ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 7/15 ojú ìwé 20-23
  • Gba Ẹ̀mí Ọmọ Rẹ Là!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gba Ẹ̀mí Ọmọ Rẹ Là!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́
  • Ìfẹ́ Ọlọ́run
  • Ìbẹ̀rù Ọlọ́run
  • Èrè Tí Ń Dùn Mọ́ni
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 7/15 ojú ìwé 20-23

Gba Ẹ̀mí Ọmọ Rẹ Là!

MICHAEL àti Alphina ń gbé ní àfonífojì ìgbèríko kan láàárín àwọn òkè kéékèèké eléwéko títutù yọ̀yọ̀ ní KwaZulu-Natal, Gúúsù Áfíríkà. Wọ́n dojú kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèníjà ní títọ́ àwọn ọmọ méje dàgbà. Pẹ̀lú gbogbo ìtìlẹ́yìn aya rẹ̀, Michael sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì sí àwọn bàbá pé: “Ẹ máa bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ṣùgbọ́n, nígbà míràn, àwọn ìṣòro máa ń dìde.

Fún àpẹẹrẹ, ó wọ́pọ̀ fún àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n jẹ́ darandaran ní ilẹ́ Áfíríkà láti da agbo ẹran àwọn òbí wọn pọ̀, kí wọ́n baà lè rí àyè láti túbọ̀ ṣeré. Nígbà míràn, wọ́n máa ń kó sínú ìjàngbọ̀n, wọn a sì sọ àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọkùnrin Michael ń da ẹran ìdílé wọn lọ, ó tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn létí dáradára láti má ṣe kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ kan báyìí. (Jákọ́bù 4:4) Síbẹ̀, nígbà tí ó bá ń darí sílé láti ibi iṣẹ́, ó máa ń rí wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ wọ̀nyí nígbà míràn. Nítorí èyí, ó máa ń bá wọn wí.—Òwe 23:13, 14.

Ìwọ ha rò pé Michael ti le koko mọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ jù bí? Àwọn kan lè ronú bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n Jésù Kristi sọ pé “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Michael àti Alphina mú kí ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín agboolé wọn, wọ́n ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń kọ́ wọn ní àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti òtítọ́ Bíbélì.

Michael àti Alphina ní ọmọbìnrin mẹ́rin—Thembekile, Siphiwe, Tholakele, àti Thembekani. Gbogbo wọ́n jẹ́ alákòókò kíkún oníwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Méjì nínú àwọn ọmọkùnrin wọn ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága nínú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọmọkùnrin wọn kẹta, tí aya rẹ̀ pẹ̀lú jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún, ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

Ọ̀pọ̀ Kristẹni òbí tí wọ́n ní ìdílé ńlá ti ṣàṣeyọrí nínú títọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà. Ṣùgbọ́n, àwọn ọmọ kan tí a tọ́ dàgbà dáradára ti fi òtítọ́ sílẹ̀. Láìsí àní-àní, àwọn òbí wọn fi àkàwé Jésù nípa ọmọ onínàákúnàá sọ́kàn, wọ́n sì nírètí pé ọmọkùnrin wọn tàbí ọmọbìnrin wọn yóò ronú pìwà dà, yóò sì rí ìgbàlà nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Lúùkù 15:21-24.

Ṣùgbọ́n, lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, ayé ń gba gbogbo ọmọ àwọn Kristẹni òbí kan mọ́ wọn lọ́wọ́. Èyí ní pàtàkì jẹ́ ìṣòro ńlá ní àwọn apá ibì kan ní Áfíríkà, níbi tí ó jọ́ pé àwọn ọmọ máa ń ṣe dáradára dìgbà tí wọ́n bá di ọ̀dọ́langba. Nígbà náà, nígbà ìtànná òdòdó èwe, àwọn ọ̀nà oníwà pálapàla inú ayé Sátánì máa ń ré wọn lọ. (Jòhánù Kíní 5:19) Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ bàbá kì í tóótun láti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ìjọ. (Tímótì Kíní 3:1, 4, 5) Lọ́nà tí ó ṣe kedere, ó yẹ kí bàbá tí ó jẹ́ Kristẹni ka ìgbàlà agbo ilé rẹ̀ sí ohun tí ó ṣe pàtàkì gidigidi. Nítorí náà, kí ni àwọn òbí lè ṣe láti gba ẹ̀mí àwọn ọmọ wọn là?

Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́

Kì í ṣe pé Jésù jẹ́ ẹni pípé nìkan ni, ṣùgbọ́n ìmọ̀ àti ìrírí tí ó ní tún ga lọ́lá gan-an ju ti ènìyàn èyíkéyìí lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ó bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ aláìpé lò gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. (Jòhánù 15:15) Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń fẹ́ láti wà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe dáradára ní àyíká rẹ̀. (Jòhánù 1:14, 16, 39-42; 21:7, 15-17) Àwọn òbí lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára èyí. Bí ewéko kékeré kan tí àwọn ewé rẹ̀ nà síhà ibi tí oòrùn ti ń yọ, àwọn ọmọ máa ń ṣe dáradára nígbà tí àyíká inú ilé bá kún fún ìfẹ́ àti ọ̀yàyà.

Ẹ̀yin òbí, àwọn ọmọ yín ha ń lómìnira láti kó àníyàn wọn wá bá a yín? Ẹ ha máa ń tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn bí? Kí ẹ tó dórí ìpinnu, ẹ ha máa ń jẹ́ kí wọ́n sọ èrò àti ìmọ̀lára wọn jáde, kí ẹ baà lè rí ọ̀ràn bí wọ́n ṣe rí gan-an? Ẹ ha máa ń fi sùúrù ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtó kan nípa ṣíṣe ìwádìí pẹ̀lú wọn nínú àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì bí?

Ìyá kan ní Gúúsù Áfíríkà ṣàlàyé pé: “Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ọmọbìnrin wa ti bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ ni a ti fún un níṣìírí láti sọ àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún wa. Fún àpẹẹrẹ, èmi yóò bi í pé: ‘Ta ni o lo àkókò oúnjẹ pẹ̀lú? Sọ fún mi nípa olùkọ́ rẹ tuntun. Báwo ni ó ṣe rí? Ìgbòkègbodò wo ni wọ́n wéèwé fún ọ̀sẹ̀ náà?’ Ní ọjọ́ kan, ọmọbìnrin wa délé, ó sì sọ fún wa pé, olùkọ́ tí ń kọ́ wọn ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ń mú kíláàsì wọn lọ wo sinimá kan, tí wọn yóò kọ ọ̀rọ̀ lé lórí lẹ́yìn náà. Àkọlé sinimá náà gbé ìbéèrè dìde. Lẹ́yìn ìwádìí tí a ṣe, a rí i pé kò ní jẹ́ ohun tí yóò dára fún Kristẹni láti wò. A jíròrò rẹ̀ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ní ọjọ́ kejì, ọmọbìnrin wa tọ olùkọ́ rẹ̀ lọ, ó ṣàlàyé fún un pé òun kò ni fẹ́ láti wo sinimá náà, níwọ̀n bí ìwà tí ó gbé yọ kì yóò bá àwọn ìgbàgbọ́ Kristẹni òun mu. Olùkọ́ náà ronú lórí ọ̀ràn yí, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọbìnrin wa, ó sọ pé òun kò ní fẹ́ mú àwọn ọmọ kíláàsì òun lọ wo ohun tí òun yóò kábàámọ̀ rẹ̀.” Àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí àwọn òbí wọ̀nyí fi hàn lemọ́lemọ́ nínú ìgbàlà ọmọbìnrin wọn mú èso rere jáde. Aláyọ̀ ènìyàn tí ń fojú sọ́nà fún rere ni, ó sì ń sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka Watch Tower Bible and Tract Society ní Gúúsù Áfíríkà.

Jésù fi àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá lélẹ̀ nínú bíbá àwọn ọmọ ẹlòmíràn lò. Ó gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ wọn. (Máàkù 10:13-16) Ẹ wo bí ó ti yẹ kí àwọn òbí láyọ̀ tó láti ṣe àwọn nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn! Ní àwọn apá ibì kan ní Áfíríkà, ó máa ń ti bàbá lójú láti di ẹni tí a rí tí ń gbá bọ́ọ̀lù tàbí ṣe àwọn eré mìíràn pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Ṣùgbọ́n Kristẹni bàbá kan kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé òun ti ṣe pàtàkì ju ẹni tí a ń rí tí ń ṣe nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ ń fẹ́ àwọn òbí tí ń gbádùn lílo àkókò pẹ̀lú wọn. Èyí ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún àwọn ọmọ láti sọ àníyàn wọn jáde. Nígbà tí a bá pa ìjẹ́pàtàkì èrò ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ tì, a lè sún àwọn ọmọ bínú tàbí kí wọ́n fà sẹ́yìn fún wa, pàápàá tí a bá ń bá wọn wí léraléra.

Ní kíkọ̀wé sí àwọn ará Kólósè nípa ìbátan ìdílé, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà sorí kodò.” (Kólósè 3:21) Èyí lè fi hàn pé, nígbà míràn, a ń bá wọn wí ju bí ó ti yẹ lọ, a kì í sì í bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́ tó. Ó ṣeé ṣe dáradára pé àwọn ọmọ, títí kan àwọn ọ̀dọ́langba, tí a nífẹ̀ẹ́, tí a sì mọrírì yóò dáhùn pa dà sí ìbáwí tí wọ́n nílò.

Ìfẹ́ Ọlọ́run

Ogún tí ó níye lórí jù lọ tí àwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn ni àpẹẹrẹ àwọn fúnra wọn ní ti fífi ìfẹ́ hàn. Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ rí àwọn òbí wọn tí ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí Ọlọ́run, kí wọ́n sì gbọ́ wọn tí wọ́n ń sọ ọ́ jáde. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń ṣiṣẹ́ sìn ní ẹ̀ka Watch Tower Bible and Tract Society ní Gúúsù Áfíríkà ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń ran bàbá mi lọ́wọ́ láyìíká ilé. Mo máa ń gbádùn ríràn án lọ́wọ́, kìkì nítorí pé Dádì máa ń mọrírì iṣẹ́ kékeré tí mo bá ṣe. Ó máa ń lo àkókò náà láti sọ ọ̀pọ̀ ohun fún mi nípa Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, mo rántí ọjọ́ Saturday kan tí a ń ṣiṣẹ́ kára ní gígé koríko àyíká ilé. Oòrùn ń mú gan-an. Dádì ń làágùn yọ̀bọ̀, nítorí náà, mo sáré lọ bu omi sínú ife méjì, mo sì ju omi dídì sínú rẹ̀. Dádì sọ pé: ‘Ọmọ, o ha ri bí ọgbọ́n Jèhófà ti pọ̀ tó bí? Omi dídì máa ń léfòó sórí omi. Bí ó bá rì, gbogbo ohun abẹ̀mí tí ń bẹ lábẹ́ adágún omi àti odò ni yóò kú. Dípò èyí, omi dídì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi kúbùsù tí ń mú nǹkan móoru! Ìyẹn kò ha ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà dáradára sí i bí?’a Lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n nítorí pé n kò dá sí tọ̀tún tòsì, mo rí àyè láti ronú. Ní alẹ́ ọjọ́ kan tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi ní yàrá tí a fi mí sí nínú ẹ̀wọ̀n, mo rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí Dádì sọ yẹn. Ẹ wo bí wọ́n ti kún fún ìtumọ̀ tó! Èmi yóò ṣiṣẹ́ sin Jèhófà títí ayérayé bí n bá lè ṣe bẹ́ẹ̀.”

Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ rí ìfẹ́ fún Ọlọ́run nínú gbogbo ohun tí àwọn òbí wọn ń ṣe. Ní pàtàkì, a gbọ́dọ̀ rí ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ìgbọràn àtọkànwá sí i gẹ́gẹ́ bí ipá asúnniṣiṣẹ́ tí ó wà lẹ́yìn pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, àti kíka Bíbélì pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé àti kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀. (Kọ́ríńtì Kíní 13:3) Ní pàtàkì jù lọ, ìfẹ́ fún Ọlọ́run yẹ kí ó fara hàn nínú àdúrà àtọkànwá ìdílé. A kò lè sọ ìjẹ́pàtàkì fífún àwọn ọmọ rẹ ní irú ogún bẹ́ẹ̀ ní àsọjù. Ìdí nìyẹn tí a fi pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ìwọ kí ó sì fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Àti ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo pa láṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà ní àyà rẹ: Kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ í sọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà, àti nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ bá dìde.”—Diutarónómì 6:5-7; fi wé Mátíù 22:37-40.

