Bí Àwọn Alábòójútó Arìnrìn Àjò Ṣe Ń Ṣiṣẹ́ Sìn Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣòtítọ́ Ìríjú
“Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kíní kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn jáde ní onírúurú ọ̀nà.”—PÉTÉRÙ KÌÍNÍ 4:10.
1, 2. (a) Báwo ni ìwọ yóò ṣe túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìríjú”? (b) Àwọn wo ni wọ́n wà lára àwọn ìríjú tí Ọlọ́run ń lò?
JÈHÓFÀ ń lo gbogbo Kristẹni olùṣòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ìríjú. Ìríjú sábà máa ń jẹ́ alámòójútó ilé. Ó tún lè máa mójú tó òwò ọ̀gá rẹ̀. (Lúùkù 16:1-3; Gálátíà 4:1, 2) Jésù pe ẹgbẹ́ àwọn adúróṣinṣin ẹni àmì òróró rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé ní “olùṣòtítọ́ ìríjú.” Ìríjú yìí ni ó fa “gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀” lé lọ́wọ́, títí kan ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba.—Lúùkù 12:42-44; Mátíù 24:14, 45.
2 Àpọ́sítélì Pétérù wí pé gbogbo Kristẹni jẹ́ ìríjú fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà. Kristẹni kọ̀ọ̀kan ní àyè kan nínú èyí tí ó ti lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ìríjú. (Pétérù Kìíní 4:10) Àwọn Kristẹni alàgbà tí a yàn sípò jẹ́ ìríjú, ara wọn sì ní àwọn alábòójútó arìnrìn àjò wà. (Títù 1:7) Ojú wo ni ó yẹ kí a máa fi wo àwọn alàgbà arìnrìn àjò wọ̀nyí? Àwọn ànímọ́ àti ète wo ni ó yẹ kí wọ́n ní? Báwo sì ni wọ́n ṣe lè ṣe ìjọ láǹfààní gíga jù lọ?
Fífi Ìmoore Hàn fún Iṣẹ́ Ìsìn Wọn
3. Èé ṣe tí a fi lè pe àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ní “ìríjú àtàtà”?
3 Nígbà tí wọ́n ń kọ̀wé sí alábòójútó arìnrìn àjò kan àti aya rẹ̀, tọkọtaya Kristẹni kan wí pé: “Àwa yóò fẹ́ láti sọ ìmoore wa jáde fún gbogbo àkókò tí ẹ ti fún wa àti ìfẹ́ tí ẹ ti fi hàn sí wa. Gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, a ti jàǹfààní ńláǹlà láti inú ìṣírí àti ìmọ̀ràn yín. A mọ̀ pé a ní láti máa bá a nìṣó ní dídàgbà nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin bíi tiyín, a mú àwọn ìṣòro tí ń bá a rìn rọrùn.” A sábà máa ń gbọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorí pé, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ń ní ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni nínú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìríjú rere kan ṣe ń mójú tó àìní agbo ilé lọ́nà rere. Àwọn kan jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ títa yọ. Àwọn kan ta yọ nínú iṣẹ́ ìwàásù, nígbà tí a sì mọ àwọn mìíràn fún jíjẹ́ ọlọ́yàyà àti oníyọ̀ọ́nú. Nípa mímú irú àwọn ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ dàgbà àti lílò wọ́n nínú ṣíṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, a lè pe àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ní “ìríjú àtàtà.”
4. Ìbéèrè wo ni a óò gbé yẹ̀ wò nísinsìnyí?
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun tí a ń wá nínú àwọn ìríjú ni pé kí a rí ènìyàn kan ní olùṣòtítọ́.” (Kọ́ríńtì Kìíní 4:2) Ṣíṣe ìránṣẹ́ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni nínú ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ àti èyí tí ń mú ìdùnnú wá. Síbẹ̀síbẹ̀, ó jẹ́ ẹrù iṣẹ́ wíwúwo. Nígbà náà, báwo ni àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ṣe lè fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ ìríjú wọn, kí wọ́n sì kẹ́sẹ járí?
