Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Ìjọsìn Tòótọ́ Sún Mọ́lé
“Jèhófà yóò di ọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—SEKARÁYÀ 14:9, NW.
1. Kí ni ìrírí àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, báwo sì ni a ṣe sọ èyí tẹ́lẹ̀?
NÍGBÀ Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró jìyà ọ̀pọ̀ ìnira àti ìfinisẹ́wọ̀n lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ara wọn jagun. A ká ẹbọ ìyìn wọn sí Jèhófà lọ́wọ́ kò gidigidi, wọ́n sì ṣubú sínú ipò ìgbèkùn nípa tẹ̀mí. Gbogbo èyí ní a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nínú Sekaráyà 14:2, tí ó ṣàpèjúwe bí àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣe gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. “Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run,” Ìjọba Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ibi tí “ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn” wà, ni ìlú tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ nípa rẹ̀. (Hébérù 12:22, 28; 13:14; Ìṣípayá 22:3) Àwọn ẹni-àmì-òróró Ọlọ́run ń ṣojú fún ìlú yẹn lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn olùṣòtítọ́ lára wọn la ìgbéjàkò yẹn já, wọ́n kọ̀ kí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ “kúrò ní ìlú náà.”a
2, 3. (a) Báwo ni ìjọsìn Jèhófà ṣe yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun láti ọdún 1919? (b) Láti ọdún 1935, kí ni àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀?
2 Ní ọdún 1919, a dá àwọn ẹni-àmì-òróró olùṣòtítọ́ sílẹ̀ kúrò nínú ipò ìgbèkùn wọn, wọ́n sì yára lo àǹfààní sáà àlàáfíà tí ó tẹ̀ lé ogun náà. Gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ fún Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run, wọ́n lo àǹfààní kíkọyọyọ náà láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti láti ṣèrànwọ́ nínú kíkó àwọn mẹ́ḿbà 144,000 tí ó ṣẹ́ kù jọ. (Mátíù 24:14; Kọ́ríńtì Kejì 5:20) Ní ọdún 1931, wọ́n tẹ́wọ́ gba orúkọ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu náà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Aísáyà 43:10, 12.
3 Láti ìgbà náà wá, àwọn ẹni-àmì-òróró Ẹlẹ́rìí Ọlọ́run kò tí ì bojú wẹ̀yìn. Àní Hitler pàápàá pẹ̀lú ètò ìṣèlú àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun Nazi rẹ̀ ni kò lè pa wọ́n lẹ́nu mọ́. Láìka inúnibíni kárí ayé sí, iṣẹ́ wọn ti méso jáde ní gbogbo ilẹ̀ ayé. Ní pàtàkì, láti ọdún 1935, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” láti inú àwọn orílẹ̀-èdè ti dara pọ̀ mọ́ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ìṣípayá. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ti ṣe ìyàsímímọ́ àti batisí, wọ́n sì ti “fọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” Jésù Kristi. (Ìṣípayá 7:9, 14) Ṣùgbọ́n, wọ́n kì í ṣe ẹni-àmì-òróró, àwọn tí wọ́n ní ìrètí ìyè ti ọ̀run. Ìrètí wọ́n jẹ́ láti jogún ohun tí Ádámù àti Éfà ti sọnù, ìyẹn ni, ìyè ẹ̀dá ènìyàn pípé nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; Mátíù 25:34) Lónìí, ogunlọ́gọ̀ ńlá ti lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ọkàn. Ìjọsìn tòótọ́ ti Jèhófà ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun, ṣùgbọ́n ayọ̀ ìṣẹ́gun rẹ̀ ìkẹyìn kò tí ì dé.
Àwọn Àlejò Nínú Tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run Nípa Tẹ̀mí
4, 5. (a) Ibo ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti ń jọ́sìn Jèhófà? (b) Àwọn àǹfààní wo ni wọ́n ń gbádùn, ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wo?
