Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
“Ilé-Ìṣọ́nà” November 1, 1995, darí àfiyèsí sí ohun tí Jésù sọ nípa “ìran yìí,” gẹ́gẹ́ bí a ti kà nínú Mátíù 24:34. Èyí ha túmọ̀ sí pé, kò sí ìdánilójú pé a gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ ní ọ̀run ní 1914 bí?
Ìjíròrò Ilé Ìṣọ́ yẹn kò yí ohun kankan pa dà nípa ẹ̀kọ́ ṣíṣe kókó tí a fi ń kọ́ni nípa 1914. Jésù ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun tí yóò sàmì sí wíwàníhìn-ín rẹ̀ nínú agbára Ìjọba. A ní ẹ̀rí tí ó pọ̀ tó pé àmì yí ti ń ṣẹlẹ̀ láti 1914. Òtítọ́ nípa ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, ìsẹ̀lẹ̀, àti àwọn ẹ̀rí mìíràn jẹ́rìí sí i pé Jésù ti ń múṣẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run láti 1914. Èyí fi hàn pé a ti wà ní òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan láti ìgbà yẹn.
Kí wá ni ohun tí Ilé Ìṣọ́ náà ń mú ṣe kedere? Ó dára, kókó inú rẹ̀ ni ọ̀nà tí Jésù gbà lo ọ̀rọ̀ náà, “ìran,” nínú Mátíù 24:34. Ẹsẹ náà kà pé: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín pé ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.” Kí ni ohun tí Jésù ní lọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ náà, “ìran,” ní ọjọ́ rẹ̀ àti ní ọjọ́ wa?
Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ jẹ́rìí sí i pé Jésù kò lo “ìran” ní ìtumọ̀ àwùjọ kékeré kan tàbí àwùjọ tí ó dá yàtọ̀ gédégbé, tí ó jẹ́ kìkì àwọn olórí Júù tàbí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ adúróṣinṣin. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lo “ìran” láti fi tàka àbùkù sí ọ̀pọ̀ jaburata Júù tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ó dùn mọ́ni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan lè ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pétérù rọ àwọn ènìyàn láti ṣe ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, kí wọ́n ronú pìwà dà kí wọ́n sì ‘gba ara wọn là kúrò lọ́wọ́ ìran oníwà wíwọ́ yìí.’—Ìṣe 2:40.
Nínú gbólóhùn yẹn, ó ṣe kedere pé Pétérù kò sọ̀rọ̀ ní pàtó nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ọjọ́ orí kan pàtó tàbí nípa àkókò kan pàtó, bẹ́ẹ̀ sì ni kò so “ìran” mọ́ déètì kan pàtó. Kò sọ pé àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ gba ara wọn là kúrò lọ́wọ́ ìran tí a bí ní ọdún kan náà tí a bí Jésù, tàbí àwọn tí a bí ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Júù àkókò yẹn tí kò gbà gbọ́—tí àwọn kan lè jẹ́ ọmọdé, tí àwọn mìíràn sì lè jẹ́ àgbà—tí a ti mú mọ ẹ̀kọ́ Jésù, tí wọ́n ti rí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ tàbí tí wọ́n ti gbọ́ nípa wọn, síbẹ̀ tí wọn kò tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà.
Ó ṣe kedere pé bí Pétérù ṣe lóye ọ̀nà tí Jésù gbà lo “ìran” nìyẹn nígbà tí òun àti àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta mìíràn wà pẹ̀lú Jésù ní orí Òkè Ólífì. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jésù, àwọn Júù àkókò yẹn—ní pàtàkì, àwọn tí wọ́n gbé ayé nígbà tí Jésù wà láyé—yóò nírìírí tàbí gbọ́ nípa ogun, ìsẹ̀lẹ̀, ìyàn, àti àwọn ẹ̀rí mìíràn tí ń fi hàn pé òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù ti ń sún mọ́lé. Ní ti gidi, ìran yẹn kò kọjá lọ kí òpin náà tó dé ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa.—Mátíù 24:3-14, 34.
A gbọ́dọ̀ gbà pé kì í ṣe ìtumọ̀ yẹn ni a lóye ọ̀rọ̀ Jésù sí tẹ́lẹ̀. Ènìyàn aláìpé máa ń nítẹ̀sí láti fẹ́ láti ṣe pàtó nípa ìgbà tí òpin yóò dé. Rántí pé àwọn àpọ́sítélì pàápàá ń wá ìgbà tí ó túbọ̀ ṣe pàtó, ní bíbéèrè pé: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba pa dà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yí bí?”—Ìṣe 1:6.
Pẹ̀lú èrò àìlábòsí kan náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní òde òní ti gbìyànjú láti wá ìgbà tí ó ṣe kedere kan jáde láti inú ohun tí Jésù sọ nípa “ìran,” nípa kíkà á láti 1914. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀nà kan tí wọ́n gbà ronú ni pé ìran kan máa ń wà fún 70 tàbí 80 ọdún, tí àwọn ènìyàn tí ó ti dàgbà tó láti lóye ìjẹ́pàtàkì Ogun Àgbáyé Kìíní àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míràn para pọ̀ jẹ́, nípa bẹ́ẹ̀, a lè ṣírò bí òpin náà ti sún mọ́lé tó.
Bí ìrònú bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ ní ète burúkú nínú, ó ha wà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tí Jésù fúnni tẹ̀ lé e bí? Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn kò sí ẹnì kan tí ó mọ̀, kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì àwọn ọ̀run tàbí Ọmọkùnrin, bí kò ṣe Bàbá nìkan. . . . Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.”—Mátíù 24:36-42.
Nítorí náà, ìsọfúnni àìpẹ́ yìí nínú Ilé Ìṣọ́ nípa “ìran yìí,” kò yí òye tí a ní nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní 1914 pa dà. Ṣùgbọ́n, ó mú kí a ní òye tí ó ṣe kedere sí i nípa bí Jésù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà, “ìran,” ní jíjẹ́ kí a lóye pé ọ̀nà tí ó gbà lò ó kò fún wa ní ìdí láti ṣèṣirò—ní bíbẹ̀rẹ̀ kíkà wa láti 1914—láti lè mọ bí a ṣe sún mọ́ òpin náà tó.