Kíkẹ́sẹ Járí Nínú Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìríjú Wọn
5, 6. Èé ṣe tí fífi tàdúràtàdúrà gbára lé Jèhófà fi ṣe pàtàkì to bẹ́ẹ̀ nínú ìgbésí ayé alábòójútó arìnrìn àjò kan?
5 Gbígbára lé Jèhófà tàdúràtàdúrà ṣe pàtàkì bí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò yóò bá kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ ìríjú wọn. Nítorí ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn àti ẹrù iṣẹ́ wọn tí ó pọ̀, nígbà míràn, wọ́n lè nímọ̀lára pé a dẹ́rù pa wọ́n. (Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 5:4.) Nítorí náà, wọ́n ní láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú orin onísáàmù náà, Dáfídì, pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Olúwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.” (Orin Dáfídì 55:22) Àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì tún tuni nínú pẹ̀lú pé: “Olùbùkún ni Jèhófà, ẹni tí ń bá wa gbé ẹrù wa lójoojúmọ́.”—Orin Dáfídì 68:19, NW.
6 Níbo ni Pọ́ọ̀lù ti rí okun láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ nípa tẹ̀mí? Ó kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni náà tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run ni Orísun okun Pọ́ọ̀lù. Bákan náà, Pétérù gbani nímọ̀ràn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kí ó ṣe ìránṣẹ́ bí ẹni tí ó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè; kí a lè yin Ọlọ́run lógo nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ Jésù Kristi.” (Pétérù Kìíní 4:11) Arákùnrin kan tí ó jẹ́ alábòójútó arìnrìn àjò fún ọ̀pọ̀ ọdún tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì gbígbára lé Ọlọ́run, ní sísọ pé: “Máa wo Jèhófà nígbà gbogbo láti yanjú ìṣòro, kí o sì máa wá ìrànlọ́wọ́ ètò àjọ rẹ̀.”
7. Báwo ni ìwàdéédéé ṣe ń kó ipa kan nínú iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn àjò kan?
7 Alábòójútó arìnrìn àjò tí yóò kẹ́sẹ járí nílò ìwàdéédéé. Bíi ti àwọn Kristẹni yòó kù, ó ń sakun láti “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10)a Nígbà tí àwọn alàgbà àdúgbò bá ní ìbéèrè nípa ọ̀ràn kan, yóò bọ́gbọ́n mu fún wọn láti fikùn lukùn pẹ̀lú alábòójútó àyíká tí ń bẹ̀ wọ́n wò. (Òwe 11:14; 15:22) Ó ṣeé ṣe kí àkíyèsí rẹ̀ wíwà déédéé àti ìmọ̀ràn rẹ̀ tí ó gbé karí Ìwé Mímọ́ jẹ́ èyí tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ gidigidi, bí àwọn alàgbà náà ṣe ń bá a nìṣó ní yíyanjú ọ̀ràn náà lẹ́yìn tí ó bá ti fi ìjọ wọn sílẹ̀. Pẹ̀lú ojú ìwòye kan náà, Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Àwọn nǹkan tí ìwọ sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí, àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́, tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.”—Tímótì Kejì 2:2.
8. Èé ṣe tí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣíṣèwádìí, àti ṣíṣàṣàrò fi ṣe pàtàkì?
