ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 3/1 ojú ìwé 25-28
  • Ìwọ Ha Ń Bẹ̀rù Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Àwọn Ẹlòmíràn Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Ń Bẹ̀rù Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Àwọn Ẹlòmíràn Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílóye Ìbẹ̀rù Náà
  • Èé Ṣe Tí O Fi Gbọ́dọ̀ Wó Ògiri Náà Lulẹ̀?
  • Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Ìdílé Rẹ
  • Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Ìjọ
  • Bí A Ṣe Lè Gbé Ipò Ìbátan Onígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé Ró
  • Fọkàn Tán Àwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Fífọkàntánni Ló Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Èèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Máa Ṣohun Táá Jẹ́ Káwọn Èèyàn Fọkàn Tán Ẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pátápátá Lákòókò Ìpọ́njú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 3/1 ojú ìwé 25-28

Ìwọ Ha Ń Bẹ̀rù Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Àwọn Ẹlòmíràn Bí?

‘KÒ SÍ ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀. Kò lè yé wọn. Ìṣòro tiwọn gan-an ti gba gbogbo àkókò wọn. Wọn kò lè ráyè tèmi.’ Ọ̀pọ̀ ń ronú lọ́nà yí, nítorí náà, wọ́n ń dé èrò wọn mọ́ra. Nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá béèrè pé, báwo ni nǹkan, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń fẹ́ sọ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Wọn kò wulẹ̀ lè ṣí ọkàn wọn payá.

Ní tòótọ́, àwọn kan wà tí wọn kò fẹ́ ìrànwọ́ àwọn ẹlòmíràn. Síbẹ̀, ogunlọ́gọ̀ wà, tí wọ́n ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì, ṣùgbọ́n, tí wọ́n ń bẹ̀rù láti ṣí ọkàn, èrò, àti ìrírí wọn payá. Ìwọ ha jẹ́ ọ̀kan lára wọn bí? Kò ha sí ẹnìkankan tí o lè gbẹ́kẹ̀ lé ní tòótọ́ bí?

Lílóye Ìbẹ̀rù Náà

Àìnígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ẹni kún inú ayé òde òní. Àwọn ọ̀dọ́ kì í bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀. Àwọn òbí kò lè bá ara wọn sọ̀rọ̀. Ìwọ̀nba ènìyàn ni ń ṣe tán láti bá àwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀. Nítorí wọn kò lè finú tán àwọn ẹlòmíràn, àwọn kan ń yíjú sí ọtí, oògùn líle, tàbí ìgbésí ayé ẹhànnà, láti gbìyànjú láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro wọn.—Òwe 23:29-35; Aísáyà 56:12.

Àìlóǹkà ìṣípayá àbòsí àti ìwà pálapàla ti mi ìgbọ́kànlé tí a ní nínú àwọn aláṣẹ, irú bí àwọn àlùfáà, dókítà, àwọn onítọ̀ọ́jú, àti àwọn olùkọ́ jìgìjìgì. Fún àpẹẹrẹ, ìdíwọ̀n kan sọ pé iye tí ó lé ní ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àlùfáà ní ń lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla. Òǹkọ̀wé kan sọ pé, àwọn “olùbàgbẹ́kẹ̀léjẹ́” wọ̀nyí “ń gbẹ́ ọ̀gbun, ihò àti kòtò sínú ìbáṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn.” Báwo ni èyí ṣe ń nípa lórí àwùjọ wọn? Ó ń pa ìgbẹ́kẹ̀lé run.

Ìtànkálẹ̀ àìsí ìwà rere mọ́ ti yọrí sí yánpọnyánrin inú ìdílé, débi pé, àwọn ìdílé tí kò bójú tó ẹrù iṣẹ́ wọn lọ́nà yíyẹ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di èyí tí ó wọ́pọ̀ jù lọ, kì í ṣe ohun àjèjì mọ́. Agbo ilé ti fìgbà kan jẹ́ àyíká tí a ti ń tọ́ni dàgbà. Lónìí, kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ibi tí a ti ń dúró rọpo sọ́kọ̀. Nígbà tí ọmọ kan bá dàgbà nínú ìdílé, níbi tí kò ti sí “ìfẹ́ni àdánidá,” àbájáde tí ó wọ́pọ̀ jẹ́ àìlègbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹlòmíràn nígbà tí ó bá dàgbà.—Tímótì Kejì 3:3.

