ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 10/1 ojú ìwé 10-15
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Dúró Láéláé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Dúró Láéláé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nígbà Tí Ó Dojú Kọ Ìgbìdánwò Láti Tẹ̀ Ẹ́ Rì
  • Dídáàbò Bo Ọ̀rọ̀ Náà Kí A Má Baà Bà Á Jẹ́
  • Ìhìn Iṣẹ́ Tàn Dé Gbogbo Ayé
  • Jèhófà Máa Ń Bá Àwa Èèyàn Sọ̀rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kí Nìdí Tí Oríṣiríṣi Bíbélì Fi Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́
    Jí!—2007
  • Orukọ Ọlọrun ati “Majẹmu Titun” Naa
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 10/1 ojú ìwé 10-15

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Dúró Láéláé

“Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa yóò dúró láéláé.”—AÍSÁYÀ 40:8.

1. (a) Kí ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa” túmọ̀ sí níhìn-ín? (b) Báwo ni ìlérí ẹ̀dá ènìyàn ṣe yàtọ̀ sí ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Ẹ̀DÁ ènìyàn ní ìtẹ̀sí láti gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí àwọn ọkùnrin àti obìnrin olókìkí. Ṣùgbọ́n láìka bí àwọn ìlérí wọ̀nyí ti lè fa àwọn tí ń yán hànhàn fún ìgbépẹ́ẹ́lí sí i nínú ipò ìgbésí ayé wọn mọ́ra tó, bí a bá fi wé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, àwọn ìlérí wọ̀nyí dà bí òdòdó tí ń rọ. (Orin Dáfídì 146:3, 4) Ní èyí tí ó lé ní 2,700 ọdún sẹ́yìn, Jèhófà Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti kọ̀wé pé: “Gbogbo ẹran ara ni koríko, gbogbo ògo rẹ̀ sì dà bí ìtànná ìgbẹ́. Koríko ń rọ, ìtànná ń rẹ̀: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa yóò dúró láéláé.” (Aísáyà 40:6, 8) Kí ni “ọ̀rọ̀” náà tí yóò dúró láéláé? Gbólóhùn Ọlọ́run nípa ète rẹ̀ ni. Lónìí, a ní àkọsílẹ̀ “ọ̀rọ̀” yẹn nínú Bíbélì.—Pétérù Kíní 1:24, 25.

2. Kí ni ìṣarasíhùwà àti ìgbésẹ̀ tí ó gbilẹ̀ nígbà tí Jèhófà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa Ísírẹ́lì ìgbàanì àti Júdà ṣẹ?

2 Àwọn tí wọ́n wà láàyè ní àwọn ọjọ́ Ísírẹ́lì ìgbàanì nírìírí ìjótìítọ́ ohun tí Aísáyà kọ sílẹ̀. Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ pé, a óò kọ́kọ́ kó ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì nígbèkùn, lẹ́yìn náà, a óò kó ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà nígbèkùn, nítorí ìwà àìṣòótọ́ wọn tí ó lé kenkà. (Jeremáyà 20:4; Ámósì 5:2, 27) Bí wọ́n tilẹ̀ ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì Jèhófà, tí wọ́n pa wọ́n, tí wọ́n dáná sun àkájọ ìwé tí ìhìn iṣẹ́ ìkìlọ̀ Ọlọ́run ń bẹ nínú rẹ̀, tí wọ́n sì ké gbàjarè sí Íjíbítì fún ìrànwọ́ ológun láti dènà ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà kò tàsé. (Jeremáyà 36:1, 2, 21-24; 37:5-10; Lúùkù 13:34) Ní àfikún sí i, ìlérí Ọlọ́run láti mú àṣẹ́kù Júù tí ó ronú pìwà dà pa dà wá sí ilẹ̀ wọn ní ìmúṣẹ tí ó kàmàmà.—Aísáyà, orí 35.

3. (a) Àwọn ìlérí tí Aísáyà kọ sílẹ̀ wo ni ó fà wá lọ́kàn mọ́ra gan-an? (b) Èé ṣe tí ó fi dá ọ lójú pé àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò nímùúṣẹ ní tòótọ́?

