Ó Ha Yẹ Kí Ọmọ Rẹ Lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Onílé Gbígbé Bí?
FINÚ wòye pé o ń gbé ní ìlú kékeré kan, ní orílẹ̀-èdè kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. O ní ọmọ púpọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá pé ọmọ ọdún 12, wọ́n yóò tẹ̀ síwájú sí ilé ẹ̀kọ́ gíga. Ní àgbègbè rẹ, àwọn ọmọ máa ń pọ̀ jù ilé ẹ̀kọ́ gíga lọ, wọn kì í ní àwọn ohun èlò tí ó pọn dandan, wọ́n kì í sì í ní olùkọ́ tí ó tó. Nígbà míràn, ìyanṣẹ́lódì máa ń jẹ́ kí a ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà pa lẹ́ẹ̀kan náà, fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ àti oṣù.
Ẹnì kan fún ọ ní ìwé pẹlẹbẹ dídán gbinrin kan tí ó ṣàpèjúwe ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé kan ní ìlú ńlá. O rí àwòrán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ aláyọ̀, tí wọ́n múra dáradára, tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú kíláàsì, ní ibi ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àti ní ibi ìkówèésí, tí wọ́n ní àwọn ohun èlò yíyẹ. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń lo kọ̀ǹpútà, wọ́n sì ń rẹjú nínú yàrá ilé gbígbé, tí ó mọ́ tónítóní, tí ó sì fani mọ́ra. O kà pé, ọ̀kan nínú àwọn góńgó ilé ẹ̀kọ́ náà ni láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ “láti lè ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó jíire jù lọ, tí ọpọlọ wọ́n gbé.” O tún kà síwájú sí i pé: “Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ni a retí pé kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà ìwà híhù tí ó fara jọ irú èyí tí a máa ń retí láàárín ìdílé, níbi tí a ti ń darí àfiyèsí sí ìwà rere, ìwà ọmọlúwàbí, ọ̀wọ̀ fún àwọn òbí àti àgbàlagbà, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, ìráragbaǹkan, inú rere, àìlábòsí àti ìwà títọ́.”
A ṣàyọlò ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ń rẹ́rìn-ín músẹ́, ní sísọ pé: “Àwọn òbí mi fún mi láǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ kan láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí ó dára jù lọ.” Ọ̀dọ́mọbìnrin kan sọ pé: “Ilé ẹ̀kọ́ ń peni níjà, ó sì ń múni lórí yá. Níhìn-ín, ó rọrùn láti kẹ́kọ̀ọ́.” Ìwọ yóò ha rán ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ lọ sí irú ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé bẹ́ẹ̀ bí?
Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ àti Ipò Tẹ̀mí
Gbogbo òbí tí ó bìkítà ń fẹ́ láti fún àwọn ọmọ wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ rere nínú ìgbésí ayé, láti lè ṣe èyí, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, tí ó sì wà déédéé ṣe pàtàkì. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àǹfààní iṣẹ́ ọjọ́ ọ̀la, ó sì ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti di àgbàlagbà tí ó lè gbọ́ bùkátà ara wọn àti ti ìdílé wọn ọjọ́ ọ̀la.
O lè béèrè pé: ‘Bí ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé kan bá pèsè ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí o jíire àti àwọn ìtọ́sọ́nà ìwà híhù kan, èé ṣe tí o kò fi lo àǹfààní tí ó nawọ́ rẹ̀ jáde?’ Ní dídáhùn ìbéèrè yẹn, ó yẹ kí àwọn Kristẹni òbí gbé kókó abájọ kan tí ó ṣe pàtàkì gidigidi yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà—ire tẹ̀mí ti àwọn ọmọ wọn. Jésù Kristi béèrè pé: “Ní ti gidi, àǹfààní wo ni ó jẹ́ fún ènìyàn kan láti jèrè gbogbo ayé kí ó sì pàdánù ọkàn rẹ̀?” (Máàkù 8:36) Dájúdájú, kò sí àǹfààní kankan nínú èyí rárá. Nítorí náà, kí wọ́n tó pinnu láti rán àwọn ọmọ wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé, ó yẹ kí àwọn Kristẹni òbí gbé ipa tí èyí lè ní lórí ìfojúsọ́nà àwọn ọmọ wọn fún ìyè àìnípẹ̀kun yẹ̀ wò.