Síwájú sí i, bí ipò ayé ṣe ń burú sí i, ó túbọ̀ ń rọrùn fún wa láti ní ìrírí onírora ọkàn. Nínú irú ipò kan náà, wòlíì Míkà kọ̀wé pé: “Má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.” (Míkà 7:5, NW) O lè nímọlára kan náà, lẹ́yìn ìjákulẹ̀ kékére kan, lẹ́yìn tí ẹnì kan ti ba ìgbẹ́kẹ̀lé tí o ní nínú rẹ̀ jẹ́, tàbí lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan tí ó wu ìgbésí ayé rẹ léwu. Ó ṣòro fún ọ láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ẹlòmíràn, o sì di ẹni tí a pa ìmọ̀lára rẹ̀ kú, tí o sì ń fi ojoojúmọ́ gbé lẹ́yìn ògiri ìmọ̀lára. (Fi wé Orin Dáfídì 102:1-7.) Ní tòótọ́, irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa bá ìgbésí ayé nìṣó, ṣùgbọ́n “ìbìnújẹ́ àyà” rẹ ń fi ojúlówó ìdùnnú èyíkéyìí nínú ìgbésí ayé dù ọ́. (Òwe 15:13) Òtítọ́ náà ni pé, fún ọ láti lera nípa tẹ̀mí, ní ti ìmọ̀lára, ní ti ẹ̀mí ìrònú, àti nípa ti ara, o gbọ́dọ̀ wó ògiri yẹn lulẹ̀, kí o sì kọ́ bí a ti ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ènìyàn. Ìyẹn ha ṣeé ṣe bí? Bẹ́ẹ̀ ni.

Èé Ṣe Tí O Fi Gbọ́dọ̀ Wó Ògiri Náà Lulẹ̀?

Fífinútán àwọn ẹlòmíràn ń mú ìtura wá fún ọkàn tí ìdààmú ti bá. Hánà ní irú ìrírí yìí. Ìgbéyàwó rẹ̀ tòrò, ilé rẹ̀ fọkàn rẹ̀ balẹ̀, ṣùgbọ́n, wàhálà bá a. Bí ó tilẹ̀ “wà nínú ìbìnújẹ́ ọkàn,” ó lo ọgbọ́n, “ó sì ń bẹ Olúwa” tagbáratagbára débi pé ètè rẹ̀ tí kò sọ̀rọ̀ síta bẹ̀rẹ̀ sí í mì. Bẹ́ẹ̀ ni, ó finú tán Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ó ṣí ọkàn rẹ̀ payá sí Élì, aṣojú Ọlọ́run. Kí ni àbájáde rẹ̀? “[Hánà] bá tirẹ̀ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́.”—Sámúẹ́lì Kíní 1:1-18.

Ọ̀pọ̀ jù lọ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ mọ àwọn àǹfààní tí ń bẹ nínú fífinúhanni. Fún àpẹẹrẹ, ṣíṣajọpín èrò àti ìrírí pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti bára wọn nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ lè ṣàǹfààní gidigidi. Àwọn aṣèwádìí dé ìparí èrò náà pé: “Yíyara ẹni sọ́tọ̀ ní ti èrò ìmọ̀lára ń kó àìsàn báni—a ní láti tú ọkàn wa jáde kí ọpọlọ wá baà lè jí pépé.” Ìwádìí sáyẹ́ǹsì tí ń pọ̀ sí i fìdí òtítọ́ òwe tí a mí sí náà múlẹ̀, tí ó sọ pé: “Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò lépa ìfẹ́ ara rẹ̀, yóò sì kọjú ìjà ńlá sí ohunkóhun tí í ṣe ti òye.”—Òwe 18:1.