4 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, ogunlọ́gọ̀ ńlá “ń jọ́sìn [Ọlọ́run] tọ̀sán tòru nínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀.” (Ìṣípayá 7:15, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé) Níwọ̀n bí wọn kì í ti í ṣe àlùfáà, Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí, ó jọ pé Jòhánù rí wọn tí wọ́n dúró nínú tẹ́ḿpìlì nínú àgbàlá ìta tí ó wà fún àwọn Kèfèrí. (Pétérù Kìíní 2:5) Ẹ wo bí tẹ́ḿpìlì Jèhófà nípa tẹ̀mí ti di ológo tó, tí gbogbo àyíká rẹ̀ kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹpẹtẹ yìí tí àwọn pẹ̀lú àṣẹ́kù Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí, jọ ń yin Jèhófà!
5 Ogunlọ́gọ̀ ńlá kò ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run nínú ipò tí àgbàlá inú lọ́hùn-ún, tí ó wà fún àwọn àlùfáà ṣàpẹẹrẹ. A kò polongo wọn ní olódodo fún ète dídi àwọn ọmọ nípa tẹ̀mí, tí Ọlọ́run sọ dọmọ. (Róòmù 8:1, 15) Síbẹ̀síbẹ̀, nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà Jésù, wọ́n ní ìdúró mímọ́ tónítóní níwájú Jèhófà. A polongo wọn ní olódodo pẹ̀lú ète dídi ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Fi wé Jákọ́bù 2:21, 23.) Àwọn pẹ̀lú ní àǹfààní láti gbé ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ka pẹpẹ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. Nípa báyìí, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 56:6, 7 ń ní ìmúṣẹ ológo sí ogunlọ́gọ̀ rẹpẹtẹ yìí lára pé: “Àwọn ọmọ àlejò tí wọ́n da ara pọ̀ mọ́ Olúwa, láti sìn ín, àti láti fẹ́ orúkọ Olúwa . . . Àwọn ni èmi óò sì mú wá sí òkè ńlá mímọ́ mi, èmi óò sì mú inú wọn dùn, nínú ilé àdúrà mi: ẹbọ sísun wọn, àti ìrúbọ wọn, yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi; nítorí ilé àdúrà ni a óò máa pe ilé mi fún gbogbo ènìyàn.”
6. (a) Irú ẹbọ wo ni àwọn àlejò ń rú? (b) Kí ni agbada omi nínú àgbàlá tí ó wà fún àwọn àlùfáà rán wọn létí?
6 Lára àwọn ẹbọ tí àwọn àlejò wọ̀nyí rú ni “èso ètè [àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà tí a lọ̀ kúnná] tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ [Ọlọ́run]” àti “rere ṣíṣe ati ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹlu àwọn ẹlòmíràn.” (Hébérù 13:15, 16) Agbada omi ńlá tí àwọn àlùfáà ní láti lò láti wẹ ara wọn tún jẹ́ ìránnilétí pàtàkì fún àwọn àlejò wọ̀nyí. Àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún ìwẹ̀mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà híhù, bí a ṣe ń mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe kedere sí wọn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé.
Ibi Mímọ́ àti Àwọn Ohun Èèlò Rẹ̀
7. (a) Ojú wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá fi ń wo àwọn àǹfààní ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́? (b) Àwọn àfikún àǹfààní wo ni àwọn àlejò rí gbà?
7 Ibi Mímọ́ àti àwọn ohun èèlò rẹ̀ ha ní ìtumọ̀ kankan fún ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àlejò yìí bí? Toò, wọn kò lè sí nínú ipò tí Ibi Mímọ́ náà ń ṣàpẹẹrẹ láéláé. A kò tún wọn bí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ aráàlú ní ọ̀run. Èyí ha mú kí wọn ṣe ìlara tàbí kí wọ́n ṣe ojúkòkòrò bí? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń hó ìhó ayọ̀ nínú àǹfààní wọn ti ṣíṣe ìtìlẹyìn fún àṣẹ́kù 144,000 náà, wọ́n sì fi ìmọrírì tí ó jinlẹ̀ hàn fún ète Ọlọ́run fún sísọ àwọn ọmọ nípa tẹ̀mí wọ̀nyí dọmọ, àwọn tí yóò ṣàjọpín pẹ̀lú Kristi nínú gbígbé aráyé dé ìjẹ́pípé. Bákan náà, ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àlejò ṣìkẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ńláǹlà tí Ọlọ́run fi hàn sí wọn, ní fífún wọn ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Àwọn kan nínú àlejò wọ̀nyí, bíi ti àwọn Nétínímù ìgbàanì, ni a ti fún ní àwọn àǹfààní ṣíṣàbójútó, ti ríran ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́ náà lọ́wọ́.b (Aísáyà 61:5) Lára àwọn wọ̀nyí ni Jésù yóò ti yan “àwọn ọmọ aládé nínú gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 45:16.