3 Nípasẹ̀ Aísáyà, Jèhófà tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣàkóso òdodo lórí aráyé nípasẹ̀ Mèsáyà, ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, àti sísọ ilẹ̀ ayé di párádísè kan. (Aísáyà 9:6, 7; 11:1-9; 25:6-8; 35:5-7; 65:17-25) Àwọn nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú yóò ha ṣẹ bí? Kò sí iyè méjì kankan nípa rẹ̀! “Ọlọ́run . . . kò lè purọ́.” Ó mú kí a kọ ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ fún àǹfààní wa, ó sì ti rí i dájú pé a pa á mọ́.—Títù 1:2; Róòmù 15:4.

4. Bí a kò tilẹ̀ pa Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a fọwọ́ kọ mọ́, báwo ni ó ṣe jẹ́ òtítọ́ tó pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “wà láàyè”?

4 Jèhófà kò pa ìwé àfọwọ́kọ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn akọ̀wé rẹ̀ ìgbàanì kọ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn sí mọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀rí fi hàn pé “ọ̀rọ̀” rẹ̀, ète rẹ̀ tí ó sọ jáde, jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń bẹ láàyè. Ète yẹn ń tẹ̀ síwájú láìṣeé dá dúró, bí ó sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, èrò inú àti ìsúnniṣe àwọn ènìyàn tí ó ti nípa lórí ìgbésí ayé wọn fara hàn. (Hébérù 4:12) Síwájú sí i, àkọsílẹ̀ ìtàn fi hàn pé pípa tí a pa Ìwé Mímọ́ tí a mí sí mọ́ àti títúmọ̀ tí a túmọ̀ rẹ̀ jẹ́ nípa ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá.

Nígbà Tí Ó Dojú Kọ Ìgbìdánwò Láti Tẹ̀ Ẹ́ Rì

5. (a) Ìsapá wo ni ọba Síríà kan ṣe láti run Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí a mí sí? (b) Èé ṣe tí ó fi kùnà?

5 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn alákòóso ti sakun láti run àwọn ìwé tí a mí sí náà. Ní ọdún 168 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọba Síríà, Antiochus Epiphanes (tí a yàwòrán rẹ̀ sí ojú ìwé 10) kọ́ pẹpẹ kan fún Súúsì nínú tẹ́ńpìlì tí a ti yà sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó tún ṣàwárí ‘àwọn ìwé Òfin,’ ó dáná sun wọ́n, ó sì sọ pé kí a pa ẹnikẹ́ni tí a bá ká irú Ìwé Mímọ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ lọ́wọ́. Láìka iye ẹ̀dà tí ó dáná sun ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà sí, kò lè tẹ Ìwé Mímọ́ rì pátápátá. Àgbègbè àdádó àwọn Júù nígbà yẹn wà káàkiri ọ̀pọ̀ ilẹ̀, sínágọ́gù kọ̀ọ̀kan sì ní àwọn àkájọ ìwé tirẹ̀.—Fi wé Ìṣe 13:14, 15.

6. (a) Ìsapá lílágbára wo ni a ṣe láti run Ìwé Mímọ́ tí àwọn Kristẹni ìjímìjí ń lò? (b) Kí ni àbájáde rẹ̀?

6 Ní ọdún 303 Sànmánì Tiwa, Olú Ọba Róòmù, Diocletian bákan náà pàṣẹ pé kí a wó ilé ìpàdé àwọn Kristẹni palẹ̀ kí a sì ‘dáná sun Ìwé Mímọ́ wọn.’ Irú ìparun bẹ́ẹ̀ bá a lọ fún ẹ̀wádún kan. Bí inúnibíni náà ti burú tó, Diocletian kò kẹ́sẹ járí nínú pípa ẹ̀sìn Kristẹni run, bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọ́run kò yọ̀ǹda fún àwọn aṣojú olú ọba náà láti run gbogbo ẹ̀dà apá èyíkéyìí nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí ó mí sí. Ṣùgbọ́n nípa ìhùwàpadà wọn sí ìpínkiri àti ìwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn alátakò fi ohun tí ń bẹ lọ́kàn wọn hàn. Wọ́n fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni tí Sátánì ti fọ́ lójú, tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Jòhánù 8:44; Jòhánù Kíní 3:10-12.