8 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ṣíṣèwádìí, àti ṣíṣàṣàrò jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì fún fífúnni ní ìmọ̀ràn tí ó yè kooro. (Òwe 15:28) Alábòójútó àgbègbè kan wí pé: “Nígbà tí a bá ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn alàgbà, kò yẹ kí a bẹ̀rù láti sọ pé a kò mọ ìdáhùn sí ìbéèrè kan pàtó.” Sísapá láti ní “èrò inú ti Kristi” lórí ọ̀ràn kan ń mú kí ó ṣeé ṣe láti fúnni ní ìmọ̀ràn tí a gbé karí Bíbélì tí yóò ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Kọ́ríńtì Kìíní 2:16) Nígbà míràn, alábòójútó arìnrìn àjò kan lè ní láti kọ̀wé sí Watch Tower Society fún ìdarí. Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti ìfẹ́ fún òtítọ́ ṣe pàtàkì fíìfíì ju irú ẹni tí a ń fi hàn pé a jẹ́ tàbí jíjẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. Dípò wíwá pẹ̀lú “ọ̀rọ̀ àsọrégèé tàbí ọgbọ́n,” Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Kọ́ríńtì “nínú àìlera àti nínú ìbẹ̀rù àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìwárìrì.” Èyí ha sọ ọ́ dí ẹni tí kò gbéṣẹ́ bí? Ní òdì kejì pátápátá, ó ran àwọn ará Kọ́ríńtì lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́, ‘kì í ṣe nínú ọgbọ́n ènìyàn, bí kò ṣe nínú agbára Ọlọ́run.’—Kọ́ríńtì Kìíní 2:1-5.
Àwọn Ànímọ́ Pàtàkì Míràn
9. Èé ṣe tí àwọn alàgbà arìnrìn àjò fi nílò ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò?
9 Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ń ran àwọn alábòójútó arìnrìn àjò lọ́wọ́ láti ní ìyọrísí rere. Pétérù rọ gbogbo Kristẹni láti “máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn,” tàbí láti jẹ́ “abánikẹ́dùn.” (Pétérù Kìíní 3:8, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Alábòójútó àyíká kan nímọ̀lára pé ó ṣe pàtàkì láti ‘ní ọkàn-ìfẹ́ nínú gbogbo ẹni tí ó wà nínú ìjọ àti láti jẹ́ olùfetísílẹ̀ ní ti gidi.’ Pẹ̀lú irú ẹ̀mí kan náà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ ń sún àwọn alábòójútó arìnrìn àjò láti sapá gidigidi láti lóye àwọn ìṣòro àti àyíká ipò àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Nígbà náà, wọ́n lè fúnni ní ìmọ̀ràn tí ń gbéni ró, tí a gbé karí Ìwé Mímọ́, tí ó lè ṣàṣeparí ohun rere gan-an bí a bá fi í sílò. Alábòójútó àyíká kan tí ó ta yọ nínú fífi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò hàn rí lẹ́tà yìí gbà láti ọ̀dọ̀ ìjọ kan lẹ́bàá Turin, Ítálì: “Bí o bá fẹ́ kí a yọ̀ mọ́ ọ, jẹ́ ẹni tí ń yọ̀ mọ́ni; bí o bá fẹ́ kí a fẹ́ràn rẹ, jẹ́ ẹni tí ń fẹ́ràn ẹni; bí o bá fẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́ rẹ, jẹ́ ẹni tí ń nífẹ̀ẹ́ ẹni; bí o bá fẹ́ kí a ràn ọ́ lọ́wọ́, múra tán láti ranni lọ́wọ́. Ohun tí a kọ́ lára rẹ nìyí!”
10. Kí ni àwọn alábòójútó àyíká àti ti àgbègbè kan sọ nípa jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀, àpẹẹrẹ wo sì ni Jésù fi lélẹ̀ nípa èyí?
