ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 6/15 ojú ìwé 8-11
  • Fífi Ìyẹ́ Gun Òkè Bí Idì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìyẹ́ Gun Òkè Bí Idì
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lábẹ́ Ọ̀págun Idì
  • Ojú Idì
  • “Ipa Idì Lójú Ọ̀run”
  • Lábẹ́ Òjìji Apá Ìyẹ́ Idì
  • Ọ̀nà Àsálà
  • Bí Ojú Ẹyẹ Idì Ṣe Lágbára Tó
    Jí!—2003
  • Jèhófà Ń Fi Agbára fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Lára Àwọn Ẹyẹ Ojú Ọ̀run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Àìsáyà 40:31—“Àwọn Tó Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Máa Jèrè Okun Pa Dà”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 6/15 ojú ìwé 8-11

Fífi Ìyẹ́ Gun Òkè Bí Idì

ÌMỌ̀LÁRA wo ni ọkùnrin kan ní lẹ́yin fífara dà fún ọdún márùn-ún nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Nazi? A ha bà á lọ́kàn jẹ́ bí? Ó ha ní ìbínú kíkorò bí? Ó ha ní ẹ̀mí ìgbẹ̀san bí?

Bí ó tilẹ̀ lè ṣàjèjì, ọkùnrin kan bẹ́ẹ̀ kọ̀wé pé: “Ìgbésí ayé mi túbọ̀ dọ́ṣọ̀ ju bí mo ti lè retí lọ.” Èé ṣe tí ó fi nímọ̀lára lọ́nà yẹn? Ó ṣàlàyé pé: “Mo rí ààbò lábẹ́ apá ìyẹ́ Ẹni Gíga Jù Lọ, mo sì rí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà, nígbà tí ó sọ pé: ‘Àwọn tí ó bá dúró de Olúwa yóò tún agbára wọn ṣe; wọn óò fi ìyẹ́ gun òkè bí idì; wọn óò . . . rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.’”—Aísáyà 40:31.

Ọkùnrin Kristẹni yìí, tí a sọ ara rẹ̀ di kẹ́jẹkẹ̀jẹ nípasẹ̀ ìbálò bíbani lẹ́rù jù lọ tí a lè ronú wòye rẹ̀, ní ẹ̀mí tí ń fò lọ sókè lọ́nà àpẹẹrẹ, ẹ̀mí tí ìwà òkú òǹrorò Nazi kò lè ṣẹ́gun. Gẹ́gẹ́ bíi Dáfídì, ó rí ààbò lábẹ́ òjìji “ìyẹ́ apá” Ọlọ́run. (Sáàmù 57:1) Kristẹni yìí lo àfiwé tààrà kan náà tí wòlíì Aísáyà lo, ní fífi okun tẹ̀mí rẹ̀ wé ti idì tí ń fò lọ lókèlókè lójú ọ̀run.

O ha ti nímọ̀lára rí pé ìṣòro bò ọ́ mọ́lẹ̀ bí? Láìsí àníàní, ìwọ pẹ̀lú yóò fẹ́ láti rí ààbò lábẹ́ apá ìyẹ́ Ẹni Gíga Jù Lọ, láti “fi ìyẹ́ gun òkè bí idì.” Láti lóye bí èyí ṣe lè ṣeé ṣe, yóò ṣèrànwọ́ láti mọ ohun kan nípa idì, tí a lò lọ́pọ̀ ìgbà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú Ìwé Mímọ́.

Lábẹ́ Ọ̀págun Idì

Nínú gbogbo ẹyẹ tí àwọn ènìyàn ìgbàanì máa ń wò, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé idì ni ó jọ wọ́n lójú jù lọ, nítorí agbára àti fífò rẹ̀ lọ́nà gíga lọ́lá. Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ìgbàanì, títí kan àwọn ti Bábílónì, Páṣíà, àti Róòmù, yan lábẹ́ ọ̀págun idì. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kírúsì Ńlá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ọba Páṣíà yìí yóò dà bí ẹyẹ apẹranjẹ tí ń bọ̀ láti ìlà oòrùn láti jẹ Ilẹ̀ Ọba Bábílónì run. (Aísáyà 45:1; 46:11) Igba ọdún lẹ́yìn tí a kọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, àwọn ọmọ ogun Kírúsì, tí a ya idì sára àsíá ìjà ogun wọn, ya bo ìlú Bábílónì bí ìgbà tí idì bá bo ẹran ọdẹ rẹ̀ mọ́lẹ̀.

