ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 9/15 ojú ìwé 10-15
  • Ìwọ Yóò Ha Jẹ́ Olùṣòtítọ́ Bí Èlíjà Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Yóò Ha Jẹ́ Olùṣòtítọ́ Bí Èlíjà Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdánwò Amúnijígìrì ti Jíjẹ́ Ọlọ́run
  • “Wòlíì Èlíjà” Ha Ṣì Ń Bọ̀ Bí?
  • Wọ́n Ní Ẹ̀mí Èlíjà
  • Wọ́n Jẹ́ Olùṣòtítọ́ Lábẹ́ Ìdánwò
  • Jẹ́ Olùṣòtítọ́ Gẹ́gẹ́ Bí Èlíjà
  • Ó Rí Ìtùnú Gbà Lọ́dọ̀ Ọlọ́run Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ọlọ́run Rẹ̀ Tù Ú Nínú
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀rù Máa Ń Bà Ẹ́ Tó O Bá Dá Wà?
    Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 9/15 ojú ìwé 10-15

Ìwọ Yóò Ha Jẹ́ Olùṣòtítọ́ Bí Èlíjà Bí?

“Èmi yóò rán wòlíì Èlíjà sí i yín, kí ọjọ́ ńláǹlà Olúwa, àti ọjọ́ tí ó ní ẹ̀rù tó dé.”—MÁLÁKÌ 4:5.

1. Yánpọnyánrin wo ni ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì ti wà ní Ilẹ̀ Ìlérí fún nǹkan bí 500 ọdún?

“ILẸ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.” (Ẹ́kísódù 3:7, 8) Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyẹn lẹ́yìn tí ó dá wọn sílẹ̀ ní oko ẹrú Íjíbítì ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n wò ó! Ọ̀rúndún márùn-ún ti kọjá, nísinsìnyí ìyàn ti ń pọ́n ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì lójú. Ó ṣòro gidigidi láti rí ewéko tútù èyíkéyìí. Àwọn ẹranko ń kú, òjò kan kò sì kán sílẹ̀ láti bí ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. (Àwọn Ọba Kìíní 18:5; Lúùkù 4:25) Kí ni ó fa àjálù yí?

2. Kí ni okùnfà yánpọnyánrin orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì?

2 Ìpẹ̀yìndà ni ó dá yánpọnyánrin yìí sílẹ̀. Ní títàpá sí Òfin Ọlọ́run, Ọba Áhábù ti fẹ́ Jésíbẹ́lì, ọmọ ọba Kénáánì, ó sì gbà á láyè láti mú ìjọsìn Báálì wọ Ísírẹ́lì. Paríparí rẹ̀, ó kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún ọlọ́run èké yìí ní Samáríà, olú ìlú náà. Họ́wù, a ti tan Ísírẹ́lì sínú gbígbàgbọ́ pé ìjọsìn Báálì yóò mú irúgbìn yanturu wá fún wọn! Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti kìlọ̀, wọ́n dojú kọ ewu ‘rírun kúrò ní ilẹ̀ rere náà.’—Diutarónómì 7:3, 4; 11:16, 17; Àwọn Ọba Kìíní 16:30-33.

Ìdánwò Amúnijígìrì ti Jíjẹ́ Ọlọ́run

3. Báwo ni wòlíì Èlíjà ṣe darí àfiyèsí sórí ìṣòro gan-an tí Ísírẹ́lì ní?

3 Nígbà tí ìyàn náà bẹ̀rẹ̀, wòlíì Ọlọ́run olùṣòtítọ́ náà, Èlíjà, sọ fún Ọba Áhábù pé: “Bí Olúwa Ọlọ́run ti wà, níwájú ẹni tí èmi dúró, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún wọ̀nyí, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi.” (Àwọn Ọba Kìíní 17:1) Lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ yí rí bí a ṣe wí gan-an, ọba di ẹ̀bi náà ru Èlíjà fún mímú kí a ta Ísírẹ́lì nú nínú ẹgbẹ́. Ṣùgbọ́n Èlíjà fèsì pé Áhábù àti agbo ilé rẹ̀ ni ó ni ẹ̀bi náà, nítorí tí wọ́n pẹ̀yìndà di olùjọ́sìn Báálì. Láti yanjú ọ̀ràn náà, wòlíì Jèhófà rọ Ọba Áhábù láti kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sórí Òkè Kámẹ́lì, pa pọ̀ pẹ̀lú 450 wòlíì Báálì àti 400 wòlíì òpó ọlọ́wọ̀. Áhábù àti àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ péjú síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n retí pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò mú òpin dé bá ọ̀dá náà. Ṣùgbọ́n Èlíjà darí àfiyèsí sórí ọ̀ràn tí ó ṣe pàtàkì jù. Ó béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin óò máa ṣiyè méjì? Bí Olúwa bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!” Ọ̀rọ̀ pèsì jẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Àwọn Ọba Kìíní 18:18-21.

