ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 12/15 ojú ìwé 5-8
  • Òtítọ́ Nípa Jésù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òtítọ́ Nípa Jésù
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìpìlẹ̀ fún Ìgbọ́kànlé
  • Ìdí Tí Wọn Kò Fi Gbà Gbọ́
  • Ṣíṣàwárí Jésù Gidi
  • Ẹni Náà Gan-an Tí a Ń Pè Ní Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Wa Nípa Jésù Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ṣé Lóòótọ́ Ló Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 12/15 ojú ìwé 5-8

Òtítọ́ Nípa Jésù

ÓDÀ bí ẹni pé àbá èrò orí àti ìméfòó nípa ẹni tí Jésù jẹ́ àti ohun tí ó gbé ṣe kò lópin. Ṣùgbọ́n Bíbélì fúnra rẹ̀ ńkọ́? Kí ni ó sọ fún wa nípa Jésù Kristi?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ní fífarabalẹ̀ ka Bíbélì, ìwọ yóò kíyè sí àwọn kókó pàtàkì wọ̀nyí:

◻ Jésù ni Ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run, àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.—Jòhánù 3:16; Kólósè 1:15.

◻ Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rúndún méjì sẹ́yìn, Ọlọ́run ta ìwàláàyè Jésù látaré sínú ilé ọlẹ̀ wúndíá kan tí ó jẹ́ Júù láti bí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn.—Mátíù 1:18; Jòhánù 1:14.

◻ Jésù kì í wulẹ̀ ṣe ènìyàn rere lásán. Ní gbogbo ọ̀nà, ó jẹ́ ìfihàn tòótọ́ ti àwọn àkópọ̀ ìwà rere ti Bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run.—Jòhánù 14:9, 10; Hébérù 1:3.

◻ Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jésù fi tìfẹ́tìfẹ́ bójú tó àìní àwọn tí a ni lára. Ó mú àwọn aláìsàn lára dá lọ́nà iṣẹ́ ìyanu, ó sì jí òkú dìde pẹ̀lú.—Mátíù 11:4-6; Jòhánù 11:5-45.

◻ Jésù pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé tí wàhálà bá, ó sì dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù yìí nìṣó.—Mátíù 4:17; 10:5-7; 28:19, 20.

◻ Ní Nísàn 14 (nǹkan bí April 1), ọdún 33 Sànmánì Tiwa, a fàṣẹ ọba mú Jésù, a gbẹ́jọ́ rẹ̀, a dájọ́ ikú fún un, a sì pa á lórí ẹ̀sùn èké ti ìdìtẹ̀ sí ìjọba.—Mátíù 26:18-20, 48–27:50.

◻ Ikú Jésù jẹ́ ìràpadà kan, ní títú aráyé tí ó gbà gbọ́ sílẹ̀ kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tí ó sì tipa báyìí ṣí ọ̀nà ìyè ayérayé sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Róòmù 3:23, 24; Jòhánù Kìíní 2:2.

◻ Ní Nísàn 16, a jí Jésù dìde, kété lẹ́yìn náà, ó sì padà sókè ọ̀run láti san ìtóye ìràpadà ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ fún Bàbá rẹ̀.—Máàkù 16:1-8; Lúùkù 24:50-53; Ìṣe 1:6-9.

◻ Gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Jèhófà yàn sípò, Jésù tí a jí dìde ní ọlá àṣẹ kíkún láti mú ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún ènìyàn ṣẹ.—Aísáyà 9:6, 7; Lúùkù 1:32, 33.

Nípa báyìí, Bíbélì fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni pàtàkì nínú mímú àwọn ète Ọlọ́run ṣẹ. Ṣùgbọ́n báwo ni o ṣe lè ní ìdánilójú pé Jésù gidi nìyí—Jésù inú ìtàn, tí a bí ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, tí ó sì rìn lórí ilẹ̀ ayé yìí ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn?

Ìpìlẹ̀ fún Ìgbọ́kànlé

A lè mú ọ̀pọ̀ iyè méjì kúrò nípa wíwulẹ̀ ka Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì láìní ẹ̀tanú. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò rí i pé àkọsílẹ̀ Bíbélì kì í ṣe òbu ìtàn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ti ìtàn àròsọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, a sọ orúkọ, àkókò pàtó, àti ibi tí nǹkan ti ṣẹlẹ̀ gan-an. (Fún àpẹẹrẹ, wo Lúùkù 3:1, 2.) Síwájú sí i, a fi àìlábòsí tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀, àti òtítọ́ inú tí ń gbin ìgbọ́kànlé sínú òǹkàwé ṣàpèjúwe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àwọn òǹkọ̀wé kò pọ́n ẹnikẹ́ni—àní wọn kò pọ́n ara wọn pàápàá—nítorí ọkàn-ìfẹ́ láti kọ àkọsílẹ̀ tí ó ṣeé gbára lé. Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ yóò rí i pé Bíbélì kún fún òtítọ́.—Mátíù 14:28-31; 16:21-23; 26:56, 69-75; Máàkù 9:33, 34; Gálátíà 2:11-14; Pétérù Kejì 1:16.