7. (a) Ìsapá wo ni a ṣe láti ṣèdíwọ́ fún títan ìmọ̀ Bíbélì kálẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn Europe? (b) Kí ni a ṣàṣeparí nínú ìtumọ̀ àti ìtẹ̀jáde Bíbélì?

7 Akitiyan láti ṣèdíwọ́ fún ìmọ̀ Bíbélì tí ń tàn kálẹ̀ tún gba àwọn ọ̀nà míràn. Nígbà tí èdè Látìn di èdè tí a kò sọ mọ́, kì í ṣe àwọn abọ̀rìṣà alákòóso bí kò ṣe àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni—Póòpù Gregory Keje (1073-85) àti Póòpù Innocent Kẹta (1198-1216)—ni wọ́n fi torítọrùn ta ko títú Bíbélì sí èdè àwọn gbáàtúù. Nínú ìsapá láti bomi paná lílòdì sí ọlá àṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì, Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ti Toulouse, ní ilẹ̀ Faransé, ní ọdún 1229, pàṣẹ pé ọmọ ìjọ lásán kò lè ní àwọn ìwé Bíbélì ní èdè àwọn gbáàtúù. Lọ́nà gbígbóná janjan, a lo Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ láti rí i pé àṣẹ yìí múlẹ̀. Síbẹ̀, lẹ́yìn 400 ọdún Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti tú Bíbélì látòkè délẹ̀, wọ́n sì pín ẹ̀dà rẹ̀ tí a tẹ̀ ní nǹkan bí 20 èdè, pẹ̀lú àwọn èdè àdúgbò míràn àti apá tí ó pọ̀ jù nínú rẹ̀ ní èdè 16 kiri.

8. Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, kí ni ó ṣẹlẹ̀ nínú apá ìgbòkègbodò títúmọ̀ Bíbélì àti pípín in kiri ní Rọ́ṣíà?

8 Kì í ṣe Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì nìkan ni ó sakun láti rí i pé Bíbélì kò tẹ àwọn gbáàtúù lọ́wọ́. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Pavsky, ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Àlùfáà ní St. Petersburg, tú Ìhìn Rere Mátíù láti èdè Gíríìkì sí èdè Russian. A tún tú àwọn ìwé mìíràn tí ó jẹ́ ti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí èdè Russian, tí Pavsky sì jẹ́ olóòtú rẹ̀. A pín ìwọ̀nyí kiri lọ́nà gbígbòòrò títí di ọdún 1826, nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì tagbọ́n, tí ó sún olú ọba láti mú Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Nílẹ̀ Rọ́ṣíà wá sábẹ́ àbójútó “Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́” ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà, tí ó sì kẹ́sẹ járí ní títẹ iṣẹ́ rẹ̀ rì nígbà náà lọ́hùn-ún. Lẹ́yìn náà, Pavsky tú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti èdè Hébérù sí èdè Russian. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní àkókò kan náà ni Makarios, àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan, pẹ̀lú tú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti èdè Hébérù sí èdè Russian. A fìyà jẹ àwọn méjèèjì fún akitiyan wọn, a sì kó àwọn ìwé tí wọ́n tú pa mọ́ sí ilé ìkówèé-ìṣẹ̀ǹbáyé-pa-mọ́-sí ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ṣọ́ọ̀ṣì pinnu láti máà jẹ́ kí Bíbélì wà ní èdè míràn yàtọ̀ sí èdè Slavic àtijọ́, tí gbáàtúù ènìyàn kì í kà nígbà náà, tí wọn kì í sì í lóye. Àfìgbà tí akitiyan àwọn ènìyàn láti jèrè ìmọ̀ Bíbélì di èyí tí kò ṣeé tẹ̀ rì mọ́ ni “Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́,” ní ọdún 1856, tó dáwọ́ lé ìtumọ̀ tìrẹ tí ẹgbẹ́ alákòóso ṣọ́ọ̀ṣì fọwọ́ sí, ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìlànà tí a fìṣọ́ra gbé kalẹ̀ láti rí i dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò bá ojú ìwòye ṣọ́ọ̀ṣì mu. Nípa báyìí, ní ti títan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kálẹ̀, a mú kí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ohun tí àwọn aṣáájú ìsìn sọ pé àwọn jẹ́ àti èrò inú wọn gan-an fara hàn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn ti ṣí i payá.—Tẹsalóníkà Kejì 2:3, 4.