Láìpẹ́ sẹ́yìn, àwọn jagunjagun bíi Charlemagne àti Napoleon àti àwọn orílẹ̀-èdè bíi United States àti Germany pẹ̀lú ti yan idì gẹ́gẹ́ bí àmì wọn. A pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti má ṣe yá ère idì tàbí ti ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn. (Ẹ́kísódù 20:4, 5) Síbẹ̀, àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì tọ́ka sí àwọn ànímọ́ idì láti ṣàkàwé ìhìn iṣẹ́ wọn. Nípa báyìí, a lo idì tí í ṣe ẹyẹ tí a mẹ́nu kàn lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ nínú Ìwé Mímọ́, láti ṣàpẹẹrẹ àwọn nǹkan bí ọgbọ́n, ààbò àtọ̀runwá, àti ìyára kánkán.

Ojú Idì

A sábà máa ń fi ojú ìríran idì tí ń ríran kedere pòwe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára káká ni idì oníwúrà fi ń tẹ̀wọ̀n ju kìlógíráàmù márùn-ún, ojú rẹ̀ tóbi ju ti ènìyàn lọ ní ti gidi, ojú ìríran rẹ̀ sì ṣe kedere ju ti ènìyàn lọ. Nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ń ṣàpèjúwe, agbára tí idì ní láti wá oúnjẹ rẹ̀ rí fún Jóòbù, ó sọ pé: “Ojú rẹ̀ sì ríran ní òkèèrè réré.” (Jóòbù 39:27, 29) Alice Parmelee ròyìn nínú ìwé rẹ̀, All the Birds of the Bible, pé, “nígbà kan, idì kan rí òkú ẹja kan tí ń léfòó lójú adágún omi kan ní nǹkan bíi ibùsọ̀ mẹ́ta [kìlómítà márùn-ún] sí i, ó sì já ṣòòròṣò lọ sí ibẹ̀ gan-an. Kì í ṣe kìkì pé idì lè rí ohun kékeré kan láti ibi tí ó jìnnà réré ju bí ènìyàn ti lè ṣe nìkan ni, ṣùgbọ́n ẹyẹ náà fojú sun ẹja náà láìtàsé bí ó ṣe ń já ṣòòròṣò lọ nínú ìrìn àjò oníbùsọ̀ mẹ́ta rẹ̀.”

Nítorí ojú ìríran kedere rẹ̀, idì jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ yíyẹ wẹ́kú fún ọgbọ́n, ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ pàtàkì ti Jèhófà. (Fi wé Ìsíkẹ́ẹ̀lì 1:10; Ìṣípayá 4:7.) Èé ṣe tí ìyẹ́n fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ọgbọ́n kan rírí àrítẹ́lẹ̀ àbájáde ìgbésẹ̀ èyíkéyìí tí a bá gbé. (Òwe 22:3) Idì, pẹ̀lú agbára rẹ̀ láti ríran jìnnà, lè rí ewu látòkèèrè, kí ó sì ṣọ́ra, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ọlọgbọ́n inú ti inú àkàwé Jésù, tí ó rí i tẹ́lẹ̀ pé ìjì lè jà, tí ó sì kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. (Mátíù 7:24, 25) Ó dùn mọ́ni pé, ní èdè Spanish, ṣíṣàpèjúwe ẹnì kan bí idì túmọ̀ sí pé ó ní òye inú tàbí ìfòyemọ̀.

