ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 8/15 ojú ìwé 4-8
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Ilẹ̀ Ìlérí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Ilẹ̀ Ìlérí
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣẹ́fẹ́là
  • Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Olókè ti Júdà
  • Àwọn Agbègbè Aginjù
  • Àwọn Òke Kámélì
  • “Bí Ọgbà Olúwa”
  • “Ilẹ̀ Kan Tí Ó Dára Tí ó Sì Ní Àyè Gbígbòòrò”
    Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 8/15 ojú ìwé 4-8

Àwọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Ilẹ̀ Ìlérí

DÁJÚDÁJÚ Ilẹ̀ Ìlérí ti inú àkọsílẹ̀ Bíbélì jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. Ní agbègbè tí ó kéré ní ìfiwéra yìí, a rí ọ̀pọ̀ onírúurú ohun fífani mọ́ra tí ó jẹ́ ti ẹkùn ilẹ̀ náà. Ní àríwá, àwọn òkè tí òjò dídì bò wà níbẹ̀; ní gúúsù, àwọn ẹkùn ilẹ̀ olóoru wà níbẹ̀. Àwọn ilẹ̀ títẹ́jú tí ń méso jáde, àwọn agbègbè aginjù ahoro, àti àwọn ẹkùn ilẹ̀ olókè fún ọgbà igi eléso àti fún sísin ohun ọ̀sìn wà níbẹ̀.

Ìyàtọ̀ nínú bí ilẹ̀ ti ga sí, ipò ojú ọjọ́, àti erùpẹ̀ fàyè gba ọ̀pọ̀ onírúurú igi, àwọn igi kéékèèké, àti àwọn ewéko mìíràn—títí kan àwọn kan tí ń dàgbà dáradára ní àwọn ẹkùn ilẹ̀ olókè tí ó tutù, àwọn mìíràn tí ń dàgbà ní aṣálẹ̀ olóoru, àti àwọn mìíràn tí ń dàgbà dáradára ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ oníyanrìn tàbí lórí òkè olókùúta títẹ́jú. Onímọ̀ nípa irúgbìn kan díwọ̀n rẹ̀ pé a lè rí onírúurú ewéko bíi 2,600 ní agbègbè náà! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ilẹ̀ náà rí ẹ̀rí agbára tí ó ní. Ìdì èso àjàrà tí wọ́n gbé wá láti àfonífojì ọlọ́gbàrá kan tóbi débi pé géńdé méjì ní láti jùmọ̀ gbé e! Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, a sọ orúkọ àfonífojì náà ní Éṣíkólì, tí ó túmọ̀ sí “Ìdì [èso Àjàrà].”a—Númérì 13:21-24.

Ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àyẹ̀wò fínnífínní nípa díẹ̀ nínú àwọn ohun fífanimọ́ra tí ó jẹ mọ́ ti ẹkùn ilẹ̀ gígùn aláìlẹ́gbẹ́ yìí, ní pàtàkì nípa apá gúúsù.

Ṣẹ́fẹ́là

Èbúté ìwọ̀ oòrùn Ilẹ̀ Ìlérí ni ààlà rẹ̀ pẹ̀lú Òkun Mẹditaréníà. Ṣẹ́fẹ́là wà nínú lọ́hùn-ún ní nǹkan bí 40 kìlómítà. Ọ̀rọ̀ náà, “Ṣẹ́fẹ́là,” túmọ̀ sí “Ilẹ̀ Títẹ́jú,” ṣùgbọ́n ní tòótọ́, èyí jẹ́ agbègbè olókè, a sì lè sọ pé ó tẹ́jú kìkì nígbà tí a bá fi wéra pẹ̀lú àwọn òkè Júdà ní ìhà ìlà oòrùn.

Wo àwòrán ilẹ̀ tí ó wà níhìn-ín, kí o sì kíyè sí ipò tí Ṣẹ́fẹ́là wà sí àwọn agbègbè ìpínlẹ̀ tí ó yí i ká. Àwọn òkè Júdà wà ní ìhà ìlà oòrun; pẹ̀tẹ́lẹ̀ etíkun ti Filísíà sì wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Nípa báyìí, Ṣẹ́fẹ́là jẹ́ agbègbè ìsénàmọ́, ibi ìdènà kan tí ó pín àwọn ènìyàn Ọlọ́run níyà sí àwọn ọ̀tá wọn ìgbàanì, ní àwọn àkókò tí a ń kọ Bíbélì. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun èyíkéyìí tí yóò bá gbé sùnmọ̀mí wá láti ìwọ̀ oòrun ní láti gba Ṣẹ́fẹ́là kọjá kí ó tó lè kọlu Jerúsálẹ́mù, olú ìlú Ísírẹ́lì.