Dídáàbò Bo Ọ̀rọ̀ Náà Kí A Má Baà Bà Á Jẹ́

9. Báwo ni àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan ṣe fi ìfẹ́ wọn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn?

9 Àwọn ọkùnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní tòótọ́, tí wọ́n sì sapá gidigidi láti mú kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn, wà lára àwọn tí wọ́n túmọ̀ Ìwé Mímọ́, tí wọ́n sì ṣe àdàkọ rẹ̀. William Tyndale kú ikú ajẹ́rìíkú (ní ọdún 1536) nítorí akitiyan rẹ̀ láti mú kí Bíbélì wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ìgbìmọ̀ Kátólíìkì Nípa Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ (lẹ́yìn ọdún 1544) ju Francisco de Enzinas sẹ́wọ̀n fún títú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí èdè Spanish àti títẹ̀ ẹ́ jáde ní èdè náà. Ní fífi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, Robert Morrison (láti ọdún 1807 sí 1818) tú Bíbélì sí èdè Chinese.

10. Àwọn àpẹẹrẹ wo ni ó fi hàn pé àwọn olùtumọ̀ kan ń bẹ tí ète tí ń sún wọn ṣiṣẹ́ yàtọ̀ pátápátá sí ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

10 Ṣùgbọ́n, nígbà míràn, àwọn ọ̀ràn míràn ni ó nípa lórí iṣẹ́ àwọn adàwékọ àti olùtumọ̀, kì í ṣe ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Gbé àpẹẹrẹ mẹ́rin yẹ̀ wò: (1) Àwọn ará Samáríà kọ́ tẹ́ńpìlì kan sórí Òkè Gérísímù gẹ́gẹ́ bí èyí tí yóò gbapò lọ́wọ́ tẹ́ńpìlì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù. Láti ti ìgbésẹ̀ yẹn lẹ́yìn, a mú ọ̀rọ̀ kan wọnú Ẹ́kísódù 20:17 nínú Pentateuch ti Àwọn Ará Samáríà. A fi àṣẹ náà kún un, bíi pé ó jẹ́ apá kan Òfin Mẹ́wàá, pé kí a kọ́ pẹpẹ òkúta kan sórí Òkè Gérísímù, kí a sì máa rúbọ níbẹ̀. (2) Ẹni tí ó kọ́kọ́ tú ìwé Dáníẹ́lì sí Septuagint èdè Gíríìkì tẹ òfin lójú nínú àwọn ìtumọ̀ tí ó ṣe. Ó mú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó rò pé yóò ṣàlàyé tàbí mú kí ohun tí ó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dùn sí i wọ̀ ọ́. Ó yọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó rò pé àwọn òǹkàwé kò ní tẹ́wọ́ gbà sílẹ̀. Nígbà tí ó túmọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àkókò tí Mèsáyà yóò fara hàn, tí a rí nínú Dáníẹ́lì 9:24-27, ó purọ́ nípa ọ̀rọ̀ àkókò ti a sọ, ó fi kún ọ̀rọ̀, ó yí wọn pa dà, ó sì pa ipò wọn dà, ó hàn gbangba pé èyí jẹ́ pẹ̀lú ète mímú kí àsọtẹ́lẹ̀ náà dà bí èyí tí ó ti ìjàkadì àwọn Maccabees lẹ́yìn. (3) Ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, nínú àkọsílẹ̀ kan ní èdè Látìn, ó hàn gbangba pé alágbàwí Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí ó jẹ́ onítara tí ó ré kọjá ààlà fi àwọn ọ̀rọ̀ náà, “Bàbá, Ọ̀rọ̀, àti ẹ̀mí mímọ́, ń bẹ ní ọ̀run; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo” kún un, bíi pé èyí jẹ́ àyọlò láti inú Jòhánù Kíní 5:7. Lẹ́yìn náà, a mú àyọkà yẹn wọnú Bíbélì tí a fọwọ́ kọ lédè Látìn. (4) Ní ilẹ̀ Faransé, Louis Kẹtàlá (ọdún 1610 sí 1643) pàṣẹ fún Jacques Corbin láti tú Bíbélì sí èdè Faransé láti baà lè dojú ìsapá àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì dé. Pẹ̀lú ète yẹn lọ́kàn, Corbin fi àwọn ọ̀rọ̀ kan kún un, títí kan títọ́ka sí “ìrúbọ mímọ́ ti Máàsì” nínú Ìṣe 13:2.

