Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
‘Ilẹ̀kùn Ńlá Tí Ń Ṣamọ̀nà sí Ìgbòkègbodò Ti Ṣí Sílẹ̀’ ní Cuba
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù ta yọ nínú àwọn oníwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó lo gbogbo àǹfààní láti ṣàjọpín ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun tí Ẹlẹ́dàá náà ṣe fún aráyé onígbọràn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí ó ń ṣèbẹ̀wò sí Éfésù ìgbàanì, Pọ́ọ̀lù kíyè sí ọ̀wọ́ àwọn àyíká ipò tuntun mìíràn tí yóò jẹ́ kí ó lè ran àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Èmi yóò wà ní Éfésù . . . , nítorí ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ni a ti ṣí sílẹ̀ fún mi.”—Kọ́ríńtì Kìíní 16:8, 9.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Cuba pẹ̀lú rí ara wọn nínú ọ̀wọ́ àwọn àyíká ipò tuntun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tí ì forúkọ wọ́n sílẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn Ẹlẹ́rìí lè ṣàjọpín ìrètí Bíbélì wọn ní gbangba pẹ̀lú àwọn ará ìlú wọn nísinsìnyí. Láìpẹ́ yìí, ìjọba Cuba sọ ọkàn-ìfẹ́ wọn jíjinlẹ̀ jáde láti jẹ́ kí onírúurú àwùjọ ìsìn máa ṣe ìsìn wọn ní fàlàlà. Ní gbangba, Ààrẹ Castro mẹ́nu kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ìsìn kan tí ìjọba Cuba ń gbádùn àjọṣe sísunwọ̀n sí i pẹ̀lú rẹ̀ nísinsìnyí.
Ipò tuntun yìí ti ṣí “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” fún àwọn Ẹlẹ́rìí sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, láìpẹ́ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣí ọ́fíìsì kan ní Cuba, tí ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe kòkáárí iṣẹ́ ìwàásù wọn ní orílẹ̀-èdè yẹn. Èyí tí ó ju 65,000 àwọn Ẹlẹ́rìí ní ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì lóye rẹ̀. Wọ́n ń lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, irú bí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ọ̀pọ̀ ará Cuba tí wọ́n ní ìtẹ̀sí fún òdodo ń jàǹfààní láti inú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe àwọn ìpàdé déédéé ní àwọn àwùjọ kéékèèké jákèjádò erékùṣù náà. Nígbà míràn pàápàá, wọ́n máa ń gbádùn àǹfààní ṣíṣe àwọn àpéjọ ńlá ní àwọn àwùjọ tí ó ní nǹkan bí 150 ènìyàn. Ní tòótọ́, wọ́n mọrírì ìyọ̀ọ̀da tí wọ́n ti rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ Cuba, tí ó fún wọn ní àǹfààní pípéjọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí, ní kíkọrin ìyìn sí Ọlọ́run, àti gbígbàdúrà pa pọ̀.
Láìpẹ́ yìí, a ṣe Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun” fún èyí tí ó ju ìgbà 1,000 láàárín kìkì òpin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré. Ìròyìn kán sọ pé, “ìwàlétòlétò, ìwà ọmọlúwàbí, àti àlàáfíà” hàn kedere ní gbogbo àpéjọpọ̀. Àwọn aláṣẹ bá àwọn Ẹlẹ́rìí yọ̀ lórí kókó yìí.
Kárí ayé, àwọn ojúlówó Kristẹni ń sakun láti kúnjú àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́wọ́ kan náà, wọ́n ń sakun láti wà ní ipò ìbátan alálàáfíà pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ìjọba. (Títù 3:1) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó kọ̀wé pé: “Nítorí náà mo gbani níyànjú, ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, àdúrà, ìbẹ̀bẹ̀fúnni, ọrẹ ẹbọ ọpẹ́, nípa gbogbo onírúurú ènìyàn, nípa àwọn ọba àti gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ibi ipò gíga; kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọ́run kíkún àti ìwà àgbà.”—Tímótì Kìíní 2:1, 2.