Ónẹ́sífórù—Olùtùnú Tí Kì Í Ṣojo
“Ẹ MÁA fi àwọn wọnnì tí ń bẹ nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n sọ́kàn bí ẹni pé a ti dè yín pẹ̀lú wọn, àti àwọn wọnnì tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́.” (Hébérù 13:3) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Tiwa, a ti ju òun fúnra rẹ̀ sẹ́wọ̀n ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i ṣáájú kí ó tó kú ikú ajẹ́rìíkú rẹ̀. (Ìṣe 16:23, 24; 22:24; 23:35; 24:27; Kọ́ríńtì Kejì 6:5; Tímótì Kejì 2:9; Fílémónì 1) Ó jẹ́ kánjúkánjú nígbà náà, bí ó ṣe jẹ́ lónìí pé, kí àwọn ìjọ máa bójú tó àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí ń fojú winá àdánwò ìgbàgbọ́.
Ọmọ ẹ̀yìn kan ní ọ̀rúndún kìíní tí ó kọbi ara sí àìní náà ní pàtàkì ni Ónẹ́sífórù. Ó bẹ Pọ́ọ̀lù wò nígbà tí a fi í sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì ní Róòmù. Àpọ́sítélì náà kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Kí Olúwa yọ̀ǹda àánú fún agbo ilé Ónẹ́sífórù, nítorí pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni òun ti mú ìtura wá fún mi, òun kò sì tijú àwọn ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó ṣẹlẹ̀ pé ó wà ní Róòmù, ó fi taápọntaápọn wá mi ó sì rí mi.” (Tímótì Kejì 1:16, 17) O ha ti fìgbà kankan sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ wọnnì túmọ̀ sí ní gidi bí? Ó ṣeé ṣe kí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ mú kí a túbọ̀ mọyì Ónẹ́sífórù. Ìwọ yóò rí i pé olùtùnú tí kì í ṣojo ni.
Ìgbà Kejì Tí A Fi Pọ́ọ̀lù Sẹ́wọ̀n
Lẹ́yìn tí a dá a sílẹ̀ kúrò ní ẹ̀wọ̀n àkọ́kọ́ tí a rán an lọ, Pọ́ọ̀lù tún ti wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Róòmù ṣùgbọ́n lábẹ́ ipò tí ó yàtọ̀. Lọ́jọ́sí, àwọn ọ̀rẹ́ lè bẹ̀ ẹ́ wò nínú ilé tí ó háyà, ó sì dà bíi pé ó dá a lójú pé a kò ní pẹ́ tú òun sílẹ̀. Wàyí o, ọ̀pọ̀ jù lọ ti pa á tì, ikú ajẹ́rìíkú sì ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀.—Ìṣe 28:30; Tímótì Kejì 4:6-8, 16; Fílémónì 22.
Ní àkókò yí, ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ní nǹkan bí ọdún kan ṣáájú—ní July ọdún 64 Sànmánì Tiwa—iná jó Róòmù, ó sì ba 10 nínú ìlú 14 tí ó wà ní ẹkùn náà jẹ́ gan-an. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Róòmù náà, Tacitus, ti sọ, kò ṣeé ṣe fún Olú Ọba Nero láti “bo èrò adárúgúdùsílẹ̀ náà mọ́lẹ̀ pé àṣẹ tí òun pa ni ó fa iná náà. Nítorí náà, láti mú èrò yí kúrò, Nero di ẹ̀bi rẹ̀ ru àwùjọ tí a ń pè ní Kristẹni, tí a kórìíra nítorí ìwà ìríra wọn, ó sì mú kí a dá wọn lóró lọ́nà gíga. . . . A pa wọ́n lọ́nà tí ó tini lójú. Ní fífi awọ ẹranko bò wọ́n lára, ajá fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, wọ́n sì ṣègbé, a kàn wọ́n mọ́ àgbélébùú, a dáná sun wọn, kí wọ́n lè pèsè ìmọ́lẹ̀ lálẹ́, nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú.”
Irú ipò yí àti àwọn ipò míràn bẹ́ẹ̀ tí ó ṣeé ṣe kí ó wáyé ni Pọ́ọ̀lù tún bá ara rẹ̀ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Abájọ tí ó fi kún fún ìmoore fún ìbẹ̀wò ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ónẹ́sífórù gidigidi! Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ kí a wo ipò kan náà yẹn gẹ́gẹ́ bí Ónẹ́sífórù ṣe wò ó.
