Aájò Àlejò Kristẹni Nínú Ayé Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
“Nítorí náà, a wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti gba irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, kí a lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.”—JÒHÁNÙ KẸTA 8.
1. Àwọn ẹ̀bùn fífani lọ́kàn mọ́ra jù lọ wo ni Ẹlẹ́dàá fi fún aráyé?
“ÈNÌYÀN kò ní ohun rere lábẹ́ oòrùn ju jíjẹ àti mímu, àti ṣíṣe àríyá: nítorí èyíinì ni yóò bá a dúró nínú làálàá rẹ̀ ní ọjọ́ ayé rẹ̀, tí Ọlọ́run fi fún un lábẹ́ oòrùn.” (Oníwàásù 8:15) Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, akónijọ, ará Hébérù ìgbàanì, sọ fún wa pé kì í ṣe kìkì pé Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn, ìṣẹ̀dá rẹ̀, jẹ́ onídùnnú àti aláyọ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún pèsè ọ̀nà tí wọn yóò fi lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún wọn. Jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, ó dà bíi pé ìfẹ́ ọkàn kan tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn ní ibi gbogbo jẹ́ láti gbádùn ara wọn, kí wọ́n sì ṣe fàájì.
2. (a) Báwo ni aráyé ṣe ṣi ohun tí Jèhófà pète fún wọn lò? (b) Kí ni àbájáde rẹ̀?
2 Lónìí, a ń gbé nínú àwùjọ onígbèésí ayé aláfẹ́, nínú èyí tí ọwọ́ àwọn ènìyàn ti dí púpọ̀ fún ìlépa adùn àti fàájì. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ti di “olùfẹ́ ara wọn, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run,” gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀. (Tímótì Kejì 3:1-4) Dájúdájú, èyí jẹ́ lílọ́ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run pète po, lọ́nà tí ó burú lékenkà. Nígbà tí ìlépa fàájì bá di lájorí góńgó ìlépa, tàbí nígbà ti títẹ́ ara ẹni lọ́rùn bá di kìkì ohun kan ṣoṣo tí a ń lépa, kì yóò sí ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́, ‘gbogbo rẹ̀ yóò sì jẹ́ asán àti ìmúlẹ̀mófo.’ (Oníwàásù 1:14; 2:11) Nítorí èyí, ayé kún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n dánìkan wà, tí ọ̀rọ̀ sì tojú sú, èyí tí ó sì yọrí sí ọ̀pọ̀ ìṣòro tí ó wà nínú àwùjọ. (Òwe 18:1) Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí ara wọn, wọ́n sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ní ti ẹ̀yà ìran, ní ti ẹ̀yà ìbílẹ̀, ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àti ní ti ọrọ̀ ajé.
3. Báwo ni a ṣe lè rí ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́?
3 Ẹ wo bí nǹkan ì bá ti yàtọ̀ tó ká ní àwọn ènìyàn fara wé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá àwọn ẹlòmíràn lò—ní jíjẹ́ onínúure, ọlọ́làwọ́, àti aláájò àlejò! Ó mú un ṣe kedere pé àṣírí ayọ̀ tòótọ́ kì í ṣe gbígbìyànjú tí a bá gbìyànjú láti tẹ́ àwọn ìfẹ́ ọkàn wa lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, kọ́kọ́rọ́ náà nìyí pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírí gbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Láti rí ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́, a gbọ́dọ̀ ṣẹ́pá àwọn ìdènà àti ìpínyà tí ó lè dí wa lọ́wọ́. A sì gbọ́dọ̀ fà mọ́ àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà. Ó ṣe pàtàkì pé kí a kọbi ara sí ìmọ̀ràn náà pé: “Nítorí náà, a wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti gba irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, kí a lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.” (Jòhánù Kẹta 8) Fífi aájò àlejò hàn sí àwọn tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí i, títí dé ibi tí àyíká ipò wa bá fàyè gbà, ṣàǹfààní lọ́nà méjì—ó ṣàǹfààní fún olùfúnni àti ẹni tí ń gbà á. Nígbà náà, àwọn wo ni ó wà lára àwọn tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí i, tí a ní láti ‘gbà pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò’?
“Bójú Tó Àwọn Ọmọ Òrukàn àti Àwọn Opó”
4. Kí ni ìyípadà nínú ipò ìbátan ìdílé tí a rí àní láàárín àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ènìyàn Jèhófà?