Irú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wáyé ní ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa. Bíbélì ròyìn pé, Ọba Hásáélì ti Síríà “gòkè lọ, ó sì bá Gátì jà, [tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ní ẹnubodè Ṣẹ́fẹ́là] ó sì kó o: Hásáélì sì dojú rẹ̀ kọ àtigòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù.” Ọba Jèhóáṣì dá Hásáélì dúró bákan ṣá, ní fífún un ní onírúurú ohun iyebíye láti inú tẹ́ḿpìlì àti láti inú ààfin gẹ́gẹ́ bí àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àkọsílẹ̀ yìí fi hàn kedere pé Ṣẹ́fẹ́là ṣe pàtàkì ní ti gidi fún ààbò Jerúsálẹ́mù.—Àwọn Ọba Kejì 12:17, 18.

A lè rí ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kọ́ láti inú èyí. Hásáélì fẹ́ láti ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n ó ní láti kọ́kọ́ gba Ṣẹ́fẹ́là kọjá. Bákan náà, Sátánì Èṣù “ń wá ọ̀nà láti pa” àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run “jẹ,” ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ la agbègbè ìsénàmọ́ lílágbára kan kọjá—rírọ̀ tí wọ́n rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì, irú bí àwọn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ búburú àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì. (Pétérù Kìíní 5:8; Kọ́ríńtì Kìíní 15:33; Tímótì Kìíní 6:10) Fífi àwọn ìlànà Bíbélì báni dọ́rẹ̀ẹ́ ni ó sábà máa ń jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ síhà dídá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo. Nítorí náà, dáàbò bo agbègbè ìsénàmọ́ náà. Tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì lónìí, ìwọ kì yóò sì rú àwọn òfin Ọlọ́run lọ́la.

Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Olókè ti Júdà

Ẹkùn Ìpínlẹ̀ olókè ti Júdà wà nínú lọ́hùn-ún níbi tí ó jìnnà sí Ṣẹ́fẹ́là. Èyí jẹ́ agbègbè olókè ńlá tí ń pèsè ọkà, òróró ólífì, àti wáìnì dáradára. Nítorí gíga tí ó ga sókè, Júdà tún jẹ́ ibi ìsádi títayọ lọ́lá. Nípa báyìí, Ọba Jótámù kọ́ “ilé odi àti ilé ìṣọ́” síbẹ̀. Ní àwọn àkókò wàhálà, àwọn ènìyàn lè sá lọ síbẹ̀ fún ààbò.—Kíróníkà Kejì 27:4.

Jerúsálẹ́mù, tí a tún ń pè ní Síónì, jẹ́ apá pàtàkì lára ẹkùn ìpínlẹ̀ olókè ti Júdà. Jerúsálẹ́mù dà bí ẹni pé ó láàbò níwọ̀n bí àfonífojì jìngòdò ti yí i ká ní ìhà mẹ́ta, bí òpìtàn ọ̀rúndún kìíní nì Josephus ti sọ, ògiri onípele mẹ́ta ni ó dáàbò bo ìhà àríwá. Ṣùgbọ́n láti mú ààbò rẹ̀ dájú, ibi ìsádi kan nílò ju àwọn ògiri àti ohun ìjà lọ. Ó tún gbọ́dọ̀ ní omi. Èyí ṣe pàtàkì nígbà ìgbóguntì, nítorí pé láìsí omi, a óò tètè fipá mú àwọn ọlọ̀tọ̀ ìlú tí a há mọ́ láti juwọ́ sílẹ̀.

Jerúsálẹ́mù ń rí ìpèsè omi láti inú Adágún Sílóámù. Ṣùgbọ́n, ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, ní ìfojúsọ́nà fún ìgbóguntì láti ọwọ́ àwọn ará Ásíríà, Ọba Hesekáyà mọ ògiri kan sẹ́yìn Adágún Sílóámù láti dáàbò bò ó, ní mímú kí ó wà láàárín ìlú ńlá náà. Ó tún dá àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú tí ó wà lẹ́yìn ìlú ńlá náà dúró, nítorí kí ó ba lè ṣòro fún àwọn ará Ásíríà tí ń gbógun láti rí omi fún ara wọn. (Kíróníkà Kejì 32:2-5; Aísáyà 22:11) Kò tán síbẹ̀ o. Hesekáyà wá ọ̀nà láti darí àfikún ìpèsè omi ní tààràtà wá sí Jerúsálẹ́mù!