Síbẹ̀, ó tún kù. Àwárí ìwalẹ̀pìtàn ti fìdí àkọsílẹ̀ Bíbélì múlẹ̀ léraléra. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá ṣe ìbẹ̀wò sí Ibi Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀m̀báyé ti Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù, ìwọ́ lè rí òkúta kan tí àkọlé tí ó wà lára rẹ̀ dárúkọ Pọ́ńtíù Pílátù. Àwọn àwárí ìwalẹ̀pìtàn míràn jẹ́rìí sí Lísáníà àti Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, tí Bíbélì mẹ́nu kàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni gidi dípò àwọn ẹ̀dá àgbélẹ̀hùmọ̀ ti àwọn Kristẹni ìjímìjí. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ròyìn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì (Májẹ̀mú Tuntun) ni àwọn òǹkọ̀wé ìgbàanì bíi, Juvenal, Tacitus, Seneca, Suetonius, Pliny Kékeré, Lucian, Celsus, àti òpìtàn Júù náà, Josephus, lo ọ̀pọ̀ yanturu ìtọ́kasí láti jẹ́rìí sí.a

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n wà láàyè ní ọ̀rúndún kìíní tẹ́wọ́ gba àwọn àkọsílẹ̀ tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì láìjanpata. Àní àwọn ọ̀tá ìsìn Kristẹni pàápàá kò sẹ́ ìjótìítọ́ ohun tí a ròyìn pé Jésù sọ, tí ó sì ṣe. Ní ti ṣíṣeé ṣe náà pé lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ àsọdùn nípa ẹni tí ó jẹ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n F. F. Bruce ṣàlàyé pé: “Dájúdájú, kò lè rọrùn rárá bí àwọn òǹkọ̀wé kan ti rò, láti hùmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù ní àwọn ọdún ìjímìjí wọnnì, nígbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ ṣì wà láàyè, tí wọ́n lè rántí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ àti ohun tí kò ṣẹlẹ̀. . . . Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò lè dágbá lé kíkọ àkọsílẹ̀ tí kò pé pérépéré (ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti mímọ̀ọ́mọ̀ yí òkodoro òtítọ́ po), èyí tí àwọn tí inú wọn yóò dùn gidigidi láti tú u fó yóò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́gán.”

Ìdí Tí Wọn Kò Fi Gbà Gbọ́

Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ṣì ń ṣiyè méjì. Bí wọ́n ti ronú pé àkọsílẹ̀ Bíbélì jẹ́ ìtàn àròsọ, wọ́n fi ìháragàgà wá inú àwọn àkọsílẹ̀ tí ìjótìítọ́ wọn kò dájú, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìwọ̀nyí bí ohun tí ó ṣeé gbà gbọ́! Èé ṣe? Ó hàn gbangba pé, àkọsílẹ̀ Bíbélì ní àwọn nǹkan tí ọ̀pọ̀ àwọn amòye òde òní kò fẹ́ láti gbà gbọ́ nínú.

Nínú ìwé rẹ̀, Union Bible Companion, tí a tẹ̀ jáde ní 1871, S. Austin Allibone gbé ìpèníjà kan dìde sí àwọn oníyèméjì. Ó kọ̀wé pé: “Béèrè lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tí ó sọ pé òún ń ṣiyè méjì nípa jíjóòótọ́ ìtàn Ìhìn Rere, ìdí tí ó ní fún gbígbà gbọ́ pé Cæsar kú sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin, tàbí pé Póòpù Leo Kẹta ni ó dé Olú Ọba Charlemagne ládé gẹ́gẹ́ bí Olú Ọba Ìwọ̀ Oòrùn ní ọdún 800? . . . A gba gbogbo ìfìtẹnumọ́kéde náà gbọ́ . . . tí a ṣe nípa àwọn ọkùnrin wọ̀nyí; ìyẹ́n sì jẹ́ nítorí pé a ní ẹ̀rí ìtàn nípa ìjótìítọ́ wọn. . . . Bí ó bá jẹ́ pé, lẹ́yìn pípèsè irú ẹ̀rí bí èyí, ẹnikẹ́ni ṣì kọ̀ láti gbà gbọ́ síbẹ̀, a óò pa wọ́n tì gẹ́gẹ́ bí òmùgọ̀ olóríkunkun tàbí òpè paraku. Nígbà náà, kí ni ká wá sọ nípa àwọn tí wọ́n ń sọ pé àwọn kò tí ì gbà gbọ́, láìka ọ̀pọ̀ ẹ̀rí yanturu tí a pèsè nísinsìnyí nípa ìjóòótọ́ Ìwé Mímọ́ sí? . . . Wọn kò fẹ́ láti gba ohun tí yóò rẹ ìgbéraga wọn sílẹ̀ gbọ́, tí yóò sì fagbára mú wọn láti gbé ìgbésí ayé tí ó yàtọ̀.”

Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn oníyèmejì kan ní àwọn ìsúnniṣe tí ó fara sin fún kíkọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ìṣòro tí wọ́n ní kò ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣeé gbà gbọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14) Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n sọ pé wọ́n jẹ́ Kristẹni ti kó wọnú àlámọ̀rí ìṣèlú ti ayé yìí jinlẹ̀jinlẹ̀, àní wọ́n ti lọ́wọ́ nínú àwọn ogun onítàjẹ̀sílẹ̀ pàápàá. Dípò mímú ara wọn bá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì mu, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fẹ́ kí Bíbélì mú ara rẹ̀ bá ọ̀pá ìdiwọ̀n tiwọn mu.

Ronú pẹ̀lú, nípa ọ̀ràn ìwà híhù. Jésù fún ìjọ tí ń bẹ ní Tíátírà ní ìmọ̀ràn lílágbára nítorí fífàyè gba ìwà panṣágà. Ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni ẹni tí ń wá inú kíndìnrín àti ọkàn-àyà, èmi yóò sì fi fún yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ yín.”b (Ìṣípayá 2:18-23) Síbẹ̀, kò ha jẹ́ òtítọ́ pé ọ̀pọ̀ tí ń sọ pé wọ́n jẹ́ Kristẹni ti sọ ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù nù bí? Wọn yóò kúkú kọ ohun tí Jésù sọ dípò kí wọ́n kọ ọ̀nà ìwà pálapàla wọn sílẹ̀.

Bí wọ́n ti ní ìtẹ̀sí láti má ṣe tẹ́wọ́ gba Jésù inú Bíbélì, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti ṣẹ̀dá Jésù tiwọn tí wọ́n hùmọ̀. Wọ́n jẹ̀bi híhùmọ̀ ìtàn àròsọ tí wọ́n fẹ̀sùn èké rẹ̀ kan àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere. Wọ́n rọ̀ mọ́ apá ìgbésí ayé Jésù tí wọ́n fẹ́ láti tẹ́wọ́ gbà, wọ́n kọ ìyókù, wọ́n sì fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ díẹ̀ ti àwọn fúnra wọn kún un. Ní tòótọ́, amòye alárìnkiri, olùṣèyípadà ìbáṣepọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tiwọn kì í ṣe Jésù inú ìtàn tí wọ́n sọ pé àwọ́n ń wá; kàkà bẹ́ẹ̀, ó wulẹ̀ jẹ́ ìhùmọ̀ kan tí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ agbéraga ronú wòye rẹ̀.

Ṣíṣàwárí Jésù Gidi

Jésù sakun láti mú ọkàn-àyà àwọn tí ebi ń pa fún òtítọ́ àti òdodo ní ti gidi wà lójúfò. (Mátíù 5:3, 6; 13:10-15) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń dáhùn padà sí ìkésíni Jésù pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ̀yin yóò sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.

Jésù gidi ni a kò lè rí nínú àwọn ìwé tí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ òde òní kọ; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè rí i nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù, tí ó ti di ibi tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti ń gbèèrú. O lè rí Jésù tí ó jẹ́ ẹni ìtàn nínú ẹ̀dà Bíbélì rẹ. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa rẹ̀? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò láyọ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s?, orí 5, ojú ìwé 55 sí 70, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

b Nínú Bíbélì, nígbà míràn, kíndìnrín máa ń dúró fún èrò àti èrò ìmọ̀lára ẹni tí ó jinlẹ̀ jù lọ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

ÀWỌN Ọ̀RÚNDÚN ÌṢELÁMÈYÍTỌ́

Ṣíṣe lámèyítọ́ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ ní ohun tí ó ju 200 ọdún sẹ́yìn, nígbà tí ará Germany ọlọgbọ́n èrò orí náà, Hermann Samuel Reimarus (1694 sí 1768), kéde pé: “A lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ìyàtọ̀ kínníkínní hàn láàárín ẹ̀kọ́ àwọn Àpọ́sítélì nínú ìwé wọn àti ohun tí Jésù Fúnra Rẹ̀ nígbà ayé Rẹ̀ polongo, tí ó sì kọ́ni.” Láti ìgbà Reimarus, a ti kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ láti ronú lọ́nà kan náà.