4. Láti yanjú ọ̀ràn jíjẹ́ Ọlọ́run, kí ni Èlíjà dábàá?

4 Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gbìyànjú láti da ìjọsìn Jèhófà pọ̀ mọ́ ìjọsìn Báálì. Láti yanjú ọ̀ràn jíjẹ́ Ọlọ́run, Èlíjà dábàá ìdíje kan. Òun yóò ṣaáyan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ẹbọ, àwọn wòlíì Báálì yóò sì ṣaáyan òmíràn. Lẹ́yìn náà, Èlíjà wí pé: “Kí ẹ . . . ké pe orúkọ àwọn ọlọ́run yín, èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa: Ọlọ́run náà tí ó fi iná dáhùn òun náà ni Ọlọ́run.” (Àwọn Ọba Kìíní 18:23, 24) Finú wòye kí iná ti ọ̀run wá ní ìdáhùn sí àdúrà!

5. Báwo ni a ṣe tú àìwúlò Báálì fó?

5 Èlíjà ní kí àwọn wòlíì Báálì bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ṣaáyan akọ màlúù kan fún ẹbọ, wọ́n sì tẹ́ ẹ sórí pẹpẹ. Lẹ́yìn náà, wọ́n ń tiro yí ká pẹpẹ náà, wọ́n ń gbàdúrà pé: “Báálì, dá wa lóhùn!” Wọ́n ṣe èyí “láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan.” Èlíjà fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Ẹ kígbe lóhùn rara.” Ó ní láti jẹ́ pé Báálì ń rí sí ọ̀ràn kánjúkánjú kan, tàbí kẹ̀ “bóyá ó ń sùn, ó yẹ kí a jí i.” Kò pẹ́ kò jìnnà, ẹ̀mí àwọn wòlíì Báálì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbóná. Ẹ wò ó! Wọ́n ń fi ọ̀bẹ asóró gún ara wọn yánnayànna, ẹ̀jẹ̀ sì ń dà yàlàyàlà jáde lójú ọgbẹ́ wọn. Ẹ sì wo bí ariwo náà yóò ti pọ̀ tó bí gbogbo 450 ti ń ké ni ohùn rara! Ṣùgbọ́n, kò sí ìdáhùn kankan.—Àwọn Ọba Kìíní 18:26-29.

6. Ìmúrasílẹ̀ wo ni Èlíjà ṣe fún ìdánwò jíjẹ́ Ọlọ́run?

6 Wàyí ò, ó yí kan Èlíjà. Ó tún pẹpẹ Jèhófà kọ́, ó gbẹ́ yàrà yí i ká, ó sì ṣètò ẹbọ náà. Lẹ́yìn náà, ó mú kí a da omi sórí igi àti ẹbọ náà. A da ìṣà omi ńlá méjìlá sórí pẹpẹ náà títí tí yàrà náà pàápàá fi kún. Ẹ wo irú àníyàn ńlá tí àwọn ènìyàn yóò ní bí Èlíjà ti ń gbàdúrà pé: “Olúwa Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísáákì àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ó di mímọ̀ lónìí pé, ìwọ ni Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì, èmi sì ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa ọ̀rọ̀ rẹ. Gbọ́ ti èmi, Olúwa, gbọ́ ti èmi, kí àwọn ènìyàn yí kí ó lè mọ̀ pé, Ìwọ Olúwa ni Ọlọ́run, àti pé, Ìwọ tún yí ọkàn wọn pa dà.”—Àwọn Ọba Kìíní 18:30-37.

7, 8. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà Èlíjà? (b) Kí ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ lórí Òkè Kámẹ́lì ṣàṣeparí?

