ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 6/15 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Kristẹni ní Ọ̀rúndún Kìíní ó Sì Ń Darí Àwa Náà Lónìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • “Ẹ̀mí Fúnra Rẹ̀ Ń Jẹ́rìí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí Kó O Sì Mú Ẹ̀jẹ́ Ìyàsímímọ́ Rẹ Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • ‘Ni Orukọ Ẹmi Mímọ́’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 6/15 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

A ha lè sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí, tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé ní ẹ̀mí Ọlọ́run bákan náà bí àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí yàn ti ní i?

Ìbéèrè yìí kì í ṣe tuntun. A jíròrò ọ̀ràn kan náà yìí nínú “Ibere Lati Ọwọ Awọn Onkawe Wa” nínú Ile-Iṣọ Na, April 15, 1952 (Gẹ̀ẹ́sì). Ọ̀pọ̀ ti di Ẹlẹ́rìí lẹ́yìn ìgbà náà, nítorí náà, a lè tún gbé ìbéèrè náà yẹ̀ wò, nígbà tí a bá sì ń ṣe bẹ́ẹ̀, a lè ṣàtúnyẹ̀wò ohun tí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ sọ.

Ní ṣàkó, ìdáhùn ni pé, bẹ́ẹ̀ ni, àwọn arákùnrin àti arábìnrin olùṣòtítọ́ ti ẹgbẹ́ àwọn àgùntàn míràn lè ṣàjọpín dọ́gbadọ́gba pẹ̀lú àwọn ẹni-àmì-òróró nínú gbígba ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.—Jòhánù 10:16.

Àmọ́ ṣáá o, èyí kò túmọ̀ sí pé ẹ̀mí náà ń ṣiṣẹ́ lọ́nà kan náà nínú ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ronú padà sẹ́yìn nípa àwọn ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ ṣáájú àwọn àkókò Kristẹni, tí wọ́n gba ẹ̀mí Ọlọ́run dájúdájú. Nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí náà, àwọn kan nínú wọn pa àwọn ẹranko ẹhànnà, wọ́n mú aláìsàn lára dá, wọ́n jí òkú pàápàá dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n nílò ẹ̀mí náà láti kọ àwọn ìwé onímìísí ti Bíbélì. (Àwọn Onídàájọ́ 13:24, 25; 14:5, 6; Àwọn Ọba Kìíní 17:17-24; Àwọn Ọba Kejì 4:17-37; 5:1-14) Ile-Iṣọ Na sọ pé: “Bí wọn kò tilẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró, wọ́n kún fún ẹ̀mí mímọ́.”

Ní ojú ìwòye mìíràn, ronú nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ní ọ̀rúndún kìíní, ní didi ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí pẹ̀lú ìrètí ti ọ̀run. Gbogbo wọn ni a ti fàmì òróró yàn, ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé lẹ́yìn ìgbà náà, ẹ̀mí náà bá gbogbo wọn ṣiṣẹ́ lọ́nà kan náà. Ìyẹ́n ṣe kedere láti inú Kọ́ríńtì Kìíní, orí 12. Níbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jíròrò ẹ̀bùn ẹ̀mí. A kà ní ẹsẹ 8, 9, àti 11 pé: “A fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún ẹnì kan nípasẹ̀ ẹ̀mí, a fún òmíràn ní ọ̀rọ̀ ìmọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí kan náà ti fúnni, a fún òmíràn ní ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, a fún òmíràn ní àwọn ẹ̀bùn ìmúniláradá nípasẹ̀ ẹ̀mí kan ṣoṣo náà. . . . Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọ̀nà ìṣiṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀mí kan ṣoṣo náà ń mú ṣe, ó ń ṣe ìpínfúnni fún olúkúlùkù lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ ìfẹ́ inú rẹ̀.”

