Ọkàn Ha Jẹ́ Àìleèkú Bí?
PẸ̀LÚ ìparọ́rọ́, tẹbí tọ̀rẹ́ rọra ń yí pósí ṣíṣí sílẹ̀ náà ká. Wọ́n ń wo òkú náà, òkú ọmọdékùnrin ọlọ́dún 17. Agbára káká ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti ilé ẹ̀kọ́ fi dá a mọ̀. Ìtọ́jú oníkẹ́míkà ti re irun rẹ̀ jẹ; àrùn jẹjẹrẹ ti mú kí ó rù hangogo. Èyí ha lè jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn ní tòótọ́ bí? Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn, ó kún fún èrò, ìbéèrè, agbára—ó sì ń ta kébékébé! Ìyá ọmọkùnrin náà ń sọ ní àsọtúnsọ pẹ̀lú omijé lójú pé: “Tommy láyọ̀ sí i nísinsìnyí. Ọlọ́run fẹ́ kí Tommy wà ní ọ̀run pẹ̀lú rẹ̀.”
Ìyá tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́ yìí, rí ìrètí àti ìtùnú díẹ̀ nínú èrò náà pé, lọ́nà kan ṣáá ọmọkùnrin òún ṣì wà láàyè. A ti kọ́ ọ ní ṣọ́ọ̀ṣì pé, ọkàn jẹ́ àìleèkú, pé òun ni ibùjókòó àkópọ̀ ìwà, ìrònú, agbára ìrántí—“ẹni náà gan-an.” Ó gbà gbọ́ pé ọkàn ọmọkùnrin òun kò tí ì kú rárá; nítorí pé ọkàn jẹ́ ẹ̀mí tí ń bẹ láàyè, ó fi ara rẹ̀ sílẹ̀ nígbà ikú, ó sì lọ sí ọ̀run láti wà pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn áńgẹ́lì.
Ní àkókò ọ̀ràn ìbànújẹ́, ọkàn-àyà ènìyàn máa ń rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ìrètí èyíkéyìí tí ó lè wà, nítorí náà, kó ṣòro láti rí ìdí tí èrò ìgbàgbọ́ yìí fi fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́kàn mọ́ra. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn J. Paterson-Smyth gbà ṣàlàyé ara rẹ̀ nínú ìwé náà, The Gospel of the Hereafter, pé: “Ohun bíńtín ni ikú jẹ́ ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀—ayé àgbàyanu, àgbàyanu, àgbàyanu náà tí Ikú ń mú wa wọ̀.
Káàkiri àgbáyé àti nínú ọ̀pọ̀ ìsìn àti ìṣẹ̀dálẹ̀, àwọn ènìyàn gbà gbọ́ pé ènìyàn ní ọkàn tí kò lè kú nínú ara rẹ̀, ẹ̀mí tí ó wà láàyè tí ó ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara ti kú. Èrò ìgbàgbọ́ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ wà káàkiri nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìsìn àti ẹ̀ya ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ó jẹ́ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ kan tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà nínú ìsìn àwọn Júù pẹ̀lú. Àwọn onísìn Híńdù gbà gbọ́ pé a dá ẹni inú lọ́hùn-ún, tàbí ọkàn, nígbà ìbẹ̀rẹ̀ àkókò, ó wà ní ẹ̀wọ̀n nínú ara nígbà ìbí, yóò sì lọ sínú ara mìíràn nígbà ikú nínú àyípoyípo àtúnwáyé. Àwọn onísìn Mùsùlùmí gbà gbọ́ pé, ọkàn ń wáyé nígbà ìbí, ó sì máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá kú. Àwọn ìsìn míràn—àwọn onímọlẹ̀ ará Áfíríkà, àwọn onísìn Ṣintó, àti àwọn onísìn Búdà pàápàá lọ́nà kan—kọ́ni ní onírúurú nǹkan lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ kan náà.
