Ó Ha Yẹ Kí O Gbà Gbọ́ Nínú Àtúnwáyé Bí?
ỌLỌ́GBỌ́N èrò orí náà, Plato, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì, so kíkó sínú ìfẹ́ mọ́ ìgbàgbọ́ àtúnwáyé. Ó gbà gbọ́ pé lẹ́yìn ikú ara, ọkàn, tí ó jẹ́ àìleèkú, yóò lọ sí “ilẹ̀ àkóso ìrísí rekete.” Láìní ara, yóò wà níbẹ̀ fún sáà kan, ní ríronú nípa ìrísí náà. Nígbà tí ó bá pa dà wá nínú ara mìíràn, ọkàn náà yóò rántí bí ẹní ń ṣe ìràn-ǹ-rán, yóò sì máa yán hànhàn fún ilẹ̀ àkóso ìrísí. Gẹ́gẹ́ bí Plato ti sọ, àwọn ènìyàn ń kó sínú ìfẹ́ nítorí pé wọ́n rí irú ìrísí ẹwà tí wọn kò lè rántí dáadáa, tí wọ́n sì ń wá, nínú olólùfẹ́ wọn.
Mímọ Orísun àti Ìpìlẹ̀ Rẹ̀
Ẹ̀kọ́ àtúnwáyé béèrè pé kí ọkàn jẹ́ àìleèkú. Nígbà náà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtúnwáyé ni a gbọ́dọ̀ tọpasẹ̀ rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Lórí ìpìlẹ̀ yí, àwọn kan rò pé ó pilẹ̀ ṣẹ̀ ní Íjíbítì ìgbàanì. Àwọn mìíràn gbà gbọ́ pé ó bẹ̀rẹ̀ ní Bábílónì ìjímìjí. Láti lè buyì kún ìsìn Bábílónì, àwùjọ àlùfáà rẹ̀ dábàá ẹ̀kọ́ ìṣípòpadà ọkàn. Wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé àwọn akọni ìsìn wọ́n jẹ́ àwọn baba ńlá olókìkí, tí wọ́n ti kú tipẹ́tipẹ́, tí wọ́n tún pa dà wáyé.
Ṣùgbọ́n, Íńdíà ni ìgbàgbọ́ nínú àtúnwáyé ti gbilẹ̀. Àwọn amòye ẹlẹ́sìn Híńdù ronú jinlẹ̀ gidigidi lórí àwọn ìṣòro àgbáyé ti ìwà ibi àti ìyà láàárín ẹ̀dá ènìyàn. Wọ́n béèrè pé, ‘Báwo ni a ṣe lè mú ìwọ̀nyí bá ìgbàgbọ́ náà pé olódodo ni Ẹlẹ́dàá mu?’ Wọ́n gbìyànjú láti yanjú ìforígbárí tí ó wà láàárín òdodo Ọlọ́run àti àjálù èèṣì pẹ̀lú ìka tí kò dọ́gba nínú ayé. Nígbà tí ó ṣe, wọ́n gbé “òfin kámà” kalẹ̀, òfin okùnfà àti àbájáde—‘ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúngbìn, ni yóò ká.’ Wọ́n gbé ‘ìsọfúnni amúǹkan-wàdéédéé’ kan kalẹ̀, níbi tí a ti ń san ẹ̀san ìwà ẹ̀yẹ tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan dá nínú ayé kan fún un nínú ayé tí ó tẹ̀ lé e.
“Kámà” wulẹ̀ túmọ̀ sí “ìwà.” A lè sọ pé ẹlẹ́sìn Híńdù kan ní kámà rere bí ó bá tẹ̀ lé àṣà tí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ìsìn tẹ́wọ́ gbà, a sì lè sọ pé ó ní kámà búburú bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwà, tàbí kámà rẹ̀, ń pinnu ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ nínú àtúnbí kọ̀ọ̀kan ní ìtòtẹ̀léra. Ọlọ́gbọ́n èrò orí náà, Nikhilananda, sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ni a bí pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìwà wọn, tí a gbé karí ìpìlẹ̀ ìwà wọn nínú ayé ìṣáájú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé apilẹ̀ àbùdá ni ó ń pinnu ìrísí wọn nípa ti ara. [Nípa báyìí] ènìyàn fúnra rẹ̀ ni olùpinnu kádàrá ara rẹ̀, òun ni olùgbé àyànmọ́ ara rẹ̀ kalẹ̀.” Ṣùgbọ́n, olórí góńgó náà ni láti bọ́ nínú ìyípoyípo ìṣípòpadà yí, kí ó sì wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Brahman—òtítọ́ gíga jù lọ. Èyí, ni a gbà gbọ́ pé ọwọ́ lè tẹ̀ nípa lílàkàkà fún ìwà tí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tẹ́wọ́ gbà àti jíjèrè àkànṣe ìmọ̀ ẹ̀sìn Híńdù.
