ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 2/1 ojú ìwé 14-19
  • “Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ẹ Kò Rí i Rí, Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ẹ Kò Rí i Rí, Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Wọ́n Gbọ́
  • Ẹ̀mí Tí Ó Fi Hàn
  • Bí Ó Ṣe Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Gbára Lé Ọlọ́run
  • Fífi Ìfẹ́ Wa Hàn Fún Un
  • Iwọ Yoo Ha Dahun Pada Si Ifẹ Jesu Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Kí Ẹ Lè “Mọ Ìfẹ́ Kristi”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ìtọ́ni Jésù Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Jẹ́rìí Kúnnákúnná
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • “Jésù . . . Nífẹ̀ẹ́ Wọn Dé Òpin”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 2/1 ojú ìwé 14-19

“Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ẹ Kò Rí i Rí, Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀”

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò máa wò ó nísinsìnyí, síbẹ̀ ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ẹ sì ń yọ̀ gidigidi.”—PÉTÉRÙ KÍNÍ 1:8.

1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnì kankan tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé lónìí tí ó tí ì rí Jésù, báwo ni àwọn ènìyàn kan tí wọ́n jẹ́ onísìn ṣe sakun láti fi ìfọkànsìn hàn sí i?

KÒ SÍ ẹnikẹ́ni tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí tí ó rí Jésù Kristi rí. Síbẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Lọ́dọọdún ní January 9, ní Manila, orílẹ̀-èdè Philippines, a máa ń wọ́ ère Jésù Kristi lórí àgbélébùú kiri ojú pópó ní àkókò ayẹyẹ híhẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ jù lọ, tí ó gba àfiyèsí jù lọ, tí ó sì jẹ́ ti ìsìn tí ó gbajúmọ̀ ní orílẹ̀-èdè náà. Àwọn èrò tí a ti ru ìmọ̀lára wọn sókè yóò máa tira wọn síwájú; àwọn ènìyàn tilẹ̀ máa ń gùn lórí ara wọn nínú ìsapá amẹ́mìígbóná láti fọwọ́ kan ère náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ó pésẹ̀ láti wò ó ni ó jẹ́ pé kìkì ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyẹyẹ yìí nìkan ni ó fà wọ́n mọ́ra. Síbẹ̀, láìsí iyè méjì àwọn kan lára wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jésù látọkànwá. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyẹn, wọ́n lè fi àgbélébùú sọ́rùn tàbí kí wọ́n máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Bí ó ti wù kí ó rí, a ha lè ka irú ìbọ̀rìṣà bẹ́ẹ̀ sí ìjọsìn tòótọ́ bí?

2, 3. (a) Àwọn wo lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ni wọ́n rí i ní ti gidi, tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? (b) Àwọn mìíràn wo ní ọ̀rúndún kìíní ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jésù, tí wọ́n sì gbà gbọ́ nínú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò fojú ará wọn rí i rí?

2 Ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń bẹ ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù ti Jùdíà, Samáríà, Péríà, àti Gálílì tí wọ́n rí Jésù Kristi kòrókòró, tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n fetí sílẹ̀ bí ó ti ń ṣàlàyé àwọn òtítọ́ amúnilọ́kànyọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n fojú rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe. Àwọn kan lára àwọn wọ̀nyí di àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olùfọkànsìn, bí a ti mú wọn gbà gbọ́ dájú pé òun ni “Kristi náà, Ọmọkùnrin Ọlọ́run alààyè.” (Mátíù 16:16) Ṣùgbọ́n, àwọn tí àpọ́sítélì Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó ní ìmísí sí kò sí lára àwọn wọ̀nyí.

3 Àwọn tí Pétérù kọ̀wé sí wà ní àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù tí í ṣe Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà, Éṣíà, àti Bítíníà—tí gbogbo wọ́n wà ní àgbègbè Turkey òde òní. Àwọn ni Pétérù kọ̀wé sí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò máa wò ó nísinsìnyí, síbẹ̀ ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ẹ sì ń yọ̀ gidigidi pẹ̀lú ìdùnnú ayọ̀ aláìṣeéfẹnusọ tí a sì ṣe lógo.” (Pétérù Kíní 1:1, 8) Báwo ni wọ́n ṣe wá mọ Jésù Kristi dórí nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti lílo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?

