Bí A Ṣe Lè Rí Ayọ̀ Nínú Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Ọ̀KAN nínú ayọ̀ jíjinlẹ̀ jù lọ tí ẹnì kan lè nírìírí rẹ̀ ni ti jíjẹ́ alájùmọ̀ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọrun. Lónìí, iṣẹ́ Ọlọrun ní kíkó àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òdodo jọ sínú ìjọ Kristian àti dídá wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bíi Kristian nísinsìnyí àti fún lílàájá sínú ayé tuntun kan.—Mika 4:1-4; Matteu 28:19‚ 20; 2 Peteru 3:13.
Ó ti jẹ́ orísun ayọ̀ ńláǹlà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Latin America láti rí i pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ti di ọmọ ẹ̀yìn Jesu Kristi láti ọdún 1980 wá. Ní pápá eléso yìí, níbi tí ọ̀pọ̀ ti ní ọ̀wọ̀ fún Bibeli, tí wọ́n sì gbà á gbọ́, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan láti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jehofa. Pẹ̀lú ìrírí tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, bóyá wọ́n lè sọ ohun kan fún wa nípa ayọ̀ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Díẹ̀ lára àwọn àbá wọn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn níbi tí ò ń gbé.
Dídá Àwọn Ẹni Tí Ó Lè Jẹ́ “Àgùntàn” Mọ̀
Nígbà tí Jesu rán àwọn aposteli rẹ̀ jáde láti wàásù, ó sọ pé: “Ìlú-ńlá tabi abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.” (Matteu 10:11) Nígbà tí ẹ bá ń bẹ àwọn ènìyàn wò, báwo ni ẹ ṣe lè mọ àwọn tí ẹ lè ràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí? Edward, tí ó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fún ohun tí ó lé ní 50 ọdún, sọ pé: “Wọ́n ń fi èyí hàn nípa àwọn ìbéèrè àtọkànwá wọn, àti ìtẹ́lọ́rùn tí wọ́n máa ń ní nígbà tí a bá fún wọn ní ìdáhùn láti inú Ìwé Mímọ́.” Carol fi kún un pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá finú tán mi, tí ó sọ ìṣòro tàbí ìdààmú ara rẹ̀ fún mi, ó jẹ́ ẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ ní tòótọ́. Mo máa ń gbìyànjú láti wá ìsọfúnni tí ó wúlò láti inú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society. Irú ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.” Síbẹ̀, àwọn olóòótọ́ inú kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti mọ̀. Luis ròyìn pé: “Àwọn kan tí ó dà bí pé wọ́n lọ́kàn ìfẹ́ gan-an máa ń yí padà di àwọn tí kò lọ́kàn ìfẹ́ rárá, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn tí ó dà bí pé wọ́n ń ṣàtakò lákọ̀ọ́kọ́ máa ń yí padà nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ohun tí Bibeli sọ ní ti gidi.” Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀pọ̀ ará Latin America ti bọ̀wọ̀ fún Bibeli, ó fi kún un pé, “Mo máa ń mọ àwọn ti mo lè ràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí nígbà tí wọ́n bá fínnúfíndọ̀ tẹ́wọ́ gba ohun tí Bibeli fi kọ́ni lẹ́yìn ti mo bá ti fi hàn wọ́n.” Ríran irú àwọn ẹni “yíyẹ” bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí ń mú ayọ̀ tòótọ́ àti ìtẹ́lọ́rùn wá. Báwo ni o ṣe lè ṣe èyí?
Bíbẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli
Lílo àwọn àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” pèsè sábà máa ń jẹ́ ọ̀nà dídára jù lọ láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ Bibeli. (Matteu 24:45) Báwo ni o ṣe lè mú ìmọrírì fún ìníyelórí irú àwọn ìrànlọ́wọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bẹ́ẹ̀ dàgbà? Edward wí pé: “Níwọ̀n bí àyíká ipò, àkópọ̀ ànímọ́, àti ojú ìwòye àwọn ènìyàn tí máa ń yàtọ̀ gidigidi síra wọn, mo máa ń gbìyànjú láti mọwọ́ yí padà nígbà tí mo bá ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́.” O kò lè lo ọgbọ́n kan náà fún gbogbo ènìyàn.
