Ápólò—Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Olùpòkìkí Òtítọ́ Kristẹni
BÓYÁ wọ́n ti jẹ́ mẹ́ḿbà ìjọ Kristẹni fún ọ̀pọ̀ ọdún tàbí fún kìkì ìwọ̀nba ọdún díẹ̀, gbogbo olùpòkìkí Ìjọba gbọ́dọ̀ lọ́kàn ìfẹ́ nínú títẹ́ síwájú gẹ́gẹ́ bí oníwàásù ìhìn rere. Ìyẹn túmọ̀ sí mímú kí ìmọ̀ wa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti agbára wa láti fi í kọ́ni pọ̀ sí i. Fún àwọn kan, ó lè túmọ̀ sí dídojú kọ àwọn ìpènijà, ṣíṣẹ́pá àwọn ìṣòro, tàbí mímú ara wọn wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i.
Bíbélì ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùfọkànsìn ti ìgbàanì, tí wọ́n kẹ́sẹ járí ní àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ní níní ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí gíga lọ́lá, tí wọ́n sì jèrè nítorí ìsapá wọn. Ọ̀kan nínú wọn ni Ápólò. Nígbà tí Ìwé Mímọ́ kọ́kọ́ sọ fún wa nípa rẹ̀, ó jẹ́ ẹni tí kò ní òye pípé pérépéré nípa àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni; ṣùgbọ́n, ní kìkì ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú arìnrìn àjò ti ìjọ ọ̀rúndún kìíní. Kí ni ó jẹ́ kí ó lè ní irú ìtẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀? Ó ní àwọn ànímọ́ tí gbogbo wa yóò ṣe dáradára láti fara wé.
“Ògbóǹkangí Nínú Ìwé Mímọ́”
Ní nǹkan bí ọdún 52 Sànmánì Tiwa, gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Lúùkù ṣe sọ, “Júù kan báyìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ápólò, ọmọ ìbílẹ̀ Alẹkisáńdíríà, ọkùnrin sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan, dé sí Éfésù; òun sì jẹ́ ògbóǹkangí nínú Ìwé Mímọ́. Ọkùnrin yìí ni a ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu fún ní ìtọ́ni ní ọ̀nà Jèhófà àti pé, bí iná ẹ̀mí ti ń jó nínú rẹ̀, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń fi àwọn nǹkan nípa Jésù kọ́ni pẹ̀lú ìpérẹ́gí, ṣùgbọ́n ìbatisí Jòhánù nìkan ni ó mọ̀. Ọkùnrin yìí sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ láìṣojo nínú sínágọ́gù.”—Ìṣe 18:24-26.
Alẹkisáńdíríà, ti Íjíbítì, ni ìlú kejì tí ó tóbi jù lọ lágbàáyé lẹ́yìn Róòmù nígbà náà lọ́hùn-ún, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibùdó ìgbòkègbodò pàtàkì jù lọ fún àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ní àkókò náà, fún àwọn Júù àti fún àwọn Gíríìkì. Ó ṣeé ṣe pé, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí Ápólò gbà ní àwùjọ ńlá ti àwọn Júù nínú ìlú ńlá yẹn ni ó mú kí ó ní ìmọ̀ yíyè kooro nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, tí ó sì mú kí ó ní ẹ̀bùn jíjẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Ó ṣòro púpọ̀ láti ronú wòye ibi tí Ápólò ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, F. F. Bruce, sọ pé: “Dájúdájú, arìnrìn àjò ni òun jẹ́—bóyá tí ó jẹ́ oníṣòwò arìnrìn àjò, ó sì ti lè pàdé àwọn Kristẹni oníwàásù ní èyíkéyìí nínú àwọn ibi tí ó ṣe ìbẹ̀wò sí.” Bí ó ti wù kí ọ̀ràn náà rí, àní bí òun tilẹ̀ sọ̀rọ̀ láìfìkan pe méjì, tí ó sì kọ́ni nípa Jésù, ó dà bí ẹni pé a ti jẹ́rìí fún un ṣáájú Pẹ́ńtíkọ́sì ti ọdún 33 Sànmánì Tiwa, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé “ìbatisí Jòhánù nìkan ni ó mọ̀.”
Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a rán ṣáájú Jésù, Jòhánù Oníbatisí ti jẹ́rìí lílágbára fún gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, a sì ti batisí ọ̀pọ̀ láti ọwọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà. (Máàkù 1:5; Lúùkù 3:15, 16) Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn kan ti sọ, láàárín àwùjọ àwọn Júù tí wọ́n wà ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ìmọ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní nípa Jésù mọ sórí ohun tí a wàásù rẹ̀ ní etí odò Jọ́dánì. W. J. Conybeare àti J. S. Howson sọ pé: “Ìsìn Kristẹni wọn kò tí ì kúrò lójú kan náà tí ó wà nígbà ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Olúwa wa. Wọn kò mọ ìtúmọ̀ ikú Kristi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́; àfàìmọ̀ bí wọ́n bá tilẹ̀ mọ òkodoro òtítọ́ nípa àjíǹde Rẹ̀ pàápàá.” Ó jọ bí ẹni pé Ápólò pẹ̀lú kò mọ̀ nípa ìtújáde ẹ̀mí mímọ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ti jèrè ìsọfúnni pípé rẹ́gí díẹ̀ nípa Jésù, kò sì jẹ́ anìkànjọpọ́n. Ní tòótọ́, ó fi ìgboyà wa àǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó mọ̀. Ṣùgbọ́n, ìtara àti ìgbónára rẹ̀ kò tí ì bá ìmọ̀ pípéye mu síbẹ̀.
Ó Ní Ìtara Ṣùgbọ́n Ó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
Ìròyìn Lúùkù ń bá a nìṣó pé: “Nígbà tí Pírísílà àti Ákúílà gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un wọ ẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.” (Ìṣe 18:26) Ákúílà àti Pírísílà ti ní láti mọ̀ pé ìgbàgbọ́ Ápólò fara jọ tiwọn gidigidi, ṣùgbọ́n lọ́nà ọgbọ́n, wọn kò gbìdánwò láti ṣàtúnṣe òye rẹ̀ tí kò péye, ní gbangba. A lè ronú pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní ìjíròrò ara ẹni díẹ̀ pẹ̀lú Ápólò, pẹ̀lú ète àtiràn án lọ́wọ́. Báwo ni Ápólò, ọkùnrin “tí ó jẹ́ alágbára nínú Ìwé Mímọ́,” ṣe hùwà padà? (Ìṣe 18:24, Kingdom Interlinear) Dájúdájú, Ápólò ti ń wàásù ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ tí kò péye, ní gbangba, fún ìgbà díẹ̀ kí ó tó pàdé Ákúílà àti Pírísílà. Ẹnì kan tí ó jẹ́ agbéraga ti lè fi ìrọ̀rùn kọ̀ láti gba àtúnṣe èyíkéyìí, ṣùgbọ́n Ápólò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fi ìmọrírì hàn pé ó ṣeé ṣe fún òun láti mú ìmọ̀ òun péye.
Ìṣarasíhùwà oníwọ̀ntúnwọ̀nsì kan náà ti Ápólò tún fara hàn nínú ìmúratán rẹ̀ láti gba lẹ́tà ìdámọ̀ràn láti ọwọ́ àwọn ará ní Éfésù lọ sí ìjọ tí ó wà ní Kọ́ríńtì. Ìròyìn náà ń bá a nìṣó pé: “Síwájú sí i, nítorí pé ó ní ìfẹ́ ọkàn láti sọdá lọ sí Ákáyà, àwọn ará kọ̀wé sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ní gbígbà wọ́n níyànjú láti fi inú rere gbà á.” (Ìṣe 18:27; 19:1) Ápólò kò béèrè pé kí a tẹ́wọ́ gba òun nítorí ànímọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì tẹ̀ lé ètò tí ìjọ Kristẹni ṣe.
Ní Kọ́ríńtì
Àbájáde iṣẹ́ òjíṣẹ́ Ápólò ní Kọ́ríńtì ní ìbẹ̀rẹ̀ tayọ lọ́lá. Ìwé Ìṣe ròyìn pé: “Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó ṣe ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti gbà gbọ́ ní tìtorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run; nítorí pé pẹ̀lú ìgbóná janjan ni ó fi hàn kínníkínní ní gbangba pé àwọn Júù kò tọ̀nà, nígbà tí ó fi hàn gbangba nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ pé Jésù ni Kristi náà.”—Ìṣe 18:27, 28.