10 Jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni tí ó ṣeé sún mọ́ ń ran àwọn alábòójútó arìnrìn àjò lọ́wọ́ láti ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere. Alábòójútó àyíká kan wí pé: “Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.” Ìkìlọ̀ rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di alábòójútó arìnrìn àjò ni pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn arákùnrin tí wọ́n rí jájẹ lo agbára ìdarí lórí yín láìyẹ nítorí ohun tí wọ́n lè ṣe fún yín, bẹ́ẹ̀ sì ni kí ẹ má ṣe fi ìbárẹ́ yín mọ sọ́dọ̀ kìkì irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ máa sakun nígbà gbogbo láti bá àwọn ẹlòmíràn lò láìṣojúsàájú.” (Kíróníkà Kejì 19:6, 7) Alábòójútó arìnrìn àjò kan tí ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní ti gidi, kì yóò ní ojú ìwòye àṣerégèé nípa bí òún ti ṣe pàtàkì tó gẹ́gẹ́ bí aṣojú Society. Alábòójútó àgbègbè kan sọ̀rọ̀ lọ́nà yíyẹ wẹ́kú pé: “Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí o sì múra tán láti tẹ́tí sí àwọn ará. Jẹ́ ẹni tí ó ṣeé sún mọ́ nígbà gbogbo.” Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tí ì gbé ayé rí, Jésù Kristi ì bá ti mú kí ara ni àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni tí ó ṣeé sún mọ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ara àwọn ọmọdé pàápàá fi balẹ̀ láti wà lọ́dọ̀ rẹ̀. (Mátíù 18:5; Máàkù 10:13-16) Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ń fẹ́ kí àwọn ọmọdé, àwọn ọ̀dọ́langba, àwọn àgbàlagbà—ní tòótọ́ ẹnikẹ́ni àti ẹni gbogbo nínú ìjọ—lómìnira fàlàlà láti tọ̀ wọ́n wá.
11. Nígbà tí a bá nílò rẹ̀, ipa wo ni títọrọ àforíjì lè ní?
11 Àmọ́ ṣáá o, “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà,” kò sì sí alábòójútó arìnrìn àjò kan tí kò lè ṣe àṣìṣe. (Jákọ́bù 3:2) Nígbà tí wọ́n bá ṣe àṣìṣe, títọrọ àforíjì látọkànwá ń fún àwọn alàgbà yòó kù ní àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Òwe 22:4 ti sọ, “èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù [ọlọ́wọ̀ fún] Olúwa ni ọrọ̀, ọlá àti ìyè.” Kò ha sì yẹ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ‘rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run wọn bí’? (Míkà 6:8) Nígbà tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ìmọ̀ràn wo ni ó ní fún alàgbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di arìnrìn àjò, alábòójútó àyíká kan wí pé: “Ní ọ̀wọ̀ àti ìkàsí gíga fún gbogbo àwọn ará, ki o sì máa wò wọ́n bí àwọn tí ó sàn jù ọ́ lọ. Ìwọ yóò kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ará. Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Hùwà gẹ́gẹ́ bí o ṣe jẹ́ gan-an. Má ṣe jẹ́ alágàbàgebè.”—Fílípì 2:3.
12. Èé ṣe tí ìtara fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?
12 Ìtara fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ń mú kí ọ̀rọ̀ alábòójútó arìnrìn àjò kan túbọ̀ tẹ̀wọ̀n sí i. Ní tòótọ́, nígbà tí òun àti aya rẹ̀ bá fi àpẹẹrẹ onítara hàn nínú iṣẹ́ ìjíhìn rere, wọ́n ń fún àwọn alàgbà, àwọn aya wọn, àti mẹ́ḿbà yòó kù nínú ìjọ níṣìírí láti fi ìtara hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Alábòójútó àyíká kan rọni pé: “Ẹ jẹ́ onítara fún iṣẹ́ ìsìn.” Ó fi kún un pé: “Mo ti rí i pé, ní gbogbogbòò, bí ìjọ kan bá ṣe jẹ́ onítara tó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìṣòro wọn yóò ṣe dín kù sí i tó.” Alábòójútó àyíká mìíràn sọ pé: “Mo gbà gbọ́ pé bí àwọn alàgbà bá ń bá àwọn arákùnrin àti arábìnrin ṣiṣẹ́ pọ̀ ní pápá, tí wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́, èyí yóò yọrí sí ìbàlẹ̀ ọkàn àti ìtẹ́lọ́rùn gíga jù lọ nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ‘máyà le láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún àwọn ará Tẹsalóníkà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàkadì.’ Abájọ tí wọ́n fi máa ń rántí ìbẹ̀wò àti ìgbòkègbodò ìwàásù rẹ̀ ṣáá, tí àárò rẹ̀ sì fi ń sọ wọn gidigidi!—Tẹsalóníkà Kìíní 2:1, 2; 3:6.