Agbára Ìdarí Tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Yòó Kù Ń Ní
Àwọn ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé kan lè ní ìlànà ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ga gan-an. Ṣùgbọ́n ìlànà ìwà híhù àwọn tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà tàbí ti àwọn tí ń bójú tó irú ilé ẹ̀kọ́ náà pàápàá ńkọ́? Nípa irú àwọn ènìyàn tí yóò pọ̀ gidigidi ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní àwòrán ìrísí ìfọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀; yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.”—Tímótì Kejì 3:1-5.
Ìwà rere àti ipò tẹ̀mí tí ń dín kù yí jẹ́ káàkiri àgbáyé, ní gbígbé ìpèníjà kan kalẹ̀ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ti fífi ìlànà Bíbélì sílò. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ń wá sílé lójoojúmọ́ ń rí i pé, ìkẹ́gbẹ́pọ̀ wọn tí ó níwọ̀n pàápàá pẹ̀lú àwọn ọmọ ilé ẹkọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lè lo agbára ìdarí òdì lórí ipò tẹ̀mí wọn. Bíbomi paná agbára ìdarí yẹn lè jẹ́ ìjàkadì gidi fún àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí, àní pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́, ìmọ̀ràn, àti ìṣírí ojoojúmọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn.
Nígbà náà, báwo ni ipò àwọn ọmọ tí a rán lọ kúrò nílé láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé ti rí? Wọ́n dá wà, wọn kò rí ìrànlọ́wọ́ déédéé nípa tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn onífẹ̀ẹ́ gbà mọ́. Níwọ̀n bí wọ́n ti ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn fún wákàtí 24 lóòjọ́, ìdààmú náà láti ṣe ohun tí gbogbo ènìyàn ń ṣe ń lo agbára ìdarí lílágbára lórí èrò inú àti ọkàn àyà ọmọdé tí wọ́n ní ju bí ó ṣe lè lò ó lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ń gbé ilé. Akẹ́kọ̀ọ́ kan wí pé: “Ní ti ìwà rere, akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé wà nínú ewu láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”
Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà. Àwọn ẹgbẹ́ búburú a máa ba àwọn àṣà ìhùwà wíwúlò jẹ́.” (Kọ́ríńtì Kíní 15:33) Kò yẹ kí àwọn Kristẹni òbí ṣi ara wọn lọ́nà ní ríronú pé, àwọn ọmọ wọn kò ní jìyà kankan nípa tẹ̀mí bí wọ́n bá ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run. Ní sáà kan, àwọn ọmọ oníwà-bí-Ọlọ́run lè di ẹni tí ó yigbì sí àwọn ìlànà Kristẹni, wọ́n sì lè pàdánù gbogbo ìmọrírì fún àwọn nǹkan tẹ̀mí. Nígbà míràn, èyí kì í fara hàn kedere sí àwọn òbí títí di ẹ̀yìn ìgbà tí àwọn ọmọ bá fi ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé sílẹ̀. Nígbà náà, ẹ̀pa kì í bóró mọ́.
Ìrírí Clement jẹ́ ohun tí ó sábà ń ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Kí n tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé, mo nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, mo sì máa ń bá àwọn ará lọ sí iṣẹ́ ìsìn pápá. Ní pàtàkì, mo máa ń gbádùn lílọ́wọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ṣùgbọ́n, gbàrà tí mo ti wọ ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé ní ẹni ọdún 14, mo fi òtítọ́ sílẹ̀ pátápátá. Jálẹ̀ ọdún márùn-ún tí mo lò ní ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé, n kò lọ sí ìpàdé rí. Nítorí ẹgbẹ́ búburú, mo di ẹni tí ń lo oògùn líle, tí ń mu sìgá, àti ọtí àmuyíràá.”
Agbára Ìdarí Tí Àwọn Olùkọ́ Ń Ní
Ní ilé ẹ̀kọ́ èyíkéyìí, àwọn olùkọ́ oníwà ìbàjẹ́ lè wà tí wọ́n ń ṣi ipò ọlá àṣẹ wọn lò. Àwọn kan jẹ́ òǹrorò, wọ́n sì burú, nígbà tí àwọn mìíràn ń kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn nífà ní ti ìbálòpọ̀. Ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé, ó ṣeé ṣe kí a má fi ẹjọ́ àwọn olùkọ́ bẹ́ẹ̀ sùn.
Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ jù lọ olùkọ́ ń gbìdánwò tọkàntọkàn láti kọ́ àwọn ọmọ láti di mẹ́ńbà tí ó wúlò láwùjọ, láti bá ayé tí ó yí wọn ká dọ́gba, kí wọ́n má sì dá yàtọ̀. Ṣùgbọ́n, ìṣòro mìíràn nìyí fún àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí. Ìlànà ayé kì í sábà bá ìlànà Kristẹni mu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùkọ́ ń fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí láti bá ayé mu, Jésù wí pé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kì yóò jẹ́ “apá kan ayé.”—Jòhánù 17:16.
Bí ìṣòro bá yọjú ńkọ́ bí àwọn ọmọ bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì? Bí ó bá jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ àdúgbò ni àwọn ọmọ ń lọ, tí wọ́n sì ń gbé nílé, wọ́n lè jíròrò irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn. Ẹ̀wẹ̀, àwọn òbí lè tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà, wọ́n sì lè bá àwọn olùkọ́ wọn sọ̀rọ̀. Nítorí èyí, a tètè máa ń yanjú àwọn ìṣòro àti èdè àìyedè.
Ọ̀ràn náà yàtọ̀ pátápátá ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé. Irú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ wà lábẹ́ ìdarí àwọn olùkọ́ wọn ní gbogbo ìgbà. Bí àwọn ọmọ bá mú ìdúró wọn fún ìlànà Kristẹni, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́ ojoojúmọ́ àwọn òbí wọn. Nígbà míràn, àwọn ọmọ ń gbìyànjú láti jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run lábẹ́ irú àwọn àyíká ipò bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ọmọ kan tẹ̀ sí ìfẹ́ inú olùkọ́ rẹ̀.
Àìlómìnira Ìrìn
Láìdà bíi yunifásítì, níbi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti sábà máa ń lómìnira láti wá àti láti lọ bí ó bá ṣe wù wọ́n, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé kì í lómìnira ìrìn. Ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ wọ̀nyí kì í gbà kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fi ọgbà ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ àyàfi ní ọjọ́ Sunday, àwọn kan kò sì tilẹ̀ gba ìyẹn láàyè pàápàá. Eru, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 11, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé sọ pé: “Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ kò gbà kí a lọ sí ìpàdé rí, kí a má tilẹ̀ sọ ti iṣẹ́ ìsìn pápá. Nínú ilé ẹ̀kọ́ náà, ààtò ìsìn wà fún kìkì àwọn onísìn Kátólíìkì àti onísìn Mùsùlùmí. Akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ yan ọ̀kan nínú méjèèjì tàbí kí ó dojú kọ àtakò gbígbóná janjan láti ọ̀dọ̀ àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́. A tún ń fipá mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti kọrin orílẹ̀-èdè àti orin ṣọ́ọ̀ṣì.”
Nígbà tí àwọn òbí bá mú àwọn ọmọ wọn lọ sí irú ilé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, èrò wo ni wọ́n ń gbìn sí àwọn ògo wẹẹrẹ wọn lọ́kàn? Èrò náà lè jẹ́ pé, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé ṣe pàtàkì ju pípéjọ fún ìjọsìn àti nínípìn-ín nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn—àní ó tún ṣe pàtàkì ju pípa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run pàápàá.—Mátíù 24:14; 28:19, 20; Kọ́ríńtì Kejì 6:14-18; Hébérù 10:24, 25.
Ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé kan, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ń gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀, ṣùgbọ́n èyí pàápàá máa ń ṣòro nígbà míràn. Ọ̀dọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Blessing, tí ó jẹ́ ẹni ọdún 16, sọ èyí nípa ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé tí ó ń lọ: “Lójoojúmọ́, àwọn tí a fẹnu lásán pè ní Kristẹni máa ń kóra jọ láti gbàdúrà. Àwa tí a jẹ́ Ẹlẹ́rìí máa ń gbìyànjú láti rọ̀ wọ́n láti jẹ́ kí àwa náà lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tiwa, ṣùgbọ́n àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àgbà sọ fún wa pé, kò sẹ́ni tó mọ òkòlò ètò àjọ wa lọ́yọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n ń gbìyànjú láti fipá mú wa láti gbàdúrà pẹ̀lú wọn. Bí a bá kọ̀, wọn yóò fìyà jẹ wá. Jíjírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún àwọn olùkọ́ ń mú kí ọ̀ràn náà burú sí i. Wọ́n ń pè wá lónírúurú orúkọ, wọ́n sì máa ń ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àgbà fìyà jẹ wá.”
