ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 3/15 ojú ìwé 31
  • A Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀tọ́ Àwọn Aláìsàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀tọ́ Àwọn Aláìsàn
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀
    Jí!—2003
  • Dídáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Ìlòkulò Ẹ̀jẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 3/15 ojú ìwé 31

A Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀tọ́ Àwọn Aláìsàn

‘Kò sí bí mo ṣe lè ṣe iṣẹ́ abẹ yìí láìlo ẹ̀jẹ̀. Bí o bá fẹ́ kí ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà, o ní láti fara mọ́ ọ̀nà ìgbàtọ́jú tí mo fẹ́ lò. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò wá dókítà míràn.’

ÀWỌN ọ̀rọ̀ dókítà náà kò mi ìgbàgbọ́ Cheng Sae Joo, ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń gbé ní Thailand. Àyẹ̀wò ara fi hàn pé meningioma, àrùn kókó ọlọ́yún nínú ọpọlọ ń yọ ọ́ lẹ́nu, Cheng nílò iṣẹ́ abẹ ní kíákíá. Ṣùgbọ́n, ó pinnu láti ṣègbọràn sí àṣẹ Bibeli náà pé: “Máa takété sí . . . ẹ̀jẹ̀.”—Ìṣe 15:28, 29.

Cheng lọ sí ilé ìwòsàn méjì míràn, ó fẹ́ kí a tọ́jú òun ní orílẹ̀-èdè òun bí ó bá ṣeé ṣe bẹ́ẹ̀. Sí ìjákulẹ̀ rẹ̀, àwọn dókítà tí ó wà níbẹ̀ tún kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni Ilé Ìwòsàn (HIS) ní Thailand darí Cheng lọ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ìtọ́jú Ọpọlọ ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Ìmọ̀ Ìṣègùn Ti Àwọn Obìnrin ní Tokyo. Ilé ìwòsàn yẹn ti tọ́jú àwọn aláìsàn tí ó lé ní 200 tí wọ́n ní kókó ọlọ́yún nínú ọpọlọ, nípa lílo ọ̀bẹ onítànṣán, ọ̀kan nínú àwọn àwárí tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe nínú ọ̀nà ìgbàtọ́jú onítànṣán.

A ṣètò kí Cheng gbé ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ará Japan tí ń gbé nítòsí ilé ìwòsàn náà. Àwùjọ kan pàdé rẹ̀ ní pápá ọkọ̀ òfuurufú, tí ó ní àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa méjì tí wọ́n ń sọ èdè Thai àti aṣojú HIS kan nínú. Lẹ́yìn nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan tí wọ́n ti ń yẹ̀ ẹ́ wò, a gba Cheng sí ilé ìwòsàn níbi tí a ti fi ọ̀bẹ onítànṣán tọ́jú rẹ̀. Ọ̀nà ìgbàṣe náà gba nǹkan bíi wákàtí kan péré. Ọjọ́ kejì ni Cheng fi ilé ìwòsàn sílẹ̀, ó sì padà sí Thailand ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e.

Cheng wí pé: “N kò mọ̀ rárá pé a lè tipasẹ̀ ìṣètò yìí pèsè irú ìrànlọ́wọ́ tí ó tó bẹ́ẹ̀. Ìfẹ́ tí a fi hàn sí mi àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn tí ọ̀ràn kàn wú mi lórí.”

Nígbà tí ó ń ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Japan, Mainichi Shimbun sọ pé: “Títí di ìsinsìnyí, a ti tẹnu mọ́ àwọn ìdí tí ó jẹ́ ti ìsìn, fún kíkọ ìfàjẹ̀sínilára. Ṣùgbọ́n, ìfàjẹ̀sínilára ní àwọn ìyọrísí búburú irú bí àrùn AIDS, ewu kíkó òkùnrùn bí ìwúlé ẹ̀dọ̀ki àti àwọn èèwọ̀ ara. Nítorí ìdí èyí, àwọn aláìsàn kan wà tí kò fẹ́ ìfàjẹ̀sínilára láìka ìgbàgbọ́ wọn ní ti ìsìn sí.”

Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ síwájú sí i pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn tí wọ́n kọ ìfàjẹ̀sínilára ni ó ti di dandan fún láti lọ sí ilé ìwòsàn míràn, ṣùgbọ́n, ó yẹ kí àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ ìṣègùn yí padà láti máa bọ̀wọ̀ fún ìfẹ́-inú àwọn aláìsàn. Ó ń béèrè ìfaramọ́ tí a lóye (aláìsàn kan yóò gba àlàyé kíkún nípa ohun tí a fẹ́ ṣe, tí yóò sì fara mọ́ ìtọ́jú náà), èyí sì kan ọ̀ràn ìfàjẹ̀sínilára pẹ̀lú. Ó yẹ kí a mọ̀ pé, èyí kì í ṣe ọ̀ràn ìsìn kan ṣoṣo pàtó.”

Bíi Cheng Sae Joo, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n fẹ́ ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ ní láti lọ sí àwọn ilé ìwòsàn míràn. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n mọrírì ìsapá àwọn dókítà tí wọ́n ṣe tán láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn aláìsàn.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dá Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni Ilé Ìwòsàn sílẹ̀ ní àwọn ẹ̀ka Watch Tower Society láti wá ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn dókítà tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ wọn. Jákèjádò ayé, HIS ń gbé ipò ìbátan onífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé ìwòsàn, dókítà, òṣìṣẹ́ alábòójútó ìlera, agbẹjọ́rò, àti àwọn adájọ́ ró.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́