7 Ní ìdáhùn sí àdúrà Èlíjà, ‘iná Olúwa já bọ́ láti ọ̀run, ó sì sun ẹbọ sísun náà, àwọn igi, àwọn òkúta, àti erùpẹ̀, ó sì lá omi tí ń bẹ nínú yàrà náà.’ Àwọn ènìyàn náà dojú bolẹ̀, wọ́n sì wí pé: “Olúwa, òun ni Ọlọ́run; Olúwa, òun ni Ọlọ́run!” (Àwọn Ọba Kìíní 18:38, 39) Wàyí o, Èlíjà gbé ìgbésẹ̀ onípinnu. Ó pàṣẹ pé: “Ẹ mú àwọn wòlíì Báálì; má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú wọn kí ó sá là.” Lẹ́yìn tí wọ́n pa wọ́n ní àfonífojì Kíṣónì, ìkùukùu dúdú bo àwọ sánmà mọ́lẹ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, eji wọwọ òjò mú òpin dé bá ọ̀dá náà!—Àwọn Ọba Kìíní 18:40-45; fi wé Diutarónómì 13:1-5.

8 Ẹ wo ọjọ́ ńlá tí èyí jẹ́! Jèhófà ja àjàṣẹ́gun nínú ìdánwò arabaríbí ti jíjẹ́ Ọlọ́run yìí. Síwájú sí i, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí yí ọkàn ọ̀pọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ní ọ̀nà yí àti ní àwọn ọ̀nà míràn, Èlíjà fẹ̀rí hàn pé wòlíì olùṣòtítọ́ ni òun jẹ́, ó sì kó ipa alásọtẹ́lẹ̀ kan.

“Wòlíì Èlíjà” Ha Ṣì Ń Bọ̀ Bí?

9. Kí ni a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Málákì 4:5, 6?

9 Nípasẹ̀ Málákì, Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ lẹ́yìn náà pé: “Wò ó, èmi óò rán wòlíì Èlíjà sí yín, kí ọjọ́ ńláǹlà Olúwa, àti ọjọ́ tí ó ní ẹ̀rù tó dé: Yóò sì pa ọkàn àwọn bàbá dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sí ti àwọn bàbá wọn, kí èmi kí ó má baà wá fi ayé gégùn-ún.” (Málákì 4:5, 6) Èlíjà gbé ní nǹkan bí 500 ọdún ṣáájú kí a tó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa ń fojú sọ́nà fún dídé Èlíjà láti ní ìmúṣẹ.—Mátíù 17:10.

10. Ta ni Èlíjà tí a sọ tẹ́lẹ̀, báwo ni a sì ṣe mọ̀?

10 Nígbà náà, ta ni Èlíjà tí ń bọ̀ yí? A fi ẹni tí ó jẹ́ hàn nígbà tí Jésù Kristi sọ pé: “Láti àwọn ọjọ́ Jòhánù Oníbatisí títí di ìsinsìnyí ìjọba àwọn ọ̀run ni góńgó náà tí àwọn ènìyàn ń fi ìsapá lépa, àwọn wọnnì tí ń fi ìsapá tẹ̀ síwájú sì ń gbá a mú. Nítorí pé gbogbo wọn, àwọn Wòlíì àti Òfin, sọ tẹ́lẹ̀ títí di ìgbà Jòhánù; bí ẹ̀yin bá sì fẹ́ láti tẹ́wọ́ gbà á, Òun fúnra rẹ̀ ni ‘Èlíjà tí a yàn tẹ́lẹ̀ láti wá.’” Bẹ́ẹ̀ ni, Jòhánù Oníbatisí ni aláfiwé Èlíjà tí a sọ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 11:12-14; Máàkù 9:11-13) Áńgẹ́lì kan ti sọ fún Sekaráyà, bàbá Jòhánù, pé Jòhánù yóò ní “ẹ̀mí àti agbára Èlíjà,” yóò sì “pèsè sílẹ̀ fún Jèhófà àwọn ènìyàn kan tí a ti múra sílẹ̀.” (Lúùkù 1:17) Ìbatisí tí Jòhánù ṣe jẹ́ àmì níwájú gbogbo ènìyàn fún ìrònúpìwàdà ẹnì kan lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ sí Òfin, tí ó yẹ kí ó sin àwọn Júù lọ sọ́dọ̀ Kristi. (Lúùkù 3:3-6; Gálátíà 3:24) Nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ Jòhánù ‘pèsè àwọn ènìyàn kan tí a ti múra sílẹ̀ fún Jèhófà.’

11. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì, kí ni Pétérù sọ nípa “ọjọ́ Jèhófà,” nígbà wo sì ni ó wáyé?

11 Iṣẹ́ Jòhánù Oníbatisí gẹ́gẹ́ bí “Èlíjà” fi hàn pé “ọjọ́ Jèhófà” ti sún mọ́lé. Àpọ́sítélì Pétérù pẹ̀lú fi bí ọjọ́ náà tí Ọlọ́run yóò gbégbèésẹ̀ lòdì sí àwọn ọ̀tá rẹ̀, tí yóò sì dá àwọn ènìyàn rẹ̀ sí ti sún mọ́lé tó hàn. Ó ṣàlàyé pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì nípa títú ẹ̀mí Ọlọ́run dà síni lórí. Pétérù fi hàn pé èyí ní láti ṣẹlẹ̀ ṣáájú “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ alókìkíkáyé ti Jèhófà.” (Ìṣe 2:16-21; Jóẹ́lì 2:28-32) Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa ni Jèhófà mú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ nípa mímú kí àwọn ọmọ ogun Róòmù mú ìdájọ́ àtọ̀runwá ṣẹ sórí orílẹ̀-èdè tí ó kọ Ọmọkùnrin rẹ̀ sílẹ̀.—Dáníẹ́lì 9:24-27; Jòhánù 19:15.

12. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù àti Pétérù sọ nípa dídé “ọjọ́ Jèhófà”? (b) Èé ṣe tí ó fi dájú pé ohun kan yóò ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ohun tí iṣẹ́ Èlíjà dúró fún?

12 Ṣùgbọ́n, ohun mìíràn ṣì ń bẹ níwájú lẹ́yìn ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù so dídé “ọjọ́ Jèhófà” mọ́ wíwàníhìn-ín Jésù Kristi. Síwájú sí i, àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa ọjọ́ náà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú “àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” tí ó ṣì wà ní ọjọ́ iwájú. (Tẹsalóníkà Kejì 2:1, 2; Pétérù Kejì 3:10-13) Rántí pé Jòhánù Oníbatisí ṣe irú iṣẹ́ tí Èlíjà ṣe kí “ọjọ́ Jèhófà” tó dé ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Gbogbo ìwọ̀nyí lápapọ̀ fi hàn pé ohun kan yóò ṣì ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ohun tí iṣẹ́ tí Èlíjà ṣe dúró fún. Kí ni ohun náà?

Wọ́n Ní Ẹ̀mí Èlíjà

13, 14. (a) Ìdọ́gba wo ni ó wà nínú ìgbòkègbodò Èlíjà àti ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti òde òní? (b) Kí ni àwọn apẹ̀yìndà Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ṣe?

13 Kì í ṣe nínú ìgbòkègbodò Jòhánù Oníbatisí nìkan ni iṣẹ́ Èlíjà ti ní ohun tí ó bá dọ́gba, ṣùgbọ́n ó tún ní ohun tí ó bá dọ́gba nínú ìgbòkègbodò àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní àkókò líle koko yìí tí ń sinni lọ sí dídé “ọjọ́ Jèhófà.” (Tímótì Kejì 3:1-5) Pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà, wọ́n jẹ́ alágbàwí dídúró ṣinṣin fún ìjọsìn tòótọ́. Ẹ sì wo bí èyí ti pọn dandan tó! Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì Kristi, ìpẹ̀yìndà kúrò nínú ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ wáyé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìjọsìn Báálì ṣe gbilẹ̀ ní Ísírẹ́lì ti ọjọ́ Èlíjà. (Pétérù Kejì 2:1) Àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà ìsìn èké lú ẹ̀sìn Kristẹni. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n gba ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà, tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu pé ènìyàn ní àìleèkú ọkàn. (Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4) Àwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà ti jáwọ́ nínú lílo orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, Jèhófà. Dípò èyí, wọ́n ń sin Mẹ́talọ́kan. Wọ́n tún ti gba àṣà bíi ti Báálì, ti fíforí balẹ̀ fún ère Jésù àti ti ìyá rẹ̀, Màríà. (Róòmù 1:23; Jòhánù Kíní 5:21) Ṣùgbọ́n kò mọ síbẹ̀ yẹn.

