Bí Àwọn Kristian Olùṣọ́ Àgùntàn Ṣe Ń Ṣiṣẹ́ Sìn Ọ́
NÍ IBI púpọ̀, ó ṣeé ṣe láti kíyè sí bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń bójú tó agbo. Wọ́n ń darí, wọ́n ń dáàbò bò, wọ́n sì ń pèsè fún àwọn àgùntàn. Èyí jẹ́ ohun tí ó fa àwọn Kristian alàgbà lọ́kàn mọ́ra, níwọ̀n bí iṣẹ́ wọ́n ti ní àwọn ìgbòkègbodò ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn nínú. Ní tòótọ́, ẹrù iṣẹ́ wọn ni “lati ṣe olùṣọ́ àgùtàn ìjọ Ọlọrun,” kí wọ́n sì ‘kíyè sí gbogbo agbo.’—Ìṣe 20:28.
Bí o bá jẹ́ mẹ́ḿbà ìjọ Kristian, báwo ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí ṣe lè ṣiṣẹ́ sìn ọ́? Báwo sì ni ó ṣe yẹ kí o hùwà padà sí àwọn ìsapá wọn lórí rẹ? Èé ṣe tí ìjọ fi nílò ìrànlọ́wọ́ wọn?
Ìdáàbòbò Lòdì sí Kí Ni?
Ní ìgbà àtijọ́, àwọn kìnnìún àti àwọn ẹranko ẹhànnà míràn máa ń wu agbo léwu, wọ́n sì máa ń fẹ́ fi olúkúlùkù àgùntàn ṣe ẹran ìjẹ. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní láti pèsè ààbò. (1 Samueli 17:34, 35) Toò, Satani Èṣù “ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ.” (1 Peteru 5:8) Ó ń fi tìbínútìbínú gbógun, kì í ṣe ti ètò-àjọ Jehofa lórí ilẹ̀ ayé lódindi nìkan ni, ṣùgbọ́n, ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú. Kí ni ète Satani? Ó fẹ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ènìyàn Jehofa, kí ó sì tilẹ̀ dí wọn lọ́wọ́ ‘pípa awọn àṣẹ Ọlọrun mọ́ àti ṣíṣe iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jesu.’—Ìṣípayá 12:17.
Jehofa fi ẹ̀sùn àìbìkítà kan àwọn olùṣọ́ àgùntàn olùṣàkóso Israeli ìgbàanì, nítorí pé, àwọn àgùntàn rẹ̀ ti di “oúnjẹ fún olúkúlùkù ẹranko ìgbẹ́.” (Esekieli 34:8) Ṣùgbọ́n, àwọn Kristian alàgbà ní ìfẹ́ àtọkànwá láti dáàbò bo àwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ, kí wọ́n má baà pàdánù ẹnì kankan nítorí àìbìkítà tàbí ipa ìdarí tí Satani, ayé, tàbí àwọn apẹ̀yìndà “ìkookò” ń ní. (Ìṣe 20:29, 30) Báwo ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń ran gbogbo mẹ́ḿbà agbo lọ́wọ́ láti pa agbára ìmòye wọn mọ́, kí wọ́n sì máa kíyè sára? Ọ̀nà kan ni nípa sísọ àwọn àsọyé tí a ti múra sílẹ̀ dáradára, tí a sì gbé karí Ìwé Mímọ́, láti orí pèpéle Gbọ̀ngàn Ìjọba. Òmíràn ni nípa àwọn ìjíròrò tí ń gbéni ró, tí ó sì ń fúnni níṣìírí ṣáájú àti lẹ́yìn àwọn ìpàdé. Ọ̀nà gbígbéṣẹ́ mìíràn tún ni nípa fífúnra wọn bẹ “àgùntàn” náà wò nínú ilé. (Fi wé Orin Dafidi 95:7.) Ṣùgbọ́n, kí ni ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn? Báwo ni ó ṣe yẹ kí a ṣe irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀? Ta sì ni ó yẹ kí a bẹ̀ wò?
Kí Ni Ìbẹ̀wò Olùṣọ́ Àgùntàn?
Ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn kì í wulẹ̀ í ṣe ìbẹ̀wò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ tí ìjíròrò rẹ̀ dá lórí àwọn nǹkan tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Alàgbà kan ṣàkíyèsí pé: “Àwọn akéde tí ó pọ̀ jù lọ máa ń gbádùn kíka ẹsẹ ìwé mímọ́ kan tàbí jíjíròrò ẹnì kan pàtó nínú Bibeli. Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe alàgbà náà nìkan ni yóò sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà. Akéde Ìjọba náà tí a bẹ̀ wò sábà máa ń gbádùn sísọ àwọn èrò rẹ̀ lórí Bibeli, ṣíṣe èyí sì máa ń fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun. Alàgbà náà lè mú ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Jí! lọ́wọ́ láti baà lè jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan tí ń gbéni ró. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìjíròrò tẹ̀mí yìí ni ohun tí ń fìyàtọ̀ sáàárín ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn àti ìbẹ̀wò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́.”