4, 5. Báwo ni àwọn ènìyàn tí wọn kò rí Jésù rí ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti láti nígbàgbọ́ nínú rẹ̀?

4 Ó ṣe kedere pé, àwọn kan wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù jẹ́rìí fún àwọn ogunlọ́gọ̀ tí wọ́n wá síbi ayẹyẹ Pẹ́ńtíkọ́sì ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Lẹ́yìn ayẹyẹ náà, ọ̀pọ̀ ọmọ ẹ̀yìn dúró ní Jerúsálẹ́mù láti baà lè rí ìtọ́ni gbà síwájú sí i láti ọ̀dọ̀ àwọn àpọ́sítélì. (Ìṣe 2:9, 41, 42; fi wé Pétérù Kíní 1:1.) Nígbà ìrìn-àjò míṣọ́nnárì tí ó ṣe léraléra, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ onítara nìṣó láàárín àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní àgbègbè tí Pétérù lẹ́yìn náà fi lẹ́tà Bíbélì àkọ́kọ́ tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀ ránṣẹ́ sí.—Ìṣe 18:23; 19:10; Gálátíà 1:1, 2.

5 Èé ṣe tí àwọn ènìyàn, tí wọn kò rí Jésù rí wọ̀nyí, fi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidigidi tó bẹ́ẹ̀? Ní ọjọ́ wa, èé ṣe ti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ sí i, yíká ayé, ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀?

Ohun Tí Wọ́n Gbọ́

6. (a) Ká ní o ti gbọ́ tí Pétérù ń jẹ́rìí nípa Jésù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, kí ni ìwọ ì bá ti kọ́? (b) Báwo ni èyí ṣe nípa lórí nǹkan bí 3,000 tí ó pésẹ̀?

6 Bí ìwọ bá ti wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí Pétérù bá àwùjọ aláyẹyẹ yẹn sọ̀rọ̀ ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, kí ni ìwọ ì bá ti kọ́ nípa Jésù? Láìsí iyè méjì kankan, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fi hàn pé Ọlọ́run ni ó rán an. Ó fi hàn pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ pa Jésù, kò sí nínú sàréè mọ́ ṣùgbọ́n a ti jí i dìde, a sì ti gbé e ga sí òkè ọ̀run sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ó fi hàn pé, Jésù, ní tòótọ́, ni Kristi, Mèsáyà náà tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé nípa rẹ̀. Ó fi hàn pé, nípasẹ̀ Jésù Kristi, a tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé, wọ́n lè jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn láti inú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kíákíá nípa àwọn ohun arabaríbí tí Ọlọ́run ń ṣe nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀. A gún ọkàn àyà ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù níbi ayẹyẹ náà ní kẹ́ṣẹ́, nǹkan bí 3,000 sì ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 2:14-42) Bí o bá ti wà níbẹ̀, ìwọ yóò ha ti gbé irú ìgbésẹ̀ onípinnu bẹ́ẹ̀ bí?

7. (a) Ká ní o wà ní Áńtíókù nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wàásù níbẹ̀, kí ni ìwọ ì bá ti kọ́? (b) Èé ṣe tí àwọn kan lára àwọn ogunlọ́gọ̀ náà fi di onígbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?

