Michael Faraday Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ẹni Ìgbàgbọ́
“Bàbá Iná Mànàmáná.” “Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì, Olùṣàyẹ̀wò Títóbi Lọ́lá Jù Lọ Tí Ó Tí ì Gbé Ayé Rí.” Ìwọ̀nyí Ní Àpèjúwe Méjì Nípa Michael Faraday, Tí A Bí Ní Ọdún 1791 Ní England, Tí Àwárí Rẹ̀ Nípa Fífi Mágínẹ́ẹ̀tì Àti Wáyà Àlọ́pọ̀ Mú Iná Mànàmáná Jáde, Yọrí Sí Ṣíṣe Àwọn Ẹrọ Tí Agbára Iná Mànàmáná Ń mú Ṣiṣẹ́ Àti Ẹrọ Amágbára Amẹ́rọṣiṣẹ́ Jáde.
FARADAY kọ́ni lọ́nà gbígbòòrò lórí ẹ̀kọ́ kẹ́mísìrì àti físíìsì ní ilé ẹ̀kọ́ Royal Institution ní London. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti pòkìkí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn èrò ìpìlẹ̀ tí ó díjú. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ yunifásítì fi oyè dá a lọ́lá. Síbẹ̀, ó ṣá kíkókìkí rẹ̀ tì. Ó jẹ́ olùfọkànsìn gidigidi, tí ó máa ń láyọ̀ jù lọ nígbà tí ó bá dá wà ní ilé oníyàrá mẹ́ta rẹ̀ àti láàárín ìdílé rẹ̀, àti láàárín àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Faraday jẹ́ apá kan àwọn tí ó ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀ya ìsìn Kristẹni tí ó kéré púpọ̀, tí a sì fojú tẹ́ḿbẹ́lú, tí a mọ̀ . . . sí àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman. Ta ni wọ́n? Kí ni wọ́n gbà gbọ́? Báwo sì ni èyí ṣe ní ipa ìdarí lórí Faraday?
Àwọn Ọmọlẹ́yìn Sandeman
Geoffrey Cantor, òǹṣèwé náà, Michael Faraday: Sandemanian and Scientist, sọ pé: “Àwọn òbí-àgbà fún Michael Faraday ni ó fọwọ́ sí ìsopọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà láàárín ìdílé Faraday àti ṣọ́ọ̀ṣì àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman.” Wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn òjíṣẹ́ arìnrìn àjò kan, tí kì í tẹ̀ lé èrò gbogbogbòò, tí àwọn olùbákẹ́gbẹ́ rẹ̀ sì ti èrò ìgbàgbọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman lẹ́yìn.
Robert Sandeman (1718 sí 1771) jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì ní Edinburgh, tí ń kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣirò, èdè Gíríìkì, àti àwọn èdè míràn, ní ọjọ́ kan, ó fetí sí òjíṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì Pirẹsibitéríà tẹ́lẹ̀ rí kan, John Glass, tí ń wàásù. Ohun tí ó gbọ́ mú kí ó fi yunifásítì sílẹ̀, ó padà sílé sí Perth, ó sì dara pọ̀ mọ́ Glass àti àwọn olùbákẹ́gbẹ́ rẹ̀.
Ní àwọn ọdún 1720, John Glass ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa àwọn ẹ̀kọ́ kan tí Ṣọ́ọ̀ṣì Scotland fi ń kọ́ni. Ẹ̀kọ́ rẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ó parí èrò sí pé, orílẹ̀-èdè inú Bíbélì náà, Ísírẹ́lì, dúró fún orílẹ̀-èdè nípa tẹ̀mí, tí àwọn ọlọ̀tọ̀ rẹ̀ wá láti inú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Kò rí ibì kan tí a ti dá níní ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan láre.
Nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ ní Tealing, lẹ́yìn odi Dundee, ní Scotland, kò tẹ́ ẹ lọ́rùn mọ́, Glass kúrò nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Scotland, ó ṣì ṣètò àwọn ìpàdé tirẹ̀. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ènìyàn dara pọ̀ mọ́ ọn, láti ìbẹ̀rẹ̀ sì ni wọ́n ti ní èrò wíwà ní ìṣọ̀kan láàárín ara wọn. Wọ́n pinnu láti tẹ̀ lé ìtọ́ni Kristi, tí a kọ sílẹ̀ nínú Mátíù orí 18, ẹsẹ 15 sí 17, láti yanjú aáwọ̀ tí wọ́n bá ní. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n ń ṣe ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, níbi tí àwọn tí wọ́n ní irú ìgbàgbọ́ kan náà máa ń péjọ pọ̀ sí, fún àdúrà àti ìgbaniníyànjú.