11. (a) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe dúró láìka àbòsí àwọn olùtumọ̀ kan sí? (b) Báwo ni ẹ̀rí ìwé àfọwọ́kọ ìgbàanì ti pọ̀ tó láti fi ohun tí Bíbélì sọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ hàn? (Wo àpótí.)

11 Jèhófà kò dènà títọwọ́bọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni títọwọ́bọ̀ ọ́ kò yí ète rẹ̀ pa dà. Ipa wo ni ó ní? Ṣíṣàfikún ìtọ́kasí nípa Òkè Gérísímù kò mú kí ìsìn àwọn ará Samáríà di ètò tí Ọlọ́run yóò lò fún bíbùkún aráyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ̀rí hàn pé, bí ìsìn àwọn ará Samáríà tilẹ̀ sọ pé òun gba Pentateuch gbọ́, a kò lè gbára lé e fún fífi òtítọ́ kọ́ni. (Jòhánù 4:20-24) Lílọ́ ọ̀rọ̀ po nínú Septuagint kò dí Mèsáyà lọ́wọ́ láti wá ní àkókò tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Dáníẹ́lì. Síwájú sí i, bí ó tilẹ̀ jẹ́ Septuagint ni a ń lò ní ọ̀rúndún kìíní, ó hàn gbangba pé ó ti mọ́ àwọn Júù lára láti máa gbọ́ kíka Ìwé Mímọ́ ní èdè Hébérù nínú sínágọ́gù wọn. Ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé, “àwọn ènìyàn náà ti wà nínú ìfojúsọ́nà” nígbà tí àkókò fún ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà sún mọ́lé. (Lúùkù 3:15) Ní ti àfikún ọ̀rọ̀ tí a ṣe nínú Jòhánù Kíní 5:7 láti ti Mẹ́talọ́kan lẹ́yìn àti nínú Ìṣe 13:2 láti ti ẹ̀kọ́ Máàsì lẹ́yìn, ìwọ̀nyí kò yí òtítọ́ pa dà. Kò sì pẹ́ púpọ̀ tí a fi tú gbogbo màgòmágó náà fó pátápátá. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ Bíbélì tí a fọwọ́ kọ ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó pèsè ọ̀nà láti ṣàyẹ̀wò bí ìtumọ̀ èyíkéyìí ti lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó.

12. (a) Àwọn ìyípadà ńláǹlà wo ni àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan ṣe? (b) Báwo ni àwọn wọ̀nyí ti lọ jìnnà tó?

12 Àwọn ìsapá mìíràn láti yí Ìwé Mímọ́ pa dà tún ní nínú ju yíyí àwọn ẹsẹ mélòó kan pa dà lọ. Ìwọ̀nyí para pọ̀ jẹ́ títako mímọ Ọlọ́run tòótọ́ náà fúnra rẹ̀. Ọ̀nà tí a gbà ṣe àwọn ìyípadà náà àti bí ó ṣe lọ jìnnà tó fi hàn kedere pé agbára ìdarí kan tí ó ré kọjá ti ènìyàn èyíkéyìí tàbí ti ètò àjọ ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí ni ó wà lẹ́yìn rẹ̀—bẹ́ẹ̀ ni, agbára ìdarí olórí elénìní Jèhófà, Sátánì Èṣù. Ní jíjuwọ́ sílẹ̀ fún agbára ìdarí náà, àwọn olùtumọ̀ àti àwọn adàwékọ—àwọn kan hára gàgà, àwọn mìíràn sì lọ́ tìkọ̀—bẹ̀rẹ̀ sí í yọ orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Jèhófà, kúrò ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ibi tí ó ti fara hàn nínú Ọ̀rọ̀ tí ó mí sí. Ní ìjímìjí, àwọn ìtumọ̀ kan tí a tú láti èdè Hébérù sí èdè Gíríìkì, Látìn, German, Gẹ̀ẹ́sì, Italian, àti Dutch, àti ọ̀pọ̀ míràn, yọ orúkọ àtọ̀runwá náà kúrò pátápátá tàbí kí wọ́n fi í sílẹ̀ sí àwọn ibi mélòó kan. Wọ́n tún yọ ọ́ kúrò pátápátá nínú àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