Nínú ohun tí a pè ní àṣeyọrí gíga ní ti ìmọ̀ ẹ̀rọ ní ìgbà ìṣẹ̀m̀báyé, Hesekáyà gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kan láti ibi ìṣẹ́lẹ̀rú Gíhónì títí dé ibi Adágún Sílóámù.b Ní gíga to mítà 1.8 ní ìpíndọ́gba, gígùn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ yìí sì jẹ́ mítà 533. Rò ó wò ná—kí á gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí ó gùn tó nǹkan bí ìdajì kìlómítà nínú àpáta! Lónìí, lẹ́yìn nǹkan bíi 2,700 ọdún, àwọn olùṣèbẹ̀wò sí Jerúsálẹ́mù lè rá pálá gba inú àgbà iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí kọjá, tí a mọ̀ lọ́nà tí ó wọ́pọ̀ sí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ti Hesekáyà.—Àwọn Ọba Kejì 20:20; Kíróníkà Kejì 32:30.

Ìsapá Hesekáyà láti dáàbò bo ìpèsè omi Jerúsálẹ́mù, kí ó sì mú un pọ̀ sí i lè kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n. Jèhófà ni “ìsun omi ìyè.” (Jeremáyà 2:13) Ìrònú rẹ̀, tí ó wà nínú Bíbélì, ń gbé ìwàláàyè ró. Ìdí nìyẹn tí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ṣe pàtàkì. Ṣùgbọ́n àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́, àti ìmọ̀ tí ń ti ibẹ̀ wá, kì yóò ṣàdéédéé wá bá ọ. O lè ní láti ‘gbẹ́ àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀,’ irú bíi gbígbẹ́ ẹ gba inú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ rẹ ojoojúmọ́ tí ó kún fọ́fọ́ kọjá, láti pèsè àyè fún un. (Òwe 2:1-5; Éfésù 5:15, 16) Gbàrà tí o bá ti bẹ̀rẹ̀, rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí o ṣe, ní fífún ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ ní ipò tí ó gba iwájú gan-an. Ṣọ́ra láti má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun já ìpèsè omi ṣíṣeyebíye yìí gbà mọ́ ọ lọ́wọ́.—Fílípì 1:9, 10.

Àwọn Agbègbè Aginjù

Aginjù Júdà, tí a tún ń pè ní Jéṣímónì, tí ó túmọ̀ sí “Aṣálẹ̀,” wà ní ìhà ìlà oòrùn àwọn òke Júdà. (Sámúẹ́lì Kìíní 23:19, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Ní Òkun Iyọ̀, ẹkùn ilẹ̀ aláìmésojáde yìí ní àwọn ọ̀nà tóóró olókùúta àti àwọn bèbè òkúta gbágungbàgun. Aginjù Júdà tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ ní nǹkan bíi 1,200 mítà ní kìkì kìlómítà 24, bọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ tí ń mú òjò wá láti ìwọ̀ oòrùn, àti nípa báyìí kìkì ìwọ̀nba òjò díẹ̀ ni ó ń rọ̀ sí ibẹ̀. Kò sí iyè méjì pé èyí ni aginjù tí a ń rán ewúrẹ́ Ásásélì lọ ní Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún. Ó tún jẹ́ ibi tí Dáfídì sá lọ kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù. Níhìn-ín, Jésù gbààwẹ̀ fún 40 ọjọ́, Èṣù sì dán an wò lẹ́yìn náà.—Léfítíkù 16:21, 22; Orin Dáfídì 63, àkọlé orí ìwé; Mátíù 4:1-11.

Aginjù Páránì wà ní nǹkan bí 160 kìlómítà ní ìhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn Aginjù Júdà. Ọ̀pọ̀ ibi tí Ísírẹ́lì fi ṣe ibùdó nígbà ìrìn àjò 40 ọdún wọn láti Íjíbítì títí dé Ilẹ̀ Ìlérí jẹ́ ní ibí yìí. (Númérì 33:1-49) Mósè kọ̀wé nípa “aginjù ńlá tí ó sì ní ẹ̀rù, níbi tí ejò amúbíiná wà, àti àkekèé, àti ọ̀dá, níbi tí omi kò sí.” (Diutarónómì 8:15) Ó jẹ́ kàyéfì pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè là á já! Síbẹ̀, Jèhófà mú wọn dúró.