Ara ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a jogún jẹ́ ìdènà ńlá sí nínífẹ̀ẹ́ àti ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Róòmù 5:12) Nítorí náà, Bíbélì tún pàṣẹ pé: “Ẹ̀yin tí ó fẹ́ Olúwa, ẹ kórìíra ibi.” (Orin Dáfídì 97:10) Èrò búburú sábà máa ń yọrí sí ìṣe búburú. Láti yẹra fún ìwọ̀nyí, ọmọ kan gbọ́dọ̀ tún mú ànímọ́ mìíràn tí ó ṣe kókó dàgbà.

Ìbẹ̀rù Ọlọ́run

Ìfẹ́ àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ láti má ṣe mú inú bí Jèhófà jẹ́ ohun kan tí ó fani mọ́ra gidigidi. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ pípé pérépéré ti ẹnì kan tí ó rí ìdùnnú ‘nínú ìbẹ̀rù Olúwa,’ lẹ́lẹ̀ fún wa. (Aísáyà 11:1-3) Irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ ṣe kókó bí ọmọ kan ti ń dé ìgbà ìtanná òdòdó èwe, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í nírìírí ìrusókè ìfẹ́ ìbálòpọ̀ lọ́nà lílágbára. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run lè ran èwe kan lọ́wọ́ láti dènà agbára ìdarí inú ayé tí ó lè yọrí sí ìwà pálapàla. (Òwe 8:13) Ní àwọn àwùjọ kan, àwọn òbí máa ń dọ́gbọ́n yẹra fún kíkọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀nà tí wọ́n lè gbà kojú ìdẹwò ìbálòpọ̀. Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ ronú pé ó lòdì láti jíròrò àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, kí ni àbájáde irú àìbìkítà àwọn òbí bẹ́ẹ̀?

Àwọn ògbóǹtagí mẹ́ta nínú ìṣègùn, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Buga, Amoko, àti Ncayiyana, fọ̀rọ̀ wá àwọn ọmọbìnrin 1,702 àti àwọn ọmọkùnrin 903, tí wọ́n wá láti ìgbèríko Transkei ní Gúúsù Áfíríkà lẹ́nu wò. Ìwé ìròyìn South African Medical Journal ròyìn pé, “ìpín 76 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọbìnrin àti ìpín 90.1 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọkùnrin nínú ìwádìí yìí ni ó ti nírìírí ìbálòpọ̀.” Ọdún 15 ni ìpíndọ́gba ọjọ́ orí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí, ipá ni a sì fi bá ọ̀pọ̀ nínú wọn lò pọ̀. Iye tí ó lé ní 250 lára wọn ni ó ti gboyún lẹ́ẹ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìlọsókè nínú àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré tún jẹ́ àbájáde mìíràn.

Ó ṣe kedere pé, ọ̀pọ̀ òbí ni kò rí ìjẹ́pàtàkì kíkọ́ àwọn ọmọ wọn ní bí wọ́n ṣe ń yẹra fún ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó. Dípò èyí, ìwé ìròyìn tí a ń fọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Bíbímọ àti jíjẹ́ màmá jẹ́ ànímọ́ bíbọ́ sí ipò obìnrin tí a gbé gẹ̀gẹ̀ ní àwùjọ ìgbèríko Transkei, àwọn ọmọdébìnrin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bàlágà sì tètè ń lóye èyí.” Irú àkọsílẹ̀ ìṣòro kan náà ni àwọn apá ibòmíràn nínú ayé ní.