14 Láti ọ̀rúndún kọkàndínlógún síwájú, àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ iyè méjì tí wọ́n ní nípa ọ̀pọ̀ apá Bíbélì jáde. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n kọ àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì nípa ìṣẹ̀dá sílẹ̀, wọ́n sì fògo fún àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n, ní pípè é ní “èyí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu.” Èyí ní tààràtà tako ẹ̀kọ́ Jésù Kristi àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. (Mátíù 19:4, 5; Kọ́ríńtì Kíní 15:47) Ṣùgbọ́n, bíi Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ìjímìjí, lónìí, àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí yàn gbé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá lárugẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.

15, 16. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí Kirisẹ́ńdọ̀mù, àwọn wo ni ó ti gbádùn ìpèsè déédéé oúnjẹ tẹ̀mí, nípasẹ̀ kí sì ni?

15 Bí ayé ti wọnú “àkókò òpin,” ìyàn nípa tẹ̀mí gbá Kirisẹ́ńdọ̀mù mú. (Dáníẹ́lì 12:4; Ámósì 8:11, 12) Ṣùgbọ́n àwùjọ kékeré ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gbádùn ìpèsè déédéé ti oúnjẹ tẹ̀mí tí Ọlọ́run ń fi fúnni “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti rí sí i pé a bọ́ Èlíjà nígbà ìyàn tí ó mú ní ọjọ́ rẹ̀. (Mátíù 24:45; Àwọn Ọba Kìíní 17:6, 13-16) Àwọn tí a mọ̀ sí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé tẹ́lẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ ti Ọlọ́run wọ̀nyí wá gba orúkọ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Aísáyà 43:10.

16 Èlíjà gbé ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀, tí ó túmọ̀ sí “Jèhófà ni Ọlọ́run mi.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé àtìgbàdégbà ti àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé tí a fàṣẹ tì lẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ ti fìgbà gbogbo lo orúkọ Ọlọ́run. Ní tòótọ́, ìtẹ̀jáde rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì (August 1879) sọ ìdánilójú náà pé Jèhófà ni alátìlẹ́yìn ìwé ìròyìn náà. Ìwé àtìgbàdégbà yí àti àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society mìíràn tú àwọn ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù àti ìyókù Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tí kó bá Ìwé Mímọ́ mu fó, bí wọ́n ti ń gbé ìjóòtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, lárugẹ.—Tímótì Kejì 3:16, 17; Ìṣípayá 18:1-5.

Wọ́n Jẹ́ Olùṣòtítọ́ Lábẹ́ Ìdánwò

17, 18. Kí ni ìhùwàpadà Jésíbẹ́lì sí pípa tí a pa àwọn wòlíì Báálì, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe ran Èlíjà lọ́wọ́?

17 Ìhùwàpadà àwùjọ àlùfáà sí ìtúfó náà rí bákan náà pẹ̀lú ti Jésíbẹ́lì nígbà tí ó gbọ́ pé Èlíjà ti pa àwọn wòlíì Báálì. Ó fi iṣẹ́ kan ránṣẹ́ sí wòlíì olùṣòtítọ́ Jèhófà, ní bíbúra láti pa á. Èyí kì í ṣe ìhalẹ̀mọ́ni lásán, nítorí tí Jésíbẹ́lì ti pa ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì Ọlọ́run tẹ́lẹ̀. Pẹ̀lú ìbẹ̀rù, Èlíjà sá lọ sí Bíá-Ṣébà, ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn. Ó fi ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, ó sì túbọ̀ rìn síwájú sí i, sínú aginjù, ó gbàdúrà fún ikú. Ṣùgbọ́n Jèhófà kò tí ì pa wòlíì rẹ̀ tì. Áńgẹ́lì kan fara han Èlíjà, láti mú kí ó gbára dì fún ìrìn àjò gígùn kan sí orí Òkè Hórébù. Nípa báyìí ó gba ohun agbẹ́mìíró fún ìrìn àjò 40 ọjọ́ tí ó lé ní 300 kìlómítà. Ní Hórébù, Ọlọ́run bá a sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ó ti fi agbára rẹ̀ hàn nínú ẹ̀fúùfù ńlá, ìsẹ̀lẹ̀, àti iná. Jèhófà kò sí nínú àwọn ohun tí ó fi hàn án wọ̀nyí. Wọ́n jẹ́ ìfihàn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá wòlíì rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ẹ wo bí ìrírí yìí yóò ti fún Èlíjà lókun tó. (Àwọn Ọba Kìíní 19:1-12) Bíi ti Èlíjà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wá nígbà tí àwọn ọ̀tá ìjọsìn tòótọ́ halẹ̀ mọ́ wa ńkọ́? Ó yẹ kí ìrírí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Jèhófà kì í pa àwọn ènìyàn rẹ̀ tì.—Sámúẹ́lì Kíní 12:22.

