Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọ́run Ó Ha Nílò Iṣẹ́ Ìyanu Bí?
ALBERT lé díẹ̀ ní 20 ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run. Ó gbìyànjú ọ̀pọ̀ ìsìn, ṣùgbọ́n, kò rí ìtẹ́lọ́rùn. Ní kíka àwọn apá díẹ̀ nínú Bíbélì, ó kọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn ènìyàn bíi Nóà, Ábúráhámù, Sárà, àti Mósè lò. Albert rí i pé a fa òun alára sún mọ́ Ọlọ́run Bíbélì. Ṣùgbọ́n, òun ha lè ní ìdánilójú pé, Ọlọ́run ń bẹ ní tòótọ́ bí?
Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, Albert wakọ̀ lọ sí ibi àdádó kan, níbi tí ó ti gbàdúrà pé, “Ọlọ́run, jọ̀wọ́ fún mi ní àmì kan—ohunkóhun tí ó lè fẹ̀rí hàn pé o wà.” Albert retí, retí títí. Ó rántí pé, nígbà tí kò sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ìfojúsọ́nà òun “di ìjákulẹ̀, ó di ìmọ̀lára àìjámọ́ nǹkan kan, ó di ìbínú.”
Gẹ́gẹ́ bí Albert, ọ̀pọ̀ rò pé àwọn ti wá Ọlọ́run kiri lórí asán. Ìwàásù àwọn àlùfáà lè ti dà wọ́n lọ́kàn rú tàbí kí ìṣòwò àwọn ajíhìnrere orí tẹlifíṣọ̀n ti mú ọkàn wọn pòrúurùu. Nítorí àgàbàgebè tí ó hàn gbangba láàárín ọ̀pọ̀ àwọn aládùúgbò wọn, àwọn kan kò mọ ohun tí àwọn ì bá gbà gbọ́. Síbẹ̀, Ọba Dáfídì ti Ísírẹ́lì ìgbàanì mú un dá ọmọkùnrin rẹ̀, Sólómọ́nì, lójú pé: “Bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí [Ọlọ́run], ìwọ óò rí i.”—Kíróníkà Kíní 28:9.
Tóò, nígbà náà, báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ṣí ara rẹ̀ payá? Ìwọ ha ní láti retí àmì—ìrírí kan tí ó ṣàjèjì tí yóò fẹ̀rí hàn ọ́ pé, Ọlọ́run ń bẹ bí? Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìsọfúnni lọ́ọ́lọ́ọ́ ti ìwé ìròyìn Time ti sọ, iye tí ó ju ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ará America ni wọ́n gbà gbọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu. Àpilẹ̀kọ náà tún sọ pé “àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí ń tètè gbilẹ̀ ní America ni àwọn ìjọ Mẹ́mìímẹ́mìí àti ti Onígbàgbọ́ Wò-ó-sàn, tí ìjọsìn wọn darí àfiyèsí sí ‘àmì àti iṣẹ́ àrà.’”
O ha nílò “àwọn àmì àti iṣẹ́ àrà” ní ti gidi láti lè gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run bí? Ó ti lo iṣẹ́ ìyanu nígbà àtijọ́. Láti ṣàkàwé: Sọ́ọ̀lù ará Tásù, tí ń ṣenúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Ọmọkùnrin Ọlọ́run, Jésù Kristi, ní ìrírí àràmàǹdà kan lójú ọ̀nà tí ó gba Jerúsálẹ́mù lọ sí Damásíkù. Fífi tí Jésù tí a jí dìde fara hàn án lọ́nà tí ó ní iṣẹ́ ìyanu nínú yìí yọrí sí yíyí Sọ́ọ̀lù lọ́kàn pa dà. (Ìṣe 9:1-22) Nípa báyìí, olùṣenúnibíni tẹ́lẹ̀ rí náà di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù—ọ̀kan nínú àwọn òléwájú alágbàwí ìsìn Kristẹni!
Ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìyanu ha máa ń fìgbà gbogbo mú irú ìdáhùnpadà lọ́nà rere bẹ́ẹ̀ wá bí? Ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ha sinmi lé níní tí ẹnì kan ní ìrírí iṣẹ́ ìyanu bí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ọmọkùnrin Ọlọ́run bá Sọ́ọ̀lù ará Tásù sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu. Ìwọ ha ní láti retí iṣẹ́ ìyanu bí?