Ǹjẹ́ kí èyí jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí pé Jèhófà lè mú àwa pẹ̀lú dúró, àní nínú ayé aláìmésojáde nípa tẹ̀mí yìí. Bẹ́ẹ̀ ni, àwa pẹ̀lú ń rìn kiri láàárín àwọn ejò àti àkekèé, àní bí wọn kò tilẹ̀ jẹ́ ejò àti àkekèé ní ti gidi. Ó lè pọn dandan pé kí a máa ní ìbáṣepọ̀ ojoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí kò fì wọ́n lẹ́nu láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ olóró tí ó lè fi ìrọ̀rùn kó bá ìrònú wa. (Éfésù 5:3, 4; Tímótì Kìíní 6:20) Ó yẹ kí a gbóríyìn fún àwọn tí ń là kàkà láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run láìka àwọn ohun ìdíwọ́ wọ̀nyí sí. Ìwà títọ́ wọ́n jẹ́ ẹ̀rí lílágbára pé Jèhófà ń mú wọn dúró ní tòótọ́.

Àwọn Òke Kámélì

Orúkọ náà, Kámélì túmọ̀ sí “Ọgbà Igi Eléso.” A fi ọgbà àjàrà, igi ólífì, àti igi eléso ṣe ẹkùn ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó wà ní àríwá yìí, nǹkan bí 50 kìlómítà lóòró, lọ́ṣọ̀ọ́. Mánigbàgbé ni ògo àti ẹwà ṣóńṣó ọ̀wọ́ ilẹ̀ olókè yìí jẹ́. Aísáyà 35:2 sọ̀rọ̀ nípa “ẹwà Kámélì” gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣàpẹẹrẹ ògo ìmésojáde ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí a mú padà bọ̀ sípò.

Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń gba àfiyèsí ṣẹlẹ̀ ní Kámélì. Níhìn-ín ni Èlíjà ti pe àwọn wòlíì Báálì níjà, tí ‘iná Olúwa sì bọ́ sílẹ̀’ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ipò Rẹ̀ gíga lọ́lá jù lọ. Pẹ̀lúpẹ̀lù, láti orí Kámélì ni Èlíjà ti pe àfiyèsí sí àwọ sánmà kékeré tí ó wá di òjò ńlá, ní títipa báyìí fi òpin sí ọ̀dá tí ó dá Ísírẹ́lì, lọ́nà ìyanu. (Àwọn Ọba Kìíní 18:17-46) Èlíṣà, agbapò Èlíjà, wà lórí Òke Kámélì nígbà tí obìnrin kan tí ó jẹ́ ará Ṣúnémù ń wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ nítorí ọmọ rẹ̀ tí ó kú, ẹni tí Èlíṣà jí dìde lẹ́yìn náà.—Àwọn Ọba Kejì 4:8, 20, 25-37.

Àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Kámélì ṣì ní ọgbà igi eléso, igi ólífì, àti àjàrà síbẹ̀. Nígbà ìrúwé, àwọn òdòdó títẹ́ rẹrẹ lọ́nà gíga lọ́lá máa ń bo àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wọ̀nyí. Sólómọ́nì sọ fún omidan Ṣúlámáítì pé: “Orí rẹ dà bíi Kámélì lára rẹ,” bóyá tí ó ń dọ́gbọ́n tọ́ka sí bí irun rẹ̀ ti jà yọ̀yọ̀ tó tàbí sí bí orí rẹ̀ tí ó gún régé ti ṣe rèǹtèrente lórí ọrùn rẹ̀.—Orin Sólómọ́nì 7:6.

Ògo ẹwà tí a fi ń dá àwọn òke Kámélì mọ̀, ń rán wa létí ẹwà tẹ̀mí tí Jèhófà ti fi jíǹkí ètò àjọ àwọn olùjọsìn rẹ̀ lónìí. (Aísáyà 35:1, 2) Ní tòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé nínú párádísè tẹ̀mí kan, wọ́n sì gbà pẹ̀lú ojú ìwòye Ọba Dáfídì, tí ó kọ̀wé pé: “Okùn títa bọ́ sọ́dọ̀ mi ní ibi dáradára; lóòótọ́, èmí ní ogún rere.”—Orin Dáfídì 16:6.

Ní tòótọ́, àwọn ìpèníjà tí ó ṣòro wà tí orílẹ̀-èdè Ọlọ́run nípa tẹ̀mí gbọ́dọ̀ kojú lónìí, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì tí dojú kọ àtakò tí kò dáwọ́ dúró láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò jẹ́ gbàgbé àwọn ìbùkún tí Jèhófà ti pèsè—títí kan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Bíbélì tí ń mọ́lẹ̀ sí i ṣáá, ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé, àti àǹfààní láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan.—Òwe 4:18; Jòhánù 3:16; 13:35.

