ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 7/1 ojú ìwé 25-27
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Ṣiṣẹ́ “Ìyanu”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Ṣiṣẹ́ “Ìyanu”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Bí Mo Ṣe Ń Wá Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run Kiri
  • Wíwàásù ní Ìlú Ìbílẹ̀ Mi
  • “Ìyanu” Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 7/1 ojú ìwé 25-27

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Ṣiṣẹ́ “Ìyanu”

GẸ́GẸ́ BÍ THÉRÈSE HÉON TI SỌ

Ní ọjọ́ kan ní 1965, mo wọ ilé iṣẹ́ okòwò kan, mo sì fi àwọn ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! lọ àwọn oníṣòwò. Bí mo ti fẹ́ máa lọ, mo gbọ́ ìró lílágbára kan. Ọta ìbọn kan balẹ̀ nítòsí ẹsẹ̀ mi. Ọ̀kan nínú àwọn oníṣòwò náà ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Bí ó ti yẹ láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lò nìyẹn.”

ÌRÍRÍ yẹn dẹ́rù bà mí—ṣùgbọ́n kò tó láti mú mi fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sílẹ̀. Òtítọ́ Bíbélì tí mo ti kọ́ ṣeyebíye gan-an ju pé kí n jẹ́ kí ohunkóhun mú mi fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi sílẹ̀ lọ. Jẹ́ kí ń ṣàlàyé ìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀.

Lẹ́yìn tí a bí mi ní July 1918, àwọn òbí mi tẹ̀ dó sí Cap-de-la-Madeleine, abúlé kékeré kan ní Quebec, ní Kánádà, tí a ń pè ní Ibi Ìyanu. Àwọn àlejò máa ń wá síhìn-ín láti júbà ní ojúbọ Màríà Wúndíá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè fi ẹ̀rí iṣẹ́ ìyanu tí a fẹnú lásán pè ní ti Màríà hàn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu ní ti gidi nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ ènìyàn, níwọ̀n bí abúlé náà ti gbèrú di ìlú kan tí ó ní èyí tí ó ju 30,000 olùgbé.

Nígbà tí mo jẹ́ nǹkan bí ọmọ 20 ọdún, bàbá mi kíyè sí ọkàn-ìfẹ́ mi nínú àwọn ọ̀ràn ìsìn, ó sì fún mi ní Bíbélì rẹ̀. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kà á, ó yà mí lẹ́nu láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Ẹ́kísódù orí 20 pé a dẹ́bi fún ìjọsìn ère ní kedere. Lójú ẹsẹ̀, n kò ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì mọ́, mo sì dáwọ́ lílọ sí Máàsì dúró. N kò fẹ́ jọ́sìn àwọn ère mọ́. Mo ṣì lè rántí ìgbà tí Bàbá sọ pé, “Thérèse, ṣe oò ní lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ni?” Mo dáhùn pé: “Rárá, mo ń ka Bíbélì.”

Bíbélì kíkà ń bá a nìṣó láti jẹ́ apá kan ìgbésí ayé mi, àní lẹ́yìn tí mo ṣe ìgbéyàwó ní September 1938 pàápàá. Níwọ̀n bí ọkọ mi, Rosaire, ti sábà máa ń ṣiṣẹ́ alẹ́, mo sọ ọ́ dàṣà láti máa ka Bíbélì nígbà tí ó bá wà lẹ́nu iṣẹ́. Kò pẹ́ tí mo fi dé ìparí èrò náà pé Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní àwọn ènìyàn kan, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá wọn kiri.

Bí Mo Ṣe Ń Wá Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run Kiri

Nítorí ohun ti mo ti kọ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, nígbà tí mo wà ní kékeré, mo máa ń bẹ̀rù láti lọ sùn nítorí ìbẹ̀rù jíjí sí ọ̀run àpáàdì. Láti ṣẹ́gun irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀, mo máa ń sọ fún ara mi pé Ọlọ́run ìfẹ́ kì yóò jẹ́ kí ohun tí ó burú bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀. Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé, mo ń ka Bíbélì nìṣó, ní wíwá òtítọ́ kiri. Ń ṣe ni mo dà bí ìwẹ̀fà ará Etiópíà tí ó kàwé ṣùgbọ́n tí kò yé e.—Ìṣe 8:26-39.