Ṣíṣèbẹ̀wò Sọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù Tí Ó Jẹ́ Ẹlẹ́wọ̀n
Ó hàn gbangba pé, Éfésù ni ìdílé Ónẹ́sífórù ń gbé. (Tímótì Kejì 1:18; 4:19) A kò lè sọ bóyá iṣẹ́ ti ara rẹ̀ ni Ónẹ́sífórù bá wá sí olú ìlú ilẹ̀ ọba náà tàbí ó wá bẹ Pọ́ọ̀lù wò pàtó. Bí ó ti wù kí ó rí, àpọ́sítélì náà sọ pé: ‘Nígbà tí Ónẹ́sífórù wà ní Róòmù, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó máa ń mú ìtura wá fún mi.’ (Tímótì Kejì 1:16, 17) Irú ìtura wo? Bí ìrànwọ́ tí Ónẹ́sífórù pèsè tilẹ̀ ti lè ní ohun ti ara nínú, ó hàn gbangba pé wíwà tí ó wà níbẹ̀ tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ohun amúnilóríyá láti pèsè okun àti ìṣírí fún Pọ́ọ̀lù. Ní tòótọ́, àwọn ìtumọ̀ kan kà pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó mú ara mi yá gágá,” tàbí “ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó ti tù mí nínú.”
Mímú ìfẹ́ ọkàn ṣẹ láti ṣèbẹ̀wò sí Kristẹni kan tí ó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n ní Róòmù nígbà náà gbé ọ̀pọ̀ ìṣòro kalẹ̀. Láìdàbí ìgbà tí a kọ́kọ́ fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n lọ́jọ́sí, ó hàn gbangba pé àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Róòmù kò ní àǹfààní láti kàn sí i mọ́. Nínú ìlú ńlá bíi Róòmù, kò rọrùn láti rí ẹlẹ́wọ̀n kan tí kì í ṣe olókìkí láàárín ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tí a fi sẹ́wọ̀n fún onírúurú ẹ̀sùn. Nítorí náà, fífi aápọn wá a kiri pọn dandan. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Giovanni Rostagno, ṣàpèjúwe ọ̀ràn náà lọ́nà yí: “Ìṣòro náà lè jẹ́ onírúurú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìwákiri náà ń béèrè ìṣọ́ra gidigidi. Gbígba ìsọfúnni níhìn-ín lọ́hùn-ún àti ṣíṣe bí ẹni tí ń ṣàníyàn láti rí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí a fi àgbàlagbà ẹlẹ́wọ̀n kan tí ó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn tí ó ti lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn tí kò lóǹkà sí, ti lè ru ìfura tí kò nídìí sókè.”
Òǹkọ̀wé P. N. Harrison ṣàpèjúwe ipò kan náà lọ́nà tí ó ṣe kedere, ní sísọ pé: “Ó jọ bí ẹni pé a lè kófìrí ẹnì kan tí ń rìn bí ẹni tí ń wá ẹnì kan láàárín èrò tí ń wọ́ gìrọ́gìrọ́, a sì lè máa fi ọkàn ìfẹ́ jíjinlẹ̀ bá àjèjì tí ó ti etíkun Aegean wá yìí lọ, bí ó ṣe ń gba ojú pópó tí kò dé rí lọ, tí ó ń kan ọ̀pọ̀ ilẹ̀kùn, tí ń tẹ̀ lé gbogbo ìjúwe, ẹni tí a ti kìlọ̀ fún nípa ohun eléwu tí ó dáwọ́ lé ṣùgbọ́n tí a kò lè yí ìpinnu rẹ̀ pa dà; títí tí ẹnì kan fi kí i láti inú ilé ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí ó wà ní kọ̀rọ̀, tí ó sì wá rí i pé Pọ́ọ̀lù tí a fi ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n dè mọ́ sójà Róòmù kan ni onítọ̀hún.” Bí ibẹ̀ bá tilẹ̀ jọ ọgbà ẹ̀wọ̀n Róòmù yòó kù rárá, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ibi tí ó tutù rinrin, tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì dọ̀tí, ibi tí ọ̀pọ̀ ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n àti onírúurú ìpọ́njú wà.
Ó léwu púpọ̀ láti mọ ẹnì kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ ẹlẹ́wọ̀n kan bíi Pọ́ọ̀lù. Ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ wá léwu jù. Láti fi ara ẹni hàn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni jẹ́ fífi ara ẹni wewu ìfàṣẹ-ọba-múni àti ikú ìdálóró. Ṣùgbọ́n ṣíṣe ìbẹ̀wò lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀méjì kò tẹ́ Ónẹ́sífórù lọ́rùn. Kò tì í lójú, bẹ́ẹ̀ sì ni kò bà á lẹ́rù láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní “ọ̀pọ̀ ìgbà.” Ní tòótọ́, Ónẹ́sífórù hùwà ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀, “Olùmú Èrè Wá,” ní fífi àìṣojo àti ìfẹ́ pèsè ìrànwọ́ láìka ewu sí.
