Jehofa Olùfẹ́ Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
Ọ̀DỌ́MỌBÌNRIN kan ní Sarajevo bí ara rẹ̀ léèrè ìdí tí àwọn ọmọdé ní ìlú rẹ̀ ṣe ní láti fara da ìyà tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “A kò ṣe ohunkóhun. A kò mọwọ́ mẹsẹ̀.” Àwọn ìyá ará Argentina, tí ń ṣàníyàn gidigidi ti ṣe ìwọ́de ní gbàgede Buenos Aires fún nǹkan bí ọdún 15, ní fífi ẹ̀hónú hàn sí bí àwọn ọmọkùnrin wọn ṣe pòórá. Ará Áfíríkà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Emmanuel, ẹni tí a pa ìyá rẹ̀ àti àwọn arábìnrin rẹ̀ mẹ́ta nípakúpa nígbà tí ìwà ipá ẹ̀yà ìran bẹ́ sílẹ̀, rin kinkin pé: “Olúkúlùkù gbọ́dọ̀ gba èrè tí ó yẹ ẹ́ . . . A ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo.”
Ìdájọ́ òdodo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olórí ànímọ́ Jehofa Ọlọrun. Bibeli sọ pé: “Ìdájọ́ òdodo ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” Ní tòótọ́, Jehofa jẹ́ “olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.” (Deuteronomi 32:4, NW; Orin Dafidi 33:5, NW) Láti mọ Ọlọrun dáradára, a gbọ́dọ̀ lóye ọgbọ́n ìdájọ́ òdodo rẹ̀, kí a sì kọ́ láti tẹ̀ lé e.—Hosea 2:19, 20; Efesu 5:1.
Ó ṣeé ṣe kí ohun tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ka ìdájọ́ òdodo sí ti nípa lórí ìpìlẹ̀ èrò wa nípa ohun tí ànímọ́ yìí jẹ́. Ní àwọn apá ibì kan nínú ayé, a sábà máa ń ṣàpèjúwe ìdájọ́ òdodo gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí a fi aṣọ dì lójú, tí ó mú idà àti òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì dání. A lérò pé ìdájọ́ òdodo ti ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ aláìṣègbè, ìyẹn ni pé, ọrọ̀ tàbí agbára kò ní ipa lórí rẹ̀. Ó ní láti fi òṣùwọ̀n wọn ẹ̀bi tàbí àre ẹni tí a fẹ̀sùn kan náà dáradára. Pẹ̀lú idà rẹ̀, ìdájọ́ òdodo ní láti dáàbò bo aláìmọwọ́mẹsẹ̀, kí ó sì fìyà jẹ oníwà àìtọ́.
Ìwé náà, Right and Reason—Ethics in Theory and Practice, sọ pé, “ìdájọ́ òdodo ní í ṣe pẹ̀lú òfin, ojúṣe, ẹ̀tọ́, àti ẹrù iṣẹ́, kí ó sì san èrè láìṣègbè tàbí ṣe ojúsàájú.” Ṣùgbọ́n ìdájọ́ òdodo Jehofa lọ ré kọjá ìyẹn. A lè rí èyí nípa gbígbé àwọn ìṣe àti ànímọ́ Jesu Kristi yẹ̀ wò, ẹni tí ó jọ Bàbá rẹ̀ ọ̀run púpọ̀.—Heberu 1:3.