Arákùnrin mi André àti aya rẹ̀, tí wọ́n ń gbé nínú iyàrá kan tí ó wà nísàlẹ̀ tiwa, bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nǹkan bíi 1957. Mo sọ fún aya arákùnrin mi láti máa ta mí lólobó nípa kíkan àjà ilé nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí bá wá wàásù nínú ilé náà. Lọ́nà yẹn, mo máa ń mọ ìgbà tí n kò ní dáhùn. Lọ́jọ́ kan, ó gbàgbé láti ta mí lólobó.

Lọ́jọ́ yẹn, mo ṣi ilẹ̀kùn mo sì ṣalábàápàdé Kay Munday, aṣáájú ọ̀nà kan, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pé àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ fún mi nípa orúkọ Ọlọ́run, ní ṣíṣàlàyé pé Ọlọ́run ní orúkọ ara ẹni kan, Jèhófà. Lẹ́yìn tí ó lọ tán, mo yẹ Bíbélì mi wo láti rí i dájú pé ẹsẹ Bíbélì ti ohun tí ó sọ lẹ́yìn ní ti gidi. Ìwádìí mi mú mi láyọ̀ gidigidi.—Ẹ́kísódù 6:3, Douay Version, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé; Mátíù 6:9, 10; Jòhánù 17:6.

Nígbà tí Kay padà wá, a jíròrò ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kátólíìkì nípa Mẹ́talọ́kan, tí ó jẹ́wọ́ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni mẹ́ta nínú Ọlọ́run kan. Lẹ́yìn ìgbà náà, mo fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Bíbélì tèmi fúnra mi láti mú un dá ara mi lójú pé kò kọ́ni ni Mẹ́talọ́kan. (Ìṣe 17:11) Ìkẹ́kọ̀ọ́ mi jẹ́rìí sí i pé Jésù kò tóbi lọ́lá tó Ọlọ́run. A ṣẹ̀dá rẹ̀ ni. Ó ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Jèhófà kò ní ìbẹ̀rẹ̀. (Sáàmù 90:1, 2; Jòhánù 14:28; Kólósè 1:15-17; Ìṣípayá 3:14) Níwọ̀n bí ohun tí mo ń kọ ti tẹ́ mi lọ́rùn, mo láyọ̀ láti máa bá ìjíròrò Bíbélì nìṣó.

Ní ọjọ́ kan ní 1958, ní àkókò ìjì oníyìnyín ti November, Kay ké sí mi láti wá sí àpéjọ àyíká tí a ṣe ní ìrọ̀lẹ́ yẹn gan-an ní gbọ̀ngàn kan tí a háyà. Mo tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà, mo sì gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Lẹ́yìn náà, nígbà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí kan tí ó tọ̀ mí wá, mo béèrè pé, “Kristian tòótọ́ kan ha gbọ́dọ̀ wàásù láti ilé dé ilé bí?”

Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, a gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere, Bíbélì sì fi hàn pé títọ àwọn ènìyàn lọ ní ilé wọ́n jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti wàásù.”—Ìṣe 20:20.

Ẹ wo bí ìdáhùn rẹ̀ ti dùn mọ́ mi nínú tó! Ó mú un dá mi lójú pé mo ti rí àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ká ní ń ṣe ni ó sọ pé, “Rárá o, kò pọn dandan,” ǹ bá ti ṣiyè méjì pé mo ti rí òtítọ́, nítorí mo mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa wíwàásù láti ilé dé ilé. Láti ìgbà náà lọ, mo tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí lọ́nà yíyára kánkán.

