Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Pétérù Wàásù ní Pẹ́ńtíkọ́sì
ÓJẸ́ òwúrọ̀ kan ní ìgbà ìrúwé fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ìdùnnú gba agbègbè náà kan! Agbo àwọn Júù àti aláwọ̀ṣe tí ń yọ̀ ṣìnkìn tú yẹ́ẹ́yẹ́ẹ́ sí àwọn òpópónà Jerúsálẹ́mù. Wọ́n wá láti ibi bíi Élámù, Mesopotámíà, Kapadókíà, Íjíbítì, àti Róòmù. Ẹ wo bí ó ti fani lọ́kàn mọ́ra tó láti rí wọn nínú aṣọ ìbílẹ̀ wọn, àti láti gbọ́ onírúurú èdè wọn! Àwọn kan ti rìnrìn àjò tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì kìlómítà láti wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí. Kí ni nǹkan náà? Pẹ́ńtíkọ́sì ni—àjọyọ̀ onídùnnú ti àwọn Júù, tí ń sàmì sí òpin ìkórè ọkà bálì.—Léfítíkù 23:15-21.
Èéfín ń rú tùù láti inú ìrúbọ lórí pẹpẹ tẹ́ḿpìlì, àwọn ọmọ Léfì sì ń kọ orin Hálélì (Orin Dáfídì 113 sí 118). Kété ṣáájú agogo 9:00 òwúrọ̀, ohun kan tí ó múni ta gìrì ṣẹlẹ̀. Láti ọ̀run wá, ‘ariwo kan gan-an gẹ́gẹ́ bí ti atẹ́gùn alágbára líle tí ń rọ́ yìì’ dún. Ó kún gbogbo ilé náà níbi tí nǹkan bíi 120 ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi kóra jọ pọ̀ sí. Ìròyìn Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Àwọn ahọ́n bí ti iná sì di rírí fún wọn a sì há wọn káàkiri, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ti ń yọ̀ǹda fún wọn lati sọ̀rọ̀ jáde.”—Ìṣe 2:1-4.
Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Gbọ́ Èdè Tirẹ̀
Káwí káfọ̀, ọ̀pọ̀ ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í tú jáde láti inú ilé. Lọ́nà yíyani lẹ́nu, wọ́n lè sọ̀rọ̀ ní onírúurú èdè ogunlọ́gọ̀ náà! Finú wòye bí yóò ti jẹ́ ìyàlẹ́nu tó, nígbà tí àlejò kan láti Páṣíà àti ará Íjíbítì gbọ́ tí àwọn ará Gálílì ń sọ èdè wọn. Lọ́nà tí ó lè yéni, àwùjọ náà kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀. Wọ́n béèrè pé: “Kí ni ìtumọ̀ tí ohun yìí gbé yọ?” Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣẹlẹ́yà, ní sísọ pé: “Wọ́n ti mu ọtí wáìnì dídùn yó.”—Ìṣe 2:12, 13.
Lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pétérù dìde dúró, ó sì bá àwùjọ náà sọ̀rọ̀. Ó ṣàlàyé pé ẹ̀bùn ahọ́n lọ́nà àgbàyanu yìí jẹ́ ìmúṣẹ ìlérí náà tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ wòlíì Jóẹ́lì pé: “Èmi yóò . . . tú lára ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo onírúurú ẹran ara.” (Ìṣe 2:14-21; Jóẹ́lì 2:28-32) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dà sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni. Èyí jẹ́ ẹ̀rí tí ó ṣe kedere pé a ti jí Jésù dìde kúrò nínú òkú, ó sì ti wà ní ọ̀rún nísinsìnyí lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Pétérù sọ pé: “Nítorí náà kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú láìsí tàbí ṣùgbọ́n pé Ọlọ́run fi í ṣe Olúwa àti Kristi, Jésù yìí tí ẹ̀yin kàn mọ́gi.”—Ìṣe 2:22-36.