7 Ká ní o wà lára àwọn tí wọ́n pésẹ̀ nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́ni ní Áńtíókù ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù ti Gálátíà, ohun mìíràn wo ni ìwọ ì bá ti kọ́ nípa Jésù? Ìwọ ì bá ti gbọ́ tí Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé dídá tí àwọn alákòóso ní Jerúsálẹ́mù dájọ́ ikú fún Jésù jẹ́ ohun tí àwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀. Ìwọ ì bá sì ti gbọ́ nípa ẹ̀rí àwọn tí ó fojú rí àjíǹde Jésù pẹ̀lú. Àlàyé Pọ́ọ̀lù pé jíjí tí Jèhófà jí Jésù dìde kúrò nínú ikú jẹ́rìí sí i pé, ní tòótọ́, èyí gan-an ni Ọmọkùnrin Ọlọ́run, ì bá ti wú ọ lórí. Inú rẹ kò ha sì ní dùn, ká ní ìwọ ti kọ́ pé, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ìgbàgbọ́ nínú Jésù ń mú kí ó ṣeé ṣe lè sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun bí? (Ìṣe 13:16-41, 46, 47; Róòmù 1:4) Ní mímọ ìjẹ́pàtàkì ohun tí wọ́n ń gbọ́, àwọn kan ní Áńtíókù di ọmọ ẹ̀yìn, ní fífi ìtara ṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àní bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ túmọ̀ sí pé wọn yóò dojú kọ inúnibíni gbígbóná janjan.—Ìṣe 13:42, 43, 48-52; 14:1-7, 21-23.

8. Ká ní o wà ní ìpàdé ní ìjọ Éfésù nígbà tí wọ́n rí lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí wọn gbà, kí ni ìwọ ì bá ti kọ́?

8 Bí ó bá jẹ́ pé o ti dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ní Éfésù ńkọ́, ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù ti Éṣíà, nígbà tí a rí lẹ́tà onímìísí tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ń bẹ níbẹ̀ gbà? Kí ni ìwọ ì bá ti kọ́ nínú rẹ̀ nípa ipa iṣẹ́ Jésù nínú ète Ọlọ́run? Nínú lẹ́tà yẹn, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé, nípasẹ̀ Kristi gbogbo ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ni a óò mú pa dà wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, pé ẹ̀bùn Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè, pé ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó ti kú lójú ìwòye Ọlọ́run nítorí àìṣedéédéé wọn ni a ti sọ di ààyè nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi, àti pé gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìpèsè yí, ó tún ṣeé ṣe lẹ́ẹ̀kan sí i fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn láti di àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́.—Éfésù 1:1, 5-10; 2:4, 5, 11-13.

9. (a) Kí ni ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fòye mọ̀ bóyá ìwọ fúnra rẹ lóye ìjẹ́pàtàkì ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Éfésù? (b) Báwo ni ohun tí àwọn ará tí Pétérù mẹ́nu kàn tí wọ́n ń gbé ní àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù kọ́ nípa Jésù ṣe nípa lórí wọn?

9 Ìmọrírì fún gbogbo èyí yóò ha ti mú kí ìfẹ́ rẹ fún Ọmọkùnrin Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i bí? Ìfẹ́ yẹn yóò ha ti nípa lórí ìgbésí ayé rẹ ojoojúmọ́, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fúnni níṣìírí nínú orí 4 sí 6 nínú ìwé Éfésù bí? Irú ìmọrírì bẹ́ẹ̀ yóò ha ti sún ọ láti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ohun àkọ́múṣe rẹ nínú ìgbésí ayé bí? Láti inú ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ìmoore fún Ọmọkùnrin rẹ̀, ìwọ yóò ha ti ṣe àtúnṣe tí ó pọn dandan kí ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run baà lè jẹ́ ohun tí o darí àfiyèsí sí nínú ìgbésí ayé rẹ? (Éfésù 5:15-17) Nípa ọ̀nà tí ohun tí àwọn Kristẹni ní Éṣíà, Gálátíà, àti àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù míràn kọ́ gbà nípa lórí wọn, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sí wọn pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí [Jésù Kristi] rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. . . . Ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ẹ sì ń yọ̀ gidigidi pẹ̀lú ìdùnnú ayọ̀ aláìṣeéfẹnusọ tí a sì ṣe lógo.”—Pétérù Kíní 1:8.

10. (a) Láìsí iyè méjì, kí ni ó fi kún ìfẹ́ tí àwọn Kristẹni ìjímìjí ní fún Jésù? (b) Báwo ni àwa pẹ̀lú ṣe lè jàǹfààní?