4 Ìdílé dídúró gbọn-in-gbọn-in àti ìgbéyàwó aláyọ̀ ṣọ̀wọ́n lónìí. Iye ìkọ̀sílẹ̀ tí ń lọ sókè àti iye àwọn ìyálọ́mọ tí kò ṣègbéyàwó tí ń pọ̀ sí i kárí ayé ti yí ìdílé tí ó wà ní ìpìlẹ̀ padà lọ́nà yíyára kánkán. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ tí ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ wá láti inú àwọn ìdílé tí ó ti tú ká. Yálà kí alábàáṣègbéyàwó wọn ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ tàbí kí wọ́n ti pínyà, tàbí kí wọ́n máa gbé gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdílé olóbìí kan. Ní àfikún sí i, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀, òtítọ́ tí ó kọ́ni ti yọrí sí ìpínyà nínú ọ̀pọ̀ ìdílé.—Mátíù 10:34-37; Lúùkù 12:51-53.
5. Kí ni Jésù sọ tí ó lè jẹ́ orísun ìṣírí fún àwọn tí ń bẹ nínú àwọn ìdílé tí ó pínyà?
5 Ó mú ọkàn wa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ láti rí àwọn ẹni tuntun tí ń mú ìdúró gbọin-in-gbọn-in fún òtítọ́, a sì sábà máa ń tù wọ́n nínú pẹ̀lú ìlérí Jésù, tí ń fúnni níṣìírí pé: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Kò sí ẹnì kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí bàbá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí, àwọn ilé àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni, àti nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”—Máàkù 10:29, 30.
6. Báwo ní a ṣe lè di ‘arákùnrin, arábìnrin, ìyá, àti ọmọ’ fún “àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó” tí ń bẹ láàárín wa?
6 Ṣùgbọ́n, ta ni ‘àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, àwọn ìyá àti àwọn ọmọ’ wọ̀nyí? Wíwulẹ̀ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí wọ́n sábà máa ń tó ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n ń pé ara wọn ní arákùnrin àti arábìnrin kì í ṣàdédé mú kí ẹnì kan nímọ̀lára pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, àwọn ìyá, àti àwọn ọmọ òun. Gbé kókó yìí yẹ̀ wò: Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù, rán wa létí pé, kí Jèhófà baà lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ ‘máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, kí a sì pa ara wa mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.’ (Jákọ́bù 1:27) Ìyẹn túmọ̀ sí pé a kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí ìrònú ayé ti ṣíṣe fọ́n-ń-té nítorí tí nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fún wa àti ẹ̀mí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́, mú kí a ti ilẹ̀kùn ìyọ́nú wa mọ́ irú “àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó” bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ lo ìdánúṣe láti nawọ́ àjọṣepọ̀ àti aájò àlejò wa sí wọn.
7. (a) Kí ni olórí ète tí a ṣe ń fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí “àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó”? (b) Ta ni ó tún lè lọ́wọ́ nínú fífi aájò àlejò Kristẹni hàn?
7 Fífi aájò àlejò hàn sí “àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó” kì í fi gbogbo ìgbà kan pípèsè ohun tí wọ́n ṣe aláìní nípa ti ara. Àwọn ìdílé olóbìí kan tàbí agboolé tí ó pínyà ní ti ìsìn lè máà ní ìṣòro ìṣúnná owó. Ṣùgbọ́n, ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé, ipò àyíká ìdílé, àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ onírúurú ọjọ́ orí, àti ṣíṣàjọpín àwọn ohun rere tẹ̀mí pa pọ̀—ìwọ̀nyí ni apá ìgbésí ayé tí ó ṣeyebíye. Nípa báyìí, ní rírántí pé kì í ṣe bí àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe fa kíki tó ni ohun tí ó ṣe pàtàkì, bí kò ṣe ẹ̀mí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tí a fi hàn, ẹ wo bí ó ti dára tó pé, nígbà míràn, àní “àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó” pàápàá lè lọ́wọ́ nínú fífi aájò àlejò hàn sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn!—Fi wé Àwọn Ọba Kìíní 17:8-16.
Àwọn Àjèjì Ha Wà Láàárín Wa Bí?