Alàgbà onírìírí mìíràn sọ pé: “Ṣáájú ìbẹ̀wò náà, alàgbà kan yóò lo àkókò láti ronú nípa akéde náà tí òún fẹ́ bẹ̀ wò. Kí ni ó lè gbé akéde yìí ró? Oríyìn àtọkànwá jẹ́ apá pàtàkì nínú ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, nítorí pé ó ń fún ẹnì kan lókun láti lo ìfaradà.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn ju ìbẹ̀wò ẹ-ǹ-lẹ́-ń-bẹ̀un lásán tí ẹnikẹ́ni nínú ìjọ lè ṣe lọ.
Èé Ṣe Tí Olùṣọ́ Àgùntàn Fi Bẹ̀ Ọ́ Wò?
Nígbà tí alàgbà kan bá bẹ ilé kan wò, ó ti múra tán láti fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níṣìírí, kí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. (Romu 1:11) Nítorí náà, nígbà tí alàgbà kan tàbí méjì bá fẹ́ bẹ̀ ọ́ wò, báwo ni o ṣe ń hùwà padà? Alábòójútó arìnrìn àjò kan wí pé: “Bí ó bá jẹ́ pé ìgbà tí ìṣòro bá wà nìkan ni a ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, ìhùwàpadà àkọ́kọ́ sí ìbẹ̀wò náà lè jẹ́, ‘Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi?’” Àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ń fara wé Jehofa, ẹni tí ó bójú tó onipsalmu náà, tí ó sì fìgbà gbogbo ‘tu ọkàn rẹ̀ lára,’ ní pàtàkì, nígbà ìdààmú àti àìní àrà ọ̀tọ̀.—Orin Dafidi 23:1-4.
Ète ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn ni láti ‘gbéni ró, kì í ṣe láti yani lulẹ̀.’ (2 Korinti 13:10) Ní tòótọ́, àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì fún níní ìfaradà, lílo ìtara, àti iṣẹ́ àfòtítọ́ṣe tí ẹni náà tí a bẹ̀ wò ṣe, yóò fún un níṣìírí. Alàgbà kan ṣàkíyèsí pé: “Nígbà ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, kò dára láti jẹ́ kí ẹnì kan ní èrò pé, a wá pẹ̀lú èrò ṣíṣàwárí àwọn ìṣòro àti jíjíròrò wọn. Àmọ́ ṣáá o, akéde náà fúnra rẹ̀ lè fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro kan pàtó. Bí àgùntàn kan bá sì ń tiro tàbí tí ó ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò láàárín agbo yòókù, alàgbà náà ní láti ṣe ohun kan láti ràn án lọ́wọ́.”
Kò sí iyè méjì pé, àwọn Kristian olùṣọ́ àgùntàn yóò fún ẹnikẹ́ni tí ó bá dà bí àwọn tí a ṣàpèjúwe wọn nínú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀: “Èmi [Jehofa] óò wá èyí tí ó sọnù lọ, èmi óò sì mú èyí tí a lé lọ padà bọ̀, èmi óò sì di èyí tí a ṣá lọ́gbẹ́, èmi óò mú èyí tí ó ṣàìsàn ní ara le.” (Esekieli 34:16) Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ní láti wá àgùntàn lọ, kí a mú un padà, kí a di ọgbẹ́ rẹ̀, tàbí kí a mú un ní ara le. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní Israeli kò ka àwọn ẹrù iṣẹ́ wọ̀nyí sí. Ṣíṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ń béèrè pé kí olùṣọ́ àgùntàn náà sún mọ́ àgùntàn kan pàtó, kí ó sì bójú tó àìní rẹ̀. Ní pàtàkì, èyí yẹ kí ó jẹ́ apá tí ń fìyàtọ̀ sí ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan lónìí.
Àwọn Àgùntàn Onílera Nílò Àbójútó
Ó ha yẹ kí a dé ìparí èrò pé, kò yẹ kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí ní òde òní fi àfiyèsí pàtó hàn sí àwọn àgùntàn onílera bí? Toò, nígbà tí àgùntàn gidi kan bá bọ́ sínú ìṣòro, ó túbọ̀ máa ń rọrùn láti ràn án lọ́wọ́ bí ó bá ní ìgbọ́kànlé nínú olùṣọ́ àgùntàn náà. Ìwé kékeré kan sọ pé “lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn àgùntàn máa ń tijú àwọn ẹ̀dá ènìyàn, kò sì fìgbà gbogbo rọrùn láti mú kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ léni.” Ní àfikún sí i, ìwé kan náà dábàá ìtọ́sọ́nà pàtàkì yìí fún mímú kí àwọn àgùntàn ní ìgbọ́kànlé nínú ẹni: “Bá àwọn ẹran náà sọ̀rọ̀ déédéé. Wọn yóò mọ ohùn rẹ, èyí tí ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Máa bẹ àwọn àgùntàn náà wò nínú pápá nígbà gbogbo.”—Alles für das Schaf. Handbuch für die artgerechte Haltung (Ohun Gbogbo fún Àwọn Àgùntàn. Ìwé Kékeré kan Lórí Bí A Ṣe Lè Tọ́jú Wọn Dáradára).