Ápólò fara rẹ̀ jìn fún iṣẹ́ ìsìn ìjọ, ní fífún àwọn ará níṣìírí nípasẹ̀ ìmúrasílẹ̀ àti ìtara rẹ̀. Kí ni kọ́kọ́rọ́ sí àṣeyọrí rẹ̀? Dájúdájú, Ápólò ní agbára àdánidá, ó sì lo ìgboyà nínú jíjiyàn pẹ̀lú àwọn Júù ní gbangba fún ìgbà pípẹ́. Ṣùgbọ́n ní pàtàkì jù, ó jíròrò ní lílo Ìwé Mímọ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ápólò ní agbára ìdarí lílágbára láàárín àwọn ará Kọ́ríńtì, ó dunni pé ìwàásù rẹ̀ mú àbáyọrí tí kò dára, tí a kò fojú sọ́nà fún wá. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù àti Ápólò ti ṣe bẹbẹ ní gbígbìn àti bíbomirin irúgbìn òtítọ́ Ìjọba ní Kọ́ríńtì. Pọ́ọ̀lù ti wàásù níbẹ̀ ní nǹkan bí 50 ọdún Sànmánì Tiwa, nǹkan bí ọdún méjì kí Ápólò tó dé. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa, ìyapa ti ṣẹlẹ̀. Àwọn kan ń wo Ápólò gẹ́gẹ́ bí aṣáájú wọn, nígbà tí àwọn mìíràn fara mọ́ Pọ́ọ̀lù tàbí Pétérù tàbí rọ̀ mọ́ Kristi nìkan ṣoṣo. (Kọ́ríńtì Kìíní 1:10-12) Àwọn kan ń sọ pé: ‘Èmi jẹ́ ti Ápólò.’ Èé ṣe?
Ọ̀kan náà ni ìhìn iṣẹ́ tí Pọ́ọ̀lù àti Ápólò wàásù rẹ̀, ṣùgbọ́n àkópọ̀ ànímọ́ ìwà wọn yàtọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹnu ara rẹ̀ sọ, Pọ́ọ̀lù jẹ́ “aláìjáfáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ”; Ápólò, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, jẹ́ “sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀.” (Kọ́ríńtì Kejì 10:10; 11:6) Ó ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí ó jẹ́ kí àwọn kan lára àwùjọ àwọn Júù ní Kọ́ríńtì tẹ́tí sí i. Ó kẹ́sẹ járí ní ‘fífẹ̀rí hàn gidigidi pé àwọn Júù kò tọ̀nà,’ nígbà tí ó sì jẹ́ pé, kò pẹ́ púpọ̀ sí àkókò náà tí Pọ́ọ̀lù fi fi sínágọ́gù sílẹ̀.—Ìṣe 18:1, 4-6.
Èyí ha lè jẹ́ ìdí tí àwọn kan fi gba ti Ápólò bí? Àwọn akọ̀ròyìn kan sọ pé ìfẹ́ ọkàn àbímọ́ni fún ìjíròrò onímọ̀ èrò orí láàárín àwọn Gíríìkì ti lè mú kí àwọn kan gba ti ọ̀nà ìgbékalẹ̀ Ápólò, tí ń runi sókè gidigidi. Giuseppe Ricciotti sọ pé “èdè dídùn tí [Ápólò] lò àti àwọn àpèjúwe rẹ̀ tí ó kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ mú kí ó jèrè ìkansáárá ọ̀pọ̀ tí ó gba tirẹ̀ ju ti Pọ́ọ̀lù, òǹsọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò já geere, tí kò sì dán mọ́rán.” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́, àwọn kan lọ́nà tí kò tọ́ jẹ́ kí irú ìfẹ́ ọkàn ara ẹni bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn ara, ó rọrùn láti lóye ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi fi tagbáratagbára ṣe lámèyítọ́ gbígbé “ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n” ga.—Kọ́ríńtì Kìíní 1:17-25.
Ṣùgbọ́n, irú ìṣelámèyítọ́ bẹ́ẹ̀ kò fi ìforígbárí kankan hàn láàárín Pọ́ọ̀lù àti Ápólò. Bí àwọn kan tilẹ̀ ti wòye kọjá àlà pé àwọn oníwàásù méjì yìí jẹ́ ọ̀tá paraku tí ń jà láti jèrè ìfẹ́ni àwọn ará Kọ́ríńtì, Ìwé Mímọ́ sọ pé kò rí bẹ́ẹ̀. Kàkà tí ì bá fi gbé ara rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ẹ̀ya kan, Ápólò kúrò ní Kọ́ríńtì, ó padà sí Éfésù, ó sì wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù nígbà tí ó kọ lẹ́tà àkọ́kọ́ sí ìjọ tí ó ti yapa náà.