Lẹ́yìn àpéjọ àyíká yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí a ń ṣe ní ìlú Trois-Rivières tí ó wà nítòsí. Kay àti alájọṣiṣẹ́ rẹ̀, Florence Bowman, ni kìkì àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń gbé ní Cap-de-la-Madeleine nígbà náà. Ní ọjọ́ kan, mo sọ pé, “Màá bá a yín lọ wàásù lọ́la.” Inú wọ́n dùn pé mo bá wọn lọ.

Wíwàásù ní Ìlú Ìbílẹ̀ Mi

Mo rò pé gbogbo ènìyàn yóò tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ Bíbélì, ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí mo fi mọ̀ pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí a pínṣẹ́ yàn fún Kay àti Florence síbòmíràn, èmi nìkan ni ó wà ní ìlú tí ń wàásù òtítọ́ Bíbélì láti ilé dé ilé. Láìṣojo, mo ń bá dídánìkan wàásù nìṣó fún nǹkan bí ọdún méjì títí tí mo fi ṣe batisí ní June 8, 1963. Ní ọjọ́ yẹn gan-an, mo forúkọ sílẹ̀ fún ohun tí a ń pè nígbà yẹn ní iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà alákòókò ìsinmi.

Mo ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà alákòókò ìsinmi fún ọdún kan. Lẹ́yìn náà, Delvina Saint-Laurent ṣèlérí pé ohun yóò wá sí Cap-de-la-Madeleine, òun yóò sì máa bá mi ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, tí mo bá di aṣáájú ọ̀nà. Nítorí èyí, mo kọ̀wé ìbéèrè ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi. Ṣùgbọ́n ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀sẹ̀ méjì péré ṣáájú ìgbà tí ń óò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, Delvina kú. Kí ni n óò ṣe? Tóò, mo ti kọ̀wé ìbéèrè ìwọṣẹ́, n kò sì fẹ́ padà sẹ́yìn. Nítorí náà, ní October 1964, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìgbésí ayé mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Fún ọdún mẹ́rin tí ó tẹ̀ lé e, èmi nìkan ń dá lọ láti ilé dé ilé.

Àwọn Kátólíìkì olùfọkànsìn ní Cap-de-la-Madeleine ṣàtakò lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn kan ké sí ọlọ́pàá nínú ìgbìyànjú láti ṣèdíwọ́ fún mi láti má ṣe wàásù. Ní ọjọ́ kan, bí mo ti sọ ní ìbẹ̀rẹ̀, oníṣòwò kan gbìyànjú láti dẹ́rù bà mí nípa yíyìnbọn sí ẹsẹ̀ mi. Tóò, èyí di ìròyìn láàárín ìlú. Ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àdúgbò pè é ní ogun ìsìn lòdì sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà lódindi yọrí sí ìjẹ́rìí àtàtà. Lọ́nà kan ṣáá, ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, ẹnì kan tí ó jẹ́ ìbátan oníṣòwò náà tí ó yìnbọn sí mi fúnra rẹ̀ di Ẹlẹ́rìí.

“Ìyanu” Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe

Jálẹ̀ àwọn ọdún, mo ti rí i tí ògiri àtakò sí òtítọ́ Bíbélì fọ́ sí wẹ́wẹ́ díẹ̀díẹ̀ ní Cap-de-la-Madeleine. Ní nǹkan bíi 1968, àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ṣí wá síhìn-ín, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn padà sí òtítọ́ Bíbélì. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, ìlọsókè gíga lọ́lá ti wà nínú iye àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó dé orí kókó kan tí ó fi jẹ́ pé mo ní láti sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo ń darí kí n baà lè máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé.