8, 9. Àǹfààní wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá rí nínú ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ohun èèlò Ibi Mímọ́?
8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọn kì yóò wọnú Ibi Mímọ́ amápẹẹrẹṣẹ náà, ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àlejò ń kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó ṣeyebíye láti inú àwọn ohun èèlò rẹ̀. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá fìtílà náà ti nílò ìpèsè òróró nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àlejò nílò ẹ̀mí mímọ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àwọn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, èyí tí ń tipasẹ̀ “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” dé ọ̀dọ̀ wọn. (Mátíù 24:45-47) Síwájú sí i, ẹ̀mí Ọlọ́run ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dáhùn padà sí ìkésíni náà pé: “Àti ẹ̀mí àti ìyàwó [àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró] ń bá a nìṣó ní wíwí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Nípa báyìí, ọ̀pá fìtílà náà jẹ́ ìránnilétí fún ogunlọ́gọ̀ ńlá nípa ojúṣe wọn láti máa tàn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni àti láti yẹra fún ohunkóhun tí yóò mú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bínú nínú ìwà, èrò, ọ̀rọ̀, tàbí ìṣe wọn.—Éfésù 4:30.
9 Tábìlì àkàrà ìfihàn rán ogunlọ́gọ̀ ńlá létí pé láti wà ní ìlera nípa tẹ̀mí, wọ́n gbọdọ̀ máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé láti inú Bíbélì àti láti inú àwọn ìtẹ̀jáde “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” náà. (Mátíù 4:4) Pẹpẹ tùràrí rán wọn létí ìjẹ́pàtàkì gbígbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n baà lè pa ìwà títọ́ wọn mọ́. (Lúùkù 21:36) Àdúrà wọn yẹ kí ó ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn àti ọpẹ́ tí ó ti ọkàn wá nínú. (Sáàmù 106:1) Pẹpẹ tùràrí tún ń rán wọn létí nípa àìní náà láti máa yin Ọlọ́run ní àwọn ọ̀nà míràn, irú bíi nípa fífi tọkàntọkàn kọrin Ìjọba náà ní àwọn ìpàdé Kristẹni àti bí wọ́n ṣe ń múra sílẹ̀ dáradára láti lè ṣe “ìpolongo” gbígbéṣẹ́ “ní gbangba fún ìgbàlà.”—Róòmù 10:10.
Ẹ̀kún Rẹ́rẹ́ Ayọ̀ Ìṣẹ́gun ti Ìjọsìn Tòótọ́
10. (a) Ìfojúsọ́nà kíkọyọyọ wo ni a ń retí? (b) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀?
10 Lónìí, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè ń rọ́ lọ sí ilé ìjọsìn Jèhófà. (Aísáyà 2:2, 3) Ní jíjẹ́rìí sí èyí, Ìṣípayá 15:4 sọ pé: “Ta ni kì yóò bẹ̀rù rẹ ní ti gidi, Jèhófà, tí kì yóò sì yin orúkọ rẹ lógo, nítorí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin? Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá wọn yóò sì jọ́sìn níwájú rẹ, nítorí a ti fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ tí ó jẹ́ òdodo hàn kedere.” Sekaráyà orí 14 ṣàpèjúwe ohun tí ó tẹ̀ lé e. Ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́, ìwà burúkú àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé yóò dé òtéńté bí wọ́n ṣe ń kóra jọ fún ìgbà ìkẹyìn láti gbógun dìde sí Jerúsálẹ́mù—àwọn aṣojú Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà náà, Jèhófà yóò gbégbèésẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Jagunjagun, òun “yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì jà,” àwọn tí wọ́n lórí láyà láti ṣe ìgbéjàkò yìí.—Sekaráyà 14:2, 3.
