Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ẹ̀jẹ́ Ìgbéyàwó rẹ!
ỌJỌ́ ìgbéyàwó jẹ́ ọjọ́ aláyọ̀. Ó tún jẹ́ àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe kókó. Ọkọ àti ìyàwó ṣe ìlérí onírònújinlẹ̀ tí yóò nípa lórí apá ìgbésí ayé wọn tí ó kù. Àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi ìgbéyàwó náà gẹ́gẹ́ bí àlejò jẹ́ àwọn ẹlẹ́rìí ìlérí onírònújinlẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n Jehofa Ọlọrun ni Ẹlẹ́rìí pàtàkì jù lọ.
Bibeli kò béèrè fún àwọn ìlànà kan ní pàtó tàbí irú ayẹyẹ àkànṣe kan fún ìgbéyàwó. Síbẹ̀, ní kíkíyè sí orísun àtọ̀runwá rẹ̀, ìgbéyàwó ni a sábà máa ń ṣe lọ́nà ọlọ́wọ̀ nípasẹ̀ lílo ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó nígbà ayẹyẹ ìsìn. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń lo ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó tí ó tẹ̀ lé e yìí: “Èmi —— mu ìwọ —— láti jẹ́ (aya/ọkọ) tí mo bá ṣe ìgbéyàwó, láti nífẹ̀ẹ́ àti láti ṣìkẹ́ rẹ̀ (Ìyàwó: àti láti máa bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún) ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọ̀runwá bí a ti là á lẹ́sẹẹsẹ nínú Ìwé Mímọ́ fún àwọn (ìyàwó/ọkọ) Kristian, níwọ̀n ìgbà tí àwa méjèèjì bá wà láàyè pa pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní ìbámu pẹ̀lú ìṣètò ìgbéyàwó tí Ọlọrun ṣe.”a
Ohun Kan Láti Ronú Lé Lórí
Bí o bá ń pète láti ṣe ìgbéyàwó, yóò jẹ́ ohun ṣíṣeyebíye láti ronú nípa bí ẹ̀jẹ́ yìí ti jinlẹ̀ tó àti ìtumọ̀ rẹ̀, ṣáájú ọjọ́ ìgbéyàwó. Solomoni wí pé: “Má ṣe fi ẹnú rẹ yára kí o má sì jẹ́ kí àyà rẹ kí ó yára sọ ọ̀rọ̀ níwájú Ọlọrun.” (Oniwasu 5:2) Bí o bá ti ṣe ìgbéyàwó ńkọ́? Nígbà náà, ìwọ yóò jàǹfààní láti inú ṣíṣàṣàrò lórí ìjẹ́pàtàkì ìlérí onírònújinlẹ̀ tí o ṣe níwájú Jehofa. O ha ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀ bí? Àwọn Kristian máa ń mú àwọn ìlérí wọn ní ọ̀kúnkúndùn. Solomoni tẹ̀ síwájú pé: “San èyí tí ìwọ́ jẹ́jẹ̀ẹ́. Ó sàn kí ìwọ kí ó máà jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju kí ìwọ kí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́, kí ó má san án. Má ṣe jẹ́ kí ẹnú rẹ kí ó mú ara rẹ ṣẹ̀: kí ìwọ kí ó má sì ṣe wí níwájú ìránṣẹ́ Ọlọrun pé, èèṣì ni o ṣe.”—Oniwasu 5:4-6.
Dájúdájú, yíyẹ àpólà gbólóhùn ẹ̀jẹ́ náà wò níkọ̀ọ̀kan, yóò mú kí o túbọ̀ lóye ìlérí ọlọ́wọ̀ yìí dáradára.
“Èmi —— mú ìwọ”: Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀jẹ́ náà. Wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé o tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ ara ẹni fún ìpinnu rẹ láti ṣe ìgbéyàwó.