13. Kí ni alábòójútó arìnrìn àjò kan yóò gbé yẹ̀ wò nígbà tí ó bá ń bá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá?
13 Nígbà tí ó bá ń bá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, alábòójútó arìnrìn àjò kan yóò gbé àwọn àyíká ipò àti ìkù-díẹ̀-káàtó wọn yẹ̀ wò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ lè ṣèrànwọ́, ó mọ̀ pé ara àwọn kan lè máà balẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń wàásù pẹ̀lú alàgbà onírìírí kan. Nítorí náà, nínú àwọn ọ̀ràn kan, ìṣírí lè wúlò ju ìmọ̀ràn lọ. Nígbà tí ó bá bá àwọn akéde tàbí aṣáájú ọ̀nà lọ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, wọ́n lè fẹ́ kí ó darí rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí èyí mú kí wọ́n di ojúlùmọ̀ àwọn ọ̀nà kan láti gbà mú ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn sunwọ̀n sí i.
14. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé alábòójútó àyíká onítara ń ru ìtara sókè nínú àwọn ẹlòmíràn?
14 Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò tí wọ́n jẹ́ onítara máa ń ru ìtara sókè nínú àwọn ẹlòmíràn. Alábòójútó àyíká kan ní Uganda fẹsẹ̀ rìn nínú igbó kìjikìji fún wákàtí kan láti baà lè bá arákùnrin kan lọ sí ibi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí ó ń tẹ̀ síwájú díẹ̀díẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń fẹsẹ̀ rìn lọ, òjò rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé, nígbà tí wọ́n débẹ̀, gbogbo ara wọn ló rin gbingbin. Nígbà tí ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́fà náà gbọ́ pé alábòójútó arìnrìn àjò ni àlejò wọn, orí wọn wú. Wọ́n mọ̀ pé àwọn òjíṣẹ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì wọn kò lè fi irú ọkàn-ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí agbo láéláé. Ní ọjọ́ Sunday tí ó tẹ̀ lé e, wọ́n wá sí ìpàdé fún ìgbà àkọ́kọ́, wọ́n sì sọ ìfẹ́ ọkàn wọn láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáde.
15. Ìrírí àtàtà wo ni alábòójútó àyíká onítara kan ní ní Mexico?
15 Ní ìpínlẹ̀ Oaxaca ti Mexico, alábòójútó àyíká kan sapá tí a kò retí lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ti gidi. Ó ṣètò láti wà nínú àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n fún òru mẹ́rin láti baà lè bẹ àwùjọ ẹlẹ́ni méje kan tí wọ́n ti di akéde Ìjọba wò. Fún ọjọ́ mélòó kan ó ń lọ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wọ̀nyí bí wọ́n ṣe ń jẹ́rìí láti inú àhámọ́ kan sí àhámọ́ kejì, tí wọ́n sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn, díẹ̀ nínú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí bá a lọ títí di ọ̀gànjọ́ òru. Alábòójútó àyíká onítara yìí kọ̀wé pé: “Ní òpin ìbẹ̀wò náà, èmi àti àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà kún fún ìdùnnú nítorí ìyọrísí ìṣírí tọ̀tún tòsì.”
16. Èé ṣe tí ó fi ṣàǹfààní gan-an nígbà tí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn bá ń fúnni níṣìírí?