11, 12. (a) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe hùwà padà sí ìgbéjàkò kárí ayé tí a óò ṣe sí àwọn olùjọsìn nínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀? (b) Kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí ogun Ọlọ́run?
11 “Èyí ni yóò sì jẹ́ àrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ti bá Jerúsálẹ́mù jà; ẹran ara wọn yóò rù nígbà tí wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ní ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì [súnkì] ní ẹnu wọn. Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàárín wọn; wọn óò sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì dìde sí ọwọ́ ẹnì kejì rẹ̀.”—Sekaráyà 14:12, 13.
12 Yálà àrùn gidi tàbí àrùn ìṣàpẹẹrẹ ni àrùn yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣì máa wò ó ná. Ṣùgbọ́n, ohun kan dájú ṣáká. Nígbà tí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run bá gbéra láti gbéjà ko àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kárí ayé, ìfihàn kíkàmàmà agbára ńlá Ọlọ́run yóò dá wọn dúró. A óò pa wọ́n lẹ́nu mọ́. Yóò dà bíi pé ahọ́n tí wọ́n fi ń ṣe fọ́n-ń-té ti súnkì. Wọn kì yóò ríran rí góńgó àjùmọ̀gbékalẹ̀ wọn mọ́, bíi pé ojú wọn ti rà dànù. Wọn yóò pàdánù agbára wọn gan-an, tí ó mú kí wọ́n láyà láti ṣe ìgbéjàkò náà. Nínú ìdàrúdàpọ̀, wọn yóò máa pa ara wọn nípakúpa. Nípa báyìí, gbogbo ọ̀tá ìjọsìn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ni a óò gbá dànù. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, a óò ti fipá mú gbogbo orílẹ̀-èdè láti gba ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jèhófà lọ́gàá. Àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò ní ìmúṣẹ pé: “Jèhófà yóò di ọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sekaráyà 14:9, NW) Lẹ́yìn náà, a óò de Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ bí Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Kristi ti ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìbùkún ńláǹlà tí ó ní ní ìpamọ́ fún aráyé.—Ìṣípayá 20:1, 2; 21:3, 4.
Àjíǹde Orí Ilẹ̀ Ayé
13. Àwọn wo ni àwọn tí “ó kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè”?
13 Àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà ń bá a nìṣó ní orí 14, ẹsẹ 16, pé: “Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí ó kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jerúsálẹ́mù yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sin Ọba, Olúwa àwọn ọmọ ogun, àti láti pa àsè àgọ́ wọnnì mọ́.” Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ láàyè lónìí, tí wọ́n bá wàláàyè títí di òpin ètò ìgbékalẹ̀ burúkú yìí, tí wọ́n sì dúró gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìjọsìn tòótọ́ yóò fara gba “ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.” (Tẹsalóníkà Kejì 1:7-9; tún wo Mátíù 25:31-33, 46.) Wọn kì yóò ní àjíǹde. Ó ṣeé ṣe, nígbà náà, kí àwọn “tí ó kù” náà, ní nínú mẹ́ḿbà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n kú ṣáájú ogun àjàkẹ́yìn Ọlọ́run, tí wọ́n sì ní ìrètí àjíǹde tí a gbé ka Bíbélì. Jésù ṣèlérí pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nínú èyí tí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àwọn ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yóò sì jáde wá, àwọn wọnnì tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn wọnnì tí wọ́n sọ ohun bíburú jáì dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.”—Jòhánù 5:28, 29.
14. (a) Kí ni àwọn tí a óò jí dìde yóò ṣe láti lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni yòówù tí ó bá kọ̀ láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣe ìjọsìn tòótọ́?