Ní ti àwọn kan, a lè ní láti lo onírúurú ìjíròrò àìjẹ́-bí-àṣà láti inú Ìwé Mímọ́, ṣáájú fífi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ̀ wọ́n. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, tọkọtaya míṣọ́nnárì kan ròyìn pé: “A sábà máa ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́.” Bákan náà, Ẹlẹ́rìí kan tí ó ti ran àwọn ènìyàn 55 lọ́wọ́ dórí ìyàsímímọ́ sọ pé: “Ọ̀nà pàtàkì tí mo máa ń gbà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli jẹ́ láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni ní tààràtà nínú ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan kórìíra kíkẹ́kọ̀ọ́ ohunkohun, àwọn mìíràn máa ń hára gàgà láti kẹ́kọ̀ọ́ ohunkóhun tí wọ́n bá gbà gbọ́ pé ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé. Fífi ìjíròrò Bibeli lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé lọ̀ wọ́n sábà máa ń dà bí ohun tí ó fa àwọn wọ̀nyí lọ́kàn mọ́ra. Àwọn míṣọ́nnárì kan ṣàpèjúwe ìfilọni yìí, wọ́n sì sọ pé: “Èmi yóò fẹ́ láti fi hàn ọ́ bí a ti ń ṣe é. Bí o bá fẹ́, o lè tẹ̀ síwájú. Bí o kò bá fẹ́, ìyẹ́n kù sí ọ lọ́wọ́.” Nígbà tí a bá gbé e kalẹ̀ ní ọ̀nà yẹn, àwọn ènìyàn kì í bẹ̀rù láti tẹ́wọ́ gbà á.
Ẹlẹ́rìí mìíràn, tí ó ti ran àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, tí wọn kò sì kàwé lọ́wọ́, sọ pé: “Mo ti rí i pé, ìwé àṣàrò kúkúrú wúlò ní pàtàkì láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.” Ìtẹ̀jáde yòówù kí wọ́n lò, àwọn olùkọ́ alákòókò kíkún náà máa ń gbìyànjú láti darí àfiyèsí ní pàtàkì sórí Bibeli. Carola sọ pé: “Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́, mo máa ń lo kìkì àwọn àwòrán àti nǹkan bí ẹsẹ ìwé mímọ́ márùn-ún, kí àwọn kókó pàtàkì baà hàn gbangba, kí Bibeli má sì dà bí èyí tí ó le koko.”
Mímú Kí Ọkàn-Ìfẹ́ Náà Máa Bá A Lọ
Àwọn ènìyàn máa ń gbádùn níní ìmọ̀lára ìtẹ̀síwájú, nítorí náà Jennifer dábàá pé: “Jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gbádùn mọ́ni. Jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa tẹ̀ síwájú.” Dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà déédéé láìpa àwọn ọ̀sẹ̀ kan jẹ tún máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti nímọ̀lára pé àwọn ń tẹ̀ síwájú. Aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan, tí a tọ́ dàgbà ní ìgbèríko, ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì mímú kí àlàyé yéni kedere àti títẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì, kí àwọn tí wọn kò tilẹ̀ kàwé púpọ̀ baà tẹ̀ síwájú. Ó wí pé: “Ní abúlé mi, a máa ń fọ́n omi sílẹ̀ lẹ́yìn gbígbin irúgbìn. Bí a bá fi omi pá ilẹ̀ náà lórí, erùpẹ̀ náà yóò lẹ̀ mọ́ra débi pé àwọn èso tí ń hù náà kì yóò lè yọ jáde, wọn yóò sì kú. Bákan náà, bí o bá fi kókó púpọ̀ pá àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ́kàn ìfẹ́ náà lórí, ó lè ṣòro púpọ̀, tí wọn yóò sì juwọ́ sílẹ̀.” Àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti wádìí pàápàá ní láti kọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí kókó kan lẹ́ẹ̀kan bí wọ́n bá ní láti tẹ̀ síwájú nínú òye. Jesu sọ fún àwọn aposteli rẹ̀ pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ lati wí fún yín, ṣugbọn ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí.”—Johannu 16:12.
Ọ̀nà míràn láti mú kí ọkàn-ìfẹ́ máa bá a lọ ni láti fún àwọn tí o bá bẹ̀ wò ní ìṣírí láti máa bá a lọ ní ríronú nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lẹ́yìn tí o bá ti lọ. Yolanda dámọ̀ràn pé: “Fi ìbéèrè kan sílẹ̀ láìdáhùn. Fún wọn ní iṣẹ́ àyànfúnni, bí i kíka apá kan nínú Bibeli tàbí ṣíṣèwádìí kókó kan tí ó kàn wọ́n.”