Báwo ni àwọn olùgbọ́ ṣe hùwà padà? Ìròyìn náà sọ pé: “Ó gún wọn dé ọkàn-àyà, wọ́n sì wí fún Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòó kù pé: ‘Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, kí ni kí àwa ṣe?’” Pétérù fèsì pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín.” Nǹkan bíi 3,000 ni ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́! Lẹ́yìn náà, “wọ́n . . . ń bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.”—Ìṣe 2:37-42.
Nípa mímú ipò iwájú ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ títayọ lọ́lá yìí, Pétérù lo ìkíní lára “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba àwọn ọ̀run” tí Jésù ti ṣèlérí láti fi fún un. (Mátíù 16:19) Kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyí ṣí àkànṣe àǹfààní sílẹ̀ fún onírúurú àwùjọ ènìyàn. Kọ́kọ́rọ́ kìíní yìí mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn Júù láti di Kristẹni tí a fẹ̀mí yàn. Lẹ́yìn ìyẹn, kọ́kọ́rọ́ kejì àti ìkẹta mú kí àǹfààní yìí kan náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn ará Samáríà àti àwọn Kèfèrí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé.—Ìṣe 8:14-17; 10:44-48.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwùjọ àwọn Júù àti aláwọ̀ṣe yìí jẹ̀bi àjùmọ̀pín fún ikú Ọmọkùnrin Ọlọ́run, Pétérù bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ní pípè wọ́n ní “ẹ̀yin ará.” (Ìṣe 2:29) Góńgó rẹ̀ jẹ́ láti sún wọn sí ìrònúpìwàdà, kì í ṣe láti dá wọn lẹ́bi. Nítorí náà, ọ̀nà ìyọsíni rẹ̀ dára. Ó gbé òkodoro òtítọ́ kalẹ̀, ó sì fi àwọn àyọkà Ìwé Mímọ́ ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn.
Yóò dára kí àwọn tí ń wàásù ìhìn rere lónìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pétérù. Kí wọ́n gbìyànjú láti bá àwọn olùgbọ́ wọn fikùn lukùn, kí wọ́n sì fi ọgbọ́n ronú pa pọ̀ pẹ̀lú wọn láti inú Ìwé Mímọ́. Nígbà tí a bá gbé òtítọ́ Bíbélì kalẹ̀ lọ́nà rere, àwọn ọlọ́kàn títọ́ yóò dáhùn padà.—Ìṣe 13:48.
Ìtara Pétérù àti ìgboyà rẹ̀ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì fara hàn gedegbe yàtọ̀ sí sísẹ́ tí ó sẹ́ Jésù ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méje ṣáájú. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ìbẹ̀rù ènìyàn sọ Pétérù dojo. (Mátíù 26:69-75) Ṣùgbọ́n Jésù ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí Pétérù. (Lúùkù 22:31, 32) Dájúdájú, fífara hàn tí Jésù fara han Pétérù lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ fún àpọ́sítélì náà lókun. (Kọ́ríńtì Kìíní 15:5) Nítorí èyí, ìgbàgbọ́ Pétérù kò ṣákìí. Láàárín àkókò kúkúrú, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láìṣojo. Lẹ́yìn ìgbà náà, kì í ṣe ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì nìkan ni ó wàásù, ṣùgbọ́n fún gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ yòó kù.
Ká sọ pé a ti ṣàṣìṣe bákan ṣáá ńkọ́, àní bí Pétérù ti ṣe? Ẹ jẹ́ kí a fi ìrònúpìwàdà hàn, kí a gbàdúrà fún ìdáríjì, kí a sì gbégbèésẹ̀ láti wá ìrànwọ́ tẹ̀mí. (Jákọ́bù 5:14-16) Nígbà náà, a lè tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé Bàbá wa ọ̀run aláàánú, Jèhófà, tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wa.—Ẹ́kísódù 34:6.