Ó hàn gbangba pé kì í ṣe gbogbo àwọn ẹni àmì òróró nígbà náà lọ́hùn-ún ni ó ní ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu ti ẹ̀mí. Ní Kọ́ríńtì Kìíní, orí 14, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ìpàdé ìjọ kan níbi tí ẹnì kan ti ní ẹ̀bùn ìfèdèfọ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí ó wà níbẹ̀ tí ó ní ẹ̀bùn ìtumọ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ní àwọn àkókò kan ṣáájú, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni a ti fẹ̀mí yàn. Yóò ha bọ́gbọ́n mu láti sọ pé arákùnrin tí ó ní ẹ̀bùn ìfèdèfọ̀ ní ẹ̀mí náà ju àwọn yòókù tí ó wà níbẹ̀ bí? Rárá o. Àwọn ẹni àmì òróró yòókù wọ̀nyẹn kò ṣàìkúnjú ìwọ̀n, bíi pé wọn kò lè lóye Bíbélì dáradára bíi ti ẹni yẹn, tàbí pé wọn kò lè kojú ìdánwò bákan náà. Ẹ̀mí bá arákùnrin tí ó lè fi èdè fọ̀ náà ṣiṣẹ́ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, òun àti àwọn ní láti sún mọ́ Jèhófà, àti gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé, kí wọ́n sì “máa kún fún ẹ̀mí.”—Éfésù 5:18.

Nípa ti àwọn àṣẹ́kù lónìí, dájúdájú wọ́n ti gba ẹ̀mí Ọlọ́run. Ní àkókò kan, ó bá wọn lò lọ́nà àrà ọ̀tọ̀—nígbà tí a fòróró yàn wọ́n, tí a sì gbà wọ́n ṣọmọ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í “máa kún fún ẹ̀mí,” ní níní ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ láti túbọ̀ lóye Bíbélì ní kedere sí i, láti ṣáájú nínú iṣẹ́ ìwàásù, tàbí láti kojú àdánwò—ti ara ẹni, tàbí ti ètò àjọ.

Bí wọn kò tilẹ̀ nírìírí ìfòróróyàn, àwọn mẹ́ḿbà “àgùntàn míràn,” ní ọ̀nà míràn ń gba ẹ̀mí mímọ́. Ile-Iṣọ Na, April 15, 1952 (Gẹ̀ẹ́sì), sọ pé:

“Lónìí, àwọn ‘àgùntàn míràn’ ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù kan náà bíi ti àṣẹ́kù náà, lábẹ́ ipò tí ń dẹni wò kán náà, wọ́n sì ń fi ìṣòtítọ́ àti ìdúróṣinṣin kan náà hàn. Wọ́n ń jẹun lórí tábìlì tẹ̀mí kan náà, wọ́n ń jẹ oúnjẹ kan náà, wọ́n ń gba òtítọ́ kan náà sínú. Bí wọ́n ti jẹ́ ẹgbẹ́ ti ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú ìrètí ti ilẹ̀ ayé àti pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn mímúná nínú àwọn nǹkan ti ilẹ̀ ayé, wọ́n túbọ̀ lè ní ìfẹ́ ọkàn sí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó jẹ mọ́ àwọn ipò ti ilẹ̀ ayé nínú ayé tuntun; nígbà tí ó sì jẹ́ pé àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró, pẹ̀lú ìrètí ti ọ̀run àti ìfẹ́ ọkàn mímúná ti ara ẹni nínú àwọn nǹkan tẹ̀mí, lè túbọ̀ fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. . . . Síbẹ̀, òkodoro òtítọ́ náà ni pé, òtítọ́ kan náà àti òye kan náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ẹgbẹ́ méjèèjì, bí oníkálùkù bá sì ṣe kẹ́kọ̀ọ́ tó ni yóò pinnu bí òye tí wọ́n jèrè nípa àwọn nǹkan tọ̀run àti ti ilẹ̀ ayé yóò ti tó. Ẹ̀mí Olúwa wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ìwọ̀n kan náà fún ẹgbẹ́ méjèèjì, a sì nawọ́ ìmọ̀ àti òye sí àwọn méjèèjì lọ́gbọọgba, pẹ̀lú àǹfààní ọgbọọgba láti gbà á sínú.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́