Òǹkọ̀wé Ìròyìn Rere náà, Matteu, lo àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah 42:3 fún Jesu, ní sísọ pé: “Kò sí esùsú kankan tí a ti pa lára tí oun yoo tẹ̀fọ́, kò sì sí òwú àtùpà kankan tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú tí oun yoo fẹ́pa, títí oun yoo fi rán ìdájọ́ òdodo jáde pẹlu àṣeyọrí sí rere.” Jesu polongo ìhìn iṣẹ́ atuninínú fún àwọn ènìyàn tí wọ́n dà bí esùsú tí a ti pa lára, tí a ti tẹ̀ kòlòbà, tí a sì ti tẹ̀ mọ́lẹ̀. Wọ́n dà bí òwú àtùpà kan tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú, bí ẹni pé a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa iná tí ó ṣẹ́ kù nínú ìgbésí ayé wọn. Dípò tí ì bá fi tẹ esùsú kan tí a ti pa lára fọ́, kí ó sì pa òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe, Jesu ṣàánú àwọn tí a pọ́n lójú, ó kọ́ wọn, ó sì wò wọ́n sàn, ó sì mú ìdájọ́ òdodo Jehofa Ọlọrun ṣe kedere sí wọn. (Matteu 12:10-21) Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah ṣe sọ ṣáájú, irú ìdájọ́ òdodo bẹ́ẹ̀ ń fún ìrètí lágbára.
Àánú àti Ìdájọ́ Òdodo Jehofa
Àánú jẹ́ apá pàtàkì nínú ìdájọ́ òdodo Ọlọrun. Èyí wá sí ojútáyé nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀ ayé. Ó fi àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìdájọ́ òdodo àti òdodo Ọlọrun hàn lọ́nà pípé. Ṣùgbọ́n, àwọn Júù akọ̀wé àti Farisi gbìyànjú láti dé ipò òdodo nípa títẹ̀ lé àwọn òfin líle koko—ọ̀pọ̀ èyí tí wọ́n ṣe fúnra wọn. Ìdájọ́ wọn tí a gbé karí òfin kì í sábà ní àánú nínú. Ọ̀pọ̀ ìforígbárí láàárín Jesu àti àwọn Farisi dá lórí ọ̀ràn yìí: Kí ni ìdájọ́ òdodo àti òdodo tòótọ́?—Matteu 9:10-13; Marku 3:1-5; Luku 7:36-47.
Jesu ṣàkàwé bí a ṣe lè bá àwọn ẹlòmíràn lò lọ́nà ẹ̀tọ́ àti lọ́nà òdodo. Ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin bi Jesu léèrè ohun tí ó pọn dandan láti lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Ní fífèsì padà, Jesu bi í ní ìbéèrè kan, ó sì gbóríyìn fún un, nígbà tí ó fèsì pé, òfin méjì tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà ẹni, gbogbo ọkàn, gbogbo èrò inú, àti gbogbo okun àti láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò ẹni gẹ́gẹ́ bí ara ẹni. Nígbà náà ni ọkùnrin náà béèrè pé: “Níti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Jesu fèsì nípa sísọ àkàwé ará Samaria aládùúgbò rere.—Luku 10:25-37.
Àkàwé Jesu nípa ará Samaria ṣàpẹẹrẹ òdodo àti ìdájọ́ òdodo aláàánú tí Jehofa ní. Nípa fífi àìmọtara ẹni nìkan ran ọkùnrin kan tí ó fara gbọgbẹ́ lọ́wọ́, ẹni tí òun kò mọ̀ rí, ará Samaria náà ṣe ohun kan tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì fi àánú hàn. Jesu fúnra rẹ̀ fi irú ẹ̀mí kan náà hàn nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ó jẹ́ olódodo, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ fún àwọn aláìní, fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé tí ó wà lábẹ́ ìjìyà, àìsàn, àti ikú. Aposteli Paulu so òdodo pọ̀ mọ́ ìpèsè ìràpadà. Ó kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ aṣemáṣe kan ìyọrísí naa fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ ìdálẹ́bi, bákan naa pẹlu ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre kan [tàbí, “ìṣe òdodo kan,” àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW] ìyọrísí naa fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè.” (Romu 5:18) “Ìṣe òdodo kan” yìí ni ọ̀nà tí Ọlọrun gbà gba aráyé onígbọràn là kúrò nínú àbájáde oníjàm̀bá ti ẹ̀ṣẹ̀ Adamu, èyí tí kì í ṣe àfọwọ́fà wọn ní tààràtà.