Nígbà tí àwọn tí ó pọ̀ díẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá sí àwọn ìpàdé àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ déédéé, a nílò àwọn ọkùnrin tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láti lè darí ìjọsìn wọn. Ṣùgbọ́n àwọn wo ni ó tóótun? John Glass àti àwọn olùbákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé àfiyèsí pàtàkì sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí. (Tímótì Kìíní 3:1-7; Títù 1:5:9) Wọn kò rí i pé ó mẹ́nu kan níní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yunifásítì tàbí lílóye èdè Hébérù àti Gíríìkì. Nítorí náà, lẹ́yìn ríronú tàdúràtàdúrà lórí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́, wọ́n yan àwọn ọkùnrin tí ó tóótun sípò láti di alàgbà. Àwọn tí ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ṣọ́ọ̀ṣì Scotland kà á sí “ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ buni kù” fún àwọn púrúǹtù ọkùnrin “tí a ń mú sá kíjokíjo, àwọn aránṣọ, àwọn atúlẹ̀” láti díbọ́n pé àwọ́n lóye Bíbélì, kí wọ́n sì máa wàásù ìhìn iṣẹ́ rẹ̀. Ní ọdún 1733, nígbà tí Glass àti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kọ́ gbọ̀ngàn ìpàdé tiwọn sí ìlú Perth, àwùjọ àlùfáà àdúgbò gbìdánwò láti fúngun mọ́ àwọn adájọ́ láti lé wọn kúrò nílùú. Ìmọ̀ wọn dòfo, àjọ náà sì gbèrú.
Robert Sandeman gbé àgbà ọmọbìnrin Glass níyàwó, ó sì di alàgbà ní ìjọ Perth ti àwọn elérò ìgbàgbọ́ Glass, ni ẹni ọdún 26. Ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alàgbà wọ̀ ọ́ lọ́rùn débi pé, ó pinnu láti yọ̀ọ̀da gbogbo àkókò rẹ̀ fún iṣẹ́ pásítọ̀. Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí aya rẹ̀ kú, ìwé ìtàn ráńpẹ́ kan nípa ìgbésí ayé rẹ̀ sọ pe, Robert “fi tayọ̀tayọ̀ gbà láti ṣiṣẹ́ sin Olúwa níbikíbi tí a bá ti nílò rẹ̀.”
Èrò Ìgbàgbọ́ Sandeman Tàn Kálẹ̀
Sandeman fi tìtaratìtara mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gbòòrò láti Scotland títí dé England, níbi tí àwùjọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti gbèèrú. Ní àkókò yẹn, awuyewuye dìde láàárín àwọn elérò ìgbàgbọ́ Calvin tí wọ́n jẹ́ ará England. Àwọn kan nínú wọn gbà gbọ́ pé a ti kádàrá wọn fún ìgbàlà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Sandeman fara mọ́ àwọn tí wọ́n gbà pé, ìgbàgbọ́ jẹ́ ohun àbéèrèfún tí ó pọn dandan fún ìgbàlà. Láti ti ojú ìwòye yìí lẹ́yìn, ó tẹ ìwé kan tí a ṣàtúntẹ̀ rẹ̀ nígbà mẹ́rin jáde, tí ó sì tún fara hàn nínú ìtẹ̀jáde méjì tí a tẹ̀ ní America. Gẹ́gẹ́ bí Geoffrey Cantor ti sọ, ìtẹ̀jáde ìdìpọ̀ yìí ni “ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí ó gbé [àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman] ga ju ìbẹ̀rẹ̀ tí ó ní gẹ́gẹ́ bí ìjọ ẹkùn ilẹ̀ Scotland lọ.”