14 Gbogbo àwọn tí a bá jí dìde gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan kí àjíǹde wọn baà lè já sí àjíǹde ìyè, kí ó má baà jẹ́ ìdájọ́ tí kò bára dé. Wọ́n gbọ́dọ̀ wá sínú àwọn àgbàlá tẹ́ḿpìlì Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì tẹrí ba nínú ìyàsímímọ́ sí Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ẹnikẹ́ni tí a bá jí dìde tí ó kọ̀ láti ṣe èyí yóò jìyà àrùn kan náà tí ó kọ lu àwọn orílẹ̀-èdè òde òní. (Sekaráyà 14:18) Ta ni ó mọ iye àwọn ẹni tí a óò jí dìde tí wọn yóò fi tayọ̀tayọ̀ dara pọ̀ mọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá náà nínú ṣíṣayẹyẹ Àsè Àgọ́ amápẹẹrẹṣẹ? Kò sí àní-àní pé, wọn yóò pọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, tẹ́ḿpìlì ńlá Jèhófà nípa tẹ̀mí yóò sì túbọ̀ di ológo!
Àsè Àgọ́ Amápẹẹrẹṣẹ
15. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn apá títayọ nínú Àsè Àgọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ń ṣe? (b) Èé ṣe tí wọ́n fi ń fi 70 akọ màlúù rúbọ nígbà àsè náà?
15 Lọ́dọọdún, a béèrè pé kí Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣayẹyẹ Àsè Àgọ́. Ó máa ń gba ọ̀sẹ̀ kan, ó sì máa ń wáyé ní òpin ìgbà ìkórè. Ó máa ń jẹ́ àkókò onídùnnú láti dúpẹ́. Títí ọ̀sẹ̀ náà yóò fi parí, wọ́n yóò máa gbé nínú àgọ́ tí a fi ewé bò, ní pàtàkì imọ̀ ọ̀pẹ. Àsè yìí rán Ísírẹ́lì létí bí Ọlọ́run ṣe gba àwọn baba ńlá wọn là kúrò ní Íjíbítì àti bí ó ṣe tọ́jú wọn bí wọ́n ti ń gbé nínú àgọ́ nígbà tí wọ́n ń rìn káàkiri fún 40 ọdún nínú aginjù títí wọ́n fi dé Ilẹ̀ Ìlérí. (Léfítíkù 23:39-43) Ní àkókò àsè náà, a óò fi 70 akọ màlúù rúbọ lórí pẹpẹ tẹ́ḿpìlì. Ó ṣe kedere pé, apá yìí nínú àsè náà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àṣepé àti àṣekúnná iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tí Jésù Kristi yóò ṣe. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà rẹ̀ yóò ṣàn dé ọ̀dọ̀ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn àtọmọdọ́mọ 70 ìdílé aráyé tí ó ṣẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Noa.—Jẹ́nẹ́sísì 10:1-29; Númérì 29:12-34; Mátíù 20:28.
16, 17. (a) Nígbà wo ni Àsè Àgọ́ amápẹẹrẹṣẹ bẹ̀rẹ̀, báwo sì ni ó ṣe tẹ̀ síwájú? (b) Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe nípìn-ín nínú ayẹyẹ náà?
16 Nípa báyìí, Àsè Àgọ́ ìgbàanì tọ́ka sí ìkójọpọ̀ onídùnnú ti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a rà padà sínú tẹ́ḿpìlì ńlá Jèhófà nípa tẹ̀mí. Ìmúṣẹ àsè yìí bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, pẹ̀lú ìbẹ̀rẹ̀ ìkójọpọ̀ onídùnnú ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí sínú ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 2:41, 46, 47) Àwọn ẹni-àmì-òróró yìí mọ̀ pé àwọ́n jẹ́ “olùgbé fún ìgbà díẹ̀” nínú ayé Satani nítorí pé “ẹ̀tọ́” wọn “gẹ́gẹ́ bí aráàlú ń bẹ ní àwọn ọ̀run.” (Pétérù Kìíní 2:11; Fílípì 3:20) Ìpẹ̀yìndà tí ó yọrí sí dídá Kirisẹ́ńdọ̀mù sílẹ̀ bo àsè onídùnnú náà mọ́lẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. (Tẹsalóníkà Kejì 2:1-3) Ṣùgbọ́n, a tún bẹ̀rẹ̀ àsè náà padà ní ọdún 1919 pẹ̀lú ìkójọpọ̀ onídùnnú ti àwọn mẹ́ḿbà tí ó ṣẹ́ kù lára 144,000, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí, èyí tí ìkójọpọ̀ ogunlọ́gọ̀ ńlá káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ti Ìṣípayá 7:9 tẹ̀ lé e.
