Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Bàbá Kan Tí Ó Ṣe Tán Láti Dárí Jini
A TI pè é ní ìtàn kúkúrú gíga lọ́lá jù lọ tí a tí ì kọ rí—pẹ̀lú ìdí rere ni a fi pè é bẹ́ẹ̀. Àkàwé Jésù nípa ìfẹ́ bàbá kan sí ọmọ rẹ̀ tí ó sọ nù dà bíi fèrèsé tí a ti ń rí ìyọ́nú ọlá ńlá Ọlọ́run sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó ronú pìwà dà.
Ó Sọ Nù A Sì Rí I
Ọkùnrin kan ní ọmọkùnrin méjì. Èyí àbúrò wí fún un pé: ‘Mo fẹ́ ogún mi nísinsìnyí, dípò dídúró dìgbà tí ìwọ yóò fi kù.’ Bàbá náà gbà, ó sì ṣeé ṣe kí ó fún un ní ìdá mẹ́ta gbogbo ohun ìní rẹ̀—ìpín tí òfin sọ pé ó tọ́ sí èyí tí ó kéré jù láàárín àwọn ọmọkùnrin méjì. (Diutarónómì 21:17) Kíákíá ni èwe náà kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ jọ, ó sì rìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, níbi tí ó ti ná gbogbo owó rẹ̀, ní lílépa ìgbésí ayé oníwà wọ̀bìà.—Lúùkù 15:11-13.
Lẹ́yìn náà, ìyàn mímúná janjan kan ṣẹlẹ̀. Ní gbígbékútà, ọ̀dọ́kùnrin náà gbà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀—iṣẹ́ tí àwọn Júù ń fojú burúkú wò. (Léfítíkù 11:7, 8) Oúnjẹ wọ́n gógó débi tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í yán hànhàn fún pódi èso kárọ́ọ̀bù tí ó jẹ́ oúnjẹ àwọn ẹlẹ́dẹ̀! Níkẹyìn, orí ọmọ náà wálé. Ó rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Àwọn ìránṣẹ́ bàbá mi ń jẹ oúnjẹ tí ó dára ju èyí tí mo ń jẹ lọ! N óò pa dà sílé, n óò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi, n óò sì bẹ̀bẹ̀ láti di ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tí bàbá mi háyà.’a—Lúùkù 15:14-19.
Ọ̀dọ́kùnrin náà wọ́ lọ sílé. Kò sí àní-àní pé ìrísí rẹ̀ ti yí pa dà gidigidi. Síbẹ̀, bàbá rẹ̀ dá a mọ̀, “nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn.” Àánú ṣe é, ó sáré lọ pàdé ọmọ rẹ̀, ó gbá a mọ́ra, ó sì “fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.”—Lúùkù 15:20.
Ìgbani tọwọ́tẹsẹ̀ yí mú kí ó rọrùn fún ọ̀dọ́kùnrin náà láti tú ọkàn rẹ̀ jáde. Ó sọ pé: “Bàbá, èmi ti ṣẹ̀ sí ọ̀run àti sí ọ. Èmi kò yẹ mọ́ ní ẹni tí a ń pè ní ọmọkùnrin rẹ. Fi mí ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí o háyà.” Bàbá náà ké sí àwọn ẹrú rẹ̀. Ó pàṣẹ pé: “Kíá! ẹ mú aṣọ ìgúnwà kan jáde wá, èyí tí ó dára jù lọ, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́, kí ẹ sì fi òrùka sí ọwọ́ rẹ̀ àti sálúbàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀. Kí ẹ sì mú àbọ́sanra ẹgbọrọ akọ màlúù wá, kí ẹ dúńbú rẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí a jẹun kí a sì gbádùn ara wa, nítorí pé ọmọkùnrin mi yìí kú ó sì tún yè; ó sọ nù a sì rí i.”—Lúùkù 15:21-24.