Lábẹ́ ìṣètò Kristian, Ìwé Mímọ́ kò kàn án nípá fún wa láti ṣe ìgbéyàwó. Jesu Kristi fúnra rẹ̀ dúró láìgbéyàwó, ó sì dábàá wíwà ní àpọ́n fún àwọn tí wọ́n “bá lè wá àyè fún un.” (Matteu 19:10-12) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn aposteli Jesu jẹ́ ọkọlóbìnrin. (Luku 4:38; 1 Korinti 9:5) Ó ṣe kedere pé, láti gbéyàwó jẹ́ ìpinnu ara ẹni. Kò sí ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó ní àṣẹ tí Ìwé Mímọ́ fún ní àṣẹ láti fipá mu ẹnì kan láti ṣe ìgbéyàwó.
Nítorí náà, ìwọ ni o ni ẹrù iṣẹ́ yíyàn láti ṣe ìgbéyàwó. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, ìwọ ni o yan ẹni tí ìwọ yóò bá ṣe ìgbéyàwó. Nígbà tí o ba ń jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó, tí o ń sọ pé, ‘Mo mú ìwọ ——,’ o mú tàbí tẹ́wọ́ gba ẹni náà pẹ̀lú àwọn ìwà funfun rẹ̀—ṣùgbọ́n àti àwọn àléébù rẹ̀ pẹ̀lú.
Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣeé ṣe kí ó rí àwọn apá kan nínú àkópọ̀ ẹ̀dá ẹnì kejì rẹ tí o kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Àwọn ìjákulẹ̀ yóò wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bibeli sọ pé, “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀ wọ́n sì ti kùnà lati kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọrun.” (Romu 3:23) Nítorí náà, o lè ní láti ṣe àwọn àtúnṣe kan kí o baà lè bá ẹnì kejì rẹ gbé. Èyí lè ṣòro, o sì lè fẹ́ láti bọ́hùn nígbà míràn. Ṣùgbọ́n rántí pé, ẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó níwájú Jehofa. Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí.
“Láti jẹ́ (aya/ọkọ) tí mo bá ṣe ìgbéyàwó”: Nígbà ìgbéyàwó àkọ́kọ́, nígbà tí a fi Efa fún Adamu gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, Jehofa Ọlọrun wí pé “wọn óò sì di ara kan.” (Genesisi 2:24; Matteu 19:4-6) Nípa báyìí, ìsopọ̀ ìgbéyàwó ni ipò ìbátan tí ó ṣe tímọ́tímọ́ jù lọ tí ó lè wà láàárín ẹ̀dá ènìyàn méjì. Ìgbéyàwó mú ọ wọnú ìbátan tuntun. O tẹ́wọ́ gba ẹnì kan gẹ́gẹ́ bí “ìyàwó tí o bá ṣe ìgbéyàwó” tàbí “ọkọ tí o bá ṣe ìgbéyàwó.” Kò rí bí ipò ìbátan kankan mìíràn. Àwọn ìwà tí kò lè ṣe ọṣẹ́ kankan nínú ipò ìbátan mìíràn, lè ṣe ọṣẹ́ gíga gan-an nínú ìṣètò ìgbéyàwó.
Fún àpẹẹrẹ, wo ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tí ó wà nínú Efesu 4:26. Bibeli sọ níbẹ̀ pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má sì ṣe ṣẹ̀; ẹ máṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín ninu ipò ìtánnísùúrù.” Bóyá o kì í fìgbà gbogbo yanjú àwọn ìṣòro rẹ pẹ̀lú àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ní kíákíá bí ó ti yẹ kí o ṣe. Ṣùgbọ́n ẹnì kejì rẹ nínú ìgbéyàwó sún mọ́ ọ ju ẹbí àti ọ̀rẹ́ kankan lọ. Kíkọ̀ láti yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ lè wu ìbátan pàtàkì tí ó wà láàárín yín léwu.
O ha ń fàyè gba èdè-kò-yedè láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ̀ nínú ìgbéyàwó láti dàgbà di orísun ìbínú tàbí ìrunú tí yóò máa bá a lọ́ bí? Èdè-kò-yedè àti àwọn ìpò tí ń mú ọkàn gbọgbẹ́ ha máa ń bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ bí? Kí o baà lè hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ rẹ, nígbà tí ìṣòro bá dìde, má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ kan lọ láìwá àlàáfíà pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ nínú ìgbéyàwó. Èyí túmọ̀ sí dídarí jini àti gbígbọ́kàn fò ó, àti pẹ̀lú, títẹ́wọ́ gba àwọn àṣìṣe àti ìṣìnà tìrẹ.—Orin Dafidi 51:5; Luku 17:3‚ 4.