10 Láìsí iyè méjì, ohun mìíràn wà tí ó fi kún ìfẹ́ tí àwọn Kristẹni ìjímìjí wọ̀nyẹn tí Pétérù kọ̀wé sí ní fún Ọmọkùnrin Ọlọ́run. Kí ni ohun yẹn? Nígbà tí Pétérù yóò fi kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, ó kéré tán méjì nínú ìwé Ìhìn Rere—Mátíù àti Lúùkù—ti wà káàkiri. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí wọn kò rí Jésù rí lè ka àwọn àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere wọ̀nyí. Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìwé Ìhìn Rere kì í ṣe àkọsílẹ̀ tí a hùmọ̀; wọ́n ní gbogbo àmì tí a fi lè dá ìtàn tí ó ṣeé gbára lé jù lọ mọ̀. Nínú àwọn àkọsílẹ̀ onímìísí wọ̀nyẹn, a rí ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó ń mú kí ìfẹ́ wa fún Ọmọkùnrin Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i.

Ẹ̀mí Tí Ó Fi Hàn

11, 12. Kí ni ó wà nínú ẹ̀mí tí Jésù fi hàn sí àwọn ènìyàn míràn tí ó mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?

11 Níbẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé Jésù, a kọ́ nípa bí ó ṣe bá àwọn ẹ̀dá ènìyàn míràn lò. Nísinsìnyí pàápàá, ní ohun tí ó lé ní 1,960 ọdún lẹ́yìn tí ó ti kú, ẹ̀mí tí ó fi hàn gún ọkàn àyà àwọn ènìyàn ní kẹ́ṣẹ́. Gbogbo ẹni tí ó wà láàyè ni àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ gbé ẹrù ìnira kà lórí. Ọ̀pọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ni a ti bá lò lọ́nà tí kò fi ìdájọ́ òdodo hàn, wọ́n ti bá àìsàn jìjàkadì, tàbí fún àwọn ìdí mìíràn ìjákulẹ̀ ti mú kí wọ́n nímọ̀lára ìnilára. Sí gbogbo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn àyà ni èmi, ẹ̀yin yóò sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.

12 Jésù fi ìmọ̀lára onídàníyàn hàn fún àwọn òtòṣì, àwọn tí ebi ń pa, àti àwọn tí inú wọ́n bà jẹ́. Nígbà tí àwọn àyíká ipò mú kí ó pọn dandan, ó tilẹ̀ bọ́ ogunlọ́gọ̀ rẹpẹtẹ lọ́nà ìyanu. (Lúùkù 9:12-17) Ó dá wọn sílẹ̀ kúrò nínú àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ asọnidẹrú. Ó tún gbé ìgbàgbọ́ wọn nínú ìpèsè Ọlọ́run láti mú òpin dé bá ìnilára ti ìṣèlú àti ti ọrọ̀ ajé ró. Jésù kò tẹ ẹ̀mí àwọn tí a ti ni lára tẹ́lẹ̀ fọ́. Lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti pẹ̀lú ìfẹ́, ó fi òye gbé àwọn onínú tútù sókè. Ó mú ìtura wá fún àwọn tí wọ́n dà bí esùsú tí a ti pa lára tí ó ti tẹ̀ àti àwọn tí wọ́n dà bí òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú tí iná rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Láti ìgbà náà títí di àkókò yí, orúkọ rẹ̀ ń múni ní ìrètí, àní nínú ọkàn àyà àwọn tí wọn kò tí ì rí i rí pàápàá.—Mátíù 12:15-21; 15:3-10.

13. Èé ṣe tí ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lò fi fa àwọn ènìyàn mọ́ra?