Ẹ̀kọ́ àtúnwáyé tipa báyìí lo ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ rẹ̀, ó sì kọ́ òfin kámà lé e lórí. Ẹ jẹ́ kí a wo ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, sọ nípa àwọn èrò wọ̀nyí.
Ọkàn Ha Jẹ́ Àìleèkú Bí?
Láti dáhùn ìbéèrè yí, ẹ jẹ́ kí a yíjú sí ọlá àṣẹ gíga jù lọ lórí kókó yìí—Ọ̀rọ̀ tí Ẹlẹ́dàá mí sí. Nínú ìwé àkọ́kọ́ pàá nínú Bíbélì, Jẹ́nẹ́sísì, a kọ́ nípa ìtumọ̀ pípéye “ọkàn.” Nípa ìṣẹ̀dá ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, Bíbélì sọ pé: “OLÚWA Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó sì mí ẹ̀mí ìyè sí ihò imú rẹ̀; ènìyàn sì di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe pé ènìyàn ní ọkàn, ṣùgbọ́n òun gan-an ni ọkàn. Neʹphesh ni ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí a lò níhìn-ín fún ọkàn. Ó fara hàn nígbà 700 nínú Bíbélì, kò sì fìgbà kankan tọ́ka sí apá kan ẹ̀dá ènìyàn tí ó wà lọ́tọ̀ tí a kò lè fojú rí, ṣùgbọ́n ó máa ń fìgbà gbogbo tọ́ka sí ohun gidi kan tí a lè fojú rí.—Jóòbù 6:7; Orin Dáfídì 35:13; 107:9; 119:28.
Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn nígbà ikú? Gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù nígbà ikú yẹ̀ wò. Nígbà tí ó dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Ìwọ [óò] pa dà sí ilẹ̀; nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá, erùpẹ̀ sáà ni ìwọ, ìwọ óò sì pa dà di erùpẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ronú nípa ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí. Kí Ọlọ́run tó dá a láti inú erùpẹ̀, Ádámù kò sí níbì kankan. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, Ádámù pa dà sí ipò àìsí níbì kankan.
Kí a sọ ọ́ lọ́nà tí ó lè tètè yéni, Bíbélì kọ́ni pé ikú ni òdì kejì ìyè. Nínú Oníwàásù 9:5, 10, a kà pé: “Alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ní èrè mọ́; nítorí ìrántí wọn ti di ìgbàgbé. Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ rí ní ṣíṣe, fi agbára rẹ ṣe é; nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà òkú níbi tí ìwọ ń rè.”
Èyí túmọ̀ sí pé kò ṣeé ṣe fún àwọn òkú láti ṣe ohunkóhun tàbí láti nímọ̀lára ohunkóhun. Wọn kò ní ìrònú mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lè rántí ohunkóhun mọ́. Onísáàmù náà sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọmọ aládé, àní lé ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.”—Orin Dáfídì 146:3, 4.
Bíbélì fi hàn ní kedere pé nígbà ikú, ọkàn kò kọjá sínú ara mìíràn, ṣùgbọ́n ó kú. Bíbélì sọ gbangba gbàǹgbà pé: “Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀, òun óò kú.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4, 20; Ìṣe 3:23; Ìṣípayá 16:3) Nípa báyìí, ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn—ìpìlẹ̀ gan-an fún àbá èrò orí àtúnwáyé—kò ní ìtìlẹ́yìn kankan nínú Ìwé Mímọ́. Láìsí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn, àbá èrò orí àtúnwáyé wó lulẹ̀. Nígbà náà, kí ni ó lè ṣàlàyé ìyà tí a ń rí nínú ayé?
Èé Ṣe Tí Àwọn Ènìyàn Fi Ń Jìyà?
Àìpé tí gbogbo wa ti jogún láti ọ̀dọ̀ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ìdí ìpìlẹ̀ fún ìyà tí ń jẹ ẹ̀dá ènìyàn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ inú ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Nítorí tí a ṣẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ádámù, gbogbo wa ni a ń ṣàìsàn, tí a ń darúgbó, tí a sì ń kú.—Orin Dáfídì 41:1, 3; Fílípì 2:25-27.
Ní àfikún sí i, òfin tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún lórí ìwà híhù, tí Ẹlẹ́dàá ṣe, sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòó wù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni òun yóò ká pẹ̀lú; nítorí ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara rẹ̀ lọ́kàn yóò ká ìdíbàjẹ́ láti inú ẹran ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:7, 8) Nípa báyìí, ìgbésí ayé oníṣekúṣe lè yọrí sí ìrora ọkàn, oyún tí a kò fẹ́, àti àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀. Ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé: “A lè dá sìgá mímu lẹ́bi ní pàtàkì fún ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún àrùn jẹjẹrẹ aṣekúpani [ní United States], a tún lè di ẹ̀bi ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún mìíràn ru ọ̀nà tí àwọn ènìyàn gbà ń gbé ìgbésí ayé, ní pàtàkì ọ̀nà ìjẹun àti àìṣeré-ìdárayá.” Àwọn ìjábá kan tí ń fa ìyà jẹ́ àbájáde ṣíṣì tí ènìyàn ń ṣi ohun àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ ayé lò.—Fi wé Ìsípayá 11:18.
Bẹ́ẹ̀ ni, ènìyàn ni ó lẹ̀bi ọ̀pọ̀ ipò ìnira rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí ọkàn kò ti jẹ́ àìleèkú, a kò lè lo òfin ‘kíká ohun tí ó fúnrúgbìn’ láti so ìyà ẹ̀dá ènìyàn mọ́ kámà—àwọn ìṣe ti ayé tí a rò pé a ti gbé ṣáájú. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (Róòmù 6:7, 23) Nípa báyìí, a kì í gbé àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ kọjá sínú ayé kan lẹ́yìn ikú.
Sátánì Èṣù pẹ̀lú ń fa ìyà púpọ̀. Ní tòótọ́, Sátánì ni ó ń ṣàkóso ayé yìí. (Jòhánù Kíní 5:19) Gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi sì ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ yóò di ‘ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ rẹ̀.’ (Mátíù 10:22) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé àwọn olódodo sábà máa ń dojú kọ ìṣòro tí ó pọ̀ ju ti àwọn ẹni búburú lọ.
Nínú ayé yìí, àwọn ohun kan máa ń ṣẹlẹ̀ tí a kì í tètè mọ ohun tí ó fà á. Sárésáré tí ó lè sáré jù lọ lè fẹsẹ̀ kọ, kí ó sì pàdánù eré ìje. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun alágbára lè ṣubú sọ́wọ́ agbo ọmọ ogun tí kò lágbára tó wọn. Ó lè má ṣeé ṣe fún ọkùnrin ọlọgbọ́n kan láti rí iṣẹ́ tí ó jọjú, ebi sì lè tìtorí bẹ́ẹ̀ pa á. Ipò nǹkan lè mú kí àwọn tí wọ́n ní òye gíga lọ́lá nínú ìṣàbójútó okòwò má lè lo ìmọ̀ wọn, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bá ara wọn nínú ipò òṣì. Àwọn olóye ènìyàn lè rí ìbínú àwọn aláṣẹ, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ojú rere wọn. Èé ṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì dáhùn pé: “Nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11, NW.
Ìyà ti ń jẹ aráyé tipẹ́ kí àwọn amòye ẹlẹ́sìn Híńdù tó gbìyànjú láti ṣàlàyé ìdí tí ó fi wà. Ṣùgbọ́n ìrètí ha wà fún ọjọ́ ọ̀la tí ó dára jù bí? Ìlérí wo sì ni Bíbélì ní fún àwọn òkú?
Ọjọ́ Ọ̀la Alálàáfíà
Ẹlẹ́dàá ti ṣèlérí pé láìpẹ́ òun yóò mú òpin dé bá àwùjọ ayé ti lọ́ọ́lọ́ọ́, tí ó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì. (Òwe 2:21, 22; Dáníẹ́lì 2:44) Àwùjọ tuntun ti ẹ̀dá ènìyàn olódodo—“ilẹ̀ ayé tuntun”—yóò di òtítọ́ gidi nígbà náà. (Pétérù Kejì 3:13) Nígbà náà, “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òtútù ń pa mí.” (Aísáyà 33:24) Àní ẹ̀dùn ọkàn tí ikú ń mú wá kò ní sí mọ́, nítorí Ọlọ́run “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.