16 Ẹ̀yin alábòójútó arìnrìn àjò, ẹ gbìyànjú láti jẹ́ afúnniníṣìírí. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù bẹ àwọn ìjọ tí ó wà ní Makedóníà wò, ó ‘fún wọn ní ìṣírí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀.’ (Ìṣe 20:1, 2) Ọ̀rọ̀ afúnniníṣìírí lè ṣèrànwọ́ púpọ̀ nínú dídarí tọmọdé tàgbà síhà àwọn góńgó tẹ̀mí. Nínú ọ́fíìsì ẹ̀ka ńlá kan tí ó jẹ́ ti Watch Tower Society, àkójọ ìsọfúnni ṣákálá kan ṣí i payá pé, àwọn alábòójútó àyíká ti fún iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni níṣìírí láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nípa àpẹẹrẹ àtàtà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba alákòókò kíkún, aya alábòójútó arìnrìn àjò pẹ̀lú ń jẹ́ orísun ìṣírí ńláǹlà.
17. Kí ni ìmọ̀lára àgbàlagbà alábòójútó àyíká kan nípa àǹfààní tí ó ní láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?
17 Ní pàtàkì, àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọkàn tí ó sorí kọ́ nílò ìṣírí. Àgbàlagbà alábòójútó àyíká kan kọ̀wé pé: “Nínú iṣẹ́ mi, apá tí ń mú inú mi dùn lọ́nà tí kò ṣeé fẹnu sọ ni àǹfààní ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ àti àwọn aláìlera nínú agbo Ọlọ́run. Àwọn ọ̀rọ̀ inú Róòmù 1:11, 12 ní ìtumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ fún mi, bí mo ṣe ń rí ìṣírí àti okun ńláǹlà gbà nígbà tí mo bá ‘ń fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kí wọ́n baà lè fìdí múlẹ̀ gbọn-in.’”
Àwọn Èrè Iṣẹ́ Onídùnnú Wọn
18. Àwọn ète tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ní?
18 Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ní ọkàn-ìfẹ́ dídára jù lọ nínú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Wọ́n fẹ́ láti fun ìjọ lókun, kí wọ́n sì gbé wọn ró nípa tẹ̀mí. (Ìṣe 15:41) Alábòójútó arìnrìn àjò kan ṣiṣẹ́ kára “láti fúnni níṣìírí, láti tuni lára, àti láti gbé ọkàn-ìfẹ́ láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣẹ lárugẹ, àti láti máa bá a nìṣó ní gbígbé nínú òtítọ́.” (Jòhánù Kẹta 3) Òmíràn ń fẹ́ láti mú kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dúró gbọ́n-in nínú ìgbàgbọ́. (Kólósè 2:6, 7) Rántí pé “ojúlówó alájọru àjàgà” ni alábòójútó arìnrìn àjò, kì í ṣe ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn. (Fílípì 4:3; Kọ́ríńtì Kejì 1:24) Ìbẹ̀wò rẹ̀ jẹ́ àkókò ìṣírí àti ìgbòkègbodò àrà ọ̀tọ̀, bákan náà sì ni ó jẹ́ àǹfààní fún ẹgbẹ́ àwọn alàgbà láti ṣàtúnyẹ̀wò ìtẹ̀síwájú tí wọ́n ti ní, kí wọ́n sì gbé àwọn góńgó kalẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la. Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ rẹ̀, àwọn akéde ìjọ, aṣáájú ọ̀nà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti àwọn alàgbà lè retí láti gbéni ró àti láti runi sókè fún iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú. (Fi wé Tẹsalóníkà Kìíní 5:11.) Nígbà náà, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fi tọkàntọkàn ṣètìlẹ́yìn fún ìbẹ̀wò alábòójútó arìnrìn àjò, kí o sì lo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí alábòójútó àgbègbè ń ṣe dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.
19, 20. Báwo ni a ti ṣe san èrè fún àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn fún iṣẹ́ ìsìn àfòtítọ́ṣe wọn?