Dídáyàtọ̀ Gédégbé
Nígbà tí a bá mọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí lè ṣiṣẹ́ fún àǹfààní wọn. Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ lè yọ̀ǹda wọn láti má ṣe lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìsìn èké tí ó pọn dandan, tí ó lòdì sí ìgbàgbọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lè jáwọ́ nínú gbígbìyànjú láti mú wọn lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí kò gbámúṣé. Àǹfààní lè ṣí sílẹ̀ láti jẹ́rìí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn olùkọ́ wọn. Síwájú sí i, ó ṣeé ṣe kí a má ronú nípa àwọn tí ń tẹ̀ lé ìlànà Kristẹni pé, wọ́n ń hùwà àìtọ́ lílékenkà, wọ́n sì máa ń jèrè ọ̀wọ̀ àwọn olùkọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nígbà míràn.
Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀. Dídá yàtọ̀ gédégbé sábà máa ń jẹ́ kí ọ̀dọ́ kan di ẹni tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ń ṣe inúnibíni sí, tí wọ́n sì ń yọ ṣùtì sí. Yinka, ọ̀dọ́mọdékùnrin ọlọ́dún 15, tí ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé, sọ pé: “Ní ilé ẹ̀kọ́, bí a bá mọ̀ ọ́ sí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọn yóò fojú rẹ̀ rí màbo. Níwọ̀n bí wọ́n ti mọ ìdúró wa nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà rere, wọ́n máa ń dẹ pańpẹ́ sílẹ̀ láti lè mú wa.”
Ẹrù Iṣẹ́ Àwọn Òbí
Kò sí olùkọ́, ilé ẹ̀kọ́, tàbí kọ́lẹ́ẹ̀jì kan tí ó lè fi ẹ̀tọ́ gba iṣẹ́ sísọ àwọn ọmọ di olùṣèyàsímímọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Ìyẹn kì í ṣe iṣẹ́ tàbí ojúṣe wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pèsè ìtọ́ni pé, àwọn òbí ni wọ́n ní láti fúnra wọn bójú tó àìní tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin, bàbá, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè fi ìmọ̀ràn àtọ̀runwá yìí sílò bí àwọn ọmọ wọn bá wà lọ́nà jíjìn ní ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé, níbi tí a ti fi ṣíṣèbẹ̀wò mọ sí ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì lóṣù?
Àwọn àyíká ipò máa ń yàtọ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n, àwọn òbí Kristẹni máa ń sakun láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú gbólóhùn tí a mí sí yìí pé: “Dájúdájú bí ẹni kan kò bá pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, òun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.”—Tímótì Kíní 5:8.
Ọgbọ́n Mìíràn Ha Wà Tí A Lè Dá Bí?
Kí ni àwọn òbí lè ṣe bí ó bá dà bíi pé yíyàn méjì péré ni wọ́n ní—ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé tàbí ilé ẹ̀kọ́ àdúgbò tí kò ní àwọn ohun èlò tí ó yẹ? Àwọn kan tí wọ́n ti bá ara wọn ní ipò yí ń ṣètò fún ẹ̀kọ́ abẹ́lé láti fi kún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àdúgbò. Àwọn òbí mìíràn ya àkókò sọ́tọ̀ láti fúnra wọn kọ́ àwọn ọmọ wọn.