Nígbàkígbà tí o bá ní àǹfààní láti rí idì nítòsí, kíyè sí bí ó ṣe ń lo ojú rẹ̀. Kì yóò wò ọ́ fírí; kàkà bẹ́ẹ̀, yóò dà bíi pé ó ń wo gbogbo ìrísí rẹ láwòfín. Bákan náà, ọkùnrin ọlọgbọ́n náà yóò fi ìrònú jinlẹ̀ gbé ọ̀ràn yẹ̀ wò kí ó tó ṣèpinnu dípo gbígbẹ́kẹ̀ lé agbára àdánidá tàbí ìmọ̀lára rẹ̀. (Òwe 28:26) Nígbà tí ojú ìríran idì tí ó ríran kedere mú kí ó jẹ́ àpẹẹrẹ yíyẹ wẹ́kú fún ànímọ́ ọgbọ́n àtọ̀runwá, àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì tún lo fífò rẹ̀ kíkọyọyọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.

“Ipa Idì Lójú Ọ̀run”

“Ipa idì lójú ọ̀run” ń yani lẹ́nu nítorí ìyára kánkán rẹ̀ àti bí ó ti dà bíi pé ó ń fò tìrọ̀rùntìrọ̀rùn, láìtẹ̀ lé ipa ọ̀nà èyíkéyìí tí a là sílẹ̀, láìsì fi ipa kankan sílẹ̀. (Òwe 30:19) A tọ́ka sí ìyára kánkán idì nínú Ẹkún Jeremáyà 4:19, níbi tí a ti ṣàpèjúwe àwọn sójà ará Bábílónì pé: “Àwọn tí ń lépa wa yára ju idì ọ̀run lọ: wọ́n ń lépa wa lórí òkè.” Nígbà tí idì tí ń pòòyì lókè bá rí ẹran ọdẹ rẹ̀, yóò na ìyẹ́ apá rẹ̀, yóò sì já ṣòòròṣò lọ sí ìsàlẹ̀, nígbà tí ó lè yára tó rírin ìrìn àjò oníkìlómítà 130 ní wákàtí kan, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn kan ti sọ. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, Ìwé Mímọ́ lo idì gẹ́gẹ́ bí ìṣàpẹẹrẹ fún ìyára kánkán, ní pàtàkì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ogun.—Sámúẹ́lì Kejì 1:23; Jeremáyà 4:13; 49:22.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Aísáyà tọ́ka sí fífò idì pẹ̀lú ìrọ̀rùn. “Àwọn tí ó bá dúró de Olúwa yóò tún agbára wọn ṣe; wọn óò fi ìyẹ́ gun òkè bí idì; wọn óò sáré, kì yóò sì rẹ̀ wọ́n; wọn óò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.” (Aísáyà 40:31) Kí ni àṣíri bí idì ṣe ń fò pẹ̀lú ìyára gíga lọ́lá? Fífò lọ sókè béèrè fún ìsapá díẹ̀ níwọ̀n bí idì ti ń lo ooru atẹ́gùn, tàbí ọ̀wọ́ ooru atẹ́gùn tí ń lọ sókè. A kò lè fi ojú rí ooru atẹ́gùn, ṣùgbọ́n idì já fáfá tó láti rí wọn. Ní gbàrà tí idì bá ti rí ooru atẹ́gùn, yóò na ìyẹ́ àti ìrù rẹ̀ jáde, yóò sì máa pòòyì láàárín ọ̀wọ́ ooru atẹ́gùn náà, tí yóò mú kí idì náà ròkè lálá. Bí ó bá ti ròkè tó, yóò ré kọjá sí ibi ooru atẹ́gùn tí ó tẹ̀ lé e, níbi tí yóò ti ṣe ohun kan náà. Lọ́nà yìí, idì lè ròkè fíofío fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìlo agbára púpọ̀.

Idì wọ́pọ̀ ní Ísírẹ́lì, ní pàtàkì ní Àfonífojì Rift, tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Esioni-gébérì ní bèbè Òkun Pupa títí dé Dánì ní àríwá. Wọ́n máa ń pọ̀ gan-an nígbà ìrúwé àti nígbà ìwọ́wé, tí wọ́n máa ń ṣí kiri. Ní àwọn ọdún kan, a fẹ́rẹ̀ẹ́ kà tó idì 100,000. Nígbà tí oòrùn òwúrọ̀ bá ti mú atẹ́gùn móoru, a lè rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹyẹ apẹranjẹ tí wọn yóò máa fò lórí àwọn bèbè òkúta tí ó wà létí Àfonífojì Rift.