13 Jésù kò fọwọ́ sí ìwà àìtọ́, síbẹ̀ ó fi òye hàn sí àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ṣe àṣìṣe nínú ìgbésí ayé ṣùgbọ́n tí wọ́n fi ìrònúpìwàdà hàn, tí wọ́n sì yíjú sí i fún ìrànlọ́wọ́. (Lúùkù 7:36-50) Òun yóò jókòó yóò sì bá àwọn ènìyàn tí a fojú tẹ́ńbẹ́lú láwùjọ jẹun bí ó bá rí i pé èyí yóò pèsè àǹfààní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. (Mátíù 9:9-13) Nítorí ẹ̀mí tí ó fi hàn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí wọ́n wà nínú irú àyíká ipò tí ó jọra, tí wọn kò tí ì rí Jésù rí, ni a ti sún láti wá mọ̀ ọ́n, kí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.

14. Kí ni ó fà ọ́ lọ́kàn mọ́ra nínú ọ̀nà tí Jésù gbà ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìsàn, àwọn aláàbọ̀ ara, tàbí àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀?

14 Ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣàìsàn tàbí tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara lò fi ẹ̀rí ìfẹ́ àti ìyọ́nú pẹ̀lú agbára rẹ̀ láti mú ìtura wá fún wọn hàn. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí ọkùnrin alárùn kan tí ẹ̀tẹ̀ bò tọ̀ ọ́ wá, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrànwọ́, ìrísí rẹ̀ kò mú kí Jésù fà sẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò sọ fún ọkùnrin náà pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àánú rẹ̀ ṣe òun, ọ̀ràn náà ti ga jù, kò sì sí ohun tí òun lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́. Ọkùnrin náà bẹ̀bẹ̀ pé: “Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Láìlọ́ tìkọ̀, Jésù nawọ́ rẹ̀ jáde, ó sì fi kan ọkùnrin adẹ́tẹ̀ náà, ní sísọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” (Mátíù 8:2, 3) Ní àkókò míràn, obìnrin kan wọ́nà àtirí ìmúláradá nípa fífọwọ́ kan etí ẹ̀wù rẹ̀ lọ́nà tí ẹnikẹ́ni kò fi lè fura. Jésù fi inú rere bá a lò, ó sì fi í lọ́kàn balẹ̀. (Lúùkù 8:43-48) Nígbà tí ó sì ṣalábàápàdé àwọn tí ń wọ́ lọ láti sìnkú, àánú opó tí ẹ̀dùn ọkàn dé bá náà ṣe é nítorí ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo ti kú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti kọ̀ láti fi agbára tí Ọlọ́run fún un ṣe iṣẹ́ ìyanu láti pèsè oúnjẹ fún ara rẹ̀, ó lò ó fàlàlà láti jí ọkùnrin tí ó kú yẹn dìde àti láti dá a pa dà fún ìyá rẹ̀.—Lúùkù 4:2-4; 7:11-16.

15. Báwo ni kíka àwọn àkọsílẹ̀ nípa Jésù àti ṣíṣàṣàrò lórí wọn ṣe nípa lórí rẹ?

15 Bí a ṣe ń ka àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí, tí a sì ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀mí tí Jésù fi hàn, a mú ìfẹ́ wa fún ẹni yìí tí ó fi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn rẹ̀ lélẹ̀ kí a baà lè wà láàyè títí láé jinlẹ̀ sí i. Bí a kò tilẹ̀ tí ì rí i rí, ọkàn wa ń fà sí i, a sì fẹ́ tẹ̀ lé ipasẹ̀ rẹ̀.—Pétérù Kíní 2:21.

Bí Ó Ṣe Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Gbára Lé Ọlọ́run

16. Ta ni Jésù darí àfiyèsí pàtàkì sí, kí sì ni ó fún wa níṣìírí láti ṣe?

16 Ju gbogbo ohun mìíràn lọ, Jésù darí àfiyèsí rẹ̀ àti tiwa sórí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run. Ó sọ ohun tí àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin jẹ́, ní sísọ pé: “Ìwọ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:36, 37) Ó ṣí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ létí pé: “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.” (Máàkù 11:22) Nígbà tí wọ́n dojú kọ ìṣòro líle koko nípa ìgbàgbọ́ wọn, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ . . . máa gbàdúrà nígbà gbogbo.”—Mátíù 26:41.