“Bí Ọgbà Olúwa”

Ilẹ̀ Ìlérí ìgbàanì jojú ní gbèsè. A ṣàpèjúwe rẹ̀ dáradára pé ó “ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:10; Ẹ́kísódù 3:8) Mósè pè é ní “ilẹ̀ rere, ilẹ̀ odò omi, ti orísun àti ti abẹ́ ilẹ̀, tí ń ru sókè láti àfonífojì àti òkè jáde wá; Ilẹ̀ àlìkámà àti ọkà bálì, àti àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi pómégíránétì; ilẹ̀ òróró ólífì, àti oyin; ilẹ̀ nínú èyí tí ìwọ kì yóò fi ìṣẹ́ jẹ oúnjẹ, ìwọ kì yóò fẹ́ ohun kan kù nínú rẹ̀; ilẹ̀ tí òkúta rẹ̀ í ṣe irin, àti láti inú òkè èyí tí ìwọ óò máa wa idẹ.”—Diutarónómì 8:7-9.

Bí Jèhófà bá lè pèsè irú ilẹ̀ ìbílẹ̀ ẹlẹ́wà, tí ó kún fún onírúurú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ìgbàanì, dájúdájú òún lè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ ti òde òní ní párádísè ológo kan, tí yóò kárí ayé—pẹ̀lú àwọn òkè, àfonífojì, odò, àti adágún omi. Bẹ́ẹ̀ ni, Ilẹ̀ Ìlérí ìgbàanì pẹ̀lú onírúurú nǹkan tí ó ní wulẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò párádísè tẹ̀mí kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń gbádùn lónìí àti ìtọ́wò Párádísè ọjọ́ ọ̀la ti ayé tuntun. Ibẹ̀ ni ìlérí tí a kọ sílẹ̀ nínú Orin Dáfídì 37:29 yóò ti ní ìmúṣẹ pé: “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì má gbé inú rẹ̀ láéláé.” Nígbà tí Jèhófà bá fún aráyé onígbọràn ní ilé Párádísè yẹn, ẹ wo bí wọn yóò ti láyọ̀ tó láti ṣàyẹ̀wò gbogbo “yàrá” rẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí láéláé!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ṣàkọsílẹ̀ pé, ìdì èso àjàrà kan láti ẹkùn ilẹ̀ yìí wọn kìlógírámù 12, òmíràn sì wọ̀n ju 20 kìlógírámù.

b Ìṣẹ́lẹ̀rú Gíhónì wà ní kété lẹ́yìn òde ààlà Jerúsálẹ́mù ní ìhà ìlà oòrùn. Ó fara sin nínú ihò kan; nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn ará Ásíríà má mọ̀ pé ó wà níbẹ̀.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 4]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

GÁLÍLÌ

Òkè Kámélì

Òkun Gálílì

SAMÁRÍÀ

SHEPHELAH

Àwọn Òkè Júdà

Òkun Iyọ̀

[Credit Line]

Fọ́tò NASA

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 4]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ṣẹ́fẹ́là jẹ́ ibi ìdènà kan láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run àti àwọn ọ̀tá wọn

MI 0 5 10

KM 0 8 16

Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Filísíà

Ṣẹ́fẹ́là

Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Olókè Ti Júdà

Aginjù Júdà

Àfonífojì Olókìtì

Òkun Iyọ̀

Ilẹ̀ Ámónì àti Móábù

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ti Hesekáyà: 533 mítà ní gígùn, tí a gbẹ́ gba inú àpáta líle koránkorán kọjá

Àfonífojì Tírópóónì

Sílóámù

ÌLÚ ŃLÁ TI DÁFÍDÌ

Àfonífojì Kídírónì

Gíhónì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ní Aginjù Júdà, Dáfídì wá ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù. Lẹ́yìn náà, Èṣù dán Jésù wò níhìn-ín

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Òkè Kámélì, níbi tí Èlíjà ti tẹ́ àwọn wòlíì Báálì

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

“OLÚWA Ọlọ́run rẹ mú ọ wá sínú ilẹ̀ rere, ilẹ̀ odò omi, ti orísun àti ti abẹ́ ilẹ̀, tí ń ru sókè láti àfonífojì àti òkè jáde wá.”—Diutarónómì 8:7

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́