Àwọn Ìbéèrè Díẹ̀ Tí Ń Dani Láàmú
Bí ìpìlẹ̀ èrò àìleèkú ọkàn kò tilẹ̀ ṣeé sẹ́, tí gbogbogbòò sì fẹ́rẹ̀ẹ́ gbà á gbọ́, síbẹ̀síbẹ̀, ó gbé àwọn ìbéèrè mélòó kan tí ń dani láàmú dìde. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn ń ṣe kàyéfì pé, níbo ni ọkàn olólùfẹ́ kan ń lọ bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá gbé ìgbésí ayé àwòfiṣàpẹẹrẹ. Yóò ha padà wáyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá rírẹlẹ̀ kan bí? Àbí a ti rán an lọ sí pọ́gátórì, níbi tí a óò ti fi iná fọ̀ ọ́ mọ́ títí tí a óò fi rí i pé ó yẹ fún lílọ sí ọ̀run? Èyí tí ó burú jù ni pé, a óò ha dá a lóró títí láé nínú iná ọ̀run àpáàdì bí? Àbí ó ha ti di ẹ̀mí kan tí a gbọ́dọ̀ tù lójú, gẹ́gẹ́ bí ìsìn ọ̀pọ̀ àwọn onímọlẹ̀ ti fi kọ́ni?
Irú ìpìlẹ̀ èrò bẹ́ẹ̀ gbé ìfojúsọ́nà tí ó kún fún ẹrù ìnira síwájú àwọn alààyè. Ó ha yẹ kí a tu ẹ̀mí àwọn olólùfẹ́ tí ó ti kú lójú, kí wọ́n má baà gbẹ̀san lára wa bí? A ha retí pé kí a ràn wọ́n lọ́wọ́ kúrò nínú pọ́gátórì tí ń kó ìpayà báni bí? Àbí a ha wulẹ̀ ní láti jẹ́ kí ìbẹ̀rù àìlèdájà-araawọn-gbè máa mú wa gbọ̀n jìnnìjìnnì nípa ríronú nípa ìjìyà wọn ní ọ̀run àpáàdì bí? Àbí a ha ní láti bá àwọn ẹranko abẹ̀mí kan lò, bí ẹni pé wọ́n ní ọkàn àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ó ti kú bí?
Àwọn ìbéèrè tí ó dìde nípa Ọlọ́run fúnra rẹ̀ tún jẹ́ agbénilọ́kànsókè. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ òbí, bí ìyá tí a mẹ́nu bà ní ìbẹ̀rẹ̀, ni èrò náà pé Ọlọ́run “mú” ọkàn àìleèkú ọmọ wọn lọ sí ọ̀run lọ́dọ̀ rẹ̀ ti kọ́kọ́ tù nínú. Ṣùgbọ́n, kò pẹ́ púpọ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ń ṣe kàyéfì pé, irú Ọlọ́run wo ni yóò fi irú àìsàn burúkú kan kọlu ọmọ tí kò mọwọ́mẹsẹ̀, ní mímú ẹni ọ̀wọ́n náà lọ lójijì kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ tí ọkàn wọ́n ti bàjẹ́, kìkì láti mú ọmọ náà lọ sí ọ̀run ṣáájú àkókò. Ìdájọ́ òdodo, ìfẹ́, àánú, tí irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ní dà? Àwọn kan tilẹ̀ gbé ìbéèrè dìde sí ọgbọ́n irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀. Wọ́n béèrè pé, èé ṣe tí Ọlọ́run ọlọgbọ́n kan yóò ṣe kọ́kọ́ fi gbogbo ọkàn wọ̀nyí sórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú èrò pé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ wọn yóò wá sí ọ̀run? Ìyẹn kò ha ní túmọ̀ sí pé ìsapá òfo lásán ni dídá ilẹ̀ ayé jẹ́ bí?—Fi wé Diutarónómì 32:4; Orin Dáfídì 103:8; Aísáyà 45:18; Jòhánù Kìíní 4:8.
Nígbà náà, ó ṣe kedere pé, ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn, láìka ọ̀nà tí a gbà ń fi ẹ̀kọ́ náà kọ́ni sí, ń gbé ìbéèrè amúniṣekàyéfì dìde, àní àìbáramu pàápàá. Èé ṣe? Ọ̀pọ̀ wàhálà náà ní í ṣe pẹ̀lú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí. O lè rí i pé ó lani lóye láti wádìí ìpilẹ̀ṣẹ̀ yìí díẹ̀; ó sì lè yà ọ́ lẹ́nu láti kọ́ ohun tí Bíbélì funra rẹ̀ sọ nípa ọkàn. Ó pèsè ìrètí tí ó sàn jù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìwàláàyè lẹ́yìn ikú ju bí àwọn ìsìn ayé ti sábà máa ń fi kọ́ni lọ.