17, 18. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fi ìrẹ̀lẹ̀ gbára lé Bàbá rẹ̀? (b) Èé ṣe tí ohun tí ó ṣe fi ṣe pàtàkì gidigidi fún wa?

17 Jésù fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Àdúrà jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ̀. (Mátíù 14:23; Lúùkù 9:28; 18:1) Nígbà tí àkókò tó fún un láti yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, Jésù kò wulẹ̀ gbára lé èrò tirẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí, gbogbo áńgẹ́lì tí ń bẹ ní ọ̀run wà lábẹ́ ìdarí rẹ̀. Ó fi ìrẹ̀lẹ̀ lo odindi òru kan nínú àdúrà sí Bàbá rẹ̀. (Lúùkù 6:12, 13) Nígbà tí ó dojú kọ ìfàṣẹ-ọba-múni àti ikú oró, lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù yíjú sí Bàbá rẹ̀, ní gbígbàdúrà taratara. Òun kò ní èrò pé òun mọ Sátánì dáradára àti pé òun lè fi ìrọ̀rùn yanjú ohunkóhun tí ẹni búburú yẹn lè pète. Ní ti gidi, Jésù mọ bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí òun má ṣe fìdí rẹmi. Ẹ wo irú ẹ̀gàn tí ìfìdírẹmi rẹ̀ yóò mú wá fún Bàbá rẹ̀! Ẹ sì wo irú àdánù tí ì bá jẹ́ fún ìran aráyé, àwọn tí ìfojúsọ́nà ìyè wọn sinmi lórí ẹbọ tí Jésù yóò rú!

18 Jésù gbàdúrà léraléra—nígbà tí ó wà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù, ó tilẹ̀ tún lágbára sí i nínú ọgbà Gẹtisémánì. (Mátíù 26:36-44; Jòhánù 17:1-26; Hébérù 5:7) Nígbà tí ó ń jìyà lórí òpó igi ìdálóró, òun kò kẹ́gàn àwọn tí ó ṣáátá rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbàdúrà fún àwọn tí wọ́n ń hùwà láìmọ̀kan pé: “Bàbá, dárí jì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” (Lúùkù 23:34) Ó pa ìrònú rẹ̀ pọ̀ sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀, “ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni náà tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ kẹ́yìn lórí òpó igi ìdálóró jẹ́ àdúrà sí Bàbá rẹ̀. (Pétérù Kíní 2:23; Lúùkù 23:46) Ẹ wo bí a ti kún fún ìmoore tó pé, pẹ̀lú gbígbára lé Jèhófà pátápátá, Jésù fi ìṣòtítọ́ parí iṣẹ́ àyànfúnni tí Bàbá rẹ̀ ti gbé lé e lọ́wọ́! Bí a kò tilẹ̀ rí Jésù Kristi rí, ẹ wo bí a ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jinlẹ̀ tó nítorí ohun tí ó ṣe!

Fífi Ìfẹ́ Wa Hàn Fún Un

19. Ní fífi ìfẹ́ hàn fún Jésù, àwọn àṣà wo ni a ní láti yẹra fún pátápátá bí ohun tí kò yẹ?

19 Báwo ni a ṣe lè fi ẹ̀rí hàn pé ìfẹ́ tí a sọ pé a ní ju ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ? Níwọ̀n bí Bàbá rẹ̀, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́, ti ka yíyá ère àti wíwo àwọn wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ohun àjúbàfún léèwọ̀, dájúdájú, àwa kì yóò bọlá fún Jésù nípa fífi irú ẹ̀gbà ọrùn tí ó ní irú eré bẹ́ẹ̀ sí ọrùn wa tàbí nípa ríru irú ère bẹ́ẹ̀ káàkiri ojú pópó. (Ẹ́kísódù 20:4, 5; Jòhánù 4:24) Kì yóò túmọ̀ sí pé a ń bọlá fún Jésù rárá bí a bá ń lọ sí ààtò ìsìn, àní tí a tilẹ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà lọ́sẹ̀, bí a kò bá gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní àwọn apá yòó kù nínú ọ̀sẹ̀ náà. Jésù wí pé: “Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi. Ẹ̀wẹ̀ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni Bàbá mi yóò nífẹ̀ẹ́.”—Jòhánù 14:21, 23; 15:10.