Ìdájọ́ òdodo Ọlọrun gbìyànjú láti ra àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ padà, lọ́wọ́ kan náà, kí ó sì di àwọn ìlànà òdodo mú. Láti gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá yóò jẹ́ ohun tí kò tọ́, tí kò sì fi ìfẹ́ hàn, nítorí pé yóò fún ìwà àìlófin níṣìírí. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun bá mọ sórí fífúnni lérè tàbí fífi ìyà jẹni nìkan, ipò aráyé ì bá ti jẹ́ aláìnírètí. Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti wí, “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,” “kò” sì “sí olódodo ènìyàn kan, kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan.” (Romu 3:10; 6:23) Jehofa pèsè ẹbọ ìpẹ̀tù fún ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí ó ná òun àti Ọmọkùnrin rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ nǹkan ti ara ẹni.—1 Johannu 2:1, 2.
Ìràpadà náà fi hàn pé, ìdájọ́ òdodo àtọ̀runwá wé pọ̀ mọ́ ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà (ní èdè Gíríìkì, a·gaʹpe). Ní tòótọ́, ìdájọ́ òdodo Ọlọrun jẹ́ ìyọrísí àwọn ìlànà òdodo rẹ̀—ìfihàn ohun tí ọ̀pá ìdiwọ̀n rẹ̀ ní ti ìwà mímọ́ jẹ́. Nítorí náà, nígbà tí Ọlọrun bá lò ó, a·gaʹpe jẹ́ ìfẹ́ tí a gbé ìdájọ́ òdodo àtọ̀runwá kà. (Matteu 5:43-48) Nítorí náà, bí a bá lóye ìdájọ́ òdodo Jehofa ní tòótọ́, a óò ní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí “Onídàájọ́ gbogbo ayé,” òún máa ń fìgbà gbogbo ṣe ohun tí ó tọ́.—Genesisi 18:25; Orin Dafidi 119:75.
Fara Wé Ìdájọ́ Òdodo Jehofa
Bibeli gbà wá níyànjú láti “di aláfarawé Ọlọrun.” (Efesu 5:1) Èyí túmọ̀ sí fífara wé ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí a ti jẹ́ aláìpé, àwọn ọ̀nà wa kò ga tó ti Jehofa Ọlọrun. (Isaiah 55:8, 9; Esekieli 18:25) Nítorí náà, báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo? Nípa gbígbé “àkópọ̀ ìwà titun wọ̀ èyí tí a dá ní ìbámu pẹlu ìfẹ́-inú Ọlọrun ninu òdodo tòótọ́ ati ìdúróṣinṣin.” (Efesu 4:24) Nígbà náà, a óò nífẹ̀ẹ́ ohun tí Ọlọrun nífẹ̀ẹ́, a óò sì kórìíra ohun tí ó kórìíra. “Òdodo tòótọ́” ń yẹra pátápátá fún ìwà ipá, ìwà pálapàla, ìwà àìmọ́, àti ìpẹ̀yìndà, nítorí ìwọ̀nyí ń ba ohun mímọ́ jẹ́. (Orin Dafidi 11:5; Efesu 5:3-5; 2 Timoteu 2:16, 17) Ìdájọ́ òdodo Ọlọrun tún ń sún wa láti fi ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú àwọn ẹlòmíràn.—Orin Dafidi 37:21; Romu 15:1-3.
