Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jehofa
Ní Kíkọbi Ara sí Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìdágbére Jesu
NÍRỌ̀LẸ́ Nisani 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jesu Kristi àti àwọn aposteli rẹ̀ 11 olùṣòtítọ́ jókòó yí tábìlì kan ká ní yàrá òkè ní Jerusalemu. Ní mímọ̀ pé ikú òun ti sún mọ́lé, ó sọ fún wọn pé: “Ìgbà díẹ̀ sí i ni emi yoo fi wà pẹlu yín.” (Johannu 13:33) Ní tòótọ́, Judasi Iskariotu ti mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti dìtẹ̀ pẹ̀lú àwọn olubi tí wọ́n fẹ́ pa Jesu.
Kò sí ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí wọ́n wà ní yàrá òkè yẹn tí ó ní òye ìjẹ́kánjúkánjú ipò náà ju bí Jesu ti ní in lọ. Ó mọ̀ dájú pé ìjìyà òún ti sún mọ́lé. Jesu tún mọ̀ pé àwọn aposteli òun yóò pa òun tì ní òru yẹn gan-an. (Matteu 26:31; Sekariah 13:7) Níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ àǹfààní ìkẹyìn tí Jesu ní láti bá àwọn aposteli rẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, a lè ní ìdánilójú pé àwọn ọ̀rọ̀ ìdágbére rẹ̀ darí àfiyèsí sí àwọn ọ̀ràn pàtàkì jù lọ.
“Ẹ Máa Ṣe Èyí ní Ìrántí Mi”
Jesu dá ayẹyẹ tuntun tí yóò rọ́pò Àjọ Ìrékọjá àwọn Júù sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn aposteli rẹ̀ olùṣòtítọ́. Aposteli Paulu pè é ní “oúnjẹ alẹ́ Oluwa.” (1 Korinti 11:20) Nígbà tí ó mú ìṣù búrẹ́dì aláìwú, Jesu gbàdúrà. Ó bu ìṣù búrẹ́dì náà, ó sì fún àwọn aposteli rẹ̀. Ó wí pé: “Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.” Lẹ́yìn náà, ó mú ife wáìnì kan, ó gbàdúrà ìdúpẹ́, ó sì fún àwọn aposteli rẹ̀, ní sísọ pé: “Ẹ mu ninu rẹ̀, gbogbo yín; nitori èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì awọn ẹ̀ṣẹ̀.”—Matteu 26:26-28.
Kí ni ìjẹ́pàtàkì ìṣẹ̀lẹ̀ yìí? Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti fi hàn, búrẹ́dì náà ṣàpẹẹrẹ ara rẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀. (Heberu 7:26; 1 Peteru 2:22, 24) Wáìnì náà dúró fún ẹ̀jẹ̀ Jesu tí a ta sílẹ̀, èyí tí yóò mú kí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ṣeé ṣe. Ẹ̀jẹ̀ ìrúbọ rẹ̀ yóò tún fìdí májẹ̀mú tuntun láàárín Jehofa Ọlọrun àti 144,000 ẹ̀dá ènìyàn múlẹ̀, àwọn tí yóò ṣàkóso pẹ̀lú Jesu ní ọ̀run ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. (Heberu 9:14; 12:22-24; Ìṣípayá 14:1) Nípa kíké sí àwọn aposteli rẹ̀ láti ṣàjọpín nínú oúnjẹ yìí, Jesu fi hàn pé, wọn yóò ṣàjọpín pẹ̀lú òun nínú Ìjọba ọ̀run.
Nípa oúnjẹ ìrántí yìí, Jesu pàṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Luku 22:19) Bẹ́ẹ̀ ni, Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa yóò di ìṣẹ̀lẹ̀ ọdọọdún, gan-an gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìrékọjá ti jẹ́. Nígbà tí Àjọ Ìrékọjá ń ṣe ìrántí ìdáǹdè àwọn ọmọ Israeli kúrò ní oko ẹrú ní Egipti, Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa yóò darí àfiyèsí sí ìdáǹdè tí ó tóbi lọ́lá jù lọ́pọ̀lọpọ̀—ti aráyé tí ó ṣeé rà padà kúrò nínú oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (1 Korinti 5:7; Efesu 1:7) Síwájú sí i, àwọn tí ń ṣàjọpín nínú búrẹ́dì àti wáìnì ìṣàpẹẹrẹ ni a óò rán létí àwọn àǹfààní wọn ọjọ́ ọ̀la gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà nínú Ìjọba Ọlọrun ní ọ̀run.—Ìṣípayá 20:6.