8. Kí ni ìyípadà tí a rí nínú ọ̀pọ̀ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
8 A ń gbé ní àkókò kan nígbà tí ọ̀pọ̀ ń ṣí kiri. Ìwé ìròyìn World Press Review, sọ pé: “Èyí tí ó jú 100 mílíọ̀nù ènìyàn kárí ayé ní ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe tiwọn, a sì lé mílíọ̀nù 23 kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè wọn.” Ìyọrísí tààràtà tí èyí ní ni pé, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè, ní pàtàkì, ní àwọn ìlú ńlá, àwọn ìjọ àwọn ènìyàn Jèhófà tí wọ́n ti fi ìgbà kan rí kún fún àwọn ẹ̀yà ìran tí púpọ̀ wọ́n jẹ́ ọ̀kan náà tàbí láti orílẹ̀-èdè kan náà, wá ń kún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ayé. Èyí lè jẹ́ òtítọ́ níbi tí o wà. Ṣùgbọ́n, ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo àwọn “àtìpó” àti “àjèjì” wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí ayé ti lè pè wọ́n, tí èdè wọn, àṣà wọn, àti ọ̀nà ìgbésí ayé wọn lè yàtọ̀ sí tiwa?
9. Ọ̀fìn wo ni ojú ìwòye wa nípa “àwọn àtìpó” àti “àwọn àjèjì” tí ń wá sínú ìjọ Kristẹni lè mú kí a jìn sí?
9 Ní ṣókí, a kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìtẹ̀sí má-fojú-kàlejò mú kí a ronú pé lọ́nà kan ṣáá, a lẹ́tọ̀ọ́ sí àǹfààní mímọ òtítọ́ ju àwọn tí ó wá láti ilẹ̀ àjèjì, tàbí ibi tí a ń pè ní ilẹ̀ kèfèrí; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì gbọdọ̀ ronú pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé wọ̀nyí ń tẹ ẹ̀tọ́ wa ti lílo Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí àwọn ohun èlò míràn lójú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí i pé ó pọn dandan láti rán àwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ Júù ní ọ̀rúndún kìíní, tí wọ́n ní irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀ létí pé, ní ti gàsíkíá, kò sí ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí i; inúure àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ni ó mú kí ó ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti jèrè ìgbàlà. (Róòmù 3:9-12, 23, 24) Ó yẹ kí inú wa dùn pé nísinsìnyí, inúure àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ń dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí a ti fi àǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere dù, lọ́nà kan tàbí òmíràn. (Tímótì Kìíní 2:4) Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé ìfẹ́ wa fún wọn jẹ́ ojúlówó?
10. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a ní ojúlówó ẹ̀mí aájò àlejò sí “àwọn àjèjì” tí ó wà láàárín wa?
10 A lè tẹ̀ lé ìṣílétí Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara yín lẹ́nì kíní kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wá, pẹ̀lú ògo fún Ọlọ́run ní iwájú.” (Róòmù 15:7) Mímọ̀ pé àwọn ènìyàn láti àwọn orílẹ̀-èdè tàbí láti ipò àtilẹ̀wá mìíràn sábà máa ń lálààṣí, a gbọ́dọ̀ fi inúure hàn sí wọn, kí a sì dàníyàn nípa wọn nígbà tí agbára wa bá gbé e láti ṣe bẹ́ẹ̀. A gbọ́dọ̀ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n sáàárín wa, kí a bá ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lò gẹ́gẹ́ bí ‘ọmọ ìbílẹ̀ wa,’ kí a sì ‘fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ara wa.’ (Léfítíkù 19:34) Èyí lè má rọrùn láti ṣe, ṣùgbọ́n a óò kẹ́sẹ járí bí a bá rántí ìmọ̀ràn náà pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ̀yin lè fún ara yín ní ẹ̀rí ìdánilójú ìfẹ́ inú Ọlọ́run tí ó dára tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà tí ó sì pé.”—Róòmù 12:2.
Ẹ Ṣàjọpín Pẹ̀lú Àwọn Ẹni Mímọ́
11, 12. Ìgbatẹnirò àkànṣe wo ni a fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mélòó kan ní (a) Ísírẹ́lì ìgbàanì (b) ní ọ̀rúndún kìíní?
