A Ha Ti Ṣe Ẹ̀tanú Sí Ọ Rí Bí?
KÍ NI ànímọ́ jíjọra tí ó wà láàárín ìwà ipá ẹ̀yà ìran, ẹ̀yà ìran tèmi lọ̀gá, àìbáni lò lọ́gbọọgba, kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́, àti ìpalápatán ẹ̀yà? Gbogbo wọn jẹ́ àbájáde ìtẹ̀sí ẹ̀dá ènìyàn tí ń gbilẹ̀ sí i—ẹ̀tanú!
Kí ni ẹ̀tanú? Ìwé gbédègbéyọ̀ kan túmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “èrò kan tí a ní láìfara balẹ̀ tàbí bìkítà láti ṣèdájọ́ lọ́nà tí ó tọ́.” Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, a ní ìtẹ̀sí láti ní ẹ̀tanú dé ìwọ̀n àyè kan. Bóyá o lè ronú nípa àwọn àkókò kan tí o ṣe ìdájọ́ láìmọ gbogbo òkodoro òtítọ́. Bibeli fi irú ìtẹ̀sí ẹlẹ́tanú bẹ́ẹ̀ wéra pẹ̀lú ọ̀nà tí Jehofa Ọlọrun gbà ń ṣèdájọ́. Ó sọ pé: “Oluwa kì í wò bí ènìyàn ti ń wò; ènìyàn a máa wo ojú, Oluwa a máa wo ọkàn.”—1 Samueli 16:7.
Ẹ̀tanú Lè Fa Ìbínú
Kò sí iyè méjì pé, gbogbo ènìyàn ni a ti ní èrò àìtọ́ nípa wọn ní àwọn ìgbà kan. (Fi wé Oniwasu 7:21, 22.) Ní gbogbogbòò, gbogbo wa ni a ti ṣe ẹ̀tanú sí rí. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí a bá tètè gbé e kúrò lọ́kàn, èrò ẹ̀tanú lè ṣe ìpalára díẹ̀ tàbí kí ó má ṣe ìpalára kankan. Mímú irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ dàgbà ni ó lè yọrí sí ìpalára. Ó lè tàn wá jẹ láti gba èké gbọ́. Fún àpẹẹrẹ, lábẹ́ ìdarí ẹ̀tanú, àwọn ènìyàn kan gbà gbọ́ pé ẹnì kan lè jẹ́ oníwọra, ọ̀lẹ, òmùgọ̀, tàbí agbéraga, kìkì nítorí pé, ó wá láti inú ìsìn kan, ẹ̀yà ìran kan, tàbí àwùjọ orílẹ̀-èdè kan.
Nínú ọ̀pọ̀ ọ̀ràn, irú èrò àìtọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí ojúsàájú, èébú, tàbí híhu ìwà ipá sí àwọn ẹlòmíràn. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìpakúpa, ìpalápatán ẹ̀yà, pípa ẹ̀yà ìran, àti oríṣi àṣerégèé ẹ̀tanú mìíràn.
Kárí ayé, ìjọba ti gbógun ti ẹ̀tanú nípa mímú ẹ̀tọ́ òmìnira, ààbò, àti ìbánilò lọ́gbọọgba dáni lójú lọ́nà tí ó bófin mu. Bí o bá ka ìwé òfin tàbí àkójọ òfin orílẹ̀-èdè rẹ, kò sí iyè méjì pé ìwọ yóò rí àpapọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí àtúnṣe kan tí a ṣe láti dáàbò bo àwọn ẹ̀tọ́ aráàlú, láìka ẹ̀yà ìran, ẹ̀yà akọ tàbí abo, tàbí ìsìn sí. Síbẹ̀, ẹ̀tanú tàbí àìbáni lò lọ́gbọọgba gbalégbòde kárí ayé.
A ha ti ṣe ẹ̀tanú sí ọ rí bí? A ha ti wò ọ́ gẹ́gẹ́ bí oníwọra, ọ̀lẹ, òmùgọ̀, tàbí agbéraga kìkì nítorí ẹ̀yà ìran rẹ, ọjọ́ orí rẹ, ẹ̀yà akọ tàbí abo tí o jẹ́, ọmọ orílẹ̀-èdè tí o jẹ́, tàbí èrò ìgbàgbọ́ ìsìn tí o ní bí? A ha ti fi àwọn àǹfààní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó yẹ, iṣẹ́, ilé gbígbé, àti àwọn ìpèsè ìjọba dù ọ́ nítorí ẹ̀tanú bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni o ṣe lè kojú rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Mímú ẹ̀tanú dàgbà ń mú kí ìkórìíra ẹ̀yà ìran dàgbà sí i
[Credit Line]
Nina Berman/Sipa Press