Ní ti gàsíkíá, ikú Jesu Kristi ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Àwọn tí wọ́n mọrírì ohun tí Jesu ṣe, ń ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ nípa Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń rántí ikú Jesu lọ́dọọdún ní ọjọ́ tí ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú Nisani 14. Ní 1996, ọjọ́ yìí bọ́ sí April 2, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. A fi tìfẹ́tìfẹ́ pè ọ́ láti wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà ní agbègbè rẹ.
‘Mo Fún Yín Ní Àṣẹ Titun’
Yàtọ̀ sí dídá Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa sílẹ̀, Jesu ní ìmọ̀ràn ìdágbére fún àwọn aposteli rẹ̀. Láìka ìdálẹ́kọ̀ọ́ àtàtà wọn sí, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣì ní ohun púpọ̀ láti kọ́. Wọn kò lóye ète Ọlọrun fún Jesu, fún wọn, tàbí fún ọjọ́ ọ̀la, lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ṣùgbọ́n, Jesu kò gbìyànjú láti mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣe kedere ní àkókò yìí. (Johannu 14:26; 16:12, 13) Dípò èyí, ó sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí ó ṣe pàtàkì púpọ̀. Ó wí pé: “Emi ń fún yín ní àṣẹ titun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nìkínní kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹlu nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nìkínní kejì.” Lẹ́yìn náà, Jesu fi kún un pé: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Johannu 13:34, 35.
Ní ọ̀nà wo ni èyí fi jẹ́ “àṣẹ titun”? Toò, Òfin Mose pàṣẹ pé: “Kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnì kejì rẹ bí ara rẹ.” (Lefitiku 19:18) Ṣùgbọ́n, Jesu ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn òún fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn tí yóò dé orí fífi ìwàláàyè ẹni lélẹ̀ nítorí àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni. Ó dájú pé, ‘òfin ìfẹ́’ yóò tún kan àwọn ipò tí kò le koko púpọ̀ jù. Ní gbogbo ipò, ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi yóò lo ìdánúṣe láti fi ìfẹ́ hàn nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti lọ́nà míràn.—Galatia 6:10.
Ní òru ọjọ́ yìí tí ó kẹ́yìn nínú ìgbésí ayé Jesu lórí ilẹ̀ ayé, ìfẹ́ sún Jesu láti gbàdúrà sí Jehofa Ọlọrun nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Lápá kan, ó gbàdúrà pé: “Wọ́n wà ní ayé emi sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn nítìtorí orúkọ tìrẹ èyí tí iwọ ti fi fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí awa ti jẹ́.” (Johannu 17:11) Ó yẹ fún àfiyèsí pé, nínú ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ yìí sí Bàbá rẹ̀, Jesu gbàdúrà fún ìṣọ̀kan onífẹ̀ẹ́ láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Johannu 17:20-23) Wọ́n ní láti ‘nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nìkíní kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí Jesu ti nífẹ̀ẹ́ wọn.’—Johannu 15:12.
Àwọn aposteli olùṣòtítọ́ kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ ìdágbére Jesu. Àwa pẹ̀lú ní láti tẹ̀ lé àwọn àṣẹ rẹ̀. Ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” líle koko wọ̀nyí, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan láàárín àwọn olùjọsìn tòótọ́ ṣe pàtàkì ju ti ìgbàkigbà rí lọ. (2 Timoteu 3:1) Ní tòótọ́, àwọn Kristian tòótọ́ ń ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jesu, wọ́n sì ń fi ìfẹ́ ará hàn. Èyí ní nínú ṣíṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ láti ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa.