A Polongo Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run Ní Aláyọ̀
“Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò pa dà, wọn óò wá sí Síónì ti àwọn ti orin, ayọ̀ àìnípẹ̀kun yóò sì wà ní orí wọn.”—AÍSÁYÀ 35:10.
1. Kí ni ayé nílò lójú méjèèjì?
LÓNÌÍ, ju ti ìgbàkigbà rí lọ, aráyé nílò ońṣẹ́ ìhìn rere. Àìní kánjúkánjú wà pé kí ẹnì kan sọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀, ẹlẹ́rìí onígboyà tí yóò kìlọ̀ fún àwọn olubi nípa ìparun tí ń bọ̀, tí yóò sì ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti rí àlàáfíà Ọlọ́run.
2, 3. Nínú ọ̀ràn ti Ísírẹ́lì, báwo ni Jèhófà ṣe mú ìlérí rẹ̀ tí a kọ sínú Ámósì 3:7 ṣẹ?
2 Ní àkókò Ísírẹ́lì, Jèhófà ṣèlérí láti pèsè irú àwọn ońṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Ní òpin ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa, wòlíì Ámósì wí pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.” (Ámósì 3:7, NW) Ní àwọn ọ̀rúndún tí ó tẹ̀ lé ìkéde yìí, Jèhófà ṣe àwọn ohun arabaríbí. Fún àpẹẹrẹ, ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó fìyà jẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ àyànfẹ́ gidigidi, nítorí pé wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀, wọ́n sì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ó tún fìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká, tí wọ́n ń ṣe jàgínníjàgínní nítorí pé Ísírẹ́lì ń jìyà. (Jeremáyà, orí 46 sí 49) Lẹ́yìn èyí, ní 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà mú ìṣubú agbára ayé ńlá ti Bábílónì wá, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé, ní 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, àṣẹ́kù Ísírẹ́lì pa dà wá sí ilẹ̀ wọn láti tún tẹ́ńpìlì kọ́.—Kíróníkà Kejì 36:22, 23.
3 Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó mi ayé tìtì, àti ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Ámósì, Jèhófà ṣí wọn payá ṣáájú fún àwọn wòlíì tí wọ́n ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́, tí ń kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì nípa ohun tí yóò dé bá wọn. Ní àárín gbùngbùn ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, ó gbé Aísáyà dìde. Ní àárín gbùngbùn ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa, ó gbé Jeremáyà dìde. Lẹ́yìn náà, bí ọ̀rúndún yẹn ti ń parí lọ, ó gbé Ìsíkẹ́ẹ̀lì dìde. Àwọn wọ̀nyí àti àwọn wòlíì olùṣòtítọ́ mìíràn, jẹ́rìí kúnnákúnná nípa àwọn ète Jèhófà.
Dídá Àwọn Ońṣẹ́ Ọlọ́run Mọ̀ Yàtọ̀ Lónìí
4. Kí ni ó fi bí aráyé ṣe nílò àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà tó hàn?
4 Lónìí ńkọ́? Ọ̀pọ̀ nínú ayé ń fura pé ohun abàmì kan fẹ́ ṣẹlẹ̀, bí wọ́n ti ń rí i ti àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ń bà jẹ́ sí i. Àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ sí òdodo máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn nígbà tí wọ́n bá rí àgàbàgebè àti ìwà búburú jáì tí ń ṣẹlẹ̀ nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù. Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu Ìsíkẹ́ẹ̀lì, wọ́n “ń kẹ́dùn, . . . wọ́n sì ń kígbe nítorí ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe láàárín rẹ̀.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 9:4) Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ kò mọ ète Jèhófà. A ní láti sọ fún wọn.
5. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé àwọn ońṣẹ́ yóò wà ní ọjọ́ wa?
5 Ẹnikẹ́ni lónìí ha ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ bíi ti Aísáyà, Jeremáyà, àti Ìsíkẹ́ẹ̀lì bí? Jésù fi hàn pé ẹnì kan yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò wáyé ní ọjọ́ wa, ó wí pé: “A óò sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Lónìí, ta ni ń mú àsọtẹ́lẹ̀ yí ṣẹ, tí ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́, oníwàásù ìhìn rere? Ìjọra tí ó wà láàárín ọjọ́ wa àti àkókò Ísírẹ́lì ìgbàanì ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn.
6. (a) Ṣàpèjúwe ìrírí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. (b) Báwo ni Ìsíkẹ́ẹ̀lì 11:17 ṣe ní ìmúṣẹ lórí Ísírẹ́lì ìgbàanì?
6 Ní àwọn ọjọ́ dídágùdẹ̀ ti Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn ènìyàn Jèhófà lóde òní, àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” lọ sí ìgbèkùn tí ó fara jọ èyí tí Ísírẹ́lì lọ ní Bábílónì. (Gálátíà 6:16) Wọ́n jìyà ìgbèkùn tẹ̀mí ní Bábílónì Ńlá, àgbájọ ìsìn èké àgbáyé, tí Kirisẹ́ńdọ̀mù jẹ́ apá títayọ jù lọ rẹ̀ tí ìbáwí tọ́ sí jù lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Ìsíkẹ́ẹ̀lì sọ fi hàn pé, a kò pa wọ́n tì. Ó wí pé: “Èmi [óò, NW] tilẹ̀ kó yín kúrò lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè; èmi óò sì kó yín jọ láti ilẹ̀ tí a ti tú yín ká sí, èmi óò sì fún yín ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 11:17) Láti lè mú ìlérí yẹn tí ó ṣe fún Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣẹ, Jèhófà gbé Kírúsì ará Páṣíà dìde, tí ó bi Agbára Ayé Bábílónì ṣubú, tí ó sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àṣẹ́kù Ísírẹ́lì láti pa dà sí ilẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n lónìí ńkọ́?
7. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ní 1919 ni ó fi hàn pé Jésù ti gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí Bábílónì Ńlá? Ṣàlàyé.
7 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, ẹ̀rí lílágbára wà pé Kírúsì Títóbi Jù kan wà lẹ́nu iṣẹ́. Ta ni òun í ṣe? Kì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Jésù Kristi, tí a gbé gorí ìtẹ́ láti ọdún 1914, nínú Ìjọba ọ̀run. Ọba títóbi lọ́lá yìí fi ìfẹ́ inú rere hàn sí àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró, tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí a dá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn tẹ̀mí, tí wọ́n sì pa dà sí “ilẹ̀” wọn, ipò tẹ̀mí wọn, ní ọdún 1919. (Aísáyà 66:8; Ìṣípayá 18:4) Nípa báyìí, Ìsíkẹ́ẹ̀lì 11:17 ní ìmúṣẹ ti òde òní. Ní ìgbàanì, ìṣubú Bábílónì pọn dandan láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti pa dà sí ilẹ̀ wọn. Lónìí, ìmúpadàbọ̀sípò Ísírẹ́lì Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀rí pé, Kírúsì Títóbi Jù ti bi Bábílónì Ńlá ṣubú. Áńgẹ́lì kejì ti Ìṣípayá orí 14 ni ó kéde ìṣubú yìí, nígbà tí ó kígbe pé: “Bábílónì Ńlá ti ṣubú, ẹni tí ó mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì ìbínú àgbèrè rẹ̀!” (Ìṣípayá 14:8) Ẹ wo irú àyípadà sí burúkú tí èyí jẹ́ fún Bábílónì Ńlá, ní pàtàkì fún Kirisẹ́ńdọ̀mù! Ẹ sì wo irú ìbùkún tí èyí jẹ́ fún àwọn Kristẹni tòótọ́!
8. Báwo ni ìwé Ìsíkẹ́ẹ̀lì ṣe ṣàpèjúwe ayọ̀ àwọn ènìyàn Ọlọ́run lẹ́yìn òmìnira wọn ní 1919?
8 Ní Ìsíkẹ́ẹ̀lì 11:18-20, a rí àpèjúwe tí wòlíì náà ṣe nípa ayọ̀ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, lẹ́yìn tí a mú wọn pa dà bọ̀ sípò. Ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ túmọ̀ sí wíwẹ Ísírẹ́lì mọ́ ní àwọn ọjọ́ Ẹ́sírà àti Nehemáyà. Ìmúṣẹ òde òní túmọ̀ sí ohun kan tí ó fara jọ ìyẹn. Ẹ jẹ́ kí a wo bí ó ṣe rí bẹ́ẹ̀. Jèhófà sọ pé: “Wọn óò sì wá [sí ilẹ̀ wọn], wọn óò sì mú gbogbo ohun ìríra rẹ̀ àti gbogbo ohun èérí rẹ̀ kúrò níbẹ̀.” Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti 1919, Jèhófà wẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́, ó sì fún wọn lókun lẹ́ẹ̀kan sí i láti ṣiṣẹ́ sìn ín. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí mú gbogbo àṣà àti ìgbàgbọ́ Bábílónì, tí ó ti sọ wọ́n dìbàjẹ́ lójú rẹ̀, kúrò ní àyíká wọn tẹ̀mí.
9. Àwọn ìbùkún pàtàkì wo ni Jèhófà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti 1919?
9 Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 19 ti sọ, Jèhófà ń bá a lọ ní sísọ pé: “Èmi óò sì fún wọn ní ọkàn kan, èmi óò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; èmi óò sì mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi óò sì fún wọn nì ọkàn ẹran.” Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ní 1919, Jèhófà mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró wà ní ìṣọ̀kan, ó fún wọn ní “ọkàn kan,” kí a sọ ọ́ ní ọ̀nà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n baà lè ṣiṣẹ́ sìn ín ní “ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sef. 3:9, NW) Síwájú sí i, Jèhófà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ láti fún wọn lókun nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí àti láti pèsè àwọn èso dáradára, tí a ṣàpèjúwe nínú Gálátíà 5:22, 23 nínú wọn. Dípò tí wọn ì bá sì fi jẹ́ ọlọ́kàn òkúta, afinigúnlágídi, Jèhófà fún wọn ní ọkàn àyà tí ó rọ̀, tí ó ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, tí ó jẹ́ onígbọràn, ọkàn àyà tí yóò dáhùn pa dà sí ìfẹ́ inú rẹ̀.
10. Èé ṣe tí Jèhófà fi bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó mú pa dà bọ̀ sípò láti 1919 síwájú?
10 Èé ṣe tí ó fi ṣe èyí? Jèhófà fúnra rẹ̀ ṣàlàyé. A kà nínú Ìsíkẹ́ẹ̀lì 11:20 pé: “Kí wọ́n lè rìn nínú àṣẹ mi, kí wọ́n sì lè pa ìlànà mi mọ́, kí wọ́n sì ṣe wọ́n: wọn óò sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi óò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.” Ísírẹ́lì Ọlọ́run kọ́ láti ṣègbọràn sí òfin Jèhófà dípò tí wọn yóò fi tẹ̀ lé èrò ti ara wọn. Wọ́n kọ́ láti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run láìbẹ̀rù ènìyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n dúró yàtọ̀ gédégbé sí àwọn afàwọ̀rajà Kristẹni ti Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ènìyàn Jèhófà ni wọ́n. Nítorí bẹ́ẹ̀, Jèhófà ṣe tán láti lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ rẹ̀, “olùṣòtítọ́ ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” rẹ̀.—Mátíù 24:45-47.
Ayọ̀ Àwọn Ońṣẹ́ Ọlọ́run
11. Báwo ni ìwé Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe ayọ̀ àwọn ènìyàn Jèhófà?
11 Ìwọ ha lè fojú yàwòrán ayọ̀ wọn nígbà tí wọ́n mọ ipò àǹfààní tí wọ́n ń gbádùn? Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, wọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà 61:10 ní àsọtúnsọ pé: “Èmi óò yọ̀ gidigidi nínú Olúwa. Ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.” A mú ìlérí Aísáyà 35:10 ṣẹ lórí wọn pé: “Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò pa dà, wọn óò wá sí Síónì ti àwọn ti orin, ayọ̀ àìnípẹ̀kun yóò sì wà ní orí wọn: wọn óò rí ayọ̀ àti inú dídùn gbà, ìkáàánú òun ìmí ẹ̀dùn yóò sì fò lọ.” Irú ayọ̀ tí àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run ti Jèhófà ní nìyẹn ní ọdún 1919, bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún láti wàásù ìhìn rere fún gbogbo aráyé. Láti ìgbà yẹn títí di ọjọ́ òní, wọn kò dẹ́kun ṣíṣe iṣẹ́ yìí, ayọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i. Nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jésù wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, níwọ̀n bí a óò ti pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run.’” (Mátíù 5:9, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró, ‘àwọn ọmọ Ọlọ́run,’ ti ń nírìírí ìjótìítọ́ ìkéde yẹn láti ọdún 1919 títí di òní.
12, 13. (a) Àwọn wo ni wọ́n dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà, iṣẹ́ wo sì ni wọ́n ṣe? (b) Ìdùnnú ńláǹlà wo ni àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà nírìírí rẹ̀?
12 Bí ọdún ti ń gorí ọdún, iye Ísírẹ́lì Ọlọ́run ń pọ̀ sí i títí di àwọn ọdún 1930, nígbà tí ìkójọ àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ẹni àmì òróró ń lọ sópin. Ìbísí nínú iye àwọn tí ń wàásù ìhìn rere náà ha dáwọ́ dúró bí? Kí a má rí i. Ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé ti bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn, àwọn wọ̀nyí sì ń dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Àpọ́sítélì Jòhánù rí ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí nínú ìran, ọ̀nà tí ó sì gbà ṣàpèjúwe wọn yẹ fún àfiyèsí: “Wọ́n . . . wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run; wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán tòru.” (Ìṣípayá 7:15) Bẹ́ẹ̀ ni, ọwọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá náà dí fún ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run. Nítorí èyí, nígbà tí iye àwọn ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù, lẹ́yìn 1935, àwọn olùṣòtítọ́ olùbákẹ́gbẹ́ wọ̀nyí ń bá iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà lọ ní pẹrẹwu pẹ̀lú ìbísí tí ń pọ̀ sí i.
13 Lọ́nà yí, Aísáyà 60:3, 4 ní ìmúṣẹ, pé: “Àwọn kèfèrí yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ, àti àwọn ọba sí títàn yíyọ rẹ. Gbé ojú rẹ sókè yíká, kí o sì wò; gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ: àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò ti ọ̀nà jíjìn wá, a óò sì tọ́jú àwọn ọmọ rẹ obìnrin ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.” Ayọ̀ tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mú wá fún Ísírẹ́lì Ọlọ́run ni a ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà fífani mọ́ra nínú Aísáyà 60:5, níbi tí a ti kà pé: “Nígbà náà ni ìwọ óò rí i, ojú rẹ óò sì mọ́lẹ̀, ọkàn rẹ yóò sì yí pa dà, yóò sì di ńlá: nítorí a óò yí ọrọ̀ òkun pa dà sí ọ, ipa àwọn Kèfèrí yóò wá sọ́dọ̀ rẹ.”
Ètò Àjọ Jèhófà Wà Lórí Ìrìn
14. (a) Ìran wo nípa àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run ni Ìsíkẹ́ẹ̀lì rí, àṣẹ wo sì ni ó gbà? (b) Kí ni àwọn ènìyàn Jèhófà lóde òní fòye mọ̀, kí sì ni ojúṣe wọn?
14 Ní 613 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ìsíkẹ́ẹ̀lì rí ìran nípa ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run, tí ó dà bíi kẹ̀kẹ́ ẹṣin, tí ó wà lórí ìrìn. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 1:4-28) Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún un pé: “Ọmọ ènìyàn, Lọ, tọ ilé Ísírẹ́lì lọ, kí o sì fi ọ̀rọ̀ mi bá wọn sọ̀rọ̀.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 3:4) Ní ọdún 1997 yìí, a fòye mọ̀ pé, ètò àjọ Jèhófà ti ọ̀run ṣì wà lórí ìrìn lọ́nà tí kò ṣeé dá dúró, láti mú ète Ọlọ́run ṣẹ. Nítorí náà, a ṣì rí i pé ó pọn dandan láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ète wọ̀nyẹn. Ní ọjọ́ rẹ̀, Ìsíkẹ́ẹ̀lì sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí ní tààràtà. Lónìí, a ń sọ̀rọ̀ láti inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí. Ẹ sì wo irú ìhìn iṣẹ́ tí ìwé yẹn ní fún aráyé! Bí ọ̀pọ̀ ti ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la, Bíbélì fi hàn pé nǹkan túbọ̀ burú gan-an—lọ́wọ́ kan náà, ó sì túbọ̀ dára gan-an—ju bí wọ́n ti rò lọ.
15. Èé ṣe tí ipò nǹkan fi burú ju bí ọ̀pọ̀ ti rò lónìí lọ?
15 Nǹkan túbọ̀ burú ju bí wọ́n ti rò lọ nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ́ nínú àwọn àpilẹ̀kọ tí ó ṣáájú, a óò pa Kirisẹ́ńdọ̀mù àti gbogbo ìsìn èké yòó kù run ráúráú láìpẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù ní 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Kì í ṣe ìyẹn nìkan, gbogbo ètò ìṣèlú àgbáyé tí a ṣàpèjúwe nínú ìwé Ìṣípayá gẹ́gẹ́ bí ẹranko ẹhànnà tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, ni a óò pa rẹ́ láìpẹ́, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tí wọ́n wà nítòsí Jerúsálẹ́mù rẹ́. (Ìṣípayá 13:1, 2; 19:19-21) Ní ọjọ́ Ìsíkẹ́ẹ̀lì, lọ́nà ṣíṣe kedere, Jèhófà ṣàpèjúwe ìpayà tí ìparun Jerúsálẹ́mù tí ń sún mọ́lé yóò kó báni. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò ní ìtumọ̀ tí ó túbọ̀ gbòòrò sí i, nígbà tí àwọn ènìyàn bá róye ìsúnmọ́lé ìparun ayé yìí. Jèhófà wí fún Ìsíkẹ́ẹ̀lì pé: “Nítorí náà kérora, ìwọ ọmọ ènìyàn, pẹ̀lú ṣíṣẹ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ, àti pẹ̀lú ìkérora kíkorò níwájú wọn. Yóò sì ṣe, nígbà tí wọ́n bá wí fún ọ pé, Èé ṣe tí ìwọ fi ń kérora? Ìwọ óò dáhùn wí pé, Nítorí ìhìn náà: nítorí pé ó dé: olúkúlùkù ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì ṣe àìlókun, olúkúlùkù ẹ̀mí yóò sì dá kú, gbogbo eékún ni yóò ṣe àìlágbára bí omi: kíyè sí i, ó dé, a óò sì mú un ṣẹ, ni Olúwa Ọlọ́run wí.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 21:6, 7; Mátíù 24:30) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ń bẹ gẹ́rẹ́ níwájú. Àníyàn jíjinlẹ̀ tí a ní fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa ń sún wa láti kéde ìkìlọ̀ náà, láti sọ “ìhìn” nípa ìrunú Jèhófà tí ń bọ̀.
16. Fún àwọn ọlọ́kàn tútù, èé ṣe tí ipò nǹkan fi dára ju bí ọ̀pọ̀ ti rò lọ?
16 Lọ́wọ́ kan náà, nǹkan túbọ̀ dára gan-an fún àwọn aláìlábòsí ọkàn ju bí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ti rò lọ. Lọ́nà wo? Ní ti pé Jésù Kristi ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí ó sì ń ṣàkóso nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Tímótì Kíní 1:15; Ìṣípayá 11:15) Àwọn ìṣòro aráyé, tí ó dà bí èyí tí kò lè yanjú, ni a óò tipasẹ̀ Ìjọba ọ̀run yẹn ṣẹ́pá láìpẹ́. Ikú, àìsàn, ìwà ìbàjẹ́, ebi, àti ìwà ọ̀daràn yóò di ohun àtijọ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò sì ṣàkóso lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan láìsí alátakò. (Ìṣípayá 21:3, 4) Aráyé yóò gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run—ipò ìbátan alálàáfíà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti láàárín ara wọn.—Orin Dáfídì 72:7.
17. Ìbísí wo ni ó ń mú kí ọkàn àyà àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀?
17 Ní àwọn apá ibì kan nínú ayé, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọlọ́kàn tútù ti wọ́n gbàfiyèsí ń dáhùn pa dà sí ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run yìí. Láti mẹ́nu kan àpẹẹrẹ díẹ̀ péré, ní èṣí, Ukraine ròyìn ìbísí ìpín 17 lórí ọgọ́rùn-ún nínú akéde. Mòsáńbíìkì ròyìn ìbísí ìpín 17 lórí ọgọ́rùn-ún, Lithuania sì ròyìn ìbísí ìpín 29 lórí ọgọ́rùn-ún. Rọ́ṣíà ní ìbísí ìpín 31 lórí ọgọ́rùn-ún, nígbà tí Albania ní ìbísí ìpín 52 lórí ọgọ́rùn-ún nínú akéde. Àwọn ìbísí wọ̀nyí dúró fún ẹgbẹẹgbàarùn-ún àwọn aláìlábòsí ọkàn, tí wọ́n fẹ́ gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run, tí wọ́n sì ti mú ìdúró wọn fún òdodo. Irú ìbísí yíyára kánkán bẹ́ẹ̀ ń mú ìdùnnú wá fún gbogbo ẹgbẹ́ ará Kristẹni.
18. Yálà àwọn ènìyàn fetí sílẹ̀ tàbí wọ́n kọ etí ikún sí wa, kí ni yóò jẹ́ ìṣarasíhùwà wa?
18 Àwọn ènìyàn ha ń dáhùn pa dà lọ́nà yíyára kánkán bẹ́ẹ̀ ní ibi tí o ń gbé bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a bá ọ yọ̀. Ṣùgbọ́n, ní àwọn ìpínlẹ̀ kan, ó ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí iṣẹ́ àṣelàágùn, kí a tó lè rí ẹyọ olùfìfẹ́hàn kan ṣoṣo pàápàá. Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sìn ní irú àwọn ìpínlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ha ń dẹ ọwọ́ wọn tàbí wọ́n ha ń sọ ìrètí nù bí? Rárá o. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí Ìsíkẹ́ẹ̀lì, nígbà tí Ó kọ́kọ́ pàṣẹ fún wòlíì ọ̀dọ́ náà láti wàásù fún àwọn Júù ará ìlú rẹ̀, pé: “Àti àwọn, bí wọn óò gbọ́, tàbí bí wọn óò kọ̀, (nítorí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n) síbẹ̀ wọn óò mọ̀ pé wòlíì kan ti wà láàárín wọn.” (Ísíkẹ́ẹ̀lì 2:5) Gẹ́gẹ́ bí Ìsíkẹ́ẹ̀lì, a ń bá a nìṣó ní sísọ fún àwọn ènìyàn nípa àlàáfíà Ọlọ́run, yálà wọ́n fetí sílẹ̀ tàbí wọn kọ etí ikún sí i. Nígbà tí wọ́n bá fetí sílẹ̀, ara wa máa ń yá gágá. Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá kọ etí ikún sí wa, tí wọ́n fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n tilẹ̀ ṣe inúnibíni sí wa, a máa ń fàyà rán an. A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Bíbélì sì sọ pé: “Ìfẹ́ . . . a máa fara da ohun gbogbo.” (Kọ́ríńtì Kíní 13:4, 7) Nítorí pé a ti lo ìfaradà nínú ìwàásù wa, àwọn ènìyàn mọ irú ẹni tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́. Wọ́n mọ ìhìn iṣẹ́ tí a ń jẹ́. Nígbà tí òpin bá dé, wọn yóò mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run.
19. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, àǹfààní ńláǹlà wo ni a ṣìkẹ́?
19 Àǹfààní kankan ha wà tí ó ju ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà lọ bí? Kò sí! Ayọ̀ títóbi jù lọ tí a ní ń wá láti inú ipò ìbátan tí a ní pẹ̀lú Ọlọ́run àti mímọ̀ pé a ń ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀. “Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí ó mọ ohùn ayọ̀ nì: Olúwa, wọn óò máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.” (Orin Dáfídì 89:15) Ǹjẹ́ kí a máa fìgbà gbogbo ṣìkẹ́ ìdùnnú jíjẹ́ ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run fún aráyé. Ǹjẹ́ kí a máa fi aápọn ṣe ipa tiwa nínú iṣẹ́ yìí, títí Jèhófà yóò fi sọ pé, ó tó gẹ́ẹ́.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Àwọn wo ni ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run lónìí?
◻ Báwo ni a ṣe mọ̀ pé, Bábílónì Ńlá ṣubú ní 1919?
◻ Kí ni ó jẹ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” lọ́kàn jù lọ?
◻ Èé ṣe tí ọjọ́ ọ̀la fi ṣókùnkùn ju bí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ti rò lọ?
◻ Fún àwọn ọlọ́kàn títọ́, èé ṣe tí ọjọ́ ọ̀la fi lè dára ju bí wọ́n ti rò lọ?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Nígbà tí wọ́n rí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí ń bà jẹ́ sí i, ọ̀pọ̀ fura pé ohun abàmì kan fẹ́ ṣẹlẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run ni àwọn ènìyàn tí ó láyọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé lónìí