17 A ṣàpèjúwe ogunlọ́gọ̀ ńlá náà pé wọ́n ní imọ̀ ọ̀pẹ ní ọwọ́ wọn, èyí tí ó fi hàn pé àwọn pẹ̀lú jẹ́ olùfìdùnnú ṣayẹyẹ Àsè Àgọ́ amápẹẹrẹṣẹ náà. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni olùṣèyàsímímọ́, wọ́n ń fi ìdùnnú nípìn-ín nínú iṣẹ́ títúbọ̀ kó àwọn olùjọsìn jọ pọ̀ sínú tẹ́ḿpìlì Jèhófà. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀, wọ́n mọ̀ pé àwọn kò ní ẹ̀tọ́ láti máa gbé ilẹ̀ ayé lọ títí láé. Àwọn, papọ̀ pẹ̀lú àwọn tí a óò jí dìde ní ọjọ́ ọ̀la, gbọ́dọ̀ máa lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi títí wọn yóò fi dé ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.—Ìṣípayá 20:5.
18. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù Kristi? (b) Báwo ni ìjọsìn tòótọ́ Jèhófà yóò ṣe yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín?
18 Nígbà náà, àwọn olùjọsìn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé yóò dúró níwájú rẹ̀ nínú ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn láìnílò ẹgbẹ́ àlùfáà kan ní òkè ọ̀run. Yóò ti tó àkókò tí Jésù Kristi yóò “fi ìjọba náà lé Ọlọ́run àti Bàbá rẹ̀ lọ́wọ́.” (Kọ́ríńtì Kìíní 15:24) A óò tú Sátánì sílẹ̀ “fún ìgbà díẹ̀” láti dán ìran ènìyàn pípé wò. Ẹni yòówù tí ó bá di aláìṣòtítọ́ ni a óò parun títí láé, papọ̀ pẹ̀lú Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Àwọn tí wọ́n bá dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ni a óò fún ní ìyè àìnípẹ̀kun. Wọn yóò máa gbé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé títí láé. Nípa báyìí, Àsè Àgọ́ amápẹẹrẹṣẹ yóò ti wá sí òpin ológo, tí ó kẹ́sẹ járí. Ìjọsìn tòótọ́ yóò ti yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun fún ògo àìnípẹ̀kun Jèhófà àti ayọ̀ ayérayé aráyé.—Ìṣípayá 20:3, 7-10, 14, 15.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé lórí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan lórí ìwé Sekaráyà orí 14, wo ìwé náà, Paradise Restored to Mankind—By Theocracy!, tí a tẹ̀ jáde ní 1972 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., orí 21 àti 22.
b Fún àlàyé púpọ̀ sí i lórí àwọn Nétínímù òde òní, wo Ilé-Ìṣọ́nà, April 15, 1992, ojú ìwé 16.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Báwo ni “Jerúsálẹ́mù” ṣe bọ́ sábẹ́ ìgbéjàkò nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní?—Sekaráyà 14:2.
◻ Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run láti ọdún 1919?
◻ Àwọn wo ni wọ́n ń nípìn-ín nínú ṣíṣayẹyẹ Àsè Àgọ́ amápẹẹrẹṣẹ lónìí?
◻ Báwo ni ìjọsìn tòótọ́ yóò ṣe yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun pátápátá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
A lo imọ̀ ọ̀pẹ láti fi ṣayẹyẹ Àsè Àgọ́