Ọ̀pọ̀ èwe ní Áfíríkà ń ṣe lámèyítọ́ àwọn òbí wọn fún kíkọ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àwọn ohun tí ó wé mọ́ ìbálòpọ̀. Ojú ń ti àwọn Kristẹni òbí kan púpọ̀ láti lo ìwé Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ.b Ní ojú ìwé 20 sí 23, ó ṣàlàyé ìlò àwọn ẹ̀yà ara tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ lọ́nà tí ó lọ́lá àti àwọn ìyípadà tí ń wáyé nígbà ìbàlágà.

Ó yẹ kí a yin àwọn Kristẹni òbí tí wọ́n kojú ìpèníjà jíjíròrò ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ó máa ń dára jù lọ láti ṣe èyí ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé, ní ìbámu pẹ̀lú agbára ọmọ kan láti lóye ọ̀ràn. Ní sísinmi lórí irú kókó bí ọjọ́ orí ọmọ náà, àwọn òbí lè ní láti sọ ojú abẹ níkòó ní dídárúkọ àwọn ẹ̀yà ara àti ohun tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èwe aláìnírìírí kan lè má lóye ohun tí a ń sọ.—Kọ́ríńtì Kíní 14:8, 9.

Bàbá kan ní Gúúsù Áfíríkà, tí ó ní ọmọbìnrin méjì àti ọmọkùnrin kan, sọ pé: “Léraléra, mo láǹfààní láti jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ ẹlẹgẹ́ ti ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pàápàá. Bí ó ti wù kí ó rí, aya mi fún àwọn ọmọbìnrin wa ní àfiyèsí pàtàkì, ní lílo ìwé Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ. [Wo ojú ìwé 26 sí 31.] Nígbà tí ọmọkùnrin mi jẹ́ ọmọ ọdún 12, mo pinnu láti mú un rìnrìn ọ̀nà jíjìn lọ sórí òkè. Ní àkókò náà, a jíròrò ní kíkún nípa bí ara ọmọkùnrin ṣe ń dàgbà àti ète dáradára tí èyí yóò ṣiṣẹ́ fún lọ́jọ́ iwájú nínú ìgbéyàwó. Mo tún jíròrò pẹ̀lú rẹ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì yíyẹra fún àṣà tí ń rẹni nípò wálẹ̀ ti ìdánìkan hùwà ìbálòpọ̀, kí ó sì fi ojú ọlá àti ọ̀wọ̀ wo àwọn ọmọbìnrin—bí ó ti fi ń wo ìyá rẹ̀ àti àwọn arábìnrin rẹ̀.”

Èrè Tí Ń Dùn Mọ́ni

Bàbá àti ìyá tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn tán yìí ṣiṣẹ́ kára, inú wọ́n sì dùn pé àwọn rí àbájáde rere nínú títọ́ àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dàgbà. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti dàgbà báyìí, wọ́n sì fẹ́ àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́. Ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọkọ àwọn ọmọ wọn ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ Kristẹni, méjì nínú àwọn tọkọtaya wọ̀nyẹn ti wà nínú iṣẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn òbí tí ó bá ṣiṣẹ́ kára fún ìgbàlà agbo ilé wọn lè retí èrè tí ń mú ìdùnnú wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ tí wọ́n yàn láti dáhùn pa dà sí irú ẹ̀kọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀, nítorí Òwe 23:24, 25 sọ pé: “Ẹni tí ó bí ọmọ ọlọgbọ́n, yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀. Bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀.” Gbé ọ̀ràn ìdílé ńlá tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí yẹ̀ wò. Alphina sọ pé: “Nígbà tí mo bá ronú nípa ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí tí àwọn ọmọ mi ti ṣe, ọkàn mi máa ń sọ púkẹ́púkẹ́ fún ayọ̀.” Ǹjẹ́ kí gbogbo Kristẹni òbí ṣiṣẹ́ fún èrè aláyọ̀ yí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí omi ti ń dì pọ̀, yóò bẹ̀rẹ̀ sí í fúyẹ́, yóò sì léfòó. Wo ojú ìwé 137 àti 138 ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

b Tún wo ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Bàbá kan lè ṣètò fún àyíká tí ó yẹ láti ṣàlàyé àwọn òkodoro ìgbésí ayé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́