18 Ọlọ́run mú kí ó ṣe kedere pé Èlíjà ṣì ní iṣẹ́ láti ṣe gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Síwájú sí i, bí Èlíjà tilẹ̀ rò pé òun nìkan ṣoṣo ni olùjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ ní Ísírẹ́lì, Jèhófà fi hàn án pé 7,000 ènìyàn kò tí ì forí balẹ̀ fún Báálì. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run rán Èlíjà pa dà sẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀. (Àwọn Ọba Kìíní 19:13-18) Bí Èlíjà, àwọn ọ̀tá ìjọsìn tòótọ́ lè máa lépa wa. A lè di ojúsun inúnibíni gbígbóná janjan, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀. (Jòhánù 15:17-20) Nígbà míràn, àyà wa lè máa já. Ṣùgbọ́n, a lè dà bí Èlíjà, tí ó gba ìdánilójú àtọ̀runwá, tí ó sì fara dà á nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tòótọ́tòótọ́.

19. Kí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nírìírí rẹ̀ ní àkókò Ogun Àgbáyé Kìíní?

19 Nítorí inúnibíni gbígbóná janjan nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ìbẹ̀rù mú kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan juwọ́ sílẹ̀, wọ́n sì jáwọ́ nínú wíwàásù. Wọ́n ṣàṣìṣe ní ríronú pé iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé ti dópin. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi àánú pèsè fún wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pèsè oúnjẹ fún Èlíjà. Bí Èlíjà, àwọn ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ tẹ́wọ́ gba àtúnṣe àtọ̀runwá, wọ́n sì kọ́fẹ pa dà nínú àìlọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò. A la ojú wọn sí àǹfààní títóbi lọ́lá ti wíwàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba.

20. Lónìí, àǹfààní wo ni a fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ bí Èlíjà?

20 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀, Jésù ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ tí yóò kárí ayé tí a óò parí kí òpin ètò búburú ìsinsìnyí tó dé. (Mátíù 24:14) Lónìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ alájọṣepọ̀ wọn, tí wọ́n fojú sọ́nà sí ìyè lórí párádísè orí ilẹ̀ ayé, ní ń ṣe iṣẹ́ yìí. Ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba títí tí yóò fi parí jẹ́ àǹfààní tí a fi fún kìkì àwọn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí Èlíjà.

Jẹ́ Olùṣòtítọ́ Gẹ́gẹ́ Bí Èlíjà

21, 22. (a) Iṣẹ́ wo ní àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń mú ipò iwájú nínú rẹ̀ lónìí? (b) Nípasẹ̀ ìrànwọ́ wo ni a fi ń ṣàṣeparí iṣẹ́ ìwàásù, èé sì ti ṣe tí a fi nílò rẹ̀?

21 Pẹ̀lú ìtara gẹ́gẹ́ bíi ti Èlíjà, àṣẹ́kù kékeré ti ojúlówó Kristẹni ẹni àmì òróró ti ṣe ojúṣe wọn ti bíbójú tó ire Jésù Kristi, Ọba náà tí a ti gbé gorí ìtẹ́, lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:47) Ní ohun tí ó lé ní 60 ọdún sí ìsinsìnyí, Ọlọ́run ti ń lo àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí láti mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, tí ó ti fún ní ìrètí àgbàyanu ti ìyè ayérayé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 28:19, 20) Ẹ wo bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọ̀nyí ti kún fún ọpẹ́ tó pé àṣẹ́kù ẹni àmì òróró tí wọ́n kéré ní ìfiwéra ń fi ìtara àti ìṣòtítọ́ bójú tó ẹrù iṣẹ́ wọn!