Nípa àwọn tí yóò gbé ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, onísáàmù náà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” (Orin Dáfídì 37:29) Ní àfikún sí i, àwọn ọlọ́kàn tútù “yóò . . . máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Orin Dáfídì 37:11.
Mukundbhai, tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tí ó ṣáájú, ti sùn nínú ikú láìmọ àwọn àgbàyanu ìlérí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí a jí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n ti kú láìmọ Ọlọ́run dìde sínú irú ayé tuntun alálàáfíà bẹ́ẹ̀, nítorí Bíbélì ṣèlérí pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15; Lúùkù 23:43.
Ọ̀rọ̀ náà, “àjíǹde,” ni a túmọ̀ níhìn-ín láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·naʹsta·sis, èyí tí ó túmọ̀ ní òwuuru sí “dídìde dúró lẹ́ẹ̀kan sí i.” Àjíǹde tipa bẹ́ẹ̀ ní nínú, pípadà mú bátànì ìgbésí ayé ẹnì kan ṣiṣẹ́.
Ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ilẹ̀ ayé kò lópin. (Jóòbù 12:13) Rírántí bátànì ìgbésí ayé àwọn tí ó ti kú kì í ṣe ìṣòro fún un. (Fi wé Aísáyà 40:26.) Jèhófà Ọlọ́run tún pọ̀ ní ìfẹ́. (Jòhánù Kíní 4:8) Nítorí náà, ó lè lo agbára ìrántí pípé rẹ̀, kì í ṣe láti fìyà jẹ àwọn òkú fún ìwà búburú tí wọ́n ti hù, ṣùgbọ́n láti mú wọn pa dà wà láàyè nínú párádísè ilẹ̀ ayé kan pẹ̀lú àkópọ̀ ìwà tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó kú.
Fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ bíi Mukundbhai, àjíǹde yóò túmọ̀ sí wíwà pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣùgbọ́n finú wòye ohun tí ó lè túmọ̀ sí fún àwọn tí ó wà láàyè nísinsìnyí. Gbé àpẹẹrẹ ọmọkùnrin Mukundbhai yẹ̀ wò, ẹni tí ó ti wá mọ àgbàyanu òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ète rẹ̀. Ẹ wo bí ó ti tù ú nínú tó láti mọ̀ pé, bàbá òun kò nírìírí ìyípoyípo àtúnbí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà lópin, tí ìwà ibi àti ìyà yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn po! Òun wulẹ̀ ń sùn nínú ikú, ní dídúró de àjíǹde. Ẹ wo bí ó ti mú un láyọ̀ tó láti ronú pé ó lè ṣeé ṣe lọ́jọ́ kan láti ṣàjọpín ohun tí òun ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti inú Bíbélì pẹ̀lú bàbá òun!
Ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (Tímótì Kíní 2:3, 4) Àkókò nìyí fún ọ láti kọ́ bí ìwọ, pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn tí ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run nísinsìnyí, ṣe lè wà láàyè títí láé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé kan.—Jòhánù 17:3.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
“Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11, NW
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àkópọ̀ Ìwà Ọlọ́run àti Òfin Kámà
Mohandas K. Gandhi ṣàlàyé pé: “Òfin Kámà kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, kò sì ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí ìdí kankan fún Ọlọ́run láti dá sí i. Ó gbé òfin náà kalẹ̀ tán, ó sì yọwọ́ yọsẹ̀, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀.” Èyí da Gandhi láàmú púpọ̀púpọ̀.
Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìlérí àjíǹde ṣí i payá pé Ọlọ́run ní ọkàn ìfẹ́ jíjinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀dá rẹ̀. Láti mú ẹnì kan tí ó ti kú pa dà wà láàyè nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run gbọ́dọ̀ mọ̀, kí ó sì rántí ohun gbogbo nípa ẹni náà. Ní tòótọ́, Ọlọ́run bìkítà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.—Pétérù Kíní 5:6, 7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìyípoyípo àtúnbí gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ Híńdù ṣe fi kọ́ni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi àjíǹde kọ́ni