13. Èé ṣe ti ìsapá láti yí Bíbélì pa dà tí ó gbalé gbòde kò fi yọrí sí pípa orúkọ Ọlọ́run rẹ́ kúrò nínú ọpọlọ ẹ̀dá ènìyàn?

13 Síbẹ̀, orúkọ ológo náà kò parẹ́ kúrò nínú ọpọlọ ẹ̀dá ènìyàn. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí a tú sí èdè Spanish, Potogí, German, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, àti ọ̀pọ̀ èdè míràn lo orúkọ Ọlọ́run gan-an láìṣàbòsí. Nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, orúkọ Ọlọ́run gan-an ti bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn nínú onírúurú ìtumọ̀ èdè Hébérù ti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì; nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún kejìdínlógún, ó ti fara hàn ní èdè German; nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ó ti fara hàn ní èdè Croatian àti Gẹ̀ẹ́sì. Bí àwọn ènìyàn tilẹ̀ gbìyànjú láti fọwọ́ rọ́ orúkọ Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, nígbà tí “ọjọ́ Jèhófà” bá dé, nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti polongo, ‘àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’ Ète tí Ọlọ́run polongo yẹn kò ní tàsé.—Pétérù Kejì 3:10; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:23, NW; Aísáyà 11:9; 55:11.

Ìhìn Iṣẹ́ Tàn Dé Gbogbo Ayé

14. (a) Nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún ogún, èdè mélòó nínú èdè tí a ń sọ ní Europe ni a ti fi tẹ Bíbélì jáde, ipa wo sì ni ó ní? (b) Nígbà tí yóò fi di òpin ọdún 1914, èdè Áfíríkà mélòó ni a ti fi tẹ Bíbélì jáde?

14 Nígbà tí ọ̀yẹ̀ ọ̀rúndún ogún yóò fi là, a ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Bíbélì jáde ní èdè 94 nínú èdè tí a ń sọ ní Europe. Ó mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìhà yẹn nínú ayé mọ òtítọ́ náà pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò mi ayé jìgìjìgì yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí Àkókò Àwọn Kèfèrí bá dópin ní ọdún 1914, wọ́n sì ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́! (Lúùkù 21:24) Kí ọdún mánigbàgbé náà, 1914, tó parí, a ti tẹ Bíbélì jáde, yálà lódindi tàbí àwọn mélòó kan nínú ìwé rẹ̀, ní 157 èdè Áfíríkà, ní àfikún sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, àti Potogí tí a ń lò níbi púpọ̀. Nípa báyìí, a fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fun kíkọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀yà àti àwùjọ orílẹ̀-èdè tí ń gbé níbẹ̀ ní àwọn òtítọ́ Bíbélì tí ń sọni dòmìnira nípa tẹ̀mí.

15. Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ṣe bẹ̀rẹ̀, báwo ni Bíbélì ṣe wà lárọ̀ọ́wọ́tó tó ní èdè àwọn ilẹ̀ America?

15 Bí ayé ṣe ń wọnú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí a sọ tẹ́lẹ̀, Bíbélì túbọ̀ ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àwọn ilẹ̀ America. Àwọn aṣíwọ̀lú láti Europe ni ó mú wọn wá ní onírúurú èdè wọn. Ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tí ó jinlẹ̀ ń lọ lọ́wọ́, pẹ̀lú àsọyé fún gbogbo ènìyàn àti pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kiri lọ́nà gbígbòòrò, tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà náà, tẹ̀ jáde. Ní àfikún sí i, àwọn ẹgbẹ́ atúmọ̀ Bíbélì tẹ Bíbélì jáde ní àwọn èdè 57 mìíràn láti kúnjú àìní àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tí ń gbé ní apá Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé.