“Láti nífẹ̀ẹ́”: Ẹni tí yóò di ọkọ ìyàwó náà jẹ́jẹ̀ẹ́ “láti nífẹ̀ẹ́ àti láti ṣìkẹ́” ìyàwó rẹ̀. Ìfẹ́ yìí ní ti eléré ìfẹ́ tí ó ṣeé ṣe kí ó mú wọn pa pọ̀ nínú. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ eléré ìfẹ́ kò tó. Ìfẹ́ tí Kristian kan jẹ́jẹ̀ẹ́ rẹ̀ fún ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ jinlẹ̀ ó sì gbòòrò ju èyí lọ.
Efesu 5:25 sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ awọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹlu ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ.” Ó dájú pé ìfẹ́ Jesu fún ìjọ kì í ṣe ti eléré ìfẹ́ tí ó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Ọ̀rọ̀ náà “nínífẹ̀ẹ́” àti “nífẹ̀ẹ́” tí a lò nínú ìwé mímọ́ yìí wá láti inú ọ̀rọ̀ náà a·gaʹpe, tí ó tọ́ka sí ìfẹ́ tí ìlànà ń darí. Níhìn-ín, Bibeli ń pàṣẹ fún àwọn ọkọ láti fi ìfẹ́ tí kò mì, tí ń fara dà nígbà gbogbo hàn fún àwọn ìyàwó wọn.
Kì í wulẹ̀ ṣe irú onímọ̀lára “mo nífẹ̀ẹ́ rẹ nítorí pé o nífẹ̀ẹ́ mi.” Ọkọ ń wá ire aya rẹ̀ ṣáájú tirẹ̀ pàápàá, aya sì nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́nà kan náà. (Filippi 2:4) Mímú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ dàgbà fún ẹnì kejì rẹ nínú ìgbéyàwó yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ.
“Láti ṣìkẹ́”: Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè kan ti wí, “láti ṣìkẹ́” túmọ̀ sí ‘láti mú gẹ́gẹ́ bí ẹni ọ̀wọ́n, láti ní ìmọ̀lára tàbí fi ìfẹ́ni hàn sí.’ O gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ rẹ hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe! Ní pàtàkì, aya ní láti rí ìfihàn ìfẹ́ ọkọ rẹ̀ nígbà gbogbo. Ọkọ rẹ̀ lè máa kájú ìwọ̀n àìní rẹ̀ nípa ti ara, ṣùgbọ́n èyí kò tó. Àwọn aya kan wà tí wọ́n ní oúnjẹ púpọ̀ tó àti ilé tí ó tura, ṣùgbọ́n tí wọn kò láyọ̀ rárá nítorí pé ẹnì kejì wọn nínú ìgbéyàwó kò bìkítà nípa wọn tàbí pé ó pa wọ́n tì.
Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, dájúdájú, aya kan tí ó mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun tí a sì ṣìkẹ́ òun ní ìdí láti láyọ̀. Òtítọ́ ni pé, èyí rí bẹ́ẹ̀ ní ti ọkọ náà pẹ̀lú. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń fi bí ẹnì kan ṣe ṣọ̀wọ́n tó hàn, ń mú ìfẹ́ tòótọ́ lágbára sí i. Nínú Orin Solomoni, olùṣọ́ àgùntàn olólùfẹ́ náà wí jáde pé: “Wo bí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ tí ń fi bí mo ṣe ṣọ̀wọ́n tó hàn ṣe dára tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Wo bí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ tí ń fi bí mo ṣe ṣọ̀wọ́n tó hàn, ṣe dùn ju wáìnì lọ àti òórùn dídùn òróró rẹ sì dára ju òórùn dídùn èyíkéyìí lọ!”—Orin Solomoni 4:10, NW.