Síwájú sí i, bí a bá mọrírì àánú ìdájọ́ òdodo Ọlọrun, a kì yóò ní ìtẹ̀sí láti ṣèdájọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí. Báwo ni ó ṣe lè ṣeé ṣe fún wa láti lóye wọn gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti ń ṣe? A kò ha ní fi ojú ìwòye ẹlẹ́tanú tiwa ṣèdájọ́ wọn bí? Nípa báyìí, Jesu kìlọ̀ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má baà dá yín lẹ́jọ́; nitori irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin fi ń dánilẹ́jọ́, ní a óò fi dá yín lẹ́jọ́; ati òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yoo fi díwọ̀n fún yín. Èéṣe tí iwọ fi wá ń wo ègé koríko tí ń bẹ ninu ojú arákùnrin rẹ, ṣugbọn tí o kò ronú nipa igi ìrólé tí ń bẹ ninu ojú iwọ fúnra rẹ? Tabi bawo ni iwọ ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Yọ̀ǹda fún mi lati yọ ègé koríko kúrò ninu ojú rẹ’; nígbà tí, wò ó! igi ìrólé kan ń bẹ ninu ojú iwọ fúnra rẹ? Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò ninu ojú tìrẹ, nígbà naa ni iwọ yoo sì ríran kedere bí o ṣe lè yọ ègé koríko kúrò ninu ojú arákùnrin rẹ.” (Matteu 7:1-5) Yíyẹ àwọn àìpé ti ara wa wò láìṣàbòsí kì yóò mú kí a ṣèdájọ́ tí Jehofa yóò kà sí àìṣòdodo.
Ojúṣe àwọn alàgbà ìjọ tí a yàn sípò ni láti ṣèdájọ́ nínú àwọn ẹjọ́ ìwà àìtọ́ wíwúwo. (1 Korinti 5:12, 13) Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n rántí pé ìdájọ́ òdodo Ọlọrun ń fẹ́ láti nawọ́ àánú síni níbikíbi tí ó bá ti ṣeé ṣe. Bí kò bá sí ìdí fún un—bíi nínú ẹjọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìronúpìwàdà—a kò lè nawọ́ àánú síni. Ṣùgbọ́n àwọn alàgbà kì yóò yọ oníwà àìtọ́ náà kúrò nínú ìjọ pẹ̀lú ẹ̀mí ọwọ́-mi-bà-á. Wọ́n nírètí pé ìgbésẹ̀ ìyọnilẹ́gbẹ́ fúnra rẹ̀ yóò pe orí rẹ̀ wálé. (Fi wé Esekieli 18:23.) Lábẹ́ ìdarí Kristi, àwọn alàgbà ń ṣiṣẹ́ sìn pẹ̀lú níní ìdájọ́ òdodo lọ́kàn, èyí sì ní jíjẹ́ “ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ẹ̀fúùfù,” nínú. (Isaiah 32:1, 2) Nítorí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ fi àìṣègbè àti òye hàn.—Deuteronomi 1:16, 17.
Gbin Irúgbìn ní Òdodo
Bí a ti ń dúró de ayé tuntun òdodo Ọlọrun, a gbọ́dọ̀ “wa òdodo” kí a baà lè gbádùn ojú rere àtọ̀runwá. (Sefaniah 2:3; 2 Peteru 3:13) A sọ èrò yìí jáde lọ́nà tí ó dùn mọ́ni nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí a rí ní Hosea 10:12 pé: “Ẹ fúnrúngbìn fún ara yín ní òdodo, ẹ ká a ní àánú: ẹ tú ilẹ̀ yín tí a kò ro: nítorí ó tó àkókò láti wá Oluwa, títí yóò fi dé, tí yóò sì fi rọ̀jò òdodo sí yín.”
Nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, a ní àǹfààní púpọ̀ láti ‘fúnrúngbìn ní òdodo,’ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jesu ti fi òwe àkàwé rẹ̀ nípa ará Samaria aládùúgbò rere ṣàkàwé. Jehofa yóò rí i dájú pé a “ká a ní àánú.” Bí a bá ń bá a nìṣó ní rírìn ní “ọ̀nà ìdájọ́ òdodo,” a óò máa bá a nìṣó láti gba ìtọ́ni ní òdodo lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba. (Isaiah 40:14, NW) Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, láìṣiyè méjì, a óò wá lóye lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé Jehofa jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.—Orin Dafidi 33:4, 5.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ará Samaria aládùúgbò rere ṣàpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Jehofa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jesu fi àánú hàn fún àwọn tí a pọ́n lójú, tí wọ́n dà bí esùsú tí a pa lára