Ọ̀nà tí idì gbà ń fò pẹ̀lú ìrọ̀rùn jẹ́ àkàwé títayọ ní ti bí okun Jèhófà ti lè ru wá sókè nípa tẹ̀mí àti ní ti èrò ìmọ̀lára kí a baà lè máa bá iṣẹ́ wa nìṣó. Gan-an gẹ́gẹ́ bí idì kò ti lè lo okun ara rẹ̀ láti fò lọ sókè fíofío, a kò lè ṣàṣeyọrí bí a bá gbára lé agbára ara wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni náà tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Gẹ́gẹ́ bí idì tí ń wá ooru tí a kò lè fojú rí káàkiri déédéé, a ń “bá a nìṣó ní bíbéèrè” fún agbára agbékánkán ṣiṣẹ́ Jèhófà tí a kò lè fojú rí, nípasẹ̀ àdúrà onítara wa.—Lúùkù 11:9, 13.

Àwọn idì tí ń ṣí kiri sábà máa ń rí ooru atẹ́gùn nípa wíwo àwọn ẹyẹ apẹranjẹ mìíràn. Onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá, D. R. Mackintosh ròyìn pé nígbà kan, a rí àwọn idì àti igún 250 tí wọ́n ń pòòyì nínú ooru atẹ́gùn kan náà. Bákan náà lónìí, àwọn Kristẹni lè kọ́ láti gbára lé okun Jèhófà, nípa fífara wé àwọn àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ ti àwọn ìránṣẹ́ mìíràn tí wọ́n jẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run.—Fi wé Kọ́ríńtì Kìíní 11:1.

Lábẹ́ Òjìji Apá Ìyẹ́ Idì

Ọ̀kan nínú sáà tí ó léwu jù lọ nínú ìgbésí ayé idì ni ìgbà tí ó bá ń kọ́ láti fò. Ọ̀pọ̀ idì ni ó máa ń kú nígbà ìfidánrawò náà. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ aláìnírìírí pẹ̀lú wà nínú ewu nígbà tí ó kúrò ní Íjíbítì. Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ Jèhófà sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá a mu gan-an pé: “Ẹ̀yín ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Íjíbítì, àti bí mo ti rù yín ní apá ìyẹ́ idì, tí mo sì mú yín tọ ara mi wá.” (Ẹ́kísódù 19:4) A gbọ́ ìròyìn nípa àwọn idì tí ń gbé ẹyẹ kékeré kan sẹ́yìn fún ìgbà díẹ̀, kí ó má baà já bọ́ nígbà tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbìdánwò láti fò. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú Palestine Exploration Quarterly lórí irú àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀, G. R. Driver sọ pé: “Nígbà náà, àkàwé [Bíbélì] kì í wulẹ̀ ṣe àsọdùn lásán, ṣùgbọ́n a gbé e karí òkodoro òtítọ́ gan-an.”

Àwọn idì tún jẹ́ òbí àwòfiṣàpẹẹrẹ ní àwọn ọ̀nà míràn pẹ̀lú. Kì í ṣe kìkì pé wọ́n ń pèsè oúnjẹ àsìkò fún àwọn ọmọ nìkan ni, ṣùgbọ́n ìyá ẹyẹ náà yóò rọra gé ẹran tí akọ idì gbé wá sínú ìtẹ́ sí wẹ́wẹ́ kí ọmọ idì náà lè gbé e mì. Nítorí pé wọ́n sábà máa ń kọ́ ìtẹ́ wọn sóri bèbè òkè tàbí sórí àwọn igi gíga, ojú ọjọ́ máa ń nípa lórí àwọn ẹyẹ kéékèèké. (Jóòbù 39:27, 28) Oòrùn gbígbóná janjan, tí ó wọ́pọ̀ ní àwọn ilẹ̀ tí a ti kọ Bíbélì, lè fa ikú ẹyẹ kékeré kan bí kì í bá á ṣe ti ìtọ́jú àwọn òbí rẹ̀. Àgbà idì náà yóò na ìyẹ́ rẹ̀ jáde, nígbà míràn fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìdáwọ́ dúró, kí ó baà lè dáàbò bo ọmọ rẹ̀ jòjòló.