22 Àwọn ènìyàn aláìpé ti ṣàṣeparí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba yìí, ó sì jẹ́ kìkì nípasẹ̀ okun tí Jèhófà fún àwọn tí wọ́n gbára lé e tàdúràtàdúrà. Nígbà tí ó ń tọ́ka sí àpẹẹrẹ wòlíì náà ní ti àdúrà láti fi agbára àdúrà olódodo hàn, Jákọ́bù sọ pé: “Èlíjà jẹ́ ènìyàn kan tí ó ní ìmọ̀lára bíi tiwa.” (Jákọ́bù 5:16-18) Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Èlíjà máa ń sọ tẹ́lẹ̀ tàbí ṣe iṣẹ́ ìyanu. Irú ìmọ̀lára àti ìkù-díẹ̀-káàtó tí a ní náà ni òun ní, ṣùgbọ́n, ó sin Ọlọ́run tòótọ́tòótọ́. Níwọ̀n bí àwa pẹ̀lú ti ní ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, tí ó sì ń fún wa lókun, a lè jẹ́ olùṣòtítọ́ bí Èlíjà.

23. Èé ṣe tí a fi ní ìdí rere fún jíjẹ́ olùṣòtítọ́ àti olùfojúsọ́nà fún rere?

23 A ní ìdí púpọ̀ láti jẹ́ olùṣòtítọ́ àti láti jẹ́ olùfojúsọ́nà fún rere. Rántí pé Jòhánù Oníbatisí ṣe irú iṣẹ́ tí Èlíjà ṣe ṣáájú kí “ọjọ́ Jèhófà” tó dé ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ṣe irú iṣẹ́ kan náà tí Ọlọ́run fi fún wọn láti ṣe jákèjádò ayé. Ní kedere, èyí fi hàn pé “ọjọ́ Jèhófà” ti sún mọ́lé.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsì?

◻ Báwo ni a ṣe fẹ̀rí jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run hàn lórí Òkè Kámélì?

◻ Ta ni ‘Èlíjà tí ń bọ̀,’ kí sì ni ó ṣe?

◻ Báwo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti òde òní ṣe fi hàn pé àwọn ní ẹ̀mí Èlíjà?

◻ Èé ṣe tí a fi lè jẹ́ olùṣòtítọ́ bí Èlíjà?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]

Ọ̀run Wo ní Èlíjà Gòkè Lọ?

“Ó SÌ ṣe, bí [Èlíjà àti Èlíṣà] ti ń lọ, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀, sì kíyè sí i, kẹ̀kẹ́ iná àti ẹṣin iná sì la àárín àwọn méjèèjì, Èlíjà sì bá àjà gòkè re ọ̀run.”​—⁠Àwọn Ọba Kejì 2:⁠11.

Kí ni ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀run,” túmọ̀ sí nínú ọ̀ràn yí? Nígbà míràn, ọ̀rọ̀ náà máa ń tọ́ka sí ibi ẹ̀mí tí Ọlọ́run àti àwọn áńgẹ́lì ọmọkùnrin rẹ̀ ń gbé. (Mátíù 6:⁠9; 18:10) “Ọ̀run” tún lè tọ́ka sí àgbáálá ọ̀run tí a lè fojú rí. (Diutarónómì 4:19) Bíbélì sì lo ọ̀rọ̀ yí láti tọ́ka sí àyíká tí ó sún mọ́ ayé jù lọ, níbi tí àwọn ẹyẹ ti máa ń fò, tí afẹ́fẹ́ ti máa ń fẹ́.​—⁠Orin Dáfídì 78:26; Mátíù 6:26.

Èwo nínú àwọn ọ̀run wọ̀nyí ni wòlíì Èlíjà gòkè lọ? Ẹ̀rí fi hàn pé a gbé e la àyíká ayé kọjá bọ́ sí apá ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé. Èlíjà ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nítorí pé ó kọ lẹ́tà kan sí Ọba Jèhórámù ti Júdà. (Kíróníkà Kejì 21:​1, 12-⁠15) Pé Èlíjà kò gòkè lọ sí ibùgbé tẹ̀mí tí Jèhófà Ọlọ́run ń gbé ni Jésù Kristi jẹ́rìí sí lẹ́yìn náà nígbà tí ó sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọkùnrin ènìyàn,” ìyẹn ni, Jésù fúnra rẹ̀. (Jòhánù 3:13) Ọ̀nà sí ìyè ní ọ̀run ni a kọ́kọ́ ṣí sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn aláìpé lẹ́yìn ikú, àjíǹde, àti ìgòkè re ọ̀run Jésù Kristi.​—⁠Jòhánù 14:​2, 3; Hébérù 9:24; 10:​19, 20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́