ipa rẹ̀”; bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni yóò fẹ̀ láti ‘fi idà wọn rọ ọ̀bẹ píláù, kí wọ́n sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.’ Kí ni Jehofa yóò ṣe sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀? Kì yóò ṣí ilẹ̀kùn àǹfààní náà sílẹ̀ títí láé tàbí kí ó dúró dè wọ́n láti yí padà. Láti mú ìwà ipá wá sí òpin, Jehofa yóò mú àwọn tí wọ́n rin kinkin mọ́ àwọn ọ̀nà oníwà ipá wọn wá sí òpin pẹ̀lú.
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Pàtàkì
Ohun tí Ọlọrun ṣe ní ọjọ́ Noa pèsè ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n fún wa lónìí. Àkọsílẹ̀ Bibeli fi irú ayé tí ó wà nígbà náà hàn pé: “Ayé sì bàjẹ́ níwájú Ọlọrun, ayé sì kún fún ìwà agbára.” Nítorí èyí, Ọlọrun sọ fún Noa pé: “Òpin gbogbo ènìyàn dé iwájú mi; nítorí tí ayé kún fún ìwà agbára láti ọwọ́ wọn; sì kíyè sí i, èmi óò sì pa wọ́n run pẹ̀lú ayé.”—Genesisi 6:11, 13.
A gbọ́dọ̀ ṣàkíyèsí ohun pàtàkì kan. Nígbà tí ó ń mú Àkúnya náà wá sórí ìran yẹn, Ọlọrun pa Noa àti ìdílé rẹ̀ mọ́. Èé ṣe? Bibeli dáhùn pé: “Noa ṣe olóòótọ́ àti ẹni tí ó pé ní ọjọ́ ayé rẹ̀. Noa ń bá Ọlọrun rìn.” (Genesisi 6:9; 7:1) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà jẹ́ gbogbo ẹni tí ó wà láàyè nígbà yẹn ni oníwà ipá, Noa àti ìdílé rẹ̀ nìkan ni ó “bá Ọlọrun rìn.” Nítorí ìyẹn, wọ́n là á já nígbà tí a mú ayé oníwà ipá yẹn wá sí òpin.
Bí a ṣe ń rí i tí ilẹ̀ ayé tún ń “kún fún ìwà agbára” lẹ́ẹ̀kan sí i, a lè ní ìdálójú pé, Ọlọrun ń ṣàkíyèsí rẹ̀. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní ọjọ́ Noa, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò gbé ìgbésẹ̀ láìpẹ́, tí yóò sì mú ìwà ipá wá sí òpin—pátápátá. Ṣùgbọ́n, òun yóò tún pèsè ọ̀nà àsálà fún àwọn tí wọ́n ń kọ́ láti ‘bá Ọlọrun tòótọ́ rìn’ nísinsìnyí, àwọn tí ń dáhùn padà sí ìgbétáásì ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gígadabú rẹ̀ fún àlàáfíà.
Nípasẹ̀ onipsalmu, Jehofa fún wa ní ìdálójú yìí pé: “Nítorí pé nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí: nítòótọ́ ìwọ óò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Orin Dafidi 37:10, 11.
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ, kí o lè dara pọ̀ mọ́ àwọn tí ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè Oluwa, sí ilé Ọlọrun Jakọbu; Òun óò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa óò sì máa rìn ní ipa rẹ̀.” (Isaiah 2:3) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ́ lè wà lára àwọn tí yóò rí òpin ìwà búburú àti ìwà ipá. Ìwọ́ lè rí “inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Reuters/Bettmann