Mímú Ìfẹ́ fún Jehofa Dàgbà
Ayọ̀ rẹ yóò pọ̀ sí i, nígbà tí o bá ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti di “olùṣe ọ̀rọ̀ naa, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.” (Jakọbu 1:22) Báwo ni o ṣe lè ṣe ìyẹn? Ìfẹ́ fún Jehofa máa ń sún àwọn Kristian tòótọ́ ṣiṣẹ́. Pedro, tí ó wá láti Mexico, ṣàlàyé pé: “Àwọn ènìyàn kò lè nífẹ̀ẹ́ ẹni tí wọn kò mọ̀, nítorí náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, mo máa ń kọ́ wọn ní orúkọ Ọlọrun láti inú Bibeli, mo sì máa ń wá àǹfààní láti tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ Jehofa.” Nínú ìbánisọ̀rọ̀, o lè mú ìmọrírì fún Jehofa dàgbà nípa sísọ ìmọ̀lára rẹ nípa rẹ̀. Elizabeth sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti mẹnu kan ìwà rere Jehofa. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ mi, bí mo bá rí òdòdó dídára, ẹyẹ rírẹwà, tàbí ọmọ ológbò tí ń ṣeré, mo sábà máa ń mẹ́nu kàn án pé iṣẹ́ Jehofa ni.” Jennifer dábàá pé: “Sọ̀rọ̀ nípa ayé tuntun tí Ọlọrun ṣèlérí gẹ́gẹ́ bí ohun gidi ti o mọ̀ ọ́n sí. Béèrè ohun tí wọn yóò fẹ́ láti ṣe nínú ayé tuntun náà.”
Nígbà tí ẹnì kan bá ń ṣàṣàrò pẹ̀lú ìmọrírì lórí ohun tí ó kọ́ nípa Jehofa, ó máa ń wọnú ọkàn rẹ̀ ṣinṣin, ó sì máa ń sún un láti gbé ìgbésẹ̀. Ṣùgbọ́n kò lè ṣàṣàrò láìjẹ́ pé ó rántí. Àtúnyẹ̀wò kúkúrú lórí kókó pàtàkì mẹ́ta tàbí mẹ́rin lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ń ranni lọ́wọ́ láti rántí. Ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ń ní kí àwọn ẹni tuntun kọ àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó ṣe pàtàkì àti àkọsílẹ̀ sẹ́yìn Bibeli wọn. Míṣọ́nnárì kan láti England, ṣàlàyé àǹfààní mìíràn tí ṣíṣàtúnyẹ̀wò ní: “Mo máa ń béèrè bí àwọn ìsọfúnni náà ti ṣe wọ́n láǹfààní tó. Èyí ń jẹ́ kí wọ́n lè ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀nà àti òfin Jehofa lọ́nà tí ó fi ìmọrírì hàn.”
Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ kan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹta ti Gilead sọ pé: “A ní láti ní ìtara ọkàn. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa gbọ́dọ̀ mọ̀ pé a gba ohun tí a ń kọ́ni gbọ́.” Ìgbàgbọ́ tí ó sọ ọ́ di aláyọ̀ “olùṣe ọ̀rọ̀ naa” lè ràn án bí o bá fi hàn.—Jakọbu 1:25.
Ẹlẹ́rìí kan tí ó ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti jọ́sìn Jehofa sọ pé: “Mo rí i pé àwọn ènìyàn ń nímọ̀lára pé àwọn túbọ̀ ń sún mọ́ Ọlọrun bí mo bá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ìdáhùn sí àwọn àdúrà wọn. Mo máa ń fún wọn ní àwọn àpẹẹrẹ láti inú ìrírí ara mi, bí irú èyí: Nígbà tí èmi àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi dé ibi iṣẹ́ àyànfúnni wa gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, a ní ewébẹ̀ díẹ̀, pákẹ́ẹ̀tì margarine kan, a kò sì ní owó. A parí oúnjẹ náà ní alẹ́, a sì wí pé, ‘Wàyí o, a kò ní ohun kankan láti jẹ ní ọ̀la.’ A gbàdúrà nípa rẹ̀, a sì lọ sùn. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Ẹlẹ́rìí kan ládùúgbò kàn sí wa, ó sì fi ara rẹ̀ hàn ní sísọ pé, ‘Mo gbàdúrà pé kí Jehofa rán àwọn aṣáájú ọ̀nà wá. Nísinsìnyí mo lè tẹ̀ lé yín fún apá tí ó pọ̀ jù lọ lóòjọ́, ṣùgbọ́n níwọ̀n bí n kì í ti í gbé ní ìgboro, mo ní láti jẹun ọ̀sán pẹ̀lú yín, nítorí náà, mo gbé oúnjẹ yìí dání fún gbogbo wa.’ Ó jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran àti ewébẹ̀. Mo máa ń sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi pé, Jehofa kì yóò fi wa sílẹ̀ láé bí a bá wá Ìjọba rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.”—Matteu 6:33.