Nígbà náà, ìbẹ̀wò fúnra ẹni ṣe pàtàkì bí ipò ìbátan onígbẹ̀ẹ́kẹ́lé yóò bá wà láàárín olùṣọ́ àgùntàn náà àti àwọn àgùntàn. Bákan náà ni ọ̀ràn rí nínú ìjọ Kristian. Alàgbà kan sọ pé: “Dídi ẹni tí a mọ̀ nínú ìjọ gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan tí ó sábà máa ń bẹ àwọn àgùntàn wò ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn láti bẹ ẹni tí ó bá ní ìṣòro wò.” Nítorí náà, àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí kò ní láti gbìyànjú láti máa bọ́ àwọn àgùntàn náà, kí wọ́n sì máa bójú tó wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba nìkan. Bí àyíká ipò bá ṣe yọ̀ọ̀da tó, àwọn alàgbà ní láti mọ àwọn àgùntàn dunjú nípa ṣíṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sí ilé wọn. Kristian kan rántí pé nígbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn án sípò gẹ́gẹ́ bí alàgbà, alábòójútó olùṣalága tẹ̀ ẹ́ láago, ó sì ní kí ó bẹ arákùnrin kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdánù ọmọbìnrin rẹ̀ nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ bíbani lẹ́rù kan wò, kí ó sì tù ú nínú. Alàgbà náà jẹ́wọ́ pé: “Ẹ wo bí ó ti bà mí lọ́kàn jẹ́ tó, níwọ̀n bí n kò tí ì bẹ arákùnrin náà wò rí, tí n kò sì tilẹ̀ mọ ibi tí ó ń gbé! Ọkàn mi balẹ̀ nígbà tí alàgbà kan tí ó dàgbà dénú gbà láti bá mi lọ.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn alàgbà máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ nínú ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn.
Ní mímúra sílẹ̀ fún ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn àti ṣíṣe é, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tí ń nàgà fún “iṣẹ́ àtàtà” ti alábòójútó, lè dara pọ̀ mọ́ alàgbà kan. (1 Timoteu 3:1, 13) Ẹ wo bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan yóò ṣe mọrírì rírí bí alàgbà kan ṣe ń ṣiṣẹ́ sin àgùntàn tó nígbà ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn! Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń tipa báyìí túbọ̀ di ojúlùmọ̀ ẹni gbogbo nínú ìjọ, wọ́n sì ń fún ìdè ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan Kristian lókun.—Kolosse 3:14.
Ṣíṣètò Àkókò fún Ìbẹ̀wò Olùṣọ́ Àgùntàn
Nígbà tí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà kan fi ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sílẹ̀ fún ìdánúṣe àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, a bẹ gbogbo àwọn akéde tí ó wà ní àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan wò láàárín oṣù mẹ́fà, nígbà tí a kò sí bẹ àwọn tí ó wà ní àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ mìíràn wò. Èyí sún alàgbà kan láti sọ pé: “Ó dà bíi pé, àwọn alàgbà kan ń lo ìdánúṣe wọn, wọ́n sì ṣe ọ̀pọ̀ ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, ṣùgbọ́n, àwọn mìíràn nílò ìṣírí láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Nítorí náà, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà kan ti ṣètò pé kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn bẹ gbogbo akéde wò láàárín sáà kan pàtó.
Àmọ́ ṣáá o, alàgbà kan tàbí akéde mìíràn lè bẹ ẹnì kan nínú ìjọ wò láìdúró de ṣíṣètò àkànṣe. Ṣáájú ṣíṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, alàgbà kan tẹ̀ mí láago, ó sì sọ pé, “Mo máa ń ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìdílé kan lóṣooṣù. Mo ha lè bẹ̀ ọ́ wò fún nǹkan bíi wákàtí kan nígbàkigbà ní oṣù tí ń bọ̀ bí? Nígbà wo ni yóò rọrùn fún ọ?”