11 Àwọn Kristẹni adàgbàdénú, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ takuntakun fún ire tẹ̀mí wa, wà lára àwọn tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìgbatẹnirò àti aájò àlejò wa ní tòótọ́. Jèhófà ṣe ìpèsè àkànṣe fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. (Númérì 18:25-29) Ní ọ̀rúndún kìíní, a tún rọ àwọn Kristẹni láti bójú tó àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sìn wọ́n ní àwọn ipò àkànṣe. Àkọsílẹ̀ tí ó wà ní Jòhánù Kẹta 5-8 fún wa ní èrò díẹ̀ nípa ìdè ìfẹ́ pẹ́kípẹ́kí tí ó wà láàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀.
12 Àpọ́sítélì Jòhánù arúgbó mọrírì inúure àti aájò àlejò tí Gáyọ́sì fi hàn sí àwọn arákùnrin arìnrìn àjò kan tí a rán láti bẹ ìjọ wò. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí—títí kan Dímẹ́tíríù, tí ó hàn gbangba pé òun ni ó fi lẹ́tà Jòhánù jíṣẹ́—lápapọ̀ jẹ́ àlejò tàbí àjèjì sí Gáyọ́sì tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n a gbà wọ́n pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò nítorí pé “tìtorí orúkọ [Ọlọ́run] ni wọ́n ṣe jáde lọ.” Jòhánù sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Nítorí náà, a wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti gba irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, kí a lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.”—Jòhánù Kẹta 1, 7, 8.
13. Àwọn wo ní pàtàkì láàárín wa lónìí ni ó yẹ fún ‘gbígbà pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò’?
13 Lónìí, láàárín ètò àjọ Jèhófà, ọ̀pọ̀ ń bẹ tí wọ́n ń lo ara wọn tokunratokunra nítorí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará. Èyí ní nínú, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò, tí wọ́n ń lo àkókò àti agbára wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti gbé àwọn ìjọ ró; àwọn míṣọ́nnárì, tí wọ́n fi àwọn ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn sẹ́yìn láti lọ wàásù ní àwọn ilẹ̀ àjèjì; àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sìn ní àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì tàbí ní àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka, tí wọ́n yọ̀ọ̀da iṣẹ́ ìsìn wọn láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé; àti àwọn tí ó wà nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, tí wọ́n ń lo apá tí ó pọ̀jù lọ lára àkókò àti agbára wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Ní pàtàkì, gbogbo àwọn wọ̀nyí ń ṣiṣẹ́ kára, kì í ṣe fún ògo tàbí èrè ara ẹni, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ nítorí ìfẹ́ fún ẹgbẹ́ ará Kristẹni àti fún Jèhófà. Ó yẹ kí a fara wé wọn nítorí ìfọkànsìn tọkàntọkàn wọn, wọ́n sì lẹ́tọ̀ọ́ sí ‘gbígbà wọ́n pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò.’
14. (a) Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé a di Kristẹni tí ó sàn jù nígbà tí a bá fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí àwọn olùṣòtítọ́? (b) Èé ṣe tí Jésù fi sọ pé Màríà yan “ipa ìpín rere”?
14 Àpọ́sítélì Jòhánù wí pé, nígbà tí a bá “gba irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò,” a óò “di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.” Lọ́nà kan, a óò di Kristẹni tí ó sàn jù ní àbájáde rẹ̀. Èyí jẹ́ nítorí pé iṣẹ́ Kristẹni kan ṣíṣe rere fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni. (Òwe 3:27, 28; Jòhánù Kìíní 3:18) Èrè tún wà lọ́nà míràn pẹ̀lú. Nígbà tí Màríà àti Màtá gba Jésù sílé wọn, Màtá fẹ́ jẹ́ olùgbàlejò rere nípa pípèsè “ohun púpọ̀” fún Jésù. Màríà fi aájò àlejò hàn lọ́nà tí ó yàtọ̀. Ó “jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa tí ó sì tẹra mọ́ fífetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀,” Jésù sì gbóríyìn fún un fún yíyan “ipa ìpín rere.” (Lúùkù 10:38-42) Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ àti ìjíròrò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti ní ìrírí fún ọ̀pọ̀ ọdún sábà máa ń jẹ́ kókó pàtàkì ní ìrọ̀lẹ́ tí ènìyàn bá lò láàárín wọn.—Róòmù 1:11, 12.