Pèsè Ìrànlọ́wọ́ Gbígbéṣẹ́
Ohun púpọ̀ wé mọ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn Kristi ju dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ. Míṣọ́nnárì kan tí ó ti ṣiṣẹ́ sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn àjò sọ pé: “Lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú wọn. Má ṣe kánjú lọ lẹ́yìn tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti parí. Bí ó bá yẹ, dúró, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀ fún ìgbà díẹ̀.” Elizabeth sọ pé: “Mo ní ọkàn-ìfẹ́ sí wọn nítorí ìwàláàyè wé mọ́ ọn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, mo máa ń ṣàníyàn nípa wọn bí i pé ọmọ mi ni wọ́n.” Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn dá àwọn àbá wọ̀nyí: “Bẹ̀ wọ́n wò nígbà tí wọ́n bá ń ṣàìsàn.” “Fún àpẹẹrẹ, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, nígbà tí o bá wà ní tòsí ilé wọn, bẹ̀ wọ́n wò ní ṣókí láti fi àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn hàn wọ́n.” Eva sọ pé: “Fetí sílẹ̀ dáradára láti lóye ipò àtilẹ̀wá ẹni náà àti ipò rẹ̀ nínú ìgbésí ayé. Àwọn wọ̀nyí ń nípa lórí bí àwọn ènìyàn ṣe ń hùwà padà sí òtítọ́, ó sì lè dí ìtẹ̀síwájú wọn lọ́wọ́. Di ọ̀rẹ́ wọn, kí ọkàn wọn lè balẹ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro wọn.” Carol fi kún un pé: “Ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ nínú ẹni náà ṣe pàtàkì nítorí pé àwọn ìyípadà tí òtítọ́ yóò mú wá bá ìgbésí ayé rẹ̀, nígbà míràn lè túmọ̀ sí pípàdánù ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó dára bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá mọ ibi tí a ń gbé, kí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ láti tọ̀ wá wá nígbàkigbà.” Ràn án lọ́wọ́ láti fojú wo ìjọ náà gẹ́gẹ́ bí ìdílé rẹ̀ tuntun.—Matteu 10:35; Marku 10:29‚ 30.
Yolanda sọ pé: “Wà lójúfò láti pèsè ìrànlọ́wọ́ gbígbéṣẹ́. Jókòó pa pọ̀ pẹ̀lú wọn ní ìpàdé, kí o sì ran àwọn àti àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́.” Fífi han àwọn ẹni tuntun, bí wọ́n ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà, mú kí ìwànítónítóní wọn sunwọ̀n sí i, múra ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé, kí wọ́n sì sọ àsọyé nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ apá kan iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Arábìnrin mìíràn fi kún un pé: “Ó ṣe pàtàkì láti dá àwọn ẹni tuntun lẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Nígbà tí a bá gbójú fo apá ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, àwọn kan yóò máa bá a lọ láti máa bẹ̀rù iṣẹ́ ìwàásù, wọn yóò sọ ayọ̀ wọn nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa nù, wọn yóò sì kùnà láti lo ìfaradà.” Nítorí náà, pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí a fara balẹ̀ ṣe nínú iṣẹ́ ilé dé ilé, nínú ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò, àti nínú bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ayọ̀ rẹ yóò kún, nígbà tí o bá rí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ tí ń tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà rẹ.