Ní ọdún 1764, Sandeman, pẹ̀lú àwọn alàgbà míràn tí wọ́n jẹ́ elérò ìgbàgbọ́ Glass rìnrìn àjò lọ sí America, ìbẹ̀wò kan tí ó ru awuyewuye àti àtakò sókè. Síbẹ̀síbẹ̀, ó yọrí sí dídá àwùjọ àwọn Kristẹni ẹlẹ́mìí kan náà sílẹ̀ ní Danbury, Connecticut.a Ibẹ̀ ni Sandeman kú sí, ní ọdún 1771.
Èrò Ìgbàgbọ́ Faraday Ní Ti Ìsìn
Michael ọ̀dọ́ tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman tí àwọn òbí rẹ̀ fi kọ́ ọ. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé, àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tí kò tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ààtò ìgbéyàwó àwọn Áńgílíkà, ní gbígbà láti fi ààlà ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn mọ́ sí ohun tí òfin sọ pé ó pọn dandan.
Wíwà lábẹ́ àwọn ìjọba, síbẹ̀ kí wọ́n wà ní àìdásí tọ̀tún tòsì nínú ìṣèlú, jẹ́ ohun tí a fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman mọ̀ yàtọ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ àwọn mẹ́ḿbà tí a bọ̀wọ̀ fún láwùjọ, wọn kì í sábà tẹ́wọ́ gba ipò ìṣèlú. Ṣùgbọ́n nínú àwọn ọ̀ràn díẹ̀ tí wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n yẹra fún ìṣèlú ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Dídi ipò yìí mú kó ẹ̀gàn bá wọn. (Fi wé Jòhánù 17:14.) Àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman gbà pé Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run ni ìṣètò ìṣàkóso pípé. Cantor sọ pé wọ́n ka ìṣèlú sí “eré ẹ̀gbin lásán, tí kò ní ìwà rere nínú.”
Bí wọ́n tilẹ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, wọn kò ní ẹ̀mí ìrònú àwọn Farisí. Wọ́n polongo pé: “A rí i pé ó pọn dandan láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, láti yẹra fún Ẹ̀mí àti Àṣà àwọn Farisí ìgbàanì, nítorí náà a óò yẹra fun Ẹ̀ṣẹ̀ tàbí Ẹrù Iṣẹ́ tí ó ju ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè lọ; a óò sì yẹra fún fífi Òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ẹ̀dá ènìyàn tàbí Ìyẹ̀sílẹ̀ tí a gbé ka ọgbọ́n orí sọ Òfin àtọ̀runwa di asán.”
Wọ́n tẹ́wọ́ gba àṣà Ìwé Mímọ́, ti yíyọ èyíkéyìí nínú mẹ́ḿbà wọn tí ó bá di ọ̀mùtípara, alọ́nilọ́wọ́gbà, panṣágà, tàbí ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo mìíràn. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bá ronú pìwà dà ní tòótọ́, wọn yóò gbìyànjú láti mú un padà bọ̀ sípò. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́, láti “mú ènìyàn burúkú náà kúrò.”—Kọ́ríńtì Kìíní 5:5, 11, 13.
Àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì láti ta kété sí ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 15:29) John Glass ti jiyàn pé, ojúṣe àwọn ènìyàn Ọlọ́run ni láti ṣègbọràn sí ìkálọ́wọ́kò lórí ẹ̀jẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bi Ọlọ́run ti pàṣẹ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ láti ta kété kúrò nínú jíjẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Àìgbọràn sí àṣẹ náà nípa ẹ̀jẹ̀ rí bákan náà pẹ̀lú kíkọ̀ láti lo ẹ̀jẹ̀ Kristi lọ́nà tí ó tọ́, ní pàtàkì gẹ́gẹ́ bí ètùtù ẹ̀ṣẹ̀. Glass mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá sí ìparí ní sísọ pé: “Ìgbà gbogbo ni a ka jíjẹ ẹ̀jẹ̀ léèwọ̀, òun ni ohun tí ó tóbi jù lọ, tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ.”