Ní Àwọn Àkókò Pàtàkì
15. Àwọn ayẹyẹ pàtàkì wo ni ó lè jẹ́ àkókò ìgbádùn fún àwọn ènìyàn Jèhófà?
15 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kì í tẹ̀ lé àwọn àṣà gbígbajúmọ̀ tàbí pa àwọn họlidé àti àjọyọ̀ ayé mọ́, àwọn àkókò máa ń wà nígbà tí wọ́n máa ń kójọ pọ̀ láti gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ara wọn. Fún àpẹẹrẹ, Jésù lọ sí ibi àsè ìgbéyàwó kan ní Kánà, ó sì fi kún ìdùnnú ayẹyẹ náà nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ níbẹ̀. (Jòhánù 2:1-11) Bákan náà lónìí, àwọn ènìyàn Jèhófà ń gbádùn pa pọ̀ ní irú ìgbà ayẹyẹ bẹ́ẹ̀, ayẹyẹ àti àjọyọ̀ tí ó sì bá a mu wẹ́kú máa ń fi ohun púpọ̀ kún irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n, kí ni ó bá a mu wẹ́kú?
16. Àwọn ìlànà wo ni a ní lórí ìwà tí ó tọ́ àní fún àwọn ayẹyẹ pàtàkì pàápàá?
16 Láti inú ohun tí a kọ́ nínú Bíbélì, a kọ́ nípa ohun tí ó jẹ́ ìwà tí ó bá a mu wẹ́kú fún àwọn Kristẹni, a sì ń tẹ̀ lé èyí ní gbogbo ìgbà. (Róòmù 13:12-14; Gálátíà 5:19-21; Éfésù 5:3-5) Àwọn ìpéjọpọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, yálà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìgbéyàwó tàbí fún ìdí èyíkéyìí mìíràn, kò fún wa ní òmìnira láti pa àwọn ìlànà Kristẹni wa tì tàbí láti ṣe ohun tí a kì bá ti ṣe bí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò bá wáyé; kò sì pọn dandan fún wa láti tẹ̀ lé gbogbo àṣà orílẹ̀-èdè tí a ń gbé. A gbé ọ̀pọ̀ nínú wọn karí àwọn àṣà ìsìn èké tàbí ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán, àwọn mìíràn sì ní àwọn ìwà tí àwọn Kristẹni ní kedere kò tẹ́wọ́ gbà nínú.—Pétérù Kìíní 4:3, 4.
17. (a) Àwọn kókó abájọ wo ni ó fi hàn pé a ṣètò àsè ìgbéyàwó tí a ṣe ní Kánà dáradára, tí a sì bójú tó o lọ́nà títọ́? (b) Kí ní fi hàn pé Jésù fọwọ́ sí ayẹyẹ yẹn?
17 Ní kíka Jòhánù 2:1-11, kò ṣòro fún wa láti rí i pé ayẹyẹ náà jẹ́ èyí tí ó fa kíki, àti pé ọ̀pọ̀ àlejò wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n, àlejò tí “a ké sí” ni Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀; kì í ṣe pé wọ́n kàn ṣe mo-gbọ́-mo-yà lásán, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó kéré tán, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan nínú wọn bá olùgbàlejò náà tan. A tún kíyè sí i pé àwọn tí “ń ṣe ìránṣẹ́” títí kan “olùdarí,” tí yóò pèsè ìdarí nípa ohun tí a ó gbé kalẹ̀ tàbí ohun tí a óò ṣe, wà níbẹ̀. Gbogbo èyí fi hàn pé a ṣètò àlámọ̀rí náà dáradára, a sì bójú tó o lọ́nà tí ó tọ́. Àkọsílẹ̀ náà parí nípa sísọ pé Jésù “mú ògo rẹ̀ ṣe kedere” nípa ohun tí ó ṣe níbi àsè náà. Òun yóò ha ti yan ibi ayẹyẹ yẹn láti ṣe ìyẹn ká ní ó jẹ́ àríyá aláriwo àti aláìṣeéṣàkóso bí? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ kọ́.
18. Ìrònújinlẹ̀ wo ni a gbọ́dọ̀ fún ayẹyẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà èyíkéyìí?