Èé ṣe tí Ónẹ́sífórù fi ṣe gbogbo èyí? Brian Rapske sọ pé: “Ọgbà ẹ̀wọ̀n kì í ṣe ibi ìjìyà nípa ti ara nìkan, àmọ́ ó jẹ́ ibi àníyàn ńláǹlà nítorí másùnmáwo tí ó ń mú bá ẹlẹ́wọ̀n. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, wíwà tí àwọn olùṣèrànwọ́ wà nítòsí àti ọ̀rọ̀ ìṣírí wọn lè pèsè ìrànwọ́ gígadabú ní ti èrò ìmọ̀lára fún ẹlẹ́wọ̀n náà.” Ó hàn gbangba pé Ónẹ́sífórù mọ ìyẹn, ó sì fi àìṣojo dúró gbágbágbá ti ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ẹ wo bí Pọ́ọ̀lù yóò ti mọrírì irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ tó!
Kí Ni Ó Ṣẹlẹ̀ sí Ónẹ́sífórù?
Nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Tímótì, Pọ́ọ̀lù fi ìkíni ránṣẹ́ sí agboolé Ónẹ́sífórù, ó sì sọ nípa rẹ̀ pé: “Kí Olúwa yọ̀ǹda fún un láti rí àánú láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní ọjọ́ yẹn.” (Tímótì Kejì 1:18; 4:19) Ọ̀pọ̀ rò pé ọ̀rọ̀ náà, “ní ọjọ́ yẹn,” ń tọ́ka sí ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ parí èrò sí pé Ónẹ́sífórù ti kú. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn rí, P. N. Harrison sọ pé, ó ti lè jẹ́ pé “Ónẹ́sífórù ti lọ sí àgbègbè eléwu yìí lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ti fi . . . ìwàláàyè rẹ̀ dí i.” Àmọ́ ṣáá o, ó wulẹ̀ lè jẹ́ pé Ónẹ́sífórù lọ sí ìrìn àjò nígbà náà, tàbí kí ó jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù fi ìkíni tirẹ̀ kún èyí tí ó fi ránṣẹ́ sí gbogbo agboolé rẹ̀.
Àwọn kan gbà gbọ́ pé ìjẹ́pàtàkì ńláǹlà wà nínú gbólóhùn yí: “Kí Olúwa yọ̀ǹda fún un láti rí àánú láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní ọjọ́ yẹn.” Wọ́n rò pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé àdúrà tí a ń gbà fún àwọn ọkàn tí ó ti dolóògbé, tàbí tí wọ́n ń jìyà ní ilẹ̀ ọba ẹ̀mí tọ̀nà. Ṣùgbọ́n, irú èrò bẹ́ẹ̀ forí gbárí pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun. (Oníwàásù 9:5, 10) Àní bí Ónẹ́sífórù bá tilẹ̀ ti kú pàápàá, ṣe ni Pọ́ọ̀lù wulẹ̀ ń sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde pé kí ọ̀rẹ́ òun rí àánú Ọlọ́run. R. F. Horton sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ni a lè sọ irú ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀ jáde fún. Ṣùgbọ́n láti gbàdúrà fún àwọn òkú, àti láti ṣe ààtò ìsìn Máàsì fún wọn, jẹ́ èrò tí kò sí lọ́kàn [àpọ́sítélì] náà rárá.”
Ẹ Jẹ́ Kí A Jẹ́ Adúróṣinṣin Olùtùnú
Bóyá Ónẹ́sífórù pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣèrànwọ́ fún Pọ́ọ̀lù tàbí kò pàdánù rẹ̀, ó dájú pé ó fi wewu kí ó baà lè rí àpọ́sítélì náà, kí ó sì lè bẹ̀ ẹ́ wò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Kò sì sí iyè méjì kankan pé Pọ́ọ̀lù mọrírì ìrànwọ́ àti ìṣírí tí ó nílò gidigidi, tí ó rí gbà láti ọ̀dọ̀ Ónẹ́sífórù.
Nígbà tí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa bá dojú kọ àdánwò, inúnibíni, tàbí tí a bá fi wọ́n sẹ́wọ̀n, a lè wà ní ipò tí a ti lè tù wọ́n nínú, kí a sì fún wọn níṣìírí. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kí a máa gbàdúrà fún wọn, kí a sì máa fi ìfẹ́ ṣe ohun gbogbo tí a bá lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Jòhánù 13:35; Tẹsalóníkà Kíní 5:25) Bí Ónẹ́sífórù, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ olùtùnú tí kì í ṣojo.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ónẹ́sífórù tu àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí a fi sẹ́wọ̀n nínú láìṣojo