Kò sí àìníṣọ̀kan tàbí ìbára-ẹni-díje láàárín wọn; kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí fi hàn pé àwọn méjèèjì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti fi ìgbọ́kànlé tọ̀tún tòsì yanjú àwọn ìṣòro tí ń bẹ ní Kọ́ríńtì. Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ṣiyè méjì nípa àwọn kan ní Kọ́ríńtì ṣùgbọ́n, ó dájú pé kì í ṣe nípa Ápólò. Iṣẹ́ àwọn ọkùnrin méjì náà ṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀; ẹ̀kọ́ wọn ṣàlékún ara wọn. Láti fa ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ yọ, ó wí pé: “Èmi gbìn, Ápólò bomi rin,” nítorí àwọn méjèèjì jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.”—Kọ́ríńtì Kìíní 3:6, 9, 21-23.
Gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, àwọn ará Kọ́ríńtì buyì kún Ápólò gidigidi, ní fífọkàn fẹ́ pé kí ó tún bẹ̀ wọ́n wò. Ṣùgbọ́n nígbà tí Pọ́ọ̀lù ké sí Ápólò láti padà lọ sí Kọ́ríńtì, ará Alẹkisáńdíríà náà kọ̀ jálẹ̀. Pọ́ọ̀lù wí pé: “Wàyí o ní ti Ápólò arákùnrin wa, mo pàrọwà fún un gidigidi láti wá sí ọ̀dọ̀ yín . . . , síbẹ̀ kì í sì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ rárá láti wá nísinsìnyí; ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí àyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.” (Kọ́ríńtì Kìíní 16:12) Ápólò ti lè lọ́ tìkọ̀ láti padà lọ nítorí ìbẹ̀rù ríru ìpínyà míràn sókè, tàbí ó wulẹ̀ lè jẹ́ nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ dí níbòmíràn ni.
Nígbà tí a mẹ́nu kan Ápólò kẹ́yìn nínú Ìwé Mímọ́, ó ń rìnrìn àjò lọ sí Kírétè, ó sì ṣeé ṣe kí ó kọjá ibẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i Pọ́ọ̀lù fún ọ̀rẹ́ àti òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àbójútó pàtàkì, ní sísọ fún Títù láti pèsè gbogbo ohun tí Ápólò àti alábàákẹ́gbẹ́ arìnrìn àjò rẹ̀, Sénásì, lè nílò fún ìrìn àjò wọn fún wọn. (Títù 3:13) Ní àkókò yìí, lẹ́yìn ọdún bíi mẹ́wàá tí ó fi ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ Kristẹni, Ápólò ti ní ìtẹ̀síwájú tí ó tó láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú arìnrìn àjò fún ìjọ.
Àwọn Ànímọ́ Oníwà-Bí-Ọlọ́run Ti Ń Mú Ìdàgbàsókè Tẹ̀mí Rọrùn
Oníwàásù ará Alẹkisáńdíríà náà fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún gbogbo àwọn oníwàásù ìhìn rere lónìí, àti ní tòótọ́, gbogbo àwọn tí ń fẹ́ láti ní ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí. A lè máà jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti jẹ́, ṣùgbọ́n dájúdájú, a lè sakun láti fara wé ìmọ̀ àti agbára ìṣe rẹ̀ ní lílo Ìwé Mímọ́, ní títipa báyìí ran àwọn olóòótọ́ ọkàn olùwá òtítọ́ kiri lọ́wọ́. Nípasẹ̀ àpẹẹrẹ ìgbòkègbodò onítara rẹ̀, Ápólò “ṣe ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti gbà gbọ́.” (Ìṣe 18:27) Ápólò jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, onífara-ẹni-rúbọ̀, ó sì múra tán láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn. Ó mọ̀ dáradára pé kò sí àyè fún ìbáradíje tàbí ìfẹ́ fún agbára nínú ìjọ Kristẹni, nítorí gbogbo wa jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.”—Kọ́ríńtì Kìíní 3:4-9; Lúùkù 17:10.
Gẹ́gẹ́ bí Ápólò, a lè ní ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí. A ha múra tán láti mú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wa sunwọ̀n tàbí gbòòrò sí i, ní fífi ara wa sí ipò tí Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ ti lè lò wá ní kíkún sí i bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a óò jẹ́ onítara akẹ́kọ̀ọ́ àti olùpòkìkí òtítọ́ Kristẹni.