Ìrònú àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman lórí Ìwé Mímọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀pọ̀ ọ̀fìn. Fún àpẹẹrẹ, nínú ọ̀ràn eré ìnàjú, wọ́n ń yíjú sí ìtọ́ni Kristi fún ìtọ́sọ́nà. Wọ́n wí pé: “A kò lórí láyà láti ṣe Òfin níbi tí Kristi kò ti ṣe é, tàbí kí a fọwọ́ rọ́ èyíkéyìí tí ó fún wa sẹ́yìn. Nítorí náà, níwọ̀n bí a kò ti lè rí ibì kan tí a ti ka Eré Ìnàjú, ní gbangba tàbí ní ìkọ̀kọ̀ léèwọ̀; a gbà pé Eré Ìnàjú èyíkéyìí, tí kò bá ti ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn Àyíká Ipò tí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ní ti gidi tọ́.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman tẹ́wọ́ gba ọ̀pọ̀ ojú ìwòye tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ lọ́nà pípéye, wọn kò lóye ìjẹ́pàtàkì ìgbòkègbodò náà gan-an tí a fi ń dá ìsìn Kristẹni tòótọ́ mọ̀, ní pàtàkì, pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fún àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 24:14) Síbẹ̀, ìpàdé wọn wà fún gbogbo ènìyàn, wọ́n sì sakun láti ṣàlàyé ìdí fún ìrètí wọn, fún ẹni gbogbo tí ó bá béèrè.—Pétérù Kìíní 3:15.
Báwo ni irú èrò ìgbàgbọ́ yìí ṣe nípa lórí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, Michael Faraday?
Faraday Ọmọlẹ́yìn Sandeman
Láìka ọlá, iyì, àti bí a ṣe gbé e gẹ̀gẹ̀ tó nítorí àwọn àwárí pípẹtẹrí tí ó ṣe sí, Michael Faraday gbé ìgbésí ayé rírọrùn. Nígbà tí àwọn olókìkí bá kú, tí a sì fẹ́ kí àwọn gbajúmọ̀ wá síbi ayẹyẹ ìsìnkú wọn, Faraday jẹ́ ẹni tí a mọ̀ bí ẹni mowó pé kò ní wá, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò fàyè gbà á láti lọ, kí ó sì kópa nínú ààtò ìsìn Ṣọ́ọ̀ṣì England.
Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, Faraday rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ohun tí ó lè fi hàn pé ó jẹ́ òkodoro òtítọ́. Ó tipa báyìí yẹra fún wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ń gbé àbá ìpìlẹ̀ tiwọn lárugẹ, tí wọ́n sì ń gbè sẹ́yìn ẹnì kan nígbà tí ó bá di ọ̀ràn àríyànjiyàn. Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún àwùjọ kan nígbà kan, ‘òkodoro òtítọ́ pọ́ńbélé kò já wa kulẹ̀ rí, ẹ̀rí rẹ̀ máa ń fìgbà gbogbo jẹ́ òtítọ́.’ Ó fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì hàn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó sinmi lé ‘àwọn òkodoro òtítọ́ tí a ṣàyẹ̀wò fínnífínní.’ Nígbà tí ó ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá sópin lórí àwọn olórí agbára tí ó ní ipa ìdarí lórí ẹ̀dá, Faraday fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ níṣìírí láti ronú nípa “Ẹni náà tí ó dá àwọn agbára wọ̀nyẹn.” Lẹ́yìn náà, ó ṣàyọlò Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Nítorí ohun rẹ̀ tí ó fara sin láti ìgbà dídá ayé a rí wọn gbangba, a ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n, àní agbára àti ìwà Ọlọ́run rẹ̀ ayérayé.”—Róòmù 1:20, King James Version.
Ohun tí ó mú kí Faraday yàtọ̀ gédégbé tó bẹ́ẹ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mìíràn ni, ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Ìwé tí Ọlọ́run mí sí, àti àwọn ìwé ìṣẹ̀dá mìíràn. Cantor sọ pé: “Nípa èrò ìgbàgbọ́ Sandeman tí ó ní, ó ṣàwárí ọ̀nà àtiṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run ní ti ìwà híhù àti láti rí ìlérí ìyè ayérayé gbà. Nípasẹ̀ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì rẹ̀, ó túbọ̀ di ojúlùmọ̀ àwọn òfin tí ó ṣeé fojú rí, tí Ọlọ́run ti yàn láti ṣàkóso àgbáyé.” Faraday gbà gbọ́ pé “ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè jin ọlá àṣẹ pátápátá tí Bíbélì ní lẹ́sẹ̀, ṣùgbọ́n bí a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ́nà tí ó bá ìlànà Kristẹni mú ní tòótọ́, ó lè tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn ìwé mìíràn tí Ọlọ́run ni.”
