Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Bíbọ́ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Ẹ̀mí Èṣù
TIPẸ́TIPẸ́ ni àṣà ìbẹ́mìílò ti jọba lórí ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe láti bọ́ nínú rẹ̀! Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ní ìlú Éfésù nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Bíbélì ṣe sọ, “ọ̀pọ̀ lára àwọn wọnnì tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀ wọ́n sì dáná sun wọ́n . . . Nípa báyìí ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí lọ́nà títóbi jọjọ.”—Ìṣe 19:19, 20.
Bákan náà, ìjọ Kristẹni lónìí ń gbádùn ìbísí. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní Éfésù, àwọn tí wọ́n ti jọ́sìn àwọn ẹ̀mí èṣù rí wà lára àwọn tí ń di onígbàgbọ́. Ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí tí ó wá láti Zimbabwe ṣàkàwé èyí.
A mọ Gogo (Ìyá àgbà) Mthupha bí ẹní mowó fún agbára ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Àwọn ènìyàn ń wá láti ibi jíjìnnà réré bí i Zambia, Botswana, àti Gúúsù Áfíríkà láti wá ìtọ́jú egbòogi ìbílẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gogo Mthupha tún kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti jẹ́ n’anga, tàbí olóògùn. Ó sì máa ń sà sí ènìyàn nígbà míràn!
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday kan, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Gogo Mthupha. Ó gbádùn ìjíròrò tí ó ní pẹ̀lú wọn gan-an nípa ìlérí Bíbélì nípa ayé tuntun òdodo kan, ayé kan tí ó bọ́ lọ́wọ́ àwọn agbára ìdarí búburú. Ó gba ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ó sì gbà láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.a Ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé lẹ́yìn tí a bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà kẹta.
Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó ń ṣe, Gogo Mthupha kẹ́kọ̀ọ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ipò ọba aláṣẹ Jèhófà ni agbára àrà ọ̀tọ̀ tí ó ní ti wá. (Pétérù Kejì 2:4; Júúdà 6) Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyí ti pinnu láti yí gbogbo ẹni tí ó bá ṣeé ṣe fún wọn pa dà lòdì sí Jèhófà àti sí ìjọsìn mímọ́ gaara. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé pípe àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú wọ̀nyí ni ó fi ń jẹun, kí ni òun yóò wá máa ṣe báyìí?
Gogo Mthupha sọ ìfẹ́ rẹ jáde láti kó gbogbo oògùn rẹ̀ àti gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí èṣù dà nù. Gèlè olóògùn tí ó máa ń wé àti “ọ̀sányìn oníwo akọ màlúù” rẹ̀ tí ó ń lò nínú iṣẹ́ n’anga rẹ̀ wà lára ìwọ̀nyí. Gogo Mthupha ń fẹ́ láti kó gbogbo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dà nù, kí ó baà lè jọ́sìn Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo tí ó sì ń bẹ láàyè náà, Jèhófà.
Ṣùgbọ́n, àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan ta ko èyí nítorí ó máa ń fowó ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí ó kó gbogbo ẹrù oògùn rẹ̀ fún àwọn, títí kan àwọn agbára ajẹ̀dálọ rẹ̀, kí wọ́n baà lè máa jèrè láti inú rẹ̀. Gogo Mthupha kọ̀ jálẹ̀.
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àdúgbò, ó kó àpò ńlá mẹ́ta tí ó kún fún ohun èlò ìbẹ́mìílò jọ, ó sì jó gbogbo wọn níná. Bí iná ti ń jó àwọn ohun tí ó ń lò láti jọ́sìn ẹ̀mí èṣù, Gogo Mthupha kígbe pé: “Ẹ wò ó! Àṣẹ yẹn kò tilẹ̀ lè gba ara rẹ̀ là.”
Kò pẹ́ kò jìnnà, Gogo Mthupha fi tayọ̀tayọ̀ fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Kí ni ó ń ṣe jẹun nísinsìnyí? Ó ń ta ẹ̀fọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, nípasẹ̀ agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni kan lè já ara rẹ̀ gbà kúrò nínú ìjọsìn ẹ̀mí èṣù. Gogo Mthupha sọ pé: “N kò lómìnira báyìí rí.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.