Nípa báyìí, ó bá a mu wẹ́kú gan-an pé a lo ìyẹ́ idì nínú Ìwé Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ààbò àtọ̀runwá. Diutarónómì 32:9-12 ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ìrìn àjò wọn nínú aginjù pé: “Nítorí pé ìpín ti OLÚWA ni àwọn ènìyàn rẹ̀; Jákọ́bù ni ìpín ìní rẹ̀. Ó rí i ní ilẹ̀ aṣálẹ̀, àti ní aginjù níbi tí ẹranko ń ké; ó yí i ká, ó tọ́jú rẹ̀, ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú rẹ̀: Bí idi ti í rú ìtẹ́ rẹ̀, tí í rá bàbà sórí ọmọ rẹ̀, tí í na ìyẹ́-apá rẹ̀, tí í gbé wọn, tí í máa gbé wọn lọ lórí ìyẹ́-apá rẹ̀: Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA nìkan ṣamọ̀nà rẹ̀.” Jèhófà yóò fún wa ní ààbò onífẹ̀ẹ́ kan náà bí a bá gbẹ́kẹ̀ lé e.

Ọ̀nà Àsálà

Nígbà míràn tí àwọn ìṣòro bá dojú kọ wa, ó lè dà bíi pé kí á sá lọ fún àwọn ìṣòro wa. Bí Dáfídì ṣe nímọ̀lára nìyẹn. (Fi wé Sáàmù 55:6, 7.) Ṣùgbọ́n bí Jèhófà tilẹ̀ ti ṣèlérí láti ràn wá lọ́wọ́ bí a ti ń kojú àwọn àdánwò àti ìjìyà nínú ètò ìgbékalẹ̀ yìí, kò pèsè àsálà pátápátá. A ní ìdánilójú Bíbélì pé: “Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti ba yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, òun kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n papọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—Kọ́ríntì Kìíní 10:13.

“Ọ̀nà àbájáde” tàbí “ọ̀nà àtiyọ” (King James Version) ní kíkọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú. Èyí ni Max Liebster, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ṣàwárí. Nígbà àwọn ọdún tí ó fi wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ó wá mọ Jèhófà, ó sì gbára lé e. Gẹ́gẹ́ bí Max ti ṣàwárí, Jèhófà ń fún wa lókun nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀. Àní nínú àgọ́ pàápàá, àwọn Ẹlẹ́rìí wá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn rí, wọ́n sì fún wọn ní ìrànwọ́ tẹ̀mí, ní ṣíṣàjọpín èrò Ìwé Mímọ́ àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì èyíkéyìí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Bí àwọn olùṣòtítọ́ olùlàájá sì ti sọ léraléra, Jèhófà fún wọn lókun. Max ṣàlàyé pé: “Mo ń bá a nìṣó láti máa béèrè lọ́wọ́ Jèhófà láti ṣèrànwọ́, ẹ̀mí rẹ̀ sì mú mi dúró.”

Ìdánwò yòówù kí a dojú kọ, àwa bákan náà lè gbára lè ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, bí a bá ń bá a nìṣó láti béèrè fún un. (Mátíù 7:7-11) Bí a óò ti fún wa lágbára nípasẹ̀ “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” ìṣòro wa yóò mú wa fò lọ sókè, dípò kí ìṣòro wá bò wá mọ́lẹ̀. A óò máa bá a nìṣó láti rìn ní ọ̀nà ti Jèhófà, kì yóò sì rẹ̀ wá. A óò fi ìyẹ́ gun òkè bí idì.—Kọ́ríntì Kejì 4:7; Aísáyà 40:31.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

Kì yóò wò ọ́ fírí

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]

Foto: Cortesía de GREFA

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]

Foto: Cortesía de Zoo de Madrid

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́