Faraday fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ kọ ọ̀pọ̀ ọlá tí àwọn mìíràn fẹ́ fi jíǹkí rẹ̀ sílẹ̀. Léraléra ni ó fi hàn pé òun kò ní ìfẹ́ ọkàn sí oyè. Ó gbà láti wà gẹ́gẹ́ bí ‘Ọ̀gbẹ́ni Faraday lásán.’ Ó yọ̀ọ̀da àkókò púpọ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alàgbà, títí kan rírìnrìn àjò déédéé láti olú ìlú sí abúlé Norfolk, láti bójú tó àwùjọ kékeré ti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹ́mìí kan náà tí ń gbé níbẹ̀.
Michael Faraday kú ní August 25, 1867, a sì sin ín sí itẹ́ Highgate ní àríwá London. Akọ̀tàn-ẹni, John Thomas, sọ fun wa pé Faraday “fi ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àṣeyọrí ògidì ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lélẹ̀ fún ìran ọjọ́ ọ̀la, ju bí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ohun tí a lè fojú rí mìíràn ti ṣe lọ, àwọn àbájáde gbígbéṣẹ́ tí àwọn àwárí rẹ̀ ní sì ti ní ipa ìdarí jíjinlẹ̀ lórí àbùdá ìgbésí ayé ọ̀làjú.” Opó Faraday, Sarah, kọ̀wé pé: “Májẹ̀mú Tuntun nìkan ni mo lè tọ́ka sí pé ó jẹ́ ìlànà àti òfin rẹ̀; nítorí ó kà á sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . tí ó de àwọn Kristẹni òde òní bákan náà gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a kọ ọ́”—ẹ̀rí tí ó ṣe kedere nípa ìlú-mọ̀ọ́ká onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ó fi tọkàntọkàn gbé ìgbésí ayé ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn tí ó kẹ́yìn nínú àwọn ọmọlẹ́yìn Sandeman, tàbí àwùjọ elérò ìgbàgbọ́ Glass ní United States kò sí mọ́ láti nǹkan bí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Nígbà tí a fi í ṣe olùkọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ Royal Institution ti Britain, Michael Faraday pòkìkí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ́nà kan tí àwọn ògowẹẹrẹ pàápàá lè lóye rẹ̀. Ìmọ̀ràn rẹ̀ sí àwọn olùkọ́ni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àwọn àbá gbígbéṣẹ́ nínú, tí ó dára kí àwọn Kristẹni òde òní tí ń kọ́ni ní gbangba gbé yẹ̀ wò.
◻ “A kò ní láti máa kánjú sọ̀rọ̀, tí yóò tipa bẹ́ẹ̀ yọrí sí ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání, ṣùgbọ́n kí a máa rọra sọ ọ́, kí a sì sọ ọ́ délẹ̀délẹ̀.”
◻ Olùbánisọ̀rọ̀ kan ní láti sakun láti ru ọkàn ìfẹ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ sókè “ní ìbẹ̀rẹ̀ àwíyé rẹ̀ àti nípasẹ̀ ọ̀wọ́ ìgbékalẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, tí àwùjọ náà kò fura sí, mú kí ọkàn ìfẹ́ wọn máa bá a lọ bí kókó ẹ̀kọ́ náà bá ti béèrè fún un tó.”
◻ “Ó bu olùkọ́ni kan kù gidigidi nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá falẹ̀ láti lè mú kí wọ́n pàtẹ́wọ́ fún òun, kí wọ́n sí gbóríyìn fún òun.”
◻ Nípa lílo àkọsílẹ̀: “Mo sábà máa ń rí i pé ó pọn dandan fún mi . . . láti kọ ìtòlẹ́sẹẹsẹ [kókó ọ̀rọ̀] tí mo fẹ́ sọ sórí bébà, kí n sì fi àwọn kókó yòókù kún un nípa rírántí wọn, yálà nípa fífi ọpọlọ so àwọn èrò náà pọ̀ tàbí lọ́nà míràn. . . . Mò ní ọ̀wọ́ àwọn lájorí àkòrí àti ìsọ̀ǹgbè àkòrí lẹ́sẹẹsẹ, inú àwọn wọ̀nyí ni mo sì ti máa ń fa kókó ẹ̀kọ́ mi yọ.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Fọ́tò méjèèjì: Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure ilé ẹ̀kọ́ Royal Institution