“Àti láti máa bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún”: Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún wá, àwọn ọkùnrin, tí wọ́n fìyà jẹ àwọn obìnrin tí wọ́n sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ wà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn World Health ti sọ, lónìí pàápàá, “ìwà ipá sí àwọn obìnrin ń wáyé ní gbogbo orílẹ̀-èdè àti ní gbogbo àwùjọ ẹ̀gbẹ́ òun ọ̀gbà àti ti ètò ọrọ̀ ajé. Nínú ọ̀pọ̀ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, wọ́n ka lílu aya sí ẹ̀tọ́ ọkùnrin.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin lè má jẹ̀bi ìwà yìí. Síbẹ̀, ó dà bíi pé púpọ̀ àwọn ọkùnrin kùnà láti fi ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú àwọn ọ̀ràn tí ó kan àwọn obìnrin. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ti mú ìṣarasíhùwà tí ó lòdì dàgbà nípa àwọn ọkùnrin. A ti gbọ́ tí àwọn aya kan sọ pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi, ṣùgbọ́n n kò kàn lè bọ̀wọ̀ fún un ni!”
Ṣùgbọ́n, Jehofa Ọlọrun gbóríyìn fún obìnrin tí ó bá ń tiraka láti bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀—bí kò bá tilẹ̀ kájú òṣùwọ̀n ohun tí ìyàwó náà ń retí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà. Ó mọ̀ pé ó ní iṣẹ́ àyànfúnni, tàbí ipò kan tí Ọlọrun fún un. (1 Korinti 11:3; Efesu 5:23) Nípa báyìí, ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀ jẹ́ apá kan ìjọsìn àti ìgbọràn rẹ̀ sí Jehofa. Ọlọrun kì í gbójú fo ìgbọràn àwọn obìnrin tí ń ṣèfẹ́ rẹ̀.—Efesu 5:33; 1 Peteru 3:1-6; fi wé Heberu 6:10.
Ọ̀wọ̀ nínú ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a ṣe ní pàṣípààrọ̀, a sì gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ fún un dípò wíwulẹ̀ retí tàbí béèrè fún un. Fún àpẹẹrẹ, kò sí àyè fún òdì ọ̀rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ ìbínú nínú ìṣètò ìgbéyàwó. Láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ń buni kù nípa ọkọ tàbí ìyàwó rẹ kì yóò fi ìfẹ́ tàbí ọ̀wọ̀ hàn. Kò sí ohun dídára kankan tí ó lè wá láti inú sísọ àwọn àléébù ẹnì kejì rẹ nínú ìgbéyàwó fún àwọn ẹlòmíràn tàbí sísọ wọ́n ní gbangba. Nínú àwàdà pàápàá, ẹnì kan lè fi àìlọ́wọ̀ tí ó ga hàn nínú ọ̀ràn yìí. Ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Efesu 4:29‚ 32 kan àtọkọ àtaya. Bibeli sọ níbẹ̀ pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà máṣe ti ẹnu yín jáde, bíkòṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní naa bá ṣe wà . . . Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nìkínní kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.”
“Ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọ̀runwá bí a ti là á lẹ́sẹẹsẹ nínú Ìwé Mímọ́”: Ọlọrun fẹ́ kí a gbádùn òmìnira yíyàn àti ìwà híhù. Kò fi àkọsílẹ̀ jàn-ànràn jan-anran àwọn ìlànà tí ń darí ìgbésí-ayé ìdílé dẹrù pa wá. Síbẹ̀, nítorí tiwa, ó pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà kan.
Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde lórí ìgbéyàwó wà ní yanturu, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ní àwọn ọgbọ́n èrò orí tiwọn. Ṣùgbọ́n ṣọ́ra! Lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó, ọ̀pọ̀ àwọn ìsọfúnni tí ń lọ káàkiri ni wọ́n forí gbárí pẹ̀lú Bibeli.