Àsè pọ̀pọ̀ ṣìnṣìn bẹ̀rẹ̀, títí kan orin àti ijó. Ọmọkùnrin àgbà gbọ́ ariwo híhó yèè, bí ó ti ń darí dé láti inú pápá. Nígbà tí ó gbọ́ pé àbúrò rẹ̀ ti darí wálé, pé èyí sì ni ó fa pọ̀pọ̀ ṣìnṣìn náà, inú bí i. Ó ṣàròyé fún bàbá rẹ̀ pé: ‘Mo ti sìnrú fún ọ fún ọ̀pọ̀ ọdún, n kò sí ṣàìgbọràn sí ọ rí, síbẹ̀ ó kò fún mi ní ọ̀dọ́ àgùntàn rí láti gbádùn ara mi pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ṣùgbọ́n, gbàrà tí ọmọkùnrin rẹ, tí ó ti fi owó rẹ ṣòfò tán pa dà dé, o se àsè ńlá fún un.’ Bàbá rẹ̀ fèsì lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ wà pẹ̀lú mi, gbogbo ohun tí ó sì jẹ́ tèmi jẹ́ tìrẹ. Ṣùgbọ́n àwa sáà ní láti yọ̀ nítorí pé arákùnrin rẹ kú ó sì yè. Ó sọ nù a sì rí i lẹ́yìn náà.’—Lúùkù 15:25-32.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Bàbá inú àkàwé Jésù dúró fún Ọlọ́run wa aláàánú, Jèhófà. Bí ọmọkùnrin tí ó sọ nù, àwọn ènìyàn kan fi abẹ́ ààbò agbo ilé Ọlọ́run sílẹ̀ fún àkókò kan, ṣùgbọ́n tí wọ́n pa dà lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn. Ojú wo ni Jèhófà fi wo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀? Àwọn tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà ní ríronúpìwàdà láti ọkàn wá lè ní ìdánilójú pé “òun kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Orin Dáfídì 103:9, NW) Nínú àkàwé náà, bàbá náà sáré lọ pàdé ọmọ rẹ̀ láti kí i káàbọ̀. Bákan náà, kì í ṣe pé Jèhófà múra tán nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún ń hára gàgà láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó ronú pìwà dà. Ó “múra àti dárí jì,” ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ “lọ́nà títóbi.”—Orin Dáfídì 86:5; Aísáyà 55:7, NW; Sekaráyà 1:3.
Nínú àkàwé Jésù, ojúlówó ìfẹ́ tí bàbá náà ní mú kí ó rọrùn fún ọmọ náà láti gbójúgbóyà láti pa dà. Ṣùgbọ́n ronú ná: Kí ni ì bá ti ṣẹlẹ̀ ká ní bàbá náà ti kọ ọmọkùnrin náà lọ́mọ tàbí tí ó ti sọ fún un tìbínútìbínú pé kò gbọ́dọ̀ fẹsẹ̀ tẹlé òun mọ́? Ó ṣeé ṣe kí irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ ti sọ ọmọ náà di ìsáǹsá pátápátá.—Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 2:6, 7.
Nígbà náà, ní èrò kan, kí ọmọ náà tó kúrò nílé, bàbá náà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ rẹ̀. Nígbà míràn, ó máa ń pọn dandan fún àwọn Kristẹni alàgbà lónìí láti yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ. (Kọ́ríńtì Kíní 5:11, 13) Bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ náà láti pa dà wá, nípa fífi ìfẹ́ tọ́ka sí àwọn ìgbésẹ̀ tí ó lè gbé fún ìgbàpadà lọ́jọ́ iwájú. Rírántí irú ìpàrọwà àtọkànwá bẹ́ẹ̀ ti sún ọ̀pọ̀ tí ó ti sọ nù nípa tẹ̀mí láti ronú pìwà dà lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn, ó sì ti sún wọn láti pa dà sínú agbo ilé Ọlọ́run.—Tímótì Kejì 4:2.
Bàbá náà tún fi ìyọ́nú hàn nígbà tí ọmọ rẹ̀ pa dà dé. Kò gbà á ní àkókò láti rí ìrònúpìwàdà àtọkànwá ọmọ náà. Lẹ́yìn náà, dípò rírin kinkin mọ́ ọn pé kí ọmọ rẹ̀ sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún òun, ó gbájú mọ́ kíkí i káàbọ̀, ó sì fi hàn pé inú òun dùn gidigidi ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn Kristẹni lè fara wé irú àpẹẹrẹ yìí. Ó yẹ kí wọ́n dunnú pé a ti rí ẹnì kan tí ó sọ nù pa dà.—Lúùkù 15:10.
Ìṣarasíhùwà bàbá náà fi hàn kedere pé ó ti pẹ́ tí ó ti ń retí ìpadàbọ̀ ọmọ rẹ̀ aṣetinú-ẹni. Àmọ́ ṣáá o, ìyẹn wulẹ̀ jẹ́ òjìji ráńpẹ́ ti ìyánhànhàn tí Jèhófà ní fún gbogbo àwọn tí wọ́n ti fi agbo ilé rẹ̀ sílẹ̀. Òun “kò ní ìfẹ́ ọkàn pé kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó ní ìfẹ́ ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (Pétérù Kejì 3:9) Nítorí náà, àwọn tí wọn ronú pìwà dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn lè rí ìdánilójú pé a óò fi “àwọn àsìkò títunilára . . . láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀” bù kún wọn.—Ìṣe 3:19.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí ó jẹ́ pé a ka ẹrú sí apá kan agboolé, ìránṣẹ́ tí a háyà jẹ́ oníṣẹ́ òòjọ́, tí a lè lé dà nù nígbàkigbà. Ọ̀dọ́kùnrin náà ronú pé òun yóò tẹ́wọ́ gba ipò tí ó rẹlẹ̀ jù lọ pàápàá nínú agbo ilé bàbá òun.