18 Nígbà náà, àwọn ayẹyẹ pàtàkì tí a ti lè jẹ́ olùgbàlejò ńkọ́? A fẹ́ fi sọ́kàn pé ète tí a fi ń fi ẹ̀mí aájò àlejò gba àwọn ẹlòmíràn jẹ́ nítorí kí gbogbo wa baà lè “di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.” Nípa báyìí, fífẹnu lásán pe ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní àpèjẹ “Ẹlẹ́rìí” kò tó. A lè béèrè pé, Ní tòótọ́, ó ha jẹ́rìí nípa ẹni tí a jẹ́ àti nípa ohun tí a gbà gbọ́ bí? A kò gbọdọ̀ wo irú àwọn ayẹyẹ yẹn gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti rí bí a ṣe lè díje pẹ̀lú àwọn ọ̀nà ayé tó, ní kíkẹ́ra bàjẹ́ pẹ̀lú “ìfẹ́ ọkàn ti ẹran ara àti ìfẹ́ ọkàn ti ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (Jòhánù Kìíní 2:15, 16) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ fi ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà hàn lọ́nà títọ́, a sì gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ohun tí a bá ṣe ń mú ògo àti ọlá wá fún Jèhófà.—Mátíù 5:16; Kọ́ríńtì Kìíní 10:31-33.
‘Ẹ Ní Ẹ̀mí Aájò Àlejò Láìsí Ìráhùn’
19. Èé ṣe tí a fi ní láti ‘ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara wa lẹ́nì kíní kejì láìsí ìráhùn’?
19 Bí ipò ayé ti ń bàjẹ́ sí i, tí àwọn ènìyàn sì ń pínyà ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a ní láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti fún ìdè pẹ́kípẹ́kí tí ó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ lókun. (Kólósè 3:14) Nítorí èyí, gẹ́gẹ́ bí Pétérù ti rọ̀ wá, a gbọ́dọ̀ ní ‘ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara wa lẹ́nì kíní kejì.’ Lẹ́yìn náà, lọ́nà gbígbéṣẹ́, ó fi kún un pé: “Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kíní kejì láìsí ìráhùn.” (Pétérù Kìíní 4:7-9) Àwa ha múra tán láti lo ìdánúṣe láti fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí àwọn ará wa, láti lo ara wa láti fi inúure hàn, kí a sì ṣèrànwọ́ bí? Tàbí àwa ha ń ráhùn nígbà tí àǹfààní náà bá ṣí sílẹ̀ bí? Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò fagi lé ayọ̀ tí ó yẹ kí a ní, a óò sì pàdánù èrè ayọ̀ tí ṣíṣe rere ní.—Òwe 3:27; Ìṣe 20:35.
20. Àwọn ìbùkún wo ní ń dúró dè wá bí a bá ní ẹ̀mí aájò àlejò nínú ayé tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lónìí?
20 Ṣíṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, jíjẹ́ onínúure àti ẹlẹ́mìí aájò àlejò sí ara wa lẹ́nì kíní kejì yóò mu ìbùkún àìlópin wá. (Mátíù 10:40-42) Jèhófà ṣèlérí fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé òun yóò “na àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n. Ebi kì yóò pa wọ́n mọ́ bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n mọ́.” Wíwà nínú àgọ́ Jèhófà túmọ̀ sí gbígbádùn ààbò àti ẹ̀mí aájò àlejò tí ó ní. (Ìṣípayá 7:15, 16; Aísáyà 25:6) Bẹ́ẹ̀ ni, ìfojúsọ́nà gbígbádùn aájò àlejò Jèhófà títí láé, wà gẹ́rẹ́ níwájú.—Orin Dáfídì 27:4; 61:3, 4.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Kí ni a kò gbọdọ̀ gbójú fò dá bí a bá ń fẹ́ láti rí ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́?
◻ Àwọn wo ni “àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó,” báwo sì ni ó ṣe yẹ kí a “bójú tó” wọn?
◻ Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo “àwọn àtìpó” àti “àwọn àjèjì” tí ó wà láàárín wa?
◻ Àwọn wo ni ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìgbatẹnirò pàtó lónìí?
◻ Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn ayẹyẹ pàtàkì fi ẹ̀mí aájò àlejò tòótọ́ hàn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Nígbà àwọn ayẹyẹ onídùnnú, a lè fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí àwọn àjèjì, àwọn ọmọ aláìníbàbá, àwọn tí ń bẹ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àti àwọn àlejò míràn