Tún mọ̀ pé àyíká ipò tọkọtaya kan yàtọ̀ sí ti àwọn mìíràn. Ní ọ̀nà kan, àwọn tọkọtaya dà bí àwọn yìnyín pẹlẹbẹ; láti òkèèrè, wọ́n lè rí bákan náà, ṣùgbọ́n ní ti gidi, ọ̀kan kò bá èkejì dọ́gba, wọ́n yàtọ̀ sí ara wọn. Ìdàpọ̀ àwọn àkópọ̀ ìwà rẹ pẹ̀lú ti ẹnì kejì rẹ kò rí bákan náà pẹ̀lú ti àwọn tọkọtaya mìíràn ní àgbáyé. Nítorí náà má ṣe yára láti gba ojú ìwòye ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn. Kò sí ọ̀nà ìgbàṣe tí ènìyàn ṣe tí ó ṣeé fi sílò nínú gbogbo ìgbéyàwó!
Ní ìyàtọ̀ gédégbé, gbogbo àwọn àṣẹ Bibeli ni ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì ṣeé fi sílò. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mí sí ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́nisọ́nà, fún mímú awọn nǹkan tọ́.” (2 Timoteu 3:16; Orin Dafidi 119:151) Bí o bá ń ka Bibeli tí o sì gba àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí atọ́nà nínú ìgbésí ayé rẹ ojoojúmọ́, ìwọ yóò lè hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ.—Orin Dafidi 119:105.
“Níwọ̀n ìgbà tí awa méjèèjì bá wà láàyè pa pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé”: Èyí tọ́ka sí ìwàpapọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́. Ọlọrun pàṣẹ pé “ọkùnrin yóò . . . fi bàbá òun ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀.” (Genesisi 2:24) Jehofa fẹ́ kí ẹ jọ wà pa pọ̀. Ẹ ṣiṣẹ́ sin Ọlọrun pa pọ̀. Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa pọ̀. Ẹ wá àyè láti rìn pa pọ̀, jókòó pa pọ̀, jẹun pa pọ̀. Ẹ gbádùn ìgbésí ayé pa pọ̀!
Àwọn tọkọtaya kan ń sapá láti fi àyè sílẹ̀ lójoojúmọ́ láti kàn bá ara wọn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún ìgbéyàwó pàápàá, ìwàpapọ̀ yìí ṣe pàtàkì fún ayọ̀ ìgbéyàwó.
“Ní ìbámu pẹ̀lú ìṣètò ìgbéyàwó ti Ọlọrun ṣe”: Ìgbéyàwó jẹ́ ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun, ẹni tí ó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀. (Owe 19:14) Kì í ṣe ayọ̀ ìgbéyàwó rẹ nìkan ni kíkùnà láti tẹ̀ lé ètò rẹ̀ yóò wu léwu, ṣùgbọ́n ipò ìbátan rẹ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá pẹ̀lú. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà tí ọkọ àti aya bá mú ipò ìbátan dídára pẹ̀lú Jehofa dàgbà, tí wọ́n fi èyí hàn nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn ètò rẹ̀, wọn yóò ní ipò ìbátan alálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, títí kan ara wọn lẹ́nì kíní kejì.—Owe 16:7.
Má ṣe gbàgbé láé pé Jehofa ni Ẹlẹ́rìí pàtàkì jù lọ sí ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ. Máa bá a nìṣó láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí onírònújinlẹ̀ yìí, ìgbéyàwó rẹ yóò sì jẹ́ orísun ìyìn àti ògo fún Jehofa Ọlọrun!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní àwọn ibì kan, wọ́n lè ní láti lo ẹ̀dà ẹ̀jẹ́ yìí tí a ti yí padà kí ó baà lè bá àwọn òfin àdúgbò mu. (Matteu 22:21) Ṣùgbọ́n, ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó pọ̀ jù, àwọn Kristian tọkọtaya ń lo ẹ̀jẹ́ òkè yìí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
Ní ọ̀nà kan, àwọn tọkọtaya dà bíi yìnyín pẹlẹbẹ. Gbogbo wọ́n lè rí bákan náà láti òkèèrè, ṣùgbọ́n ní ti gidi, tọkọtaya kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ gédégbé
[Credit Line]
Snow Crystals/Dover