Àwọn Afarapitú Lórí Òkè Ńlá Ti Àpáta Gàǹgà
ÌLÚ ńlá ìgbàanì àti aginjù tí ó yí i ká tí a ń pè ní Ẹ́ń-gédì wà ní etí bèbè ìwọ̀ oòrùn Òkun Òkú. Àwọn ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ àárín àwọn àpáta àgbègbè náà àti ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà pèsè ilé tí ó ṣeé gbé fún ewúrẹ́ orí òkè ńlá ti Ilẹ̀ Ìlérí, tí ó jọ àwọn tí a rí níhìn-ín.
Ẹ̀dá abẹsẹ̀ dídúró tepọ́n yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá àràmàǹdà tí ń bẹ láwùjọ ẹranko. Jẹ́ kí a ṣí Bíbélì, kí a sì wo ẹranko fífani mọ́ra yìí láwòfín.
“Àwọn Òkè Ńlá Gíga Wà fún Àwọn Ewúrẹ́ Orí Òkè Ńlá”
Bí onísáàmú náà ṣe fi kọrin nìyẹn. (Orin Dáfídì 104:18, NW) A mú àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá gbára dì fún gbígbé ní ibi gíga! Ara wọ́n yá gágá, èyí sì ń mú kí wọ́n lè fi ìdára-ẹni-lójú ńláǹlà rìn lórí àpáta gbágungbàgun, kí wọ́n sì sáré lórí rẹ̀. Lápá kan, èyí ṣeé ṣe nítorí bí a ṣe ṣẹ̀dá pátákò wọn. Ẹ̀là tí ń bẹ láàárín ọmọ ìkasẹ̀ wọn lè fẹ̀ sí i lábẹ́ ọ̀ọ̀rìn ewúrẹ́ náà, ni mímú kí ẹranko náà lè dúró tepọ́n tàbí kí ó rìn lórí àwọn ìyọgọnbu àpáta tóóró.
Ìdúró tepọ́n àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá tún ṣàrà ọ̀tọ̀. Wọ́n lè bẹ́ sí ibi jíjìnnà gan-an, kí wọ́n sì balẹ̀ ṣẹ́ẹ́ sórí ìyọgọnbu àpáta tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè gba ẹsẹ̀ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè náà, Douglas Chadwick, nígbà kan rí ṣàkíyèsí oríṣi ewúrẹ́ orí òkè ńlá mìíràn kan, tí ó lo ìdúró tepọ́n rẹ̀ láti yẹra fún híhá sáàárín àwọn ìyọgọnbu àpáta tí ó há fún un láti ṣẹ́rí pa dà. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí ó ti rí ìyọgọnbu àpáta kejì fìrí ní nǹkan bí 120 mítà sísàlẹ̀, ewúrẹ́ náà dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì ti iwájú, ó sì rọra kó ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì tẹ̀yìn sókè lórí àpáta náà bí ẹni pé ó ń gbókìtì. Bí mo ṣe ń wò ó tìyanutìyanu, ewúrẹ́ náà tẹ̀ síwájú títí tí ẹsẹ̀ ẹ̀yìn rẹ̀ fi wálẹ̀, tí ó sì fi kọjú sí ibi tí ó ti ń bọ̀.” (National Geographic) Abájọ tí a ṣe ń pe àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá ní “àwọn afarapitú lórí òkè ńlá ti àpáta gàǹgà”!
‘Ìwọ Ha Mọ Ìgbà Tí Àwọn Ewúrẹ́ Orí Òkè Ńlá Ń Bímọ?’
Àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá jẹ́ ẹ̀dá tí ń tijú púpọ̀. Ó tẹ́ wọn lọ́rùn láti gbé ní ibi tí kò sí ènìyàn kankan. Ní tòótọ́, ó ṣòro fún ènìyàn láti sùn mọ̀ wọn dáradára kí ó sì rí wọn ní ibi tí a dá wọn sí láti gbé gẹ́gẹ́ bí ẹranko. Nípa báyìí, Olówó “àwọn ẹranko tí ń bẹ lórí ẹgbẹ̀rún òkè ńlá” lẹ́tọ̀ọ́ láti béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà, Jóòbù, pé: “Ìwọ ha ti wá mọ àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá ti àpáta gàǹgà láti bímọ?”—Orin Dáfídì 50:10, NW; Jóòbù 39:1, NW.
Ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti dá mọ́ abo ewúrẹ́ orí òkè ńlá ń jẹ́ kí ó mọ ìgbà tí àkókò bá tó láti bímọ. Yóò wa ibi kùlùmọ́, yóò sì bí ọmọ kan tàbí méjì, lọ́pọ̀ ìgbà ni ìparí oṣù May tàbí ni oṣù June. Láàárín ọjọ́ díẹ̀ àwọn ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí náà ti mọ bí a ṣe ń dúró tepọ́n.
“Egbin Dídára Lẹ́wà àti Ewúrẹ́ Olóòfà Ẹwà Ti Orí Òkè Ńlá”
Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì rọ àwọn ọkọ pé: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ, egbin dídára lẹ́wà àti ewúrẹ́ olóòfà ẹwà ti orí òkè ńlá.” (Òwe 5:18, 19) A kò sọ èyí láti tàbùkù àwọn obìnrin. Ó hàn gbangba pé, Sólómọ́nì ń fọgbọ́n tọ́ka sí ẹwà, ìrísí rèǹtè rente, àti àwọn ànímọ́ títayọ mìíràn tí àwọn ẹranko wọ̀nyí ní.
Ewúrẹ́ orí òkè ńlá jẹ́ ọ̀kan lára àìlóǹkà “ẹ̀dá alààyè” tí ń jẹ́rìí kíkọyọyọ sí ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:24, 25) A kò ha láyọ̀ pé Ọlọ́run fi ọ̀pọ̀ ẹ̀dá fífani mọ́ra bẹ́ẹ̀ kẹ́ wa bí?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìyọ̀nda Onínúure ti Athens University