Ìpàdé Ọdọọdún October 5, 1996
ÌPÀDÉ ỌDỌỌDÚN ti mẹ́ḿbà Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania yóò wáyé ní October 5, 1996, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. A óò ṣe ìpàdé àṣeṣáájú ti kìkì àwọn mẹ́ḿbà ní agogo 9:30 òwúrọ̀, tí ìpàdé ọdọọdún ti gbogbogbòò yóò sì tẹ̀ lé e ní agogo 10:00 òwúrọ̀.
Àwọn mẹ́ḿbà Àjọ ní láti fi ìyípadà èyíkéyìí nínú àwọn àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ wọn nínú ọdún tí ó kọjá tó Ọ́fíìsì Akọ̀wé létí nísinsìnyí kí àwọn lẹ́tà ìfitónilétí tí a ń lò déédéé àti ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni baà lè dé ọ̀dọ̀ wọn ní July.
A ní láti dá àwọn ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni, tí a óò fi ránṣẹ́ sí àwọn mẹ́ḿbà pẹ̀lú ìfitónilétí nípa ìpàdé ọdọọdún náà, padà kí ó baà lè dé Ọ́fíìsì Akọ̀wé Society ó pẹ́ tán ní August 1. Mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan ní láti kọ ọ̀rọ̀ kún ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni tirẹ̀ ní kíámọ́sá kí ó sì dá a padà, ní sísọ yálà òun fúnra òun yóò wà ní ibi ìpàdé náà tàbí òun kì yóò wà níbẹ̀. Ìsọfúnni tí a kọ sórí ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣe pàtó lórí kókó yìí, níwọ̀n bí a óò ti gbára lé e fún pípinnu àwọn wo ni yóò wà níbẹ̀ fúnra wọn.
A retí pé gbogbo àkókò ìjókòó náà, títí kan ìpàdé iṣẹ́ àmójútó tí a ń ṣe déédéé àti àwọn ìròyìn, yóò parí ní agogo 1:00 ọ̀sán tàbí ní kété lẹ́yìn náà. Kì yóò sí àkókò ìjókòó ọ̀sán. Nítorí àyè tí ó mọ níwọ̀n, ìgbàwọlé yóò jẹ́ nípasẹ̀ tíkẹ́ẹ̀tì nìkan ṣoṣo. Kì yóò sí ìṣètò kankan fún síso ìpàdé ọdọọdún náà pọ̀ mọ́ wáyà tẹlifóònù lọ sí àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ mìíràn.