Fún Wọn Lókun Láti Lo Ìfaradà
Ẹnì kan tí ó jẹ́ onírìírí nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn kìlọ̀ pé: “Ìtẹ̀sí náà wà láti gbójú fo kíkẹ́kọ̀ọ́ dá, gbàrà tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti ṣe batisí.” Olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ rántí pé, Kristian kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí kò tí ì dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. Ó ní púpọ̀ láti ṣe nínú mímú ìgbàgbọ́ rẹ̀, ìmọrírì rẹ̀ fún òfin Ọlọrun, àti ìfẹ́ rẹ̀ fún Jehofa dàgbà. Ó ṣe pàtàkì láti fún un ní ìṣírí láti mú àṣà ìdákẹ́kọ̀ọ́ dídára dàgbà, kí ó lè máa bá a nìṣó láti máa tẹ̀ síwájú.—1 Timoteu 4:15.
Ẹni tuntun náà lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú, kí ó sì di mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ àwọn ará tí ó lẹ́mìí àlejò. Ó lè nílò ìtọ́sọ́nà ní bíbá àìpé àwọn arákùnrin lò bí ó ti ń sún mọ́ wọn sí i. (Matteu 18:15-35) Ó lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti di olùkọ́ni tí ó jáfáfá, tí ó lè dá ṣe ìwádìí fúnra rẹ̀. Míṣọ́nnárì kan ròyìn pé: “Akẹ́kọ̀ọ́ kan lẹ́yìn ṣíṣe batisí, fẹ́ láti mú agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni dàgbà, nítorí náà ó wí fún mi pé, ‘Mo ní láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun kan ní ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n mo ní láti rán ara mi létí àwọn orí àkọ́kọ́ tí mo kẹ́kọ̀ọ́. Jọ̀wọ́, o ha lè ṣàyẹ̀wò àwọn orí wọ̀nyí pẹ̀lú mi lẹ́ẹ̀kan sí i bí, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí n lè ṣe àwọn àkọsílẹ̀ àwọn àlàyé ìwé mímọ́ àti àwọn àpèjúwe, nígbà náà kí n sì lè lò wọ́n nígbà tí mo bá lọ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ tèmi?’ Ó ti di olùkọ́ni títayọ lọ́lá, tí mẹ́rin nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe batisí ní àpéjọ kan.”
Ìdí Tí Ìsapá Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Fi Yẹ
Pamela sọ pé: “Sísọni di ọmọ ẹ̀yìn túmọ̀ sí pé àwọn olùyin Jehofa yóò pọ̀ sí i. Ó túmọ̀ sí ìyè fún àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Mo ṣáà nífẹ̀ẹ́ sí kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́—ó wuyì púpọ̀! Ènìyàn ń rí i bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń dàgbà díẹ̀díẹ̀, tí wọ́n ń ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn, tí wọ́n sì ń borí àwọn ìṣòro tí ó dà bí ohun tí kò ṣe é borí bí kì í bá ṣe ti ẹ̀mí Jehofa. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jehofa báyìí ti di ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n.”
Míṣọ́nnárì kan láti Germany ròyìn pé: “Nígbà tí mo bá rántí àwọn tí mo ti ràn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn, mo máa ń rí àwọn ojo ènìyàn tí wọ́n ti tẹ̀ síwájú dáradára gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ fún Ọlọrun, tí ó sì máa ń yà mí lẹ́nu gidigidi. Mo rí àwọn ènìyàn tí ó dájú pé ìrànlọ́wọ́ Jehofa ti mú kí wọ́n borí àwọn ìdènà apániláyà. Mo rí àwọn ìdílé tí wọ́n ti fìgbà kan yapa, ṣùgbọ́n tí wọ́n ti wà pa pọ̀ nísinsìnyí—àwọn ọmọ aláyọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí tí wọ́n níláárí. Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbádùn ìgbésí ayé tí ó nítumọ̀, tí ń yin Jehofa. Èyí ni ayọ̀ sísọ ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn.”
Bẹ́ẹ̀ ni, jíjẹ́ alájùmọ̀ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ orísun ayọ̀ tí kò láfiwé. Ìrírí àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà ti fi ẹ̀rí hàn pé èyí jẹ́ òtítọ́. O lè rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn kan náà, bí o bá fi àwọn àbá náà sílò, tí o sì ń ṣiṣẹ́ lé e lórí tọkàntọkàn. Pẹ̀lú ìbùkún Jehofa, ayọ̀ rẹ yóò pé pérépéré.—Owe 10:22; 1 Korinti 15:58.