Nígbà míràn, àwọn òbí máa ń yẹra fún ìṣòro, nípa wíwéwèé dáradára ṣáájú kí àwọn ọmọ wọn tó dàgbà tó wíwọ ilé ẹ̀kọ́ gíga. Bí o bá ní àwọn ọ̀dọ́mọdé tàbí tí o ń wéwèé láti bímọ, o lè ṣàyẹ̀wò bóyá o lè rí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí ó dára ní àgbègbè rẹ. Bí kò bá sí, o lè kó lọ sí itòsí ọ̀kan.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí ti mọ̀ dáradára, ó ń béèrè òye, sùúrù, àti ọ̀pọ̀ àkókò láti gbin ìfẹ́ fún Jèhófà sínú ọmọ kan. Bí èyí bá ṣòro nígbà tí ọmọ kan bá ń gbé nílé, ẹ wo bí yóò ti ṣòro tó bí ọmọ náà bá ń gbé ọ̀nà jíjìn! Níwọ̀n bí ìyè àìnípẹ̀kun ọmọ kan ti wé mọ́ ọn, àwọn òbí gbọ́dọ̀ fọwọ́ dan-in dan-in mú pípinnu bóyá ó tọ́ láti jọ̀wọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ wọn fún ewu lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé tàbí kò tọ́, kí wọ́n sì fi àdúrà gbé e yẹ̀ wò. Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ojú ìwòye aláìronújinlẹ̀ tó láti fi ire tẹ̀mí ọmọ kan rúbọ fún àǹfààní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé! Èyí yóò dà bí sísá wọnú ilé kan tí ń jó láti yọ ohun ọ̀ṣọ́ kékeré kan—kìkì láti jẹ́ kí iná jóni pa.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọlọgbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó sì pa ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè a kọjá, à sì jẹ wọ́n níyà.” (Òwe 22:3) Ó sàn láti yẹra fún ipò búburú kan ju láti tún un ṣe lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Yóò bọ́gbọ́n mu láti ní èyí lọ́kàn nígbà tí o bá bi ara rẹ pé, ‘Ó ha yẹ kí ọmọ mi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé bí?’
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Rántí Ilé Ẹ̀kọ́ Onílé Gbígbé
“Ní ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé, a ń fi àǹfààní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tẹ̀mí du àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí. Ó jẹ́ àyíká rírorò gidigidi, tí ń kó ìdààmú báni láti hùwà àìtọ́.”—Rótìmí, tí ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé ní ọmọ ọdún 11 sì 14.
“Lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ ohun tí ó ṣòro gidigidi. Ọjọ́ Sunday nìkan ni mo lè lọ, láti lè ṣe ìyẹn, mo ní láti yọ́ jáde nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá wà lórí ìlà láti lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Inú mi kò fìgbà kankan dùn, nítorí pé, ní ilé, lílọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ ti mọ́ mi lára, mo sì máa ń jáde fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lọ́jọ́ Saturday àti Sunday. Ilé ẹ̀kọ́ kò jẹ́ ìrírí agbéniró. Mo pàdánù ọ̀pọ̀ nǹkan.”—Esther, tí àwọn olùkọ́ máa ń nà lẹ́gbà ní gbogbo ìgbà, nítorí pé, kì í lọ́wọ́ nínú ààtò ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì.
“Jíjẹ́rìí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni kò rọrùn ní ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé. Kò rọrùn láti dá yàtọ̀ gédégbé. Mo fẹ́ máa ṣe bíi ti àwọn ojúgbà mi. Bóyá ǹ bá ti túbọ̀ nígboyà bí ó bá ti ṣeé ṣe fún mi láti lọ sí àwọn ìpàdé, kí n sì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ṣùgbọ́n kìkì ìgbà ìsinmi nìkan ni mo lè ṣe ìyẹn, tí kò ju ìgbà mẹ́ta lọ lọ́dún. Bí o bá ní àtùpà tí a kò rọ epo sí, iná rẹ̀ yóò máa jó lọ́úlọ́ú. Bẹ́ẹ̀ náà ni nǹkan rí ní ilé ẹ̀kọ́.”—Lará, tí ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé ní ọmọ ọdún 11 sí 16.
“Nísinsìnyí tí n kò sí ní ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé mọ́, mo láyọ̀ pé mo lè lọ sí gbogbo àwọn ìpàdé, pé mo lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, kí n sì gbádùn ẹsẹ ojoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn yòó kù nínú ìdílé. Bí gbígbé ní ilé ẹ̀kọ́ tilẹ̀ ní àwọn àǹfààní kan, kò sí ohun tí ó ṣe pàtàkì ju ipò ìbátan mi pẹ̀lú Jèhófà.”—Naomi, tí ó yí bàbá rẹ̀ lọ́kàn pa dà láti mú un kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ onílé gbígbé.