16, 17. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe wà lárọ̀ọ́wọ́tó tó nígbà tí àkókò dé fún ìwàásù kárí ayé? (b) Báwo ni a ṣe jẹ́rìí sí i ní tòótọ́ pé Bíbélì dúró láéláé, pé ó sì jẹ́ ìwé tí ń nípa lórí ẹni?

16 Nígbà tí àkókò dé fún wíwàásù ìhìn rere náà kárí ayé ṣáájú kí ‘òpin tó dé,’ Bíbélì kì í ṣe ohun tuntun mọ́ fún Éṣíà àti àwọn erékùṣù Pásífíìkì. (Mátíù 24:14) A ti tẹ̀ ẹ́ jáde ní 232 èdè tí a mọ̀ mọ apá ayé yẹn. Àwọn kan jẹ́ odindi Bíbélì; ọ̀pọ̀ jẹ́ ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì; àwọn mìíràn sì jẹ́ ẹyọ ìwé kan ṣoṣo nínú Ìwé Mímọ́ Ọlọ́wọ̀.

17 Ó ṣe kedere pé, Bíbélì kò dúró láéláé gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣẹ̀ǹbáyé lásán. Nínú gbogbo ìwé tí ń bẹ, òun ni ìwé tí a tí ì túmọ̀ lọ́nà gbígbòòrò jù lọ, tí a sì tí ì pín kiri jù lọ. Ní ṣíṣe déédéé pẹ̀lú ẹ̀rí ojú rere àtọ̀runwá yẹn, ohun tí a kọ sílẹ̀ nínú ìwé náà ń nímùúṣẹ. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti ẹ̀mí tí ó mí sí i pẹ̀lú ń ní ipa pípẹ́ títí lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀. (Pétérù Kíní 1:24, 25) Ṣùgbọ́n ó kù ni ìbọn ń ró—ohun púpọ̀ ṣì ń bẹ níwájú.

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Kí ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tí ó dúró láéláé?

◻ Ìgbìdánwò wo ni a ti ṣe láti tẹ Bíbélì rì, kí sì ni ó yọrí sí?

◻ Báwo ni a ti ṣe dáàbò bo ìpéye Bíbélì?

◻ Báwo ni gbólóhùn Ọlọ́run nípa ète rẹ̀ ṣe jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń bẹ láàyè?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

A Ha Mọ Ohun Tí Bíbélì Sọ Ní Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ní Tòótọ́ Bí?

Nǹkan bí 6,000 ìwé àfọwọ́kọ ti èdè Hébérù jẹ́rìí sí ohun tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Díẹ̀ lára ìwọ̀nyí ti wà ṣáájú sànmánì àwọn Kristẹni. Ó kéré tán, 19 nínú àwọn odindi Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí a fọwọ́ kọ, tí kò sọ nù, ti wà ṣáájú ìhùmọ̀ fífi ẹ̀rọ ọlọ́rọ̀ títò tẹ̀wé. Ní àfikún sí i, láti àkókò kan náà yẹn, àwọn ìtumọ̀ ń bẹ tí a tú sí èdè 28 míràn.

Ní ti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, nǹkan bí 5,000 ìwé àfọwọ́kọ ti èdè Gíríìkì ni a ti tò jọ. Ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ti wà ṣáájú ọdún 125 Sànmánì Tiwa, ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ lẹ́yìn àkókò tí a kọ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àwọn àjákù kan sì ń bẹ tí a rò pé wọ́n ti wà fún ìgbà pípẹ́ ṣáájú àkókò yẹn. Odindi ìwé àfọwọ́kọ ọlọ́rọ̀ gàdàgbà gàdàgbà 10 sí 19 ń bẹ, tí ó wà fún 22 nínú ìwé 27 tí a mí sí. Ní apá yìí nínú Bíbélì, ìwé tí ó ní odindi ọlọ́rọ̀ gàdàgbà gàdàgbà tí ó kéré jù lọ ló ní mẹ́ta—ìyẹn ni Ìṣípayá. Ìwé àfọwọ́kọ kan ti odindi Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti wà láti ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa.

Kò sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìṣẹ̀ǹbáyé mìíràn tí ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀rí alákọsílẹ̀ tó bẹ́ẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́