Ní ọjọ́ kan, ọ̀dọ́bìnrin kan gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye lọ́wọ́ mi. Alájọṣepọ̀ rẹ̀ nígbà yẹn jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń jẹ́ André, ọ̀daràn tí ìrísí rẹ̀ jẹ́ ti oníjàgídíjàgan, ẹni tí ó dara pọ̀ nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ náà. Ìjíròrò pẹ̀lú André ru ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ sókè, a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí ó ń kọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Ní àkókò kan, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn jàǹdùkú mẹ́rin, tí ọ̀kan nínú wọn kì í sọ̀rọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n tí ó máa ń fetí sílẹ̀ gidigidi. Orúkọ rẹ̀ ni Pierre. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ní nǹkan bí agogo méjì, èmi àti ọkọ mi gbọ́ ìró ilẹ̀kùn kíkàn. Fojú inú wo ìran yẹn: Àwọn jàǹdùkú mẹ́rin wà lórí ìdúró tí wọ́n fẹ́ béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ mi. Ó dára pé, Rosaire kò ṣàròyé rí nípa irú ìbẹ̀wò tí kò bágbà mu bẹ́ẹ̀.

Ní ìbẹ̀rẹ̀, àwọn ọkùnrin mẹ́rin náà ń wá sí ìpàdé. Ṣùgbọ́n, André àti Pierre ni kò dáwọ́ dúró. Wọ́n mú ìgbésí ayé wọn bá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run mu, wọ́n sì ṣe batisí. Fún ohun tí ó ti ju 20 ọdún lọ nísinsìnyí, àwọn ọkùnrin méjèèjì ti fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, a mọ̀ wọ́n bí ẹní mowó fún ìwà ọ̀daràn wọn, àwọn ọlọ́pàá sì ń ṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Ní àwọn ìgbà kan, àwọn ọlọ́pàá wá, tí wọ́n sì ń wá wọn kiri lẹ́yìn ọ̀kan nínú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tàbí nígbà ìpàdé ìjọ. Mo láyọ̀ pé mo wàásù fún “gbogbo onírúurú ènìyàn,” mo sì tipa báyìí rí i ní tààràtà bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń ṣe àwọn ìyípadà tí ó dà bí ìyanu ní tòótọ́.—Tímótì Kìíní 2:4.

Ká ní a sọ fún mi ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi pé Gbọ̀ngàn Ìjọba kan yóò wà ní Cap-de-la-Madeleine, tí àwọn ènìyàn Jèhófà yóò sì kún inú rẹ̀, n kì bá ti gbà á gbọ́. Inú mi dùn pé, ìjọ kékeré náà tí ó wà ní ìlú Trois-Rivières nítòsí ti gbèrú di ìjọ mẹ́fà tí ń gbilẹ̀ sí i, tí ń pàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta, tí èyí tí ó wà ní Cap-de-la-Madeleine jẹ́ ara wọn.

Èmi fúnra mi ti ní ayọ̀ ríran nǹkan bí 30 ènìyàn lọ́wọ́ dé orí ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti batisí. Nísinsìnyí, ní ẹni ọdún 78, mo lè sọ ní tòótọ́ pé mo láyọ̀ pé mo ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Ṣùgbọ́n, mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé mo ti dojú kọ àwọn sáà tí ń múni rẹ̀wẹ̀sì. Láti kojú irú àwọn sáà bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àṣeyọrí, mo máa ń ṣí Bíbélì mi nígbà gbogbo, mo sì ń ka ojú ewé mélòó kan tí ń tù mí lára. Kò ṣeé ṣe fún mi láti jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá láìka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ní pàtàkì ni Jòhánù 15:7 ń fúnni níṣìírí, níbi tí ó ti sọ pé: “Bí ẹ bá dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi tí àwọn àsọjáde mi sì dúró nínú yín, ẹ béèrè ohun yòówù tí ẹ bá fẹ́ yóò sì ṣẹlẹ̀ fún yín.”

Ó jẹ́ ìrètí mi láti rí Rosaire nínú ayé tuntun tí ó sún mọ́ tòsí. (Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) Kété ṣáájú ikú rẹ̀ ní 1975, ó ń tẹ̀ síwájú dáradára síhà batisí. Ní báyìí ná, mo pinnu láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nìṣó, kí n sì máa yọ̀ nínú iṣẹ́ Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́