Bí o kò bá ṣí ọkàn rẹ payá fún àwọn ẹlòmíràn, báwo ni wọn yóò ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́? Bí Jèhófà Ọlọ́run tilẹ̀ jẹ́ olùmọ ọkàn, àwọn ìdílé àti ọ̀rẹ́ rẹ kò mọ èrò ọkàn àti ìmọ̀lára rẹ—àyàfi bí o bá ṣí i payá fún wọn. (Kíróníkà Kíní 28:9) Nígbà tí ìṣòro náà bá jẹ́ rírú òfin Ọlọ́run, lílọ́tìkọ̀ láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ẹni yóò wulẹ̀ mú kí ọ̀ràn burú sí i ni.—Òwe 28:13.

Dájúdájú, àǹfààní sísọ wàhálà wa jáde fún àwọn ẹlòmíràn pọ̀ gan-an ju ewu dídi ẹni tí a pa lára lọ. Àmọ́ ṣáá o, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé, kí a tú kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ ara wa fó fún gbogbo ayé gbọ́ láìlo ọgbọ́n. (Fi wé Àwọn Onídàájọ́ 16:18; Jeremáyà 9:4; Lúùkù 21:16.) Òwe 18:24 kìlọ̀ pé: “Àwọn olùbákẹ́gbẹ́pọ̀ kan ń bẹ tí wọ́n ṣe tán láti fọ́ ẹnì kíní kejì yángá.” Ṣùgbọ́n, ó fi kún un pé: “Ọ̀rẹ́ kan ń bẹ tí ó sún mọ́ni pẹ́kípẹ́kí ju arákùnrin lọ.” Ibo ni a ti lè rí irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀?

Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Ìdílé Rẹ

Bí o bá ní ìṣòro, o ha ti gbìyànjú jíjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó rẹ tàbí àwọn òbí rẹ bí? Onímọ̀ràn kan, tí ó nírìírí dáradára, gbà pé: “Ní ti ọ̀pọ̀ ìṣòro, sísọ wọ́n jáde pátápátá ni gbogbo ohun tí a nílò.” (Òwe 27:9) Àwọn Kristẹni ọkọ, tí wọ́n ‘nífẹ̀ẹ́ aya wọn bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn,’ àwọn aya tí wọ́n “wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn,” àti àwọn òbí tí wọ́n fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹrù iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn láti ‘tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà nínú ìlànà èrò orí Jèhófà,’ yóò ṣiṣẹ́ kára láti jẹ́ olùfetísílẹ̀ tí ń fọ̀ràn rora ẹni wò àti agbaninímọ̀ràn tí ó ṣàǹfààní. (Éfésù 5:22, 33; 6:4) Bí òun kò tilẹ̀ ní aya tàbí ọmọ ní èrò ti ara, ẹ wo irú àpẹẹrẹ àgbàyanu tí Jésù fi lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yí!—Máàkù 10:13-16; Éfésù 5:25-27.

Bí ìṣòro náà bá ju èyí tí ìdílé lè bójú tó ńkọ́? Kò yẹ kí a nímọ̀lára ìdánìkanwà, nínú ìjọ Kristẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ta ní jẹ́ aláìlera, tí èmi kò sì jẹ́ aláìlera?” (Kọ́ríńtì Kejì 11:29) Ó ṣíni létí pé: “Ẹ máa bá a lọ ní ríru àwọn ẹrù ìnira ara yín lẹ́nì kíní kejì.” (Gálátíà 6:2; Róòmù 15:1) Láàárín àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tẹ̀mí, kò sí àníàní pé, a lè rí ju ‘arákùnrin kanṣoṣo lọ tí a bí fún ìgbà ìpọ́njú.’—Òwe 17:17.

Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Ìjọ

Nínú èyí tí ó lé ní 80,000 ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, àwọn ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú ayọ̀ yín,” ń bẹ níbẹ̀. (Kọ́ríńtì Kejì 1:24) Àwọn wọ̀nyí ni àwọn alàgbà. Aísáyà sọ pé: “Ẹnì kan yóò sì jẹ́ bí ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ẹ̀fúùfù, àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì; bí odò omi ní ibi gbígbẹ, bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.” Ohun tí àwọn alàgbà ń sakun láti jẹ́ nìyẹn.—Aísáyà 32:2; 50:4; Tẹsalóníkà Kíní 5:14.

Àwọn alàgbà dé ojú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè fún kí “ẹ̀mí mímọ́” tó “yàn wọ́n sípò.” Mímọ èyí yóò fún ìgbọ́kànlé rẹ nínú wọn lókun. (Ìṣe 20:28; Tímótì Kíní 3:2-7; Títù 1:5-9) Ohun tí o bá bá alàgbà kan sọ yóò jẹ́ ọ̀rọ̀ àṣírí títí ayé. Jíjẹ́ ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ó mú un tóótun.—Fi wé Ẹ́kísódù 18:21; Nehemáyà 7:2.

Àwọn alàgbà nínú ìjọ “ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn wọnnì tí yóò ṣe ìjíhìn.” (Hébérù 13:17) Èyí kò ha sún ọ láti gbọ́kàn lé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí bí? Ní ti ẹ̀dá, kì í ṣe gbogbo alàgbà ni ó tayọ nínú àwọn ànímọ́ kan náà. Ó lè jọ bíi pé àwọn kan rọrùn láti sún mọ́, wọ́n jẹ́ onínúure, tàbí olóye ju àwọn mìíràn lọ. (Kọ́ríńtì Kejì 12:15; Tẹsalóníkà Kíní 2:7, 8, 11) Èé ṣe tí o kò fi finú tán alàgbà kan tí ọkàn rẹ máa ń balẹ̀ nígbà tí o bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀?

Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kì í ṣe akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí a ń san owó fún. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ “àwọn ẹ̀bùn nínú ènìyàn,” tí Jèhófà pèsè láti ràn wá lọ́wọ́. (Éfésù 4:8, 11-13; Gálátíà 6:1) Lọ́nà wo? Ní fífi ìjáfáfá lo Bíbélì, wọn yóò lo agbára ìmúniláradá rẹ̀ fún ipò rẹ. (Orin Dáfídì 107:20; Òwe 12:18; Hébérù 4:12, 13) Wọn yóò gbàdúrà pẹ̀lú rẹ àti fún ọ. (Fílípì 1:9; Jákọ́bù 5:13-18) Ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ irú àwọn agbaninímọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè ṣe púpọ̀ láti wo ọkàn tí ìdààmú bá sàn, kí ó sì fúnni ní ìfọ̀kànbalẹ̀.

Bí A Ṣe Lè Gbé Ipò Ìbátan Onígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé Ró

Bíbéèrè fún ìrànwọ́, ìmọ̀ràn, tàbí wíwulẹ̀ fẹ́ kí a tẹ́tí síni, kì í ṣe àmì àìlera tàbí ti àìlèdá-nǹkan-ṣe. Ó wulẹ̀ jẹ́ dídojúkọ òtítọ́ bí ọ̀ràn ti rí pé, a jẹ́ aláìpé, àti pé kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n tán. Dájúdájú, agbaninímọ̀ràn àti olùfọkàntán títóbi lọ́lá jù lọ tí a ní ni Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run. A fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú onísáàmù tí ó kọ̀wé pé: “Olúwa ni agbára àti asà mi; òun ni àyà mí gbẹ́kẹ̀ lé, a sì ń ràn mí lọ́wọ́.” (Orin Dáfídì 28:7) A lè ‘tú ọkàn wa jáde’ sí i pátápátá nínú àdúrà, ní gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ìdánilójú pé ó ń gbọ́ wa, ó sì bìkítà fún wa.—Orin Dáfídì 62:7, 8; Pétérù Kíní 5:7.