20. Àwọn ohun wo ni yóò fi hàn bóyá a nífẹ̀ẹ́ Jésù ní tòótọ́?

20 Àṣẹ wo ni ó fún wa? Àkọ́kọ́ ni pé, kí a jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà, òun nìkan ṣoṣo. (Mátíù 4:10; Jòhánù 17:3) Nítorí ipa tí ó ń kó nínú ète Ọlọ́run, Jésù tún kọ́ni pé a gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú òun gẹ́gẹ́ bí Ọmọkùnrin Ọlọ́run, àti pé, a gbọ́dọ̀ fi ìyẹn hàn nípa ṣíṣe họ́ọ̀ sí àwọn iṣẹ́ búburú àti nípa rírìn nínú ìmọ́lẹ̀. (Jòhánù 3:16-21) Ó gbà wá nímọ̀ràn láti máa wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, ní fífi ìwọ̀nyí ṣáájú àníyàn nípa ohun ti ara. (Mátíù 6:31-33) Ó pàsẹ pé kí a nífẹ̀ẹ́ ẹnì kíní kejì bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. (Jòhánù 13:34; Pétérù Kíní 1:22) Ó sì yanṣẹ́ fún wa láti jẹ́ ẹlẹ́rìí nípa ète Ọlọ́run, àní bí òun pàápàá ti jẹ́. (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Ìṣípayá 3:14) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí Jésù rí, nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-ún Àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà lónìí ni ojúlówó ìfẹ́ fún un sún láti pa àwọn àṣẹ wọ̀nyẹn mọ́. Lọ́nàkọnà, rírí tí wọn kò fojú ara wọn rí Jésù rí kò bomi paná ìpinnu wọn láti ṣègbọràn sí i. Wọ́n rántí ohun tí Olúwa wọn sọ fún àpọ́sítélì Tọ́másì pé: “Ṣé nítorí pé ìwọ rí mi ni o fi gbà gbọ́? Aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí kò rí síbẹ̀ tí wọ́n sì gbà gbọ́.”—Jòhánù 20:29.

21. Báwo ni a ṣe ń jàǹfààní nínú lílọ sí ibi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi, èyí tí a óò ṣe ní ọdún yìí ní Sunday, March 23?

21 A nírètí pé ìwọ yóò wà lára àwọn wọnnì tí wọn yóò pé jọ kárí ayé sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní Sunday, March 23, 1997, láti rántí ọ̀nà títóbi lọ́lá jù lọ tí Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ hàn sí aráyé àti láti ṣe ìrántí ikú adúróṣinṣin Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi. Ohun tí a bá sọ tí a bá sì ṣe nígbà ayẹyẹ yẹn yẹ kí ó mú kí ìfẹ́ fún Jèhófà àti Ọmọkùnrin rẹ̀ jinlẹ̀ sí i, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìfẹ́ ọkàn láti pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ pọ̀ sí i.—Jòhánù Kíní 5:3.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Báwo ni àwọn tí a kọ ìwé àkọ́kọ́ ti Pétérù sí ṣe wá mọ Jésù, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?

◻ Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ohun tí àwọn Kristẹni ìjímìjí gbọ́ tí ó fà ọ́ lọ́kàn mọ́ra?

◻ Kí ni ó wà nínú ẹ̀mí tí Jésù fi hàn tí ó mú kí ìfẹ́ rẹ fún un jinlẹ̀ sí i?

◻ Èé ṣe tí fífi tí Jésù fi ìrẹ̀lẹ̀ gbára lé Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì sí wa?

◻ Báwo ni a ṣe lè fi ìfẹ́ wa fún Jésù Kristi hàn?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ọkàn wa fà sí Jésù nítorí ẹ̀mí tí ó fi hàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́