Ìwé náà, The Real Jesus, sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn olùṣelámèyítọ́ nígbà àtijọ́ kò ka ara wọn sí apẹ̀yìndà. Kàkà bẹ́ẹ̀, “wọ́n wo ara wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tí ó túbọ̀ jẹ́ ojúlówó nítorí jíjá ara wọn gbà kúrò lọ́wọ́ ìdè ìgbàgbọ́ aláìjampata àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán.” Wọ́n ronú pé, ṣíṣe lámèyítọ́ Ìwé Mímọ́ jẹ́ “irú ìsìn Kristẹni kan tí a wẹ̀ mọ́.”

Òkodoro òtítọ́ tí ń bani nínú jẹ́ náà ni pé Kirisẹ́ńdọ̀mù ti di ibi tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti ń gbèèrú. Ẹ̀kọ́ nípa àìleèkú ọkàn, Mẹ́talọ́kan, àti iná ọ̀run àpáàdì jẹ́ kìkì díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí ó lòdì sí Bíbélì. Ṣùgbọ́n kì í ṣe àwọn òǹkọ̀wé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ni ó fa yíyí òtítọ́ po yìí. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, wọ́n gbógun ti àwọn ipa ẹ̀kọ́ èké tí ó kọ́kọ́ fara hàn ní ìdajì ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ìpẹ̀yìndà ti “wà lẹ́nu iṣẹ́” láàárín àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni. (Tẹsalóníkà Kejì 2:​3, 7) A lè ní ìgbọ́kànlé pé ohun tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jẹ́ àkọsílẹ̀ ìtàn àti ẹ̀kọ́ tòótọ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

NÍGBÀ WO NI A KỌ ÀWỌN ÌWÉ ÌHÌN RERE?

Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣelámèyítọ́ Májẹ̀mú Tuntun rin kinkin mọ́ ọn pé a kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere lẹ́yìn tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sọ tí ṣẹlẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, nítorí náà, àfàìmọ̀ ni kò fi ní àṣìṣe nínú.

Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí fi hàn pé a tètè kọ ìwé Mátíù, Máàkù, àti Lúùkù. Àwọn àmì ẹsẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú àwọn ẹ̀dà ìwé àfọwọ́kọ kan ti Mátíù fi hàn pé ìkọ̀wé tí a kọ́kọ́ ṣe wáyé ní ọdún 41 Sànmánì Tiwa. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìwé Lúùkù ni a kọ láàárín ọdún 56 àti 58 Sànmánì Tiwa, nítorí ìwé Ìṣe (tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ọdún 61 Sànmánì Tiwa ni a parí rẹ̀) fi hàn pé ẹni tí ó jẹ́ òǹkọ̀wé rẹ̀, Lúùkù, ti ṣàkójọ “ìròyìn lẹ́sẹẹsẹ àkọ́kọ́,” ti Ìhìn Rere rẹ̀ tán. (Ìṣe 1:⁠1) A ronú pé Ìhìn Rere Máàkù ni a ṣàkójọ rẹ̀ ní Róòmù nígbà ìfisẹ́wọ̀n àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lákọ̀ọ́kọ́ tàbí lẹ́ẹ̀kejì​—⁠bóyá láàárín 60 ọdún àti ọdún 65 Sànmánì Tiwa.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Craig L. Blomberg fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú kíkọ tí a kọ àwọn Ìhìn Rere wọ̀nyẹn ṣáájú. Ó sọ pé kódà nígbà tí a bá fi Ìhìn Rere Jòhánù kún un, èyí tí a kójọ ní òpin ọ̀rúndún kìíní, “a ṣì sún mọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà gidigidi ju ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìtàn ìgbésí ayé ìgbàanì lọ ní ìfiwéra. Fún àpẹẹrẹ, àwọn méjì tí wọ́n kọ́kọ́ sọ ìtàn ìgbésí ayé Alexander Ńlá, Arrian àti Plutarch, kọ ọ́ ni ohun tí ó ju irinwó ọdún lẹ́yìn ikú Alexander ní ọdún 323 ṣááju Sànmánì Tiwa, síbẹ̀ àwọn òpìtàn ní gbogbogbòò gbà pé wọ́n ṣeé gbà gbọ́. Àwọn ìtàn àgbàyanu nípa ìgbésí ayé Alexander ti gbèèrú bí àkókò ti ń lọ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọ́n wáyé ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn àwọn òǹkọ̀wé méjì wọ̀nyí.” Ó kéré tán, àwọn apá tí ó jẹ́ ti onítàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì dájúdájú yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà kan náà tí àwọn ìtàn tí kì í ṣe ti ìsìn ní.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Gbogbo ènìyàn ni yóò kún fún ìdùnnú gíga lọ́lá nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́