Àwọn Ìbùkún Ìbẹ̀wò Olùṣọ́ Àgùntàn
Bí pákáǹleke ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ìbẹ̀wò oníṣìírí láti ọ̀dọ̀ àwọn olóye olùṣọ́ àgùntàn túbọ̀ ń di ohun tí ń mú àǹfààní wá sí i. Nígbà tí a bá fún gbogbo àwọn tí ó wà nínú agbo ní ìṣírí, tí a sì tipasẹ̀ ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn ràn wọ́n lọ́wọ́, àgùntàn kọ̀ọ̀kan yóò nímọ̀lára ààbò àti àìséwu.
A ròyìn ìjọ kan tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti ń bẹ gbogbo àwọn akéde Ìjọba wò déédéé pé: “Àwọn akéde náà wá nífẹ̀ẹ́ sí ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn gidigidi. Ó wọ́pọ̀ kí akéde kan tọ ọ̀kan nínú àwọn alàgbà lọ, kí ó sì béèrè ìgbà tí yóò tún bẹ òun wò, nítorí tí ẹni tí ń béèrè náà ti gbádùn ìjíròrò tí ń gbéni ró nígbà ìbẹ̀wò ìṣáájú. Ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn jẹ́ kókó abájọ kan tí ó ṣèrànwọ́ láti mú kí ẹ̀mí ìjọ sunwọ̀n sí i.” Àwọn ìròyìn míràn fi hàn pé, nígbà tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn bá fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́nà yìí, ìjọ náà lè dàgbà nínú ìfẹ́, ìṣọ̀kan, àti ọ̀yàyà. Ẹ wo irú ìbùkún tí èyí jẹ́!
Àwọn Kristian olùṣọ́ àgùntàn ń ṣe ìbẹ̀wò láti mú kí ire tẹ̀mí àgùntàn náà sunwọ̀n sí i. Àwọn alàgbà fẹ́ láti fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn níṣìírí, kí wọ́n sì fún wọn lókun. Bí ìṣòro ńlá kan tí ń béèrè fún ìmọ̀ràn bá jẹ yọ nígbà ìbẹ̀wò kan, yóò jẹ ohun tí ó dára jù lọ láti ṣètò fún ìjíròrò nígbà míràn, ní pàtàkì, bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan bá tẹ̀ lé alàgbà náà lọ. Ohun yòówù tí ó lè ṣẹlẹ̀, ó yẹ kí a fi àdúrà parí ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn náà.
Olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí ha fẹ́ láti bẹ ilé rẹ wò ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, máa fi tayọ̀tayọ̀ fojú sọ́nà fún ìṣírí tí ń dúró dè ọ́. Ó ń bọ̀ láti ṣiṣẹ́ sìn ọ́, kí ó sì fún ọ lókun nínú ìpinnu rẹ láti wà ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Matteu 7:13, 14.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn Àbá fún Ìbẹ̀wò Olùṣọ́ Àgùntàn
◻ Sọ ìgbà tí ìwọ yóò wá: Ó dára láti sọ ìgbà tí ìwọ yóò wá. Bí alàgbà náà bá wéwèé láti yanjú ìṣòro ńlá kan, yóò yẹ láti sọ fún akéde náà ṣáájú.
◻ Ìmúrasílẹ̀: Gbé àbùdá ẹni náà yẹ̀ wò àti ipò rẹ̀. Fún un ní oríyìn àtọkànwá. Fi í ṣe góńgó rẹ láti fún un ní “ẹ̀bùn ẹ̀mí” tí ń fúnni níṣìírí, tí ó sì ń fúnni lókun. —Romu 1:11, 12.
◻ Ẹni tí o lè mú lọ́wọ́: Alàgbà míràn tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tí ó tóótun.
◻ Nígbà ìbẹ̀wò náà: Ara alàgbà náà ní láti balẹ̀, ó ní láti jẹ́ onífẹ̀ẹ́, olùfojúsọ́nà fún rere, àti ẹni tí ó mọwọ́ yí padà. Béèrè nípa ìdílé, nípa ire rẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Fetí sílẹ̀ dáradára. Bí ìṣòro ńlá bá jẹ yọ, ó lè jẹ́ ohun tí ó dára jù lọ láti ṣètò fún àkànṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn.
◻ Bí ìbẹ̀wò náà ṣe ní láti pẹ́ tó: Má ṣe kọjá àkókò tí ẹ fohùn ṣọ̀kan lé lórí, gbéra àtilọ nígbà tí ẹni tí ó gbà ọ́ ní àlejò ṣì ń gbádùn ìbẹ̀wò náà.
◻ Mímú ìbẹ̀wò náà wá sí ìparí: Ó dára láti gbàdúrà, a sì mọrírì rẹ̀ ní tòótọ́.—Filippi 4:6, 7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn Kristian olùṣọ́ àgùntàn ń pèsè ààbò nípa tẹ̀mí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn ń pèsè àǹfààní àtàtà fún ìṣírí nípa tẹ̀mí