19 A ń bù kún àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn jìngbìnnì fún iṣẹ́ ìsìn àfòtítọ́ṣe wọn, wọ́n sì lè ní ìgbọ́kànlé pé, Jèhófà yóò bù kún wọn fún ohun rere tí wọ́n gbé ṣe. (Òwe 19:17; Éfésù 6:8) Georg àti Magdalena jẹ́ tọkọtaya àgbàlagbà kan tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́ arìnrìn àjò. Ní àpéjọpọ̀ kan ní Luxembourg, ẹnì kan tí Magdalena ti jẹ́rìí fún rí, ní ohun tí ó lé ní 20 ọdún sẹ́yìn tọ̀ ọ́ wá. Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí Magdalena fi sílẹ̀ fún obìnrin Júù yìí ni ó ru ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ nínú òtítọ́ sókè, kò pẹ́ kò jìnnà ó ṣe ìbatisí. Arábìnrin kan nípa tẹ̀mí tọ Georg wa, ẹni tí Georg rántí pé òún ṣèbẹ̀wò sí ilé rẹ̀ ní nǹkan bí 40 ọdún sẹ́yìn. Ìgbékalẹ̀ onítara rẹ̀ nípa ìhìn rere náà mú kí obìnrin náà àti ọkọ rẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ lá ń sọ pé, ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún Georg àti Magdalena.
20 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ amésojáde tí Pọ́ọ̀lù ṣe ní Éfésù mú ìdùnnú wá fún un, ó sì ti lè sún un láti ṣàyọlò àwọn ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírí gbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Níwọ̀n bí iṣẹ́ arìnrìn àjò ti máa ń ní fífúnni nígbà gbogbo nínú, àwọn tí ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀ ń láyọ̀, ní pàtàkì, nígbà tí wọ́n bá rí ìyọrísí rere iṣẹ́ wọn. A sọ fún alábòójútó àyíká kan tí ó ran alàgbà kan tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì lọ́wọ́ nínú lẹ́tà kan pé: “Ẹ ti jẹ́ ‘àrànṣe afúnnilókun’ ńláǹlà nínú ìgbésí ayé mi nípa tẹ̀mí—ju bí ẹ̀yín ti rò lọ. . . . Ẹ kò lè mọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ láéláé bí ẹ ti ṣe ran Ásáfù òde òní lọ́wọ́ tó, ẹni ‘tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ yẹ̀ tán.’”—Kólósè 4:11; Orin Dáfídì 73:2.
21. Èé ṣe tí o fi lè sọ pé Kọ́ríńtì Kìíní 15:58 kan ìgbòkègbodò àwọn alábòójútó arìnrìn àjò?
21 Kristẹni àgbàlagbà kan tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ àyíká fún ọ̀pọ̀ ọdún fẹ́ràn láti máa ronú lórí Kọ́ríńtì Kìíní 15:58, níbi tí Pọ́ọ̀lù ti rọni pé: “Ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” Dájúdájú, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa. Ẹ sì wo bí a ṣe kún fún ọpẹ́ tó pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn tìdùnnútìdùnnú gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ìríjú ti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Iwọ Ha Le Layọ Pẹlu Pupọ Lati Ṣe Bi?” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, May 15, 1991, ojú ìwé 28 sí 31.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsì?
◻ Èé ṣe tí a fi lè ka àwọn alábòójútó arìnrìn àjò sí “ìríjú àtàtà”?
◻ Àwọn kókó abájọ wo ni ó ń ran àwọn alábòójútó àyíká àti àgbègbè lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí ọ̀pọ̀ ohun rere?
◻ Èé ṣe tí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtara fi ṣe pàtàkì púpọ̀ fún àwọn tí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ arìnrìn àjò?
◻ Àwọn ète àtàtà wo ni àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ń fẹ́ láti fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn níṣìírí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Tọmọdé tàgbà lè jàǹfààní láti inú kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti àwọn aya wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Iṣẹ́ òjíṣẹ́ onítara tí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ń ṣe ń ru ìtara sókè nínú àwọn ẹlòmíràn