Ṣùgbọ́n, báwo ni o ṣe lè kọ́ bí a ti ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn alàgbà àti àwọn mìíràn nínú ìjọ? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, yẹ ara rẹ wò. Ìbẹ̀rù rẹ ha lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bí? O ha ń fura sí ète àwọn ẹlòmíràn bí? (Kọ́ríńtì Kíní 13:4, 7) Ọ̀nà ha wà tí o lè gbà dín ewu dídi ẹni tí a pa lára kù bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Lọ́nà wo? Gbìyànjú láti di ojúlùmọ̀ àwọn ẹlòmíràn dáradára ní àyíká ipò tẹ̀mí. Bá wọn sọ̀rọ̀ ní àwọn ìpàdé ìjọ. Ẹ jọ lọ nínú iṣẹ́ ilé dé ilé. A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ láti jèrè ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ bí a ti ń ṣiṣẹ́ láti jèrè ọ̀wọ̀. Nítorí náà, mú sùúrù. Fún àpẹẹrẹ, bí o ti ń mọ olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí kan, ìgbọ́kànlé rẹ nínú rẹ̀ yóò máa gbèrú sí i. Sọ àníyàn rẹ fún un ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Bí ó bá dáhùn pa dà ní ọ̀nà tí ó yẹ, lọ́nà ìbánikẹ́dùn, tí ó fi ọgbọ́n inú hàn, nígbà náà, o lè gbíyànjú láti sọ púpọ̀ sí i fún un.

Àwọn ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn Jèhófà, pàápàá àwọn Kristẹni alàgbà, ń ṣiṣẹ́ kára ní fífarawé àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí Ọlọ́run ní, nínú ipò ìbátan wọn pẹ̀lú ara wọn lẹ́nì kíní kejì. (Mátíù 5:48) Èyí ń yọrí sí àyíká onígbẹkẹ̀lé nínú ìjọ. Alàgbà ọlọ́jọ́ pípẹ́ kan sọ pé: “Àwọn ará ní láti mọ ohun kan: Ohun yòó wù kí ẹnì kan ṣe, alàgbà kan kì í sọ ìfẹ́ Kristẹni tí ó ní fún un nù. Ó lè má nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n, ó ṣì nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, ó sì fẹ́ ràn án lọ́wọ́.”

Nítorí náà, kò sí ìdí láti bo ìṣòro rẹ mọ́ra. Bá ẹnì kan tí ó “tóótun nípa ti ẹ̀mí,” tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ẹrù ìnira rẹ sọ̀rọ̀. (Gálátíà 6:1) Rántí pé “ìbìnújẹ́ ní àyà ènìyàn ní ń dorí rẹ̀ kọ odò,” ṣùgbọ́n “ọ̀rọ̀ dídùn dà bí afárá oyin, ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ṣe ìlera fún egungun.”—Òwe 12:25; 16:24.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]

A lè ké sí Kristẹni èyíkéyìí láti ṣèrànwọ́ fún ìbátan, ọ̀rẹ́, tàbí arákùnrin nípa tẹ̀mí, tí ó ní ìṣòro ara ẹni. Ìwọ ha mọ bí o ṣe lè ṣèrànwọ́ bí?

Ọ̀jáfáfá Agbaninímọ̀ràn

jẹ́ ẹni tí ó ṣeé sún mọ́: Mátíù 11:28, 29; Pétérù Kíní 1:22; 5:2, 3

máa ń wá àkókò tí ó dára: Máàkù 9:33-37

máa ń wá àtilóye ìṣòro: Lúùkù 8:18; Jákọ́bù 1:19

kì í hùwà pa dà lọ́nà àṣerégèé: Kólósè 3:12-14

máa ń ranni lọ́wọ́ láti kojú ìrora ọkàn: Tẹsalóníkà Kíní 5:14; Pétérù Kíní 3:8

mọ ìwọ̀n rẹ̀: Gálátíà 6:3; Pétérù Kíní 5:5

máa ń fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó ṣe ṣàkó: Orin Dáfídì 19:7-9; Òwe 24:26

máa